Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?

Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?

Ṣáwọn Míṣọ́nnárì Dé Ìpẹ̀kun Ìlà Oòrùn Ayé?

KÒ TÍÌ pé ọgbọ̀n [30] ọdún lẹ́yìn tí Jésù kú tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé àwọn ti wàásù ìhìn rere náà nínú “gbogbo ìṣẹ̀dá” tó wà lábẹ́ ọ̀run. (Kólósè 1:23) Ohun tó sọ yìí ò túmọ̀ sí pé gbogbo àwọn èèyàn tó wà láyé nígbà yẹn ló ti gbọ́ ìhìn rere náà. Ohun tí Pọ́ọ̀lù ń sọ ṣe kedere dáadáa, ìyẹn ni pé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì ń fi taratara wàásù níbi gbogbo tí wọ́n ń dé láyé ìgbà yẹn.

Ibo gan-an ni wọ́n wàásù dé nígbà yẹn? Ìwé Mímọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ọkọ̀ ojú omi táwọn oníṣòwò ń wọ̀ láyé ìgbà yẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún Pọ́ọ̀lù láti wàásù lọ jìnnà dé orílẹ̀-èdè Ítálì lápá ìwọ̀ oòrùn ayé. Ògbóǹkangí míṣọ́nnárì yìí tún fẹ́ láti wàásù lórílẹ̀-èdè Sípéènì.—Ìṣe 27:1; 28:30, 31; Róòmù 15:28.

Apá ìlà oòrùn ayé ńkọ́? Báwo làwọn míṣọ́nnárì ṣe lọ jìnnà tó níbẹ̀? A ò fi bẹ́ẹ̀ mọ bí wọ́n ṣe lọ jìnnà tó lápá ìlà oòrun, torí pé Bíbélì ò sọ nǹkan kan nípa ẹ̀. Àmọ́ ṣá o, ó lè yà wá lẹ́nu láti mọ̀ pé ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn oníṣòwò máa ń lọ jìnnà gan-an láti apá ibi tí Òkun Mẹditaréníà wà títí dé apá Ìlà Oòrùn ayé. Èyí fi hàn pé, ó ṣeé ṣe láti rìnrìn àjò lọ sápá ìlà oòrun ayé nígbà yẹn.

Ìlànà Tí Alẹkisáńdà Fi Lélẹ̀

Nígbà tí Alẹkisáńdà Ńlá jagun mólú lọ́nà tó lékenkà, ó ṣẹ́gun àwọn ìlú tó wà lápá ìlà oòrùn láti orílẹ̀-èdè Babilóníà àti Páṣíà títí lọ dé ìlú Punjab lápá àríwá orílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwọn ìrìn àjò akọni tí Alẹkisáńdà rìn lọ sápá ìlà oòrùn yìí ló jẹ́ káwọn Gíríìkì mọ etíkun tó fẹ̀ láti etí odò Yúfírétì, lápá ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà, títí lọ dé apá ibi tí odò Indus ti wọnú òkun ilẹ̀ Arébíà.

Kò pẹ́ sígbà yẹn táwọn oníṣòwò fi bẹ̀rẹ̀ sí í gbé àwọn nǹkan tó máa ń mú oúnjẹ ta sánsán àti tùràrí láti òdìkejì Òkun Íńdíà gba orí Òkun Pupa kọjá lọ sáwọn ilẹ̀ táwọn ará Gíríìsì ń gbé. Àwọn oníṣòwò ará ilẹ̀ Íńdíà àti Arébíà ló kọ́kọ́ ń ṣerú òwò yìí. Àmọ́ nígbà táwọn Tọ́lẹ́mì ti Íjíbítì mọ̀ nípa bí ojú ọjọ́ ṣe máa ń rí lórí Òkun Íńdíà, àwọn náà bẹ̀rẹ̀ sí í ṣòwò gba orí Òkun Íńdíà.

Ẹ̀fúùfù tó máa ń wá láti apá gúúsù ìwọ̀ oòrùn máa ń rọra fẹ́ láti oṣù May sí oṣù September, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn ọkọ̀ òkun láti máa gbéra létí Òkun Pupa lọ sáwọn etíkun tó wà lápá gúúsù ilẹ̀ Arébíà tàbí lọ sápá gúúsù orílẹ̀-èdè Íńdíà. Tó bá wá di oṣù November sí March, ẹ̀fúùfù yẹn máa bẹ̀rẹ̀ sí í fẹ́ lọ sódìkejì ibi tó ti ń fẹ́ wá tẹ́lẹ̀, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kó rọrùn fáwọn oníṣòwò yìí láti pa dà sílé. Ọjọ́ pẹ́ táwọn ará Arébíà àtàwọn ará Íńdíà tó máa ń tukọ̀ òkun ti ń fọgbọ́n rìnrìn àjò lórí òkun yìí torí pé wọ́n mọ bí ẹ̀fúùfù orí òkun náà ṣe máa ń fẹ́, wọ́n máa ń kó igi kaṣíà, igi sínámónì, náádì àti ata láti ilẹ̀ Íńdíà lọ sí Òkun Pupa.

Àwọn Ọ̀nà Tó Lọ sí Alẹkisáńdíríà àti Róòmù Lórí Òkun

Nígbà táwọn ará Róòmù ṣẹ́gun àwọn tó gbàjọba lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà kú, ilẹ̀ Róòmù di ojúkò ọjà tí wọ́n ti ń ta àwọn nǹkan iyebíye táwọn ará ìlà oòrùn ń kó wá, àwọn ará Áfíríkà ń kó eyín erin wá, àwọn ará Arébíà ń kó tùràrí àti òjíá wá, orílẹ̀-èdè Íńdíà ni wọ́n ti ń kó àwọn nǹkan tó ń mú kí oúnjẹ ta sánsán àtàwọn òkúta iyebíye wá, nígbà tó jẹ́ pé sílíìkì làwọn ará Ṣáínà wá ń tà ní tiwọn. Àwọn Etíkun ńláńlá méjì tó wà létí Òkun Pupa nílẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn Berenice àti Myos Hormos làwọn ọkọ̀ òkun tó ń kó àwọn oníṣòwò àtàwọn ọjà wọ̀nyí wá ti máa ń pàdé. Àwọn ọ̀nà tó lọ sí Coptos létí odò Náílì wà láwọn etíkun méjèèjì wọ̀nyí.

Àwọn oníṣòwò máa ń gbé ọjà wọn láti Coptos gba odò Náílì, táwọn ará Íjíbítì máa ń gbà dáadáa, kọjá lọ sí Alẹkisáńdíríà níbi tí wọ́n ti máa ń kó àwọn ẹrù náà sínú àwọn ọkọ̀ òkun tó ń lọ sórílẹ̀-èdè Ítálì àtàwọn ibòmíì. Ọ̀nà míì tí wọ́n tún lè gbà lọ sí Alẹkisáńdíríà ni ọ̀gbun tó wà láàárín Òkun Pupa, nítòsí ìlú Suez òde òní àti odò Náílì. Orílẹ̀-èdè Íjíbítì àtàwọn ibùdó ọkọ̀ òkun tó wà lórílẹ̀-èdè náà ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sáwọn ilẹ̀ tí Jésù ti wàásù, ó sì rọrùn láti débẹ̀.

Ọ̀gbẹ́ni Strabo, tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní, tó sì jẹ́ ògbóǹkangí nínú ìmọ̀ nípa ilẹ̀ ayé àtàwọn nǹkan tó wà nínú rẹ̀ sọ pé, ọgọ́fà [120] ọkọ̀ òkun àwọn ará Alẹkisáńdíríà ló máa ń gbéra láti Myos Hormos láti lọ ṣòwò lórílẹ̀-èdè Íńdíà lọ́dọọdún. Ìwé kan tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún kìíní, tó dá lórí bí wọ́n ṣe ń rìnrìn àjò láwọn àgbègbè yìí ṣì wà títí dòní olónìí. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé oníṣòwò ọmọ ilẹ̀ Íjíbítì kan tó ń sọ èdè Gíríìkì ló kọ ọ́ káwọn oníṣòwò yòókù lè máa rí i lò. Kí làwọn nǹkan tá a lè rí kọ́ látinú ìwé àtayébáyé yìí?

Lédè Látìn, orúkọ ìwé yìí ni Periplus Maris Erythraei, tó túmọ̀ sí Ìrìn Àjò Lórí Òkun Ilẹ̀ Ẹ̀rítíríà. Ìwé náà ṣàlàyé àwọn ọ̀nà tó jìn tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún kìlómítà táwọn atukọ̀ òkun máa ń gbà lórí agbami lọ sápá gúúsù orílẹ̀-èdè Íjíbítì, títí lọ dé erékùṣù Zanzibar. Nígbà tẹ́ni tó kọ ìwé náà ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tó rí lápá ìlà oòrùn, ó mẹ́nu kan báwọn ìlú tó wà lápá ìlà oòrùn náà ṣe jìnnà tó, ó sọ̀rọ̀ nípa irú àwọn ìdákọ̀ró ti wọ́n máa ń lò àtàwọn ilé ìtajà ńláńlá tó wà níbẹ̀, tó fi mọ́ irú ọjà tí wọ́n ń tà. Ó sì tún jẹ́ ká mọ ìwà àwọn tó ń gbé ní etíkun gúúsù ilẹ̀ Arébíà, tàwọn tó wà ní etíkun ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè Íńdíà, tàwọn tó ń gbé lórílẹ̀-èdè Sri Lanka, tó fi mọ́ ìwà àwọn tó ń gbé ní etíkun ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Íńdíà títí lọ dé odò Ganges. Àwọn àlàyé tó péye tí òǹkọ̀wé náà ṣe lọ́nà tó sojú abẹ níkòó yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó ti dé gbogbo ìlú tó dárúkọ yẹn rí.

Àwọn Ará Ìwọ̀ Oòrùn Dé Orílẹ̀-èdè Íńdíà

Yavanas làwọn ará Íńdíà máa ń pe àwọn oníṣòwò tó bá wá láti àwọn ìlú tó wà lápá ìwọ̀ oòrùn orílẹ̀-èdè náà. Ìwé Periplus jẹ́ ká mọ̀ pé ìlú Muziris, tí kò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sí gúúsù orílẹ̀-èdè Íńdíà, a wà lára àwọn ìlú táwọn oníṣòwò wọ̀nyí sábà máa ń lọ ní ọ̀rúndún kìíní. Àwọn ewì táwọn Tamil kọ nígbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀, sọ̀rọ̀ nípa àwọn oníṣòwò wọ̀nyí léraléra. Ọ̀kan lára àwọn ewì náà kà pé: “Wúrà ni ọkọ̀ òkun àwọn Yavanas tó rẹwà bí egbin máa ń kó wá, bí wọ́n bá sì ń lọ wọn a kó ata dání, ariwo kì í dá nílùú Muziris.” Ewì míì tún rọ ọmọ ọba kan láti gúúsù orílẹ̀-èdè Íńdíà pé kó mu ògidì wáìnì tó ń ta sánsán táwọn Yavanas gbé wá. Lára àwọn ọjà táwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn máa ń kó wá, wàràwàrà làwọn nǹkan èèlò tí wọ́n fi gíláàsì ṣe, àwọn mẹ́táàlì, ilẹ̀kẹ̀ iyùn àti aṣọ máa ń tà lórílẹ̀-èdè Íńdíà.

Àwọn awalẹ̀pìtàn ti rí ọ̀pọ̀ ẹ̀rí láti fi hàn pé àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn máa ń kó ọjà lọ sórílẹ̀-èdè Íńdíà. Bí àpẹẹrẹ, ní abúlé Arikamedu tó wà ní etíkun lápá gúúsù ìlà oòrùn orílẹ̀-èdè Íńdíà, lára àwọn nǹkan táwọn awalẹ̀pìtàn rí níbẹ̀ ni àfọ́kù ìgò wáìnì àtàwọn àwo táwọn amọ̀kòkò ìlú Arezzo lórílẹ̀-èdè Ítálì sàmì sí. Òǹkọ̀wé kan kọ̀wé pé: “Awalẹ̀pìtàn òde òní kan túbọ̀ fojúunú yàwòrán bí nǹkan ṣe rí nígbà láéláé bó ṣe ń hú àwọn àfọ́kù ìkòkò kan jáde nínú ilẹ̀ lábẹ́ omi lápá ibi tí òkun ti ya wọ àgbègbè Bengal, orúkọ àwọn oníṣẹ́ ọnà tí wọ́n máa ń sun ìkòkò létí ìlú Arezzo ló sì wà lára àwọn àfọ́kù ìkòkò náà.” Onírúurú owó ẹyọ ilẹ̀ Róòmù, wúrà àti fàdákà táwọn awalẹ̀pìtàn tún rí lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Íńdíà tún jẹ́rìí sí i pé àwọn oníṣòwò máa ń gba Òkun Mẹditaréníà lọ sórílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwòrán àwọn Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù, irú bí Ọ̀gọ́sítọ́sì, Tìbéríù àti Nérò wà lára ọ̀pọ̀ àwọn owó ẹyọ wọ̀nyí, ẹ̀rí sì fi hàn pé ọ̀rúndún kìíní ni wọ́n ti ná irú àwọn owó yẹn.

