Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Tí Ìmọ́tótó Fi Ṣe Pàtàkì?

Kí Nìdí Tí Ìmọ́tótó Fi Ṣe Pàtàkì?

Kí Nìdí Tí Ìmọ́tótó Fi Ṣe Pàtàkì?

Ọjọ́ pẹ́ tí àjàkálẹ̀ àrùn ti ń bá aráyé fínra. Àwọn kan ti parí èrò sí pé bóyá ni kì í ṣe pé Ọlọ́run ń lò ó láti fìyà jẹ àwọn èèyàn búburú. Ìwádìí táwọn kan fara balẹ̀ ṣe fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn ẹ̀dà kéékèèké tá ò kà sí láyìíká wa ni eku ẹdá tó ń dá ìṣòro ọ̀hún sílẹ̀.

Àwọn tó ń ṣèwádìí nípa ọ̀ràn ìlera ti rí i pé eku, aáyán, eṣinṣin àti ẹ̀fọn lè kó àìsàn ran èèyàn. Wọ́n tún ti kíyè sí i pé àwọn tó ya ọ̀bùn lè kó àìsàn ran àwọn ẹlòmíì. Nítorí náà, ó dájú pé ọ̀ràn ikú àti ìyè lọ̀rọ̀ ìmọ́tótó.

Ká sóòótọ́, ohun táwọn kan máa ṣe láti fi hàn pé àwọn mọ́ tónítóní kọ́ làwọn míì máa ṣe torí àṣà àti ipò wọn lè yàtọ̀ síra. Bí àpẹẹrẹ, ó lè ṣòro láti mọ́ tónítóní láwọn ibi tí kò ti sí omi ẹ̀rọ, tí kò sì sí ibi tí wọ́n lè máa da ìdọ̀tí sí. Síbẹ̀, Ọlọ́run fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ìgbàanì láwọn ìtọ́ni kan nípa ìmọ́tótó nígbà tí wọ́n ń rìnrìn àjò nínú aginjù, ọ̀pọ̀ ibi tí wọ́n sì ń dé nínú aginjù náà ló ti ń nira gan-an láti wà ní mímọ́ tónítóní.

Kí nìdí tí Ọlọ́run fi ka ìmọ́tótó sí pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Irú ojú wo ló yẹ káwa náà máa fi wo ìmọ́tótó? Kí làwọn nǹkan táwọn èèyàn lè má fi bẹ́ẹ̀ kà sí tíwọ àti ìdílé ẹ lè máa ṣe kẹ́ ẹ bàa lè dín àìsàn kù?

NÍGBÀ táwọn ọmọ iléèwé jáde lọ́jọ́ kan, Máyọ̀wá a tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù dorí kọlé. Ebi ti ń pa á, òǹgbẹ sì ti ń gbẹ ẹ́ nígbà tó máa fi délé, ó gbé ajá rẹ̀ mọ́ra, ó gbé báàgì rẹ̀ sórí tábìlì tí wọ́n ti máa ń jẹun, ó sì jókòó, bẹ́ẹ̀ lọ̀fun ẹ̀ ń dá tòló.

Inú yàrá ìdáná ni ìyá Máyọ̀wá wà nígbà tí Máyọ̀wá wọlé, bó sì ṣe gbúròó ọmọ ẹ̀ ló ti gbé ìrẹsì àtẹ̀wà tó ń gbóná fẹlifẹli wá fún un. Àmọ́ ojú ẹ̀ kọ́rẹ́ lọ́wọ́ nígbà tó rí i pé orí tábìlì tí wọ́n ti ń jẹun ni Máyọ̀wá gbé báàgì iléèwé ẹ̀ sí. Ó fojú bá a sọ̀rọ̀, ó sì pe orúkọ ẹ̀, ó ní: “Má-yọ̀-wááá!” Ọ̀rọ̀ náà ti yé Máyọ̀wá, kíá ló gbé báàgì ẹ̀ kúrò lórí tábìlì náà, tó sì sáré lọ fọwọ́ ẹ̀. Kò pẹ́ tó fi pa dà wọlé tó sì wá jókòó láti jẹ oúnjẹ tí ọ̀nà ọ̀fun ẹ̀ ti ń torí ẹ̀ dá tòló. Máyọ̀wá mọ̀ pé òun ti jẹ̀bi, ló bá rọra sọ pé: “Ẹ máà bínú màámi, mo ti gbàgbé ni.”

Àwọn ìyá tó mọṣẹ́ wọn níṣẹ́ máa ń forí ṣe fọrùn ṣe láti rí i pé ìdílé wọn ní ìlera tó jí pépé kí ilé wọn sì wà ní mímọ́ tónítóní, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n nílò ìrànlọ́wọ́ bàbá àtàwọn ọmọ. Bá a ṣe rí i nínú ọ̀rọ̀ Máyọ̀wá, ó ṣe pàtàkì pé káwọn òbí tètè bẹ̀rẹ̀ sí í fọ̀rọ̀ ìmọ́tótó kọ́ àwọn ọmọ wọn, torí ìmọ́tótó ilé kì í ṣe iṣẹ́ kékeré rárá, wọ́n sì ní láti máa rán àwọn ọmọ wọn létí léraléra.

Ìyá Máyọ̀wá mọ̀ pé oríṣiríṣi ọ̀nà ni kòkòrò àrùn lè gbà wọnú oúnjẹ. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé yàtọ̀ sí pé ó máa ń fọwọ́ ẹ̀ dáadáa kó tó fọwọ́ kan oúnjẹ, ó tún máa ń bo oúnjẹ kí eṣinṣin má bàa bà lé e. Torí pé ó máa ń tọ́jú oúnjẹ dáadáa tó sì máa ń túnlé ṣe, eku àti aáyán kì í fi bẹ́ẹ̀ ríbi sá sí nínú ilé.

Ìdí pàtàkì kan tí ìyá Máyọ̀wá fi ń ṣe gbogbo èyí ni pé ó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn. Ó ṣàlàyé pé: “Bíbélì sọ pé àwọn èèyàn Ọlọ́run gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́ torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́.” (1 Pétérù 1:16) Ó tún sọ pé: “Ọmọ ìyá ni jíjẹ́ mímọ́ àti ìmọ́tótó. Torí náà, mo fẹ́ kí ilé mi máa wà ní mímọ́, káwọn aráalé mi sì dùn ún wò. Àmọ́ ká sòótọ́, bí gbogbo àwọn aráalé mi ṣe ń ràn mí lọ́wọ́ ló jẹ́ kéyìí ṣeé ṣe.”

Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ Àwọn Aráalé Ṣe Pàtàkì

Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìyá Máyọ̀wá kíyè sí, gbogbo aráalé ló yẹ kí wọ́n jọ máa rí sí ọ̀rọ̀ ìmọ́tótó ilé. Àwọn ìdílé kan máa ń ṣèpàdé látìgbàdégbà kí wọ́n lè jíròrò àwọn ohun tí wọ́n nílò àtàwọn nǹkan tí wọ́n ní láti ṣiṣẹ́ lé lórí nínú ilé àti láyìíká ilé. Èyí tún máa ń jẹ́ kí ìdílé wà níṣọ̀kan, ó sì máa ń jẹ́ kí kálukú rántí iṣẹ́ tí wọ́n yàn fóun nínú ilé. Bí àpẹẹrẹ, ìyá lè jẹ́ káwọn ọmọ tó ti dàgbà mọ ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa fọwọ́ lẹ́yìn tí wọ́n bá dé láti ilé ìyàgbẹ́, tí wọ́n bá fọwọ́ kan àwọn nǹkan bí owó àti kí wọ́n tó jẹun. Àwọn ọmọ tó ti dàgbà yìí ló máa wá rí sí i pé àwọn àbúrò àwọn fọwọ́ pàtàkì mú ọ̀ràn náà.

Àwọn aráalé lè pín iṣẹ́ ilé láàárín ara wọn. Wọ́n lè pinnu láti máa rí i pé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ làwọn ń ṣe ìmọ́tótó ilé, kí wọ́n sì ṣètò láti máa tún gbogbo kọ́lọ́fín ilé ṣe lẹ́ẹ̀kan tàbí ẹ̀ẹ̀mejì lọ́dún. Àyíká ilé ńkọ́? Ọ̀gbẹ́ni Stewart L. Udall tó nífẹ̀ẹ́ sọ́ràn àyíká tó dùn-ún wò, sọ nípa orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà pé: “À ń gbé nílẹ̀ tí ẹwà rẹ̀ ti ń ṣá, tó sì túbọ̀ ń burẹ́wà sí i, kò sí ilẹ̀ gbalasa bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ mọ́, ariwo ò jẹ́ káwọn èèyàn gbádùn, èéfín sì ń ba gbogbo àyíká jẹ́ lójoojúmọ́.”

Ṣóhun tíwọ náà ń rò nípa àyíká yín nìyẹn? Láyé àtijọ́, àwọn akígbe ìlú máa ń laago káwọn èèyàn lè gbọ́rọ̀ wọn, kódà ó ṣì ń ṣẹlẹ̀ títí dòní láwọn àgbègbè kan lórílẹ̀-èdè Central Africa. Wọ́n máa ń sọ̀rọ̀ ketekete láti rán àwọn èèyàn létí pé kí wọ́n tún ìlú ṣe, kí wọ́n kó gọ́tà, kí wọ́n gé ọwọ́ àwọn igi, kí wọ́n ro oko àyíká, kí wọ́n sì da ìdọ̀tí nù.

Ìṣòro tó kárí ayé lọ̀rọ̀ dída ìdọ̀tí nù, ìjọba sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máà rí ojútùú sí ìṣòro yìí. Àwọn tó yẹ kó wá kó ìdọ̀tí lè má tètè wá kó o, ìyẹn sì lè wá di òkìtì àkìtàn sáàárín ìlú. Wọ́n lè pe àwọn aráàlú pé kí wọ́n tún ibẹ̀ ṣe. Gẹ́gẹ́ bí ọmọ ìlú rere, àwọn Kristẹni máa ń wà lára àwọn tó máa ń kọ́kọ́ gbà láti ṣe irú iṣẹ́ yìí torí pé wọ́n máa ń fara mọ́ òfin Késárì láìṣàwáwí. (Róòmù 13:3, 5-7) Àwọn Kristẹni tòótọ́ máa ń fẹ́ láti ṣe gbogbo ohun tí wọ́n bá lè ṣe láti ṣèrànlọ́wọ́. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí àdúgbò tó mọ́ tónítóní, kò sì dìgbà tí akígbe ìlú bá rán wọn létí kí wọ́n tó tọ́jú àdúgbò wọn. Wọ́n mọ̀ pé ìmọ́tótó jẹ́ àmì pé èèyàn gbẹ̀kọ́ tó dáa, ó sì níwà ọmọlúwàbí. Ilé sì la ti ń kẹ́ṣọ̀ọ́ ròde. Tá a bá ń jẹ́ kí àyíká wa mọ́ tónítóní tá a sì ń ṣèmọ́tótó ilé, ìyẹn á jẹ́ ká ní ìlera tó dáa, àdúgbò tá à ń gbé á sì dùn-ún wò.

Ìmọ́tótó Ara Máa Ń Bọlá fún Ọlọ́run Tá À Ń Sìn

Ìmọ́tótó ara àti ìrísí wa tó bójú mu jẹ́ ara ìjọsìn wa, èyí sì máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé a yàtọ̀ léèyàn. Àwọn ọ̀dọ́kùnrin àtàwọn ọ̀dọ́bìnrin bíi mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] wọ ilé oúnjẹ kan lẹ́yìn tí wọ́n parí àpéjọ àgbègbè àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tí wọ́n ṣe nílùú Toulouse, lórílẹ̀-èdè Faransé. Àwọn tọkọtaya àgbàlagbà kan tí wọ́n jókòó sí tábìlì tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn ń retí pé wọ́n máa bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo, wọ́n sì máa da ilé oúnjẹ náà rú. Àmọ́, báwọn ọ̀dọ́ tó múra lọ́nà tó bójú mu yìí ṣe ṣe nǹkan létòlétò tí wọn ò sì pariwo wú tọkọtaya náà lórí gan-an. Nígbà táwọn ọ̀dọ́ náà fẹ́ máa lọ, tọkọtaya náà gbóríyìn fún wọn fún ìwà ọmọlúwàbí tí wọ́n hù, wọ́n sì sọ fún ọ̀kan lára àwọn ọ̀dọ́ náà pé irú ìwà bẹ́ẹ̀ ṣọ̀wọ́n lóde òní.

Ẹnu sábà máa ń ya àwọn tó máa ń wá ṣèbẹ̀wò sáwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì, àwọn ilé ìtẹ̀wé àtàwọn ilé gbígbé tó wà láwọn ẹ̀ka ọ́fíìsì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà torí bí wọ́n ṣe máa ń rí i tibẹ̀ máa ń wà ní mímọ́ tónítóní. Ara àwọn ohun tí wọ́n ń retí lọ́wọ́ àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa ṣiṣẹ́ tí wọ́n sì ń gbé láwọn ibi tá a mẹ́nu kàn yìí ni pé kí wọ́n máa fọ aṣọ wọn, kí wọ́n sì máa wẹ̀ déédéé. Àwọn òórùn dídùn tó máa ń bo àágùn mọ́lẹ̀ àti lọ́fínńdà ò lè gbapò ìmọ́tótó ara. Báwọn tó yọ̀ǹda ara wọn, tí wọ́n sì ń fi gbogbo àkókò wọn ṣiṣẹ́ Ọlọ́run yìí ṣe máa ń mọ́ tónítóní nígbà tí wọ́n bá ń wàásù fáwọn aládùúgbò wọn nírọ̀lẹ́ àti lópin ọ̀sẹ̀ tún máa ń buyì kún iṣẹ́ ìwàásù tí wọ́n ń ṣe.

“Ẹ Di Aláfarawé Ọlọ́run”

Bíbélì rọ àwọn Kristẹni pé kí wọ́n “di aláfarawé Ọlọ́run.” (Éfésù 5:1) Wòlíì Aísáyà ṣàkọsílẹ̀ ìran kan níbi tó ti ráwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ń ṣàpèjúwe Ẹlẹ́dàá pẹ̀lú àwọn ọ̀rọ̀ yìí: “Mímọ́, mímọ́, mímọ́.” (Aísáyà 6:3) Àpèjúwe yìí jẹ́ kó hàn kedere pé ìmọ́tótó Ọlọ́run ò láfiwé. Abájọ tí Ọlọ́run ṣe fẹ́ kí gbogbo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ jẹ́ mímọ́, kí wọ́n sì mọ́ tónítóní. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ mímọ́, nítorí pé èmi jẹ́ mímọ́.”—1 Pétérù 1:16.

Bíbélì gba àwọn Kristẹni níyànjú láti “wọ aṣọ bí ó ti yẹ.” (1 Tímótì 2:9, Ìròhìn Ayọ̀) Abájọ tó fi jẹ́ pé nínú ìwé Ìṣípayá, ‘aṣọ ọ̀gbọ̀ àtàtà, títànyòyò, mímọ́’ ló dúró fún ìwà òdodo táwọn tí Ọlọ́run kà sí ẹni mímọ́ ń hù. (Ìṣípayá 19:8) Yàtọ̀ síyẹn, èérí tàbí ìdọ̀tí ni Ìwé Mímọ́ sábà máa fi ń ṣàpèjúwe ẹ̀ṣẹ̀.—Òwe 15:26; Aísáyà 1:16; Jákọ́bù 1:27.

Lóde òní, àìmọye àwọn èèyàn ló ń gbé láwọn àgbègbè tí kò ti rọrùn láti jẹ́ kí ìrísí wọn, ìwà wọn àti ìjọsìn wọn wà ní mímọ́. Ó dìgbà tí Ọlọ́run bá “sọ ohun gbogbo di tuntun,” kí ọ̀ràn tó wà ńlẹ̀ yìí tó yanjú pátápátá. (Ìṣípayá 21:5) Nígbà tí ìlérí yẹn bá nímùúṣẹ, ìdọ̀tí àti gbogbo onírúurú àìmọ máa dàwátì títí láé.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Orúkọ rẹ̀ gan-an kọ́ nìyí.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 10]

Ọlọ́run Fẹ́ Ká Mọ́ Tónítóní

Nígbà táwọn ọmọ Ísírẹ́lì wà nínú aginjù, Ọlọ́run fún wọn nítọ̀ọ́ni tí wọ́n gbọ́dọ̀ máa tẹ̀ lé tí wọ́n bá fẹ́ yàgbẹ́. (Diutarónómì 23:12-14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn fún wọn láti tẹ̀ lé àwọn òfin yìí torí pé ibùdó náà tóbi, àmọ́ ó dájú pé èyí ràn wọ́n lọ́wọ́ láti dènà àwọn àrùn bí ibà táífọ́ọ̀dù àti kọ́lẹ́rà.

Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn èèyàn náà pé kí wọ́n fọ ohunkóhun tó bá ti fara kan òkú èyíkéyìí tàbí kí wọ́n kúkú má lò ó mọ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lè máà lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fún wọn lófin yìí, síbẹ̀ ó ràn wọ́n lọ́wọ́ láti bọ́ lọ́wọ́ àwọn àrùn tó ń ranni.—Léfítíkù 11:32-38.

Àwọn àlùfáà gbọ́dọ̀ fọ ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn kí wọ́n tó bójú tó ojúṣe wọn nínú àgọ́ ìjọsìn. Ó lè má rọrùn láti máa pọnmi kúnnú bàsíà bàbà tí wọ́n máa fi ń fọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, síbẹ̀ wọn ò gbọ́dọ̀ kọtí ikún sófin yìí.—Ẹ́kísódù 30:17-21.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 11]

Àwọn Ohun Tí Dókítà Kan Rán Wa Létí

Omi ṣe pàtàkì láyé ẹ̀dá, àmọ́ omi tí kò dáa lè fa àìsàn séèyàn lára, ó sì lè pààyàn. Nínú ìfọ̀rọ̀wánilẹ́nuwò kan, Dókítà J. Mbangue Lobe tó jẹ́ ọ̀gá àgbà ní ẹ̀ka ìtọ́jú ìṣègùn tó wà ní èbúté Douala, lórílẹ̀-èdè Kamẹrúùnù, sọ àwọn àbá mélòó kan tó máa wúlò fún wa.

“Máa se omi tó o bá fẹ́ mu, tí kò bá dá ẹ lójú bóyá omi tó o pọn mọ́.” Àmọ́ ó kìlọ̀ pé: “Kò sóhun tó burú téèyàn bá lo àwọn kẹ́míkà láti sọ omi di mímọ́, àmọ́ ó léwu béèyàn ò bá lò ó bó ṣe yẹ. Máa fi ọṣẹ fọwọ́ kó o tó jẹun àti lẹ́yìn tó o bá jáde nílé ìyàgbẹ́. Ọṣẹ ò kúkú wọ́n, àwọn tálákà pàápàá ò lè sọ pé àwọn ò lówó ọṣẹ. Máa fọ aṣọ rẹ déédéé, omi tó gbóná ni kó o sì máa lò tó o bá ní kòkòrò tàbí àrùn lára.”

Dókítà náà tún sọ pé: “Gbogbo aráalé ló gbọ́dọ̀ máa rí sí i pé inú ilé àti àyíká rẹ̀ wà ní mímọ́ tónítóní. Àwọn èèyàn kì í sábà bójú tó ilé ìyàgbẹ́ àti yàrá ìkẹ́rùsí, ìdí sì nìyẹn tí aáyán àti ẹ̀fọn fi máa ń fibẹ̀ ṣelé.” Ó wá fi ohun pàtàkì kan tó kíyè sí nípa àwọn ọmọdé kún ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó kìlọ̀ pé: “Ẹ ṣọ́ra fún lílúwẹ̀ẹ́ nínú àwọn odò kéékèèké tó wà ládùúgbò yín. Àwọn kòkòrò tó lè fa àrùn síni lára ló kúnnú wọn. Ẹ máa wẹ̀ lálẹ́ kẹ́ ẹ tó lọ sùn, kẹ́ ẹ fọnu dáadáa, abẹ́ nẹ́ẹ̀tì tí ò ní jẹ́ kí ẹ̀fọn jẹ yín ni kẹ́ ẹ sì máa sùn.” Àbálọ àbábọ̀ gbogbo ohun tí dókítà yìí sọ ni pé kó o ṣètò bí wàá ṣe máa jẹ́ kí gbogbo nǹkan rẹ wà ní mímọ́ tónítóní, kó o sì máa tẹ̀ lé ìṣètò yìí, ìyẹn ló máa gbà ẹ́ lọ́wọ́ ìṣòro tí ìwà ọ̀bùn máa ń fà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Wà á dènà àwọn kòkòrò ara àti àrùn tó o bá ń fọṣọ ẹdéédéé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Kò sẹ́ni tó máa ń kọ́ àwọn Kristẹni kí wọ́n tó máa bójú tó àyíká wọn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ìyá tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ gbọ́dọ̀ rí i dájú pé gbogbo aráalé ló mọ́ tónítóní