Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Mi?
Ṣé Ọlọ́run Bìkítà Nípa Mi?
Àwọn kan lè dáhùn pé:
▪ “Ọlọ́run tóbi ju ẹni tó lè máa ronú nípa àwọn ìṣòro tí mo ní.”
▪ “Mi ò rò pó rí tèmi rò.”
Kí ni Jésù sọ?
▪ Jésù sọ pé: “Ológoṣẹ́ márùn-ún ni a ń tà ní ẹyọ owó méjì tí ìníyelórí rẹ̀ kéré, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Síbẹ̀síbẹ̀, kò sí ọ̀kan nínú wọn tí a gbàgbé níwájú Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n irun orí yín pàápàá ni a ti ka iye gbogbo wọn. Ẹ má bẹ̀rù; ẹ níye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́.” (Lúùkù 12:6, 7) Láìsí àní-àní, Jésù kọ́ wa pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa.
▪ Jésù sọ pé: “Ẹ má ṣàníyàn láé, kí ẹ sì wí pé, ‘Kí ni a ó jẹ?’ tàbí, ‘Kí ni a ó mu?’ tàbí, ‘Kí ni a ó wọ̀?’ Nítorí gbogbo ìwọ̀nyí ni nǹkan tí àwọn orílẹ̀-èdè ń fi ìháragàgà lépa. Nítorí Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run mọ̀ pé ẹ nílò gbogbo nǹkan wọ̀nyí.” (Mátíù 6:31, 32) Ó dá Jésù lójú pé Ọlọ́run mọ ohun tí kálukú wa nílò.
BÍBÉLÌ jẹ́ kó dá wa lójú pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa. (Sáàmù 55:22; 1 Pétérù 5:7) Tó bá bìkítà nípa wa lóòótọ́, kí wá nìdí tá a fi ń jìyà tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ lónìí? Tí Ọlọ́run bá nífẹ̀ẹ́ wa tágbára ẹ̀ ò sì láàlà, kí nìdí tí kò fi tíì wá nǹkan ṣe sọ́rọ̀ ìyà tó ń jẹ aráyé?
Òótọ́ kan tọ́pọ̀ èèyàn ò mọ̀ ni pé Sátánì Èṣù ni olùṣàkóso ayé búburú yìí. Nígbà tí Sátánì dẹ Jésù wò, ó fi gbogbo ìjọba ayé hàn án, ó wá sọ pé: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú, nítorí pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹnì yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni èmi yóò fi í fún.”—Lúùkù 4:5-7.
Ta ló fi Sátánì ṣe olùṣàkósó ayé? Nígbà táwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà, ṣègbọràn sí Sátánì tí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ kọtí ikún sáṣẹ Ọlọ́run, ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé Sátánì làwọ́n fẹ́ kó máa ṣàkóso àwọn. Látìgbà tí wọ́n sì ti hùwà ọ̀tẹ̀ yẹn ni Jèhófà Ọlọ́run ti fọwọ́ lẹ́rán kí gbogbo èèyàn lè mọ̀ pé ìṣàkóso Sátánì ti kùnà pátápátá. Jèhófà ò fipá mú àwa èèyàn láti máa jọ́sìn òun, àmọ́ ó fún wa láǹfààní láti pa dà bá òun rẹ́.—Róòmù 5:10.
Torí pé Ọlọ́run bìkítà nípa wa ló ṣe jẹ́ kí Jésù wá gbà wá sílẹ̀ lábẹ́ ìṣàkóso Sátánì. Lọ́jọ́ iwájú, Jésù máa “sọ ẹni tí ó ní ọ̀nà àtimú ikú wá di asán, èyíinì ni, Èṣù.” (Hébérù 2:14) Ó máa tipa bẹ́ẹ̀ “fọ́ àwọn iṣẹ́ Èṣù túútúú.”—1 Jòhánù 3:8.
Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè lẹ́ẹ̀kan sí i. Lákóòkó yẹn, Ọlọ́run máa “nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [àwọn èèyàn], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [á] ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:4, 5. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà, wo orí 11 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 8]
Ọlọ́run máa sọ ayé yìí di Párádísè lẹ́ẹ̀kan sí i