Ṣé Ọlọ́run Lórúkọ?
Ṣé Ọlọ́run Lórúkọ?
Àwọn kan lè dáhùn pé:
▪ “Ọlọ́run náà lorúkọ Ọlọ́run.”
▪ “Kò lórúkọ àbísọ kankan.”
Kí ni Jésù sọ?
▪ Jésù sọ pé: “Nítorí náà, kí ẹ máa gbàdúrà ní ọ̀nà yìí: ‘Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.’” (Mátíù 6:9) Jésù mọ̀ pé Ọlọ́run lórúkọ.
▪ Jésù sọ pé: “Mo sì ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀ fún wọn, ṣe ni èmi yóò sì sọ ọ́ di mímọ̀, kí ìfẹ́ tí ìwọ fi nífẹ̀ẹ́ mi lè wà nínú wọn àti èmi ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú wọn.” (Jòhánù 17:26) Jésù jẹ́ káwọn èèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run.
▪ Jésù sọ pé: “Ẹ kì yóò rí mi lọ́nàkọnà títí ẹ ó fi wí pé, ‘Alábùkún ni ẹni tí ń bọ̀ wá ní orúkọ Jèhófà!’” (Lúùkù 13:35; Sáàmù 118:26) Jésù lo orúkọ Ọlọ́run.
ỌLỌ́RUN fúnra rẹ̀ jẹ́ ká mọ orúkọ rẹ̀. Ọlọ́run sọ nínú Bíbélì pé: ‘Èmi sì fara han Ábúráhámù, Ísákì àti Jákọ́bù, ní Ọlọ́run Olódùmarè, ṣùgbọ́n orúkọ mi Jèhófà ni wọn kò fi mọ̀ mí.’ a (Ẹ́kísódù 6:3, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Lédè Yorùbá, Jèhófà làwọn èèyàn sábà máa ń pe orúkọ Hébérù tí Ọlọ́run fún ara rẹ̀. Ó lè yà ẹ́ lẹ́nu láti mọ̀ pé ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìgbà lorúkọ Hébérù tí ò láfiwé yìí fara hàn nínú àwọn ìwé àfọwọ́kọ ayé àtijọ́ tí wọ́n ti ṣàdàkọ Bíbélì. Kódà, ó fara hàn lọ́pọ̀ ìgbà ju àwọn orúkọ míì tó wà nínú Bíbélì lọ.
Tá a bá bi àwọn míì pé, “Kí ni orúkọ Ọlọ́run,” wọ́n lè sọ pé “Ọlọ́run náà ni.” Ká sòótọ́, ìdáhùn yẹn ò nítumọ̀ kankan, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n bi ẹnì kan pé, “Ta ló wọlé nínú ìbò tí wọ́n dì,” tónítọ̀hún sì sọ pé “Ẹni tó díje” ni. Kò sí ìdáhùn tó tọ̀nà nínú méjèèjì, torí pé “Olúwa” kì í ṣe orúkọ, kò sì sẹ́ni tórúkọ ẹ̀ ń jẹ́ “ẹni tó díje.”
Kí nìdí tí Ọlọ́run fi sọ orúkọ rẹ̀ fún wa? Ìdí ni pé ó fẹ́ ká mọ òun dáadáa. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn lè máa pe ẹnì kan ní Alàgbà, Ọ̀gá, Dádì tàbí Bàbá Àgbà torí irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́. Àwọn orúkọ oyè yìí ń sọ nǹkan kan nípa onítọ̀hún, àmọ́ orúkọ tó ń jẹ́ gan-an ló máa jẹ́ ká rántí gbogbo ohun tá a ti mọ̀ nípa ẹ̀. Bákàn náà, àwọn orúkọ oyè bí Olúwa, Olódùmarè, Bàbá àti Ẹlẹ́dàá ń jẹ́ ká rántí oríṣiríṣi nǹkan tí Ọlọ́run ti ṣe, àmọ́ orúkọ rẹ̀, Jèhófà, nìkan ló ń jẹ́ ká rántí gbogbo ohun tá a ti mọ̀ nípa rẹ̀. Kò sí béèyàn ṣe lè mọ Ọlọ́run dáadáa láìjẹ́ pé èèyàn kọ́kọ́ mọ orúkọ rẹ̀.
Yàtọ̀ sí kéèyàn mọ orúkọ Ọlọ́run, ó tún ṣe pàtàkì pé kéèyàn máa fi orúkọ yẹn pè é. Kí nìdí? Ìdí ni pé Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé: “Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.”—Róòmù 10:13; Jóẹ́lì 2:32.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Tó o bá fẹ́ mọ̀ síwájú sí i nípa ohun tí orúkọ Ọlọ́run túmọ̀ sí àti ìdí tí orúkọ yẹn ò fi sí nínú àwọn ìtúmọ̀ Bíbélì kan, o lè wo ojú ìwé 195 sí 197 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Àwọn èèyàn lè máa pe ẹnì kan ní Alàgbà, Ọ̀gá, Dádì tàbí Bàbá Àgbà torí irú ẹni tónítọ̀hún jẹ́, àmọ́ orúkọ tó ń jẹ́ gan-an ló máa jẹ́ ká rántí gbogbo ohun tá a ti mọ̀ nípa ẹ̀