Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Lo Ère Láti Jọ́sìn Ọlọ́run?

Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Lo Ère Láti Jọ́sìn Ọlọ́run?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Kí Nìdí Táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Kì Í Fi Í Lo Ère Láti Jọ́sìn Ọlọ́run?

Kárí ayé làwọn ẹlẹ́sìn Híńdù, Búdà, Kátólíìkì àtàwọn oníṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ka lílo ère sí apá pàtàkì nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run. Láwọn ibì kan ní Áfíríkà, àwọn èèyàn máa ń bọ igi tàbí òkúta, torí wọ́n gbà pé ọlọ́run kan tàbí ẹ̀mí ọlọ́run kan wà nínú igi tàbí òkúta náà.

Ṣùgbọ́n, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í lo ère èyíkéyìí láti jọ́sìn Ọlọ́run. Tó o bá wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba wa, ìyẹn ibi tá a ti máa ń jọ́sìn, o ò lè rí ère àwọn ẹni táwọn kan kà sí ẹni mímọ́, o ò lè rí ti Jésù ká má ṣẹ̀ṣẹ̀ wá sọ ti Màríà. a Kí nìdí? Ó dáa, gbọ́ ohun tí Bíbélì sọ nípa ọ̀rọ̀ yìí.

Kí Ni Ọlọ́run Ní Káwọn Ọmọ Ísírẹ́lì Máa Ṣe?

Lẹ́yìn tí Jèhófà Ọlọ́run gba àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, ó sọ bóun ṣe fẹ́ káwa èèyàn máa jọ́sìn òun. Èkejì lára òfin tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Òfin Mẹ́wàá sọ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ṣe ère gbígbẹ́ fún ara rẹ tàbí ìrísí tí ó dà bí ohunkóhun tí ó wà nínú ọ̀run lókè tàbí tí ó wà lábẹ́ ilẹ̀ tàbí tí ó wà nínú omi lábẹ́ ilẹ̀. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ tẹrí ba fún wọn tàbí kí a sún ọ láti sìn wọ́n, nítorí èmi Jèhófà Ọlọ́run rẹ jẹ́ Ọlọ́run tí ń béèrè ìfọkànsìn tí a yà sọ́tọ̀ gedegbe.”—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Lásìkò tí Ọlọ́run ń fún Mósè láwọn òfin yìí, ńṣe làwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń ṣe ère ọmọ màlúù kan, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ará Íjíbítì tó máa ń bọ ẹranko ni wọ́n ń fara wé. Wọn ò fún ère yẹn lórúkọ òòṣà àwọn ará Íjíbítì. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n sọ pé ìjọsìn Jèhófà làwọn fi ń gbé lárugẹ. (Ẹ́kísódù 32:5, 6) Báwo lohun tí wọ́n ṣe yẹn ṣe rí lára Ọlọ́run? Ọlọ́run bínú sáwọn tó ṣe ère náà, Mósè sì fọ́ ère náà yángá.—Ẹ́kísódù 32:9, 10, 19, 20.

Nígbà tó yá, Jèhófà Ọlọ́run fàwọn àlàyé míì kún òfin kejì. Jèhófà tipasẹ̀ Mósè rán àwọn ọmọ Ísírẹ́lì létí pé wọn ò gbọ́dọ̀ ṣe ‘ère gbígbẹ́ kankan fún ara wọn ní ti gidi tàbí ìrísí àpẹẹrẹ èyíkéyìí, àwòrán akọ tàbí abo, àwòrán ