Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọ̀pá Tín-ín-rín Kanlẹ̀ ó Kànrun

Ọ̀pá Tín-ín-rín Kanlẹ̀ ó Kànrun

Ọ̀pá Tín-ín-rín Kanlẹ̀ ó Kànrun

ÒJÒ wúlò fún wa lọ́pọ̀lọpọ̀, òun ló sì dà bí ọ̀pá tín-ín-rín tó kanlẹ̀ tó kànrun. Àmọ́ tó bá pọ̀ lápọ̀jù, ó lè fa omíyalé. Àwọn èèyàn tí wọ́n sì ń gbé láwọn ilẹ̀ olótùútù tàbí láwọn ilẹ̀ olómi lè má fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí òjò. (Ẹ́sírà 10:9) Àmọ́ fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tó ń gbé láwọn ilẹ̀ olóoru tó máa ń gbẹ táútáú, ńṣe ló máa ń dà bíi kí òjò máa rọ̀ nígbà gbogbo, torí ó máa ń tù wọ́n lára gan-an ni.

Bọ́ràn ṣe rí láwọn ilẹ̀ tí Bíbélì mẹ́nu kàn nìyẹn, irú bí àwọn àgbègbè tó wọnú nílẹ̀ Éṣíà Kékeré, níbi tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ti ṣe míṣọ́nnárì. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù wà níbẹ̀, ó sọ fáwọn ará Likaóníà ìgbàanì pé: “[Ọlọ́run] kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ láìsí ẹ̀rí ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín ní òjò láti ọ̀run àti àwọn àsìkò eléso, ó ń fi oúnjẹ àti ìmóríyágágá kún ọkàn-àyà yín dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́.” (Ìṣe 14:17) Kíyè sí i pé òjò ni Pọ́ọ̀lù kọ́kọ́ mẹ́nu kàn, torí pé bójò ò bá rọ̀ ohun ọ̀gbìn ò lè dàgbà, kò sì ní sí “àwọn àsìkò eléso.”

Bíbélì sọ ọ̀pọ̀lọpọ̀ nǹkan nípa òjò. Ó ju ọgọ́rùn-ún kan [100] ìgbà lọ táwọn tó kọ Bíbélì lo àwọn ọ̀rọ̀ Hébérù àti ti Gíríìkì tó túmọ̀ sí òjò. Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa òjò, ìyẹn ẹ̀bùn tó dà bí ọ̀pá tín-ín-rín tó kanlẹ̀ tó kànrun, tí Ọlọ́run fi ta wá lọ́rẹ? Ṣé wàá tún fẹ́ mọ báwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì ṣe bá ìwádìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ṣe nípa òjò mu kí ìgbàgbọ́ ẹ bàa lè túbọ̀ lágbára sí i?

Ohun Tí Bíbélì Sọ Nípa Òjò

Jésù Kristi jẹ́ ká mọ ohun pàtàkì kan tó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ kí òjò tó lè rọ̀. Ó ní: “Baba yín . . . ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, . . . ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:45) Kíyè sí i pé oòrùn ni Jésù kọ́kọ́ mẹ́nu kàn kó tó sọ̀rọ̀ nípa òjò. Kò kúkú purọ́, torí yàtọ̀ sí pé oòrùn ló ń fún ewéko lágbára láti máa dàgbà, òun náà ló tún máa ń fa omi lọ sókè kó lè rọ̀ bí òjò nígbà tó bá yá. Kò sí àní-àní pé ooru tó ń wá látara oòrùn ló máa ń mú kí èyí tó pọ̀ lára àrágbáyamúyamù omi òkun máa gbẹ lọ́dọọdún, táá sì wá rọ̀ bí òjò. Torí pé Jèhófà Ọlọ́run ló dá oòrùn, òun ló wà lẹ́yìn omi tó dà bí ọ̀pá tín-ín-rín tó kanlẹ̀ tó kànrun.

Nígbà tí Bíbélì máa ṣàpèjúwe bí omi ṣe máa ń lọ sókè tó sì tún máa ń rọ̀ bí òjò, ó ní: “Ọlọ́run . . . a máa fa ẹ̀kán omi sókè; wọ́n a máa kán wínníwínní bí òjò fún ìkùukùu rẹ̀, tí àwọsánmà fi ń sẹ̀, wọ́n ń kán tótó lọ́pọ̀ yanturu sórí aráyé.” (Jóòbù 36:26-28) Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún táwọn ọ̀rọ̀ tó bá ìwádìí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mu yìí ti wà lákọọ́lẹ̀, àwọn èèyàn ti ń gbìyànjú láti lóye ohun tó wà nídìí bí omi ṣe máa ń lọ sókè tó sì tún máa wá rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé. Ìwé kan tí wọ́n fi ń kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì nípa omi, ìyẹn Water Science and Engineering, ti ọdún 2003, sọ pé: “Títí di báyìí, a ò tíì fi bẹ́ẹ̀ lóye bí ẹ̀kán omi òjò ṣe máa ń kóra jọ.”

Ohun táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì mọ̀ ni pé àwọn nǹkan tíntìntín kan ló máa ń pilẹ̀ àwọn ẹ̀kán omi òjò tó ń wá láti ojú ọ̀run. Kí ọ̀kọ̀ọ̀kan àwọn nǹkan tíntìntín wọ̀nyí sì tó lè tó ẹ̀kán omi òjò kan, ó gbọ́dọ̀ ti tóbi ní ìwọ̀n mílíọ̀nù kan sí bó ṣe wà tẹ́lẹ̀ tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ pàápàá. Ohun tá à ń sọ yìí díjú débi pé ó lè gba ọ̀pọ̀ wákàtí. Ìwé Hydrology in Practice sọ pé: “Oríṣiríṣi àlàyé làwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ṣe lórí bí àwọn nǹkan tíntìntín tó wá látinú àdìpọ̀ yìnyín ṣe máa ń di ẹ̀kán omi òjò, ọ̀pọ̀ ìwádìí ló sì ń lọ lọ́wọ́ láti lè mọ àwọn àlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí onírúurú ohun táwọn ẹlòmíì ń sọ lórí ọ̀rọ̀ yìí.”

Ẹlẹ́dàá tó ṣètò bí òjò ṣe ń rọ̀ bi Jóòbù ìránṣẹ́ rẹ̀ láwọn ìbéèrè tó ń múni ronú jinlẹ̀ wọ̀nyí, ó ní: “Òjò ha ní baba, tàbí, ta ní bí ìrì tí ń sẹ̀? Ta ní fi ọgbọ́n sínú àwọn ipele àwọsánmà? . . . Ta ní lè fi ọgbọ́n ka iye àwọsánmà ní pàtó, tàbí àwọn ìṣà omi ọ̀run—ta ní lè mú wọn dà jáde?” (Jóòbù 38:28, 36, 37) Ó ti lé ní ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] báyìí táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì ti ń bá ìbéèrè yìí fà á, àmọ́ ibi pẹlẹbẹ lọ̀bẹ wọn fi ń lélẹ̀.

Ibo Lomi Ń Gbà Lọ?

Àwọn onímọ̀ ọgbọ́n èrò orí nílẹ̀ Gíríìkì kọ́ àwọn èèyàn pé omi òjò kọ́ ló wà nínú àwọn odò, wọ́n ní ibú omi òkun tó ń ṣàn lábẹ́ ilẹ̀ ló ń sun láwọn orí òkè tó sì wá ń di omi odò tó mọ́ lóló. Ìwé kan tó máa ń ṣàlàyé Bíbélì sọ pé Sólómọ́nì gba àbá yẹn wọlé. Sólómọ́nì sọ pé: “Gbogbo ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ń ṣàn lọ sínú òkun, síbẹ̀síbẹ̀ òkun kò kún. Ibi tí àwọn ọ̀gbàrá ìgbà òtútù ti ń ṣàn jáde lọ, ibẹ̀ ni wọ́n ń padà sí, kí wọ́n bàa lè ṣàn jáde lọ.” (Oníwàásù 1:7) Ṣóhun tí Sólómọ́nì ń sọ ni pé omi òkun máa ń sun gba inú àwọn òkè jáde tá á sì wá di orísun àwọn omi odò? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, ẹ jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun táwọn èèyàn tó gbé ìlú kan náà pẹ̀lú Sólómọ́nì gbà gbọ́ nípa bí omi ṣe ń lọ sókè táá sì wá rọ̀ bí òjò. Ṣáwọn náà fara mọ́ èrò yẹn?

Kó tó pé ọgọ́rùn-ún [100] ọdún lẹ́yìn tí Sólómọ́nì sọ̀rọ̀ yìí, Èlíjà tó jẹ́ wòlíì Ọlọ́run jẹ́ ká mọ apá ibi tó yẹ ká máa retí pé òjò máa gbà rọ̀. Ó ju ọdún mẹ́ta lọ tí ọ̀dá òjò fi wà ní ìlú tí Èlíjà wà. (Jákọ́bù 5:17) Jèhófà Ọlọ́run ló ń fìyà yìí jẹ àwọn èèyàn rẹ̀ torí pé wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, tí wọ́n sì wá lọ ń jọ́sìn Báálì, ọlọ́run òjò àwọn ará Kénáánì. Àmọ́ Èlíjà ran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lọ́wọ́ kí wọ́n lè ronú pìwà dà, ó sì wá fẹ́ gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òjò rọ̀. Nígbà tó ń gbàdúrà, Èlíjà sọ fún ìránṣẹ́ rẹ̀ pé kó “wo ìhà òkun.” Nígbà tí ìránṣẹ́ rẹ̀ sọ fún un pé òun rí i tí “àwọsánmà kékeré kan bí àtẹ́lẹwọ́ ènìyàn ń gòkè bọ̀ láti inú òkun,” Èlíjà mọ̀ pé Ọlọ́run ti gbọ́ àdúrà òun. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni “àwọsánmà àti ẹ̀fúùfù mú ojú ọ̀run ṣókùnkùn, eji wọwọ ńláǹlà sì bẹ̀rẹ̀.” (1 Àwọn Ọba 18:43-45) Èlíjà tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé òun mọ bí omi ṣe máa ń lọ sókè tó sì máa wá rọ̀ bí òjò. Ó mọ̀ pé ìkùukùu máa wà lójú ọ̀run lọ́ọ̀ọ́kán ibi tí òkun wà, ẹ̀fúùfù sì máa wá gbé ìkùukùu yìí lọ sọ́ọ̀ọ́kán Ilẹ̀ Ìlérí. Ohun tó máa ń ṣẹlẹ̀ títí dòní olónìí nìyẹn kójò tó rọ̀.

Ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún kan [100] ọdún lẹ́yìn tí Èlíjà gbàdúrà pé kí Ọlọ́run jẹ́ kí òjò rọ̀, Ámósì tó jẹ́ àgbẹ̀ tí ò fi bẹ́ẹ̀ rí já jẹ tẹnu mọ́ kókó pàtàkì kan nípa ohun tó ń jẹ́ kí omi máa lọ sókè tó sì tún máa wá rọ̀ bí òjò. Ọlọ́run lo Ámósì láti sọ tẹ́lẹ̀ lòdì sáwọn ọmọ Ísírẹ́lì torí pé wọ́n ń fìyà jẹ àwọn òtòṣì, wọ́n sì ń jọ́sìn àwọn ọlọ́run èké. Ámósì rọ̀ wọ́n pé tí wọn ò bá fẹ́ pa run, wọ́n ní láti “wá Jèhófà, kí [wọ́n] sì máa wà láàyè nìṣó.” Ẹ̀yìn ìyẹn ni Ámósì wá ṣàlàyé pé Jèhófà nìkan ló yẹ kí wọ́n máa sìn torí pé Òun ni Ẹlẹ́dàá wọn, “Ẹni tí ń pe omi òkun, kí ó lè dà wọ́n sórí ilẹ̀ ayé.” (Ámósì 5:6, 8) Ámósì tún kókó ọ̀rọ̀ pàtàkì yìí sọ nípa bí omi ṣe ń lọ sókè tó sì máa wá rọ̀ sílẹ̀, ó sì tún ṣàlàyé ibi tí omi ń gbà lọ. (Ámósì 9:6) Ó tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ ká mọ̀ pé òkun ni orísun omi òjò tó ń rọ̀ sórí ilẹ̀ ayé.