Àwòrán ilẹ̀ tí wọ́n ti yà tipẹ́tipẹ́ tó ṣì wà títí dòní olónìí tún jẹ́rìí sí i pé, ó ṣeé ṣe káwọn ọmọ ilẹ̀ Róòmù ti máa wá ṣòwò láwọn àgbègbè kan tó wà ní àdádó lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Íńdíà. Àwòrán ilẹ̀ yìí tí wọ́n máa ń pè ní Àtẹ Peutinger sọ ibi tí tẹ́ńpìlì Ọ̀gọ́sítọ́sì wà nílùú Muziris, ó sì jẹ́ ká mọ ọ̀pọ̀ nǹkan táwọn ará Róòmù máa ń ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. Ìwé Rome’s Eastern Trade: International Commerce and Imperial Policy, 31 BC–AD 305 sọ pé: “Kò sẹ́lòmíì tó lè kọ́ irú tẹ́ńpìlì yẹn àyàfi àwọn tó wà lábẹ́ Ilẹ̀ Ọba Róòmù, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn tó ń gbé nílùú Muziris tàbí àwọn tó sábà máa ń lọ síbẹ̀ lára wọn ló kọ́ ọ.”

Àkọsílẹ̀ àwọn ará Róòmù fi hàn pé àwọn aṣojú ìjọba ilẹ̀ Íńdíà bíi mẹ́ta ló wá sílùú Róòmù nígbà tí Ọ̀gọ́sítọ́sì ń ṣàkóso láti ọdún kẹtàdínlọ́gbọ̀n [27] ṣáájú Sànmánì Kristẹni sí ọdún kẹrìnlá [14] Sànmánì Kristẹni. Ìwádìí táwọn kan ṣe lórí ìbẹ̀wò yìí fi hàn pé, “ọ̀rọ̀ pàtàkì kan làwọn aṣojú ìjọba nílẹ̀ òkèèrè wọ̀nyí bá wá,” ìyẹn sì ni bí wọ́n ṣe fẹ́ fẹnu kò lórí ibi táwọn oníṣòwò tó bá wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra á ti máa dúnà-ándúrà, àwọn ibi tí wọ́n á ti máa gbowó orí, ibi táwọn ọmọ ilẹ̀ òkèèrè á máa dé sí àtàwọn nǹkan míì.

Èyí fi hàn pé ní ọ̀rúndún kìíní, àwọn èèyàn sábà máa ń rìnrìn àjò láàárín àgbègbè Òkun Mẹditaréníà àti orílẹ̀-èdè Íńdíà. Torí náà, kò ní ṣòro fáwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì láti wọ ọkọ̀ lọ sórílẹ̀-èdè Íńdíà láti àríwá Òkun Pupa.

Ṣé Wọ́n Kọjá Orílẹ̀-Èdè Íńdíà?

Kò rọrùn láti mọ báwọn oníṣòwò àtàwọn arìnrìn àjò tó wà lágbègbè Òkun Mẹditaréníà ṣe lọ jìnnà tó lápá ìlà oòrùn, bẹ́ẹ̀ ni kò sì rọrùn láti mọ ìgbà tí wọ́n kọ́kọ́ lọ síbẹ̀. Àmọ́ a gbà pé, àwọn arìnrìn àjò kan láti ìwọ̀ oòrùn rìnrìn tó jìnnà lọ sí orílẹ̀-èdè Thailand, Kàǹbódíà àtàwọn erékùṣù Sumatra àti Java.

Ìwé Hou Han-Shou, tó sọ ìtàn àwọn ọba ilẹ̀ Ṣáínà láti ọdún kẹtàlélógún [23] Sànmánì Kristẹni sí okòó-lérúgba [220] ọdún Sànmánì Kristẹni sọ àwọn déètì tí wọ́n rìnrìn àjò wọ̀nyẹn. Lọ́dún kẹrìndínláàádọ́sàn-án [166] Sànmánì Kristẹni, An-tun tó jẹ́ aṣojú ọba Daqin lọ sí kóòtù ilẹ̀ Ṣáínà láti san ìṣákọ́lẹ̀ fún Olú Ọba Huan-ti. Daqin làwọn ará Ṣáínà máa ń pe Ilẹ̀ Ọba Róòmù, wọ́n sì máa ń pe Antoninus ní An-tun. Antoninus yìí ni orúkọ ìdílé tí Marcus Aurelius, tó jẹ́ olú ọba ilẹ̀ Róòmù nígbà yẹn ti wá. Àwọn òpìtàn ronú pé kì í ṣe ọ̀dọ̀ ọba ni aṣojú yẹn ti wá ní tààràtà, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn oníṣòwò kan láti ìwọ̀ oòrùn ló rán ẹnì kan láti lọ ṣàdéhùn pẹ̀lú ìjọba orílẹ̀-èdè Ṣáínà, kí wọ́n lè máa rí sílíìkì rà láti Ṣáínà ní tààràtà dípò kí wọ́n máa rà á lọ́wọ́ àwọn aláròóbọ̀.

Tá a bá wá pa dà sórí ìbéèrè tí àpilẹ̀kọ yìí dá lé, Ṣé àwọn ọkọ̀ òkun ayé àtijọ́ gbé àwọn Kristẹni tí wọ́n jẹ́ míṣọ́nnárì dé ìpẹ̀kun ìlà oòrùn? Ṣé wọ́n dé orílẹ̀-èdè Íńdíà àbí wọ́n tiẹ̀ kọjá ibẹ̀? Ó ṣeé ṣe kọ́ràn rí bẹ́ẹ̀. Ó dájú pé ìhìn rere táwọn Kristẹni ń wàásù rẹ̀ tàn kárí ayé dáadáa, ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi lè sọ pé ó ń “so èso, . . . ó sì ń bí sí i ní gbogbo ayé,” ìyẹn ni pé ìhìn rere náà dé àwọn apá ibi tó jìnnà jù lọ láyé ìgbà yẹn.—Kólósè 1:6.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tó mọ ọ̀gangan ibi tí ìlú Muziris wà, àwọn ọ̀mọ̀wé sọ pé ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìtòsí odò Periyar ní ìpínlẹ̀ Kerala ló wà.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Olú Ọba Kan Sọ Ẹ̀dùn Ọkàn Ẹ̀

Lọ́dún kejìlélógún [22] Sànmánì Kristẹni, Tìbéríù Olú Ọba ilẹ̀ Róòmù sọ ẹ̀dùn ọkàn ẹ̀ nípa àṣejù àwọn ará ìlú ẹ̀. Bí wọ́n ṣe ń fi ìwàǹwara nífẹ̀ẹ́ sí ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì àti báwọn obìnrin ilẹ̀ Róòmù ṣe ń yán hànhàn fáwọn nǹkan tó ṣeyebíye ń ṣàkóbá fún ilẹ̀ Róòmù. Ṣe ni wọ́n ń sọ àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ ilẹ̀ ọba Róòmù di tàwọn “orílẹ̀-èdè àjèjì tàbí tàwọn òǹrorò.” Ọ̀gbẹ́ni Pliny Àgbà tó jẹ́ òpìtàn ọmọ ilẹ̀ Róòmù, tí wọ́n bí lọ́dún kẹtàlélógún [23] Sànmánì Kristẹni, tó sì kú lọ́dún kọkàndínlọ́gọ́rin [79] Sànmánì Kristẹni náà sọ fáyé gbọ́ pé ìnákúùná àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò tẹ́ òun lọ́rùn. Ó kọ̀wé pé: “Ńṣe là ń tara wa lọ́pọ̀ fáwọn ará Íńdíà, àwọn ará Serica àtàwọn ará Arébíà, ọgọ́rùn-ún kan [100] mílíọ̀nù owó sesterces ni wọ́n ń kó lọ mọ́ wa lọ́wọ́ lọ́dọọdún, owó gọbọi tá à ń ná nìyẹn torí àwọn obìnrin wa àti nítorí pé à ń fẹ́ láti gbé ìgbésí ayé yọ̀tọ̀mì.” b

