Ipa Tí Màríà Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
Ipa Tí Màríà Kó Nínú Mímú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ
NÍGBÀ tí Jésù ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, obìnrin kan pariwo débi pé ohùn ẹ̀ bo ariwo àwọn ogunlọ́gọ̀ tó ń gbọ́rọ̀ Jésù mọ́lẹ̀, ohun tó sì sọ ni pé: “Aláyọ̀ ni ilé ọlẹ̀ tí ó gbé ọ àti ọmú tí ìwọ mu!” Tó bá jẹ́ pé Jésù fẹ́ ká máa jọ́sìn ìyá òun ni, àsìkò yìí gan-an ni ò bá ti fi irú ìjọsìn bẹ́ẹ̀ lọ́lẹ̀. Àmọ́, ńṣe ló dáhùn pé: “Ó tì o, kàkà bẹ́ẹ̀, Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—Lúùkù 11:27, 28.
Jésù ò pàfiyèsí sí ìyá rẹ̀ káwọn èèyàn lè máa bọlá fún un lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, kódà kò sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn pé kí wọ́n máa ṣe bẹ́ẹ̀. Báwo nìṣẹ̀lẹ̀ yìí ṣe kan àpọ́nlé táwọn onígbàgbọ́ tòótọ́ kan ń fún Màríà? Ẹ jẹ́ ká jíròrò ohun tí Ìwé Mímọ́ sọ nípa àwọn ẹ̀kọ́ tó gbayé kan lónìí nípa Màríà ìyá Jésù.
“Ó Kún fún Àánú,” Ó sì Jẹ́ “Alábùkún . . . Láàárín Àwọn Obìnrin”
Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì sọ ipa tí Màríà máa kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ. Nígbà tí áńgẹ́lì yẹn máa kí Màríà, ohun tó sọ ni pé: “Kú déédéé ìwòyí o, ẹni tí a ṣe ojú rere sí lọ́nà gíga, Jèhófà wà pẹ̀lú rẹ.” (Lúùkù 1:28) Ọ̀nà míì téèyàn tún lè gbà tú ìkíni yìí ni: “Mo kí ẹ, ìwọ ẹni tó kún fún àánú, kí Olúwa wà pẹ̀lú rẹ.” Kò pẹ́ lẹ́yìn èyí ni Èlísábẹ́tì kí Màríà pé: “Alábùkún ni ìwọ láàárín àwọn obìnrin, alábùkún sì ni èso ilé ọlẹ̀ rẹ!” (Lúùkù 1:42) Ṣáwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n fi kí Màríà yìí tó kéèyàn máa jọ́sìn ẹ̀ lóòótọ́?
Ká sòótọ́, kò tó bẹ́ẹ̀. Òótọ́ ni pé àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí wà nínú àdúrà táwọn ẹlẹ́sìn Mátíù 6:9.
Kátólíìkì máa ń gbà sí Màríà, àmọ́ Bíbélì ò sọ pé ìdí kankan wà tá a fi ní láti máa darí irú àdúrà bẹ́ẹ̀ sí Màríà. Gébúrẹ́lì àti Èlísábẹ́tì gbà láìjanpata pé Màríà láǹfààní àrà ọ̀tọ̀ láti jẹ́ ìyá Mèsáyà, àmọ́ kò síbi tí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé ká máa darí àdúrà sí i. Kàkà bẹ́ẹ̀, nígbà táwọn ọmọlẹ́yìn Jésù sọ fún un pé kó kọ́ àwọn báwọn á ṣe máa gbàdúrà, ó jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé Bàbá òun tó wà lọ́run ni kí wọ́n máa darí àdúrà sí. Abájọ tó fi jẹ́ pé ohun tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà àwòfiṣàpẹẹrẹ tó kọ́ àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ni: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run.”—Ó Wà Lára Àwọn Tó Máa Ṣàkóso
Ẹ̀kọ́ míì tó tún gbayé kan ni pé Màríà ti di “Ọbabìnrin ọ̀run” báyìí. Bíbélì ò pe orúkọ oyè yìí mọ́ ọn rí. Àmọ́, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé òótọ́ ló wà nípò kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú ètò kan tí Ọlọ́run ti ṣe lọ́run. Ipò wo wá nìyẹn?
Jésù jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa jọba pẹ̀lú òun nínú Ìjọba òun. (Lúùkù 22:28-30) Jésù máa fún àwọn tí Ọlọ́run ti yàn wọ̀nyí ní ọlá àṣẹ láti sìn gẹ́gẹ́ bí “àlùfáà fún Ọlọ́run wa, wọn yóò sì ṣàkóso gẹ́gẹ́ bí ọba lé ilẹ̀ ayé lórí.” (Ìṣípayá 5:10) Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere sí wa níparí ọ̀rọ̀ náà pé Màríà wà lára àwọn tó máa láǹfààní àgbàyanu yìí. Báwo nìyẹn ṣe lè rí bẹ́ẹ̀?
Ó ṣeé ṣe kó o rántí pé lẹ́yìn tí Jésù kú, Màríà “tẹpẹlẹ mọ́ àdúrà” gbígbà pẹ̀lú àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àtàwọn àbúrò Jésù. Ọgọ́fà [120] èèyàn ló wà níbẹ̀ lọ́jọ́ yẹn, “àwọn obìnrin kan” sì wà lára wọn. (Ìṣe 1:12-15) Bíbélì sọ pé bí “àjọyọ̀ Pẹ́ńtíkọ́sì ti ń lọ lọ́wọ́, gbogbo wọ́n wà pa pọ̀ ní ibì kan náà” nígbà tí Ọlọ́run tú ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ sórí wọn, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ fún wọn lágbára láti máa sọ àwọn èdè ilẹ̀ òkèrè.—Ìṣe 2:1-4.
Bó ṣe jẹ́ pé Màríà wà lára àwọn tí Ọlọ́run bù kún lọ́nà yìí jẹ́ ká mọ̀ pé òun àtàwọn obìnrin tó gba ẹ̀mí mímọ́ Ọlọ́run lọ́jọ́ yẹn wà lára àwọn tí Ọlọ́run yàn láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù nínú Ìjọba rẹ̀ ọ̀run. Torí náà, ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro wà pé Màríà ti jókòó pẹ̀lú Jésù báyìí nínú ògo rẹ̀ lọ́run. (Róòmù 8:14-17) Ronú lórí ipa pàtàkì tóun àtàwọn tó kù tó máa ṣàkóso pẹ̀lú Jésù máa kó nínú mímú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ pàtápàtá.
Ó Pín Ìbùkún Jìgbìnnì Fáráyé
Ìwé Ìṣípayá tó wà nínú Bíbélì sọ pé àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì [144,000] èèyàn ló máa jí dìde sínú ògo lọ́run láti sìn pẹ̀lú Jésù gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, adájọ́ àti ọba. (Ìṣípayá 14:1, 4; 20:4, 6) Gẹ́gẹ́ bí àlùfáà, àwọn náà máa ṣe nínú iṣẹ́ fífún aráyé onígbọràn láǹfààní tó wà nínú ẹbọ ìràpadà Jésù, wọ́n á sì tipa bẹ́ẹ̀ jẹ́ kí wọ́n di pípé ní ti ọ̀nà tí wọ́n gbà ń jọ́sìn Ọlọ́run, ní ti ìwà híhù àti nípa tara. (Ìṣípayá 21:1-4) Àǹfààní aláìlẹ́gbẹ́ mà ló máa jẹ́ fáwọn tó ń fi tọkàntara jọ́sìn Jèhófà láti rí àkókò àgbàyanu yìí o! a
Màríà ti ṣe bẹbẹ, ó sì ń kó ipa ribiribi lọ́wọ́lọ́wọ́ láti mú ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ. Ẹni tó yẹ ká fara wé ni, torí onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni, ó nígbàgbọ́ tó lágbára, ó jẹ́ onígbọràn, ìyá tó mọṣẹ́ ẹ̀ níṣẹ́ ni, ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ bó ṣe fara da inúnibíni àti ìṣòro. Ó sì yẹ ká bọ̀wọ̀ fún un torí ipa tó kó láti bí Mèsáyà sáyé àti láti pín àwọn ìbùkún jìgbìnnì fáráyé.
Àmọ́, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ tá a kọ́ lára Màríà ni pé bíi ti gbogbo àwọn olùfọkànsìn Ọlọ́run, Jèhófà nìkan ló jọ́sìn, kò jọ́sìn ọlọ́run míì. Màríà máa gbé ohùn rẹ̀ sókè pa pọ̀ pẹ̀lú àwọn tó kù tó máa jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run láti sọ pé: “Ẹni tí ó jókòó lórí ìtẹ́ [ìyẹn Jèhófà Ọlọ́run] àti Ọ̀dọ́ Àgùntàn náà [ìyẹn Jésù Kristi] ni kí ìbùkún àti ọlá àti ògo àti agbára ńlá wà fún títí láé àti láéláé.”—Ìṣípayá 5:13; 19:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa àwọn ìbùkún wọ̀nyí, wo orí 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 10]
Ó yẹ ká fara wé Màríà torí onírẹ̀lẹ̀ èèyàn ni, ìgbàgbọ́ ẹ̀ lágbára, ó sì jẹ́ onígbọràn