Ọ̀gbẹ́ni Edmond Halley fìdí ọ̀rọ̀ yìí múlẹ̀ lágbo àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lọ́dún 1687. Àmọ́, ó gba àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì yòókù lákòókò tó pọ̀ kí wọ́n tó fara mọ́ ohun tó sọ. Ìwé Encyclopædia Britannica Online sọ pé: “Títí di ọ̀rúndún kejìdínlógún [18], àwọn èèyàn ronú pé ìlànà kan wà tí Ilẹ̀ Ayé fi máa ń gbé omi lọ sórí àwọn òkè tó sì máa ń tú u jáde níbẹ̀.” Lóde òní, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá mọ òótọ́ nípa bí oòrùn ṣe máa ń fa omi lọ sókè tó sì máa wá rọ̀ bí òjò. Ìwé yẹn tún ṣàlàyé pé: “Oòrùn máa ń fa díẹ̀ lára omi òkun lọ sójú ọ̀run, ó sì máa ń di yìnyín nígbà tó bá dókè. Nígbà tí yìnyín yẹn bá yọ́, ó máa ń di òjò tó máa rọ̀ sórí Ilẹ̀ Ayé. Omi òjò yẹn máa wá ṣàn lọ sínú odò, odò sì máa wá ṣàn lọ sínú òkun.” Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé ọ̀rọ̀ nípa bí ìkùukùu ṣe máa ń di òjò tí omi látinú òkun sì tún máa ń pa dà sókè ni Sólómọ́nì ń sọ nínú ìwé Oníwàásù 1:7.

Kí Ló Wá Yẹ Kó O Ṣe?

Bí onírúurú àwọn òǹkọ̀wé Bíbélì ṣe ṣàwọn àpèjúwe tó péye lórí bí omi ṣe máa ń lọ sókè tó sì máa wá di òjò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro pé Jèhófà Ọlọ́run, Ẹlẹ́dàá wa ló mí sáwọn tó kọ Bíbélì. (2 Tímótì 3:16) Báwọn èèyàn ṣe ń ṣi ayé yìí lò ni ò jẹ́ kí ojú ọjọ́ wà déédéé mọ́, ìdí sì nìyẹn tó fi jẹ́ pé àkúnya omi ń da àwọn ibì kan láàmú, nígbà tó jẹ́ pé ọ̀dá omi nìṣòro láwọn ibòmíì. Àmọ́, tipẹ́tipẹ́ ni Ẹlẹ́dàá tó ṣètò bí omi ṣe ń lọ sókè tó sì ń rọ̀ bí òjò, ti ṣèlérí pé òún máa dá sọ́ràn náà, òún sì máa “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.”—Ìṣípayá 11:18.

Àmọ́ ní báyìí ná, kí lo lè ṣe láti fi hàn pé o mọyì òjò tó wà lára àwọn ẹ̀bùn tí Ọlọ́run fi ta àwa èèyàn lọ́rẹ? Tó o bá ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀, tó o sì ń fàwọn nǹkan tó ò ń kọ́ sílò nígbèésí ayé rẹ, ńṣe lò ń fi hàn pé o mọyì àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run. Ìyẹn á sì jẹ́ kó o lè nírètí láti wà nínú ayé tuntun Ọlọ́run, níbi tí wàá ti lè máa gbádùn gbogbo àwọn ẹ̀bùn Ọlọ́run títí láé. Torí, ó dájú pé Jèhófà Ọlọ́run ló wà lẹ́yìn ọ̀pá tín-ín-rín tó kanlẹ̀ tó kànrun, ọ̀dọ̀ rẹ̀ sì ni “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ti wá.—Jákọ́bù 1:17.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

OMI DI YÌNYÍN

EJI WỌWỌ OMI LÁTARA EWÉKO OMI LÁTINÚ ÒKUN

Ọ̀GBÀRÁ

OMI INÚ ILẸ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Nígbà tí Èlíjà ń gbàdúrà, ìránṣẹ́ rẹ̀ ń “wo apá ìhà òkun”