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

b Àwọn tó ń ṣírò owó sọ pé ìdá méjì nínú ọgọ́rùn-ún ọrọ̀ ajé Ilẹ̀ Ọba Róòmù ni ọgọ́rùn-ún kan [100] mílíọ̀nù owó sesterces.

[Credit Line]

Àwòrán látọwọ́ Museo della Civiltà Romana, Roma; Todd Bolen/Bible Places.com

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ibi Táwọn Oníṣòwò Ti Ń Rajà

Jésù sọ̀rọ̀ nípa “olówò arìnrìn-àjò kan tí ń wá àwọn péálì àtàtà.” (Mátíù 13:45) Ìwé Ìṣípayá náà tún mẹ́nu ba “àwọn olówò arìnrìn-àjò” tó máa ń ra àwọn òkúta iyebíye, aṣọ ṣẹ́dà, igi olóòórùn dídún, eyín erin, igi sínámónì, tùràrí àtàwọn èròjà tó ń ta sánsán láti orílẹ̀-èdè Íńdíà. (Ìṣípayá 18:11-13) Àwọn ibi táwọn oníṣòwò sábà máa ń dé lápá ìlà oòrùn ilẹ̀ Palẹ́sìnì ni wọ́n ti máa ń rí àwọn ọjà wọ̀nyí rà. Orílẹ̀-èdè Íńdíà ni wọ́n ti máa ń rí àwọn igi olóòórùn dídùn bíi sandalwood. A lè ráwọn péálì tó ṣeyebíye gan-an lápá ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà àti ní Òkun Pupa. Ẹni tó kọ ìwé Periplus Maris Erythraei sì tún jẹ́ ká mọ̀ pé a lè rí i nítòsí ìlú Muziris àti lórílẹ̀-èdè Sri Lanka. Ó ṣeé ṣe káwọn péálì tí wọ́n ń rí nínú Òkun Íńdíà wà lára àwọn péálì tó dára jù lọ tó sì wọ́n jù lọ.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 20, 21]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Àwọn ibi táwọn oníṣòwò sábà máa ń dé láàárín ilẹ̀ Róòmù àti ilẹ̀ Éṣíà ní ọ̀rúndún kìíní

Arezzo

Róòmù

ÒKUN MEDITARÉNÍÀ

ÁFÍRÍKÀ

Alẹkisáńdíríà

ÍJÍBÍTÌ

Coptos

Odò Náílì

Myos Hormos

Berenice

Zanzibar

Òkun Pupa

Jerúsálẹ́mù

ARÉBÍÀ

Odò Yúfírétì

BABILÓNÍÀ

Ibi tí òkun ti ya wọ ilẹ̀ Páṣíà

PÁSÍÀ

Afẹ́fẹ́ láti àríwá ìlà oòrùn

Afẹ́fẹ́ láti gúúsù ìwọ̀ oòrùn

Odò Indus

PUNJAB

Odò Ganges

Ibi tí òkun ti ya wọ ìlú Bengal

ÍŃDÍÀ

Arikamedu

Muziris

SRI LANKA

OKUN ÍŃDÍÀ (ÒKUN Ẹ̀RÍTÍRÍÀ)

ṢÁÍNÀ

ILẸ̀ ỌBA HAN

THAILAND

KÀǸBÓDÍÀ

VIETNAM

Sumatra

Java

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Bí ọkọ̀ òkun táwọn ará Róòmù fi máa ń kẹ́rù ṣe rí rèé

[Credit Line]

Ọkọ̀ òkun: Látọwọ́ Pictorial Archive (Near Eastern History) Est.