Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Nípa Jésù

Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Nípa Jésù

Ohun Táwọn Èèyàn Sọ Nípa Jésù

“Kò sí àníàní pé Jésù ará Násárétì . . . kì í ṣe ẹnì kan lásán nínú ìtàn.” —H. G. Wells, òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì.

“Kristi . . . dá yàtọ̀ nínú gbogbo àwọn akọni tó wà nínú ìtàn.” —Philip Schaff, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àti òpìtàn ọmọ ìlú Switzerland.

TA LA lè pè ní ọkùnrin títóbi lọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí? Kí la lè fi mọ̀ bóyá ẹnì kan jẹ́ èèyàn ńlá? Ṣé bó ṣe gbóná tó nídìí iṣẹ́ ológun ni? Ṣé agbára tó ní ni? Ṣé ti orí ẹ̀ tó pé bí nǹkan míì ni? Àbí ṣé a lè fi bí ìwà àti ọ̀rọ̀ ẹnu ẹ̀ ṣe ń nípa lórí àwọn èèyàn àti bó ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún wọn dá a mọ̀ yàtọ̀?

Ṣàyẹ̀wò ohun táwọn òpìtàn, àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀, àwọn ọ̀mọ̀wé, àwọn òǹkọ̀wé, àwọn olóṣèlú àtàwọn míì láyé àtijọ́ àti lóde òní sọ nípa Jésù Kristi ará Násárétì:

“Kẹ́nikẹ́ni tó lè jiyàn pé Jésù ará Násárétì kọ́ ló lókìkí jù lọ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún sẹ́yìn àti nínú gbogbo ìtàn ẹ̀dá èèyàn, àfi kónítọ̀hún jókòó, kó sì ro orí ara ẹ̀ dáadáa.”—Reynolds Price, òǹkọ̀wé ọmọ orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àti ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ nínú Bíbélì.

“Ọkùnrin kan tí kò mọwọ́ mẹsẹ̀ nínú ọ̀ràn tó wà ńlẹ̀ gbà láti kú kí nǹkan lè dáa fáwọn tó kù, títí kan àwọn ọ̀tá rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ ra gbogbo aráyé pa dà. Oore tó ṣe yẹn ò láfiwé.”—Mohandas K. Gandhi, aṣáájú nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ìjọsìn lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

“Nígbà tí mo wà lọ́mọdé, mo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì àti Támọ́dì, ìyẹn ìwé òfin àwọn Júù. Júù ni mí, àmọ́ ìtàn ọkùnrin ará Násárétì yẹn wú mi lórí gan-an.”—Albert Einstein, onímọ̀ ìjìnlẹ̀ ọmọ ilẹ̀ Jámánì.

“Ní tèmi, Jésù Kristi lẹni tó ta yọ jù lọ nínú ìtàn lọ́jọ́kọ́jọ́, gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Ọlọ́run àti gẹ́gẹ́ bí Ọmọ Èèyàn. Gbogbo nǹkan tó sọ tó sì ṣe ló wúlò fún wa lónìí, kò sì sẹ́lòmíì tó ṣì wà láàyè tàbí tó ti kú tá a lè sọ irú ọ̀rọ̀ yìí nípa ẹ̀.”—Sholem Asch, òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Polish tá a fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ látinú ìwé Christian Herald; ìkọ̀wé wínníwínní jẹ́ ti ìwé Christian Herald.

“Odindi ọdún márùndínlógójì [35] ni mi ò fi gba ohunkóhun gbọ́ nígbèésí ayé mi. Àmọ́ lọ́dún márùn-ún sẹ́yìn mo gbà pé ẹnì kan wà tó ń jẹ́ Jésù. Mo nígbàgbọ́ nínú ẹ̀kọ́ Jésù Kristi, ìgbésí ayé mi sì yí pa dà bìrí.”—Count Leo Tolstoy, onímọ̀ ọgbọ́n orí àti òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Rọ́ṣíà.

“[Jésù] lẹni tó tíì gbáyé rí tó sì tíì nípa lórí àwọn èèyàn jù lọ, kódà títí dòní olónìí.”—Kenneth Scott Latourette, òpìtàn àti òǹkọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Amẹ́ríkà.

“Ṣé ká kàn gbà pé ìtàn àròsọ lásán ni ìtàn nípa ìgbésí ayé Jésù ni? Má jẹ n tàn ẹ́ ọ̀rẹ́, kò síbì kan tó fi jọ ìtàn àròsọ. Yàtọ̀ síyẹn, ìtàn Socrates, tó dà bíi pé kò sẹ́ni tó kọminú nípa ẹ̀ ò fẹsẹ̀ múlẹ̀ tó ìtàn Jésù Kristi.”—Jean-Jacques Rousseau, onímọ̀ ọgbọ́n orí ọmọ ilẹ̀ Faransé.

Ó ṣe kedere pé, tẹ́nikẹ́ni bá máa jẹ́ àpẹẹrẹ tá ó máa fara wé nígbèésí ayé, Jésù Kristi lonítọ̀hún. Pọ́ọ̀lù, ọkùnrin ọ̀mọ̀wé kan tí Jésù yàn pé kó di ọmọlẹ́yìn òun ní ọ̀rúndún kìíní, kó sì sọ̀rọ̀ nípa òun fáyé gbọ́, gbà wá níyànjú pé ká “tẹjú mọ́” Jésù. (Hébérù 12:2; Ìṣe 9:3) Kí la lè rí kọ́ lára Jésù nípa bó ṣe yẹ ká máa gbé ìgbésí ayé wa? Báwo sì ni ìgbésí ayé Jésù ṣe lè ṣe ẹ́ láǹfààní?