Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Ǹjẹ́ O Mọ̀?

Kí ni Jésù ì bá ti ṣe nídìí iṣẹ́ káfíńtà?

Káfíńtà ni Jósẹ́fù alágbàtọ́ Jésù. Iṣẹ́ yẹn náà sì ni Jésù kọ́. Nígbà tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní “nǹkan bí [ọmọ] ọgbọ̀n ọdún,” kì í ṣe pé àwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí “ọmọkùnrin káfíńtà náà” nìkan, àmọ́ wọ́n tún mọ̀ ọ́n sí akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nídìí iṣẹ́ yẹn.—Lúùkù 3:23; Mátíù 13:55; Máàkù 6:3.

Nílùú tí wọ́n ti bí Jésù, àwọn àgbẹ̀ máa ń nílò àwọn irinṣẹ́ tó máa múṣẹ́ yá lóko, irú bí ohun èlò ìtúlẹ̀ àti àjàgà, igi sì ni wọ́n sábà máa ń fi ṣe àwọn nǹkan wọ̀nyí. Lára àwọn nǹkan míì táwọn káfíńtà tún máa ń ṣe ni tábìlì, àga, àpótí ìjókòó, àpótí ẹrù, ilẹ̀kùn, fèrèsé, igi ìrólé àti àyígbè. Kódà, ilé kíkọ́ wà lára iṣẹ́ wọn.

Nínú àpèjúwe kan tí Jòhánù Olùbatisí ṣe, ó mẹ́nu kan àáké, ìyẹn irinṣẹ́ kan tó ṣeé ṣe kí Jésù àtàwọn káfíńtà yòókù máa lò láti fi gé igi lulẹ̀. Lẹ́yìn náà, wọ́n á la igi náà níbẹ̀ tàbí kí wọ́n gbé e lọ sí ṣọ́ọ̀bù. Ó dájú pé irú iṣẹ́ yìí gba kéèyàn lágbára gan-an. (Mátíù 3:10) Aísáyà náà dárúkọ àwọn irinṣẹ́ míì táwọn káfíńtà máa ń lò nígbà tó wà láyé, ó ní: “Ní ti agbẹ́gi, ó na okùn ìdiwọ̀n; ó fi ẹfun pupa sàmì sí i; ó fi ìfági fá a; ó sì ń fi kọ́ńpáàsì sàmì sí i.” (Aísáyà 44:13) Àwọn ohun táwọn awalẹ̀pìtàn ṣàwárí ẹ̀ fi hàn pé nígbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì àwọn èèyàn máa ń lo ayùn, òòlù olókùúta àti ìṣó onídẹ. (Ẹ́kísódù 21:6; Aísáyà 10:15; Jeremáyà 10:4) Ó bọ́gbọ́n mu nígbà náà láti ronú pé Jésù pẹ̀lú á ti lo irú àwọn irinṣẹ́ bẹ́ẹ̀.

Àwọn wo làwọn “oníṣẹ́ báǹkì” tí Jésù sọ̀rọ̀ nípa wọn nínú ọ̀kan lára àwọn àpèjúwe rẹ̀, kí sì niṣẹ́ wọn?

Jésù sọ̀rọ̀ nípa ọ̀gá kan tó bá ẹrú rẹ̀ tí ò fẹ́ nǹkan kan ṣe wí, ó sọ fún un pé: “Ó yẹ kí ìwọ ti kó àwọn owó fàdákà mi sọ́wọ́ àwọn oníṣẹ́ báǹkì, nígbà tí mo bá sì dé, èmi ì bá wá gba ohun tí ó jẹ́ tèmi pẹ̀lú èlé.”—Mátíù 25:26, 27.

Àwọn báǹkì ńláńlá tó wà lónìí ò sí nígbà tí Jésù wà láyé. Àmọ́, tipẹ́tipẹ́ kí Jésù tó wá sáyé làwọn ayánilówó ti máa ń san èlé lórí owó táwọn èèyàn bá kó sí wọn lọ́wọ́ fákòókò kan, tí wọ́n sì máa ń gba èlé lọ́wọ́ àwọn tí wọ́n bá yá lówó. Gẹ́gẹ́ bí ìwé The Anchor Bible Dictionary ṣe sọ, nígbà tó máa fi di ọ̀rúndún kẹrin ṣáájú Sànmánì Kristẹni, yíyáwó èlé kì í ṣe nǹkan tuntun mọ́ nílẹ̀ Gíríìsì. Nígbà tó sì fi máa di àkókò tí ìjọba Róòmù máyé dẹrùn fáwọn èèyàn, iye èlé táwọn tó ń gbé lágbègbè tí ìjọba Róòmù ń ṣàkóso máa ń san lọ́dún lórí owó tí wọ́n bá yá kì í pọ̀. Iye èlé náà ò ju ká sọ pé kẹ́ni tó yá ọgọ́rùn-ún kan [100] náírà san náírà mẹ́rin sí náírà mẹ́fà lórí owó tó yá lọ.

Àmọ́, Òfin Mósè ka gbígba èlé lọ́wọ́ ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ aláìní léèwọ̀. (Ẹ́kísódù 22:25) Ó dà bíi pé kìkì àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó jẹ́ òtòṣì nìkan ni òfin yìí wà fún. Àmọ́, bó ṣe wà nínú àpèjúwe Jésù, kò sóhun tó burú níbẹ̀ téèyàn bá gba èlé lórí owó tó kó sọ́wọ́ àwọn ayánilówó tàbí èyí tó kó sọ́wọ́ “àwọn oníṣẹ́ báǹkì.” Nítorí náà, bí Jésù ti máa ń ṣe, ó lo nǹkan táwọn olùgbọ́ rẹ̀ mọ̀ dáadáa láti fi ṣàpèjúwe ọ̀rọ̀ rẹ̀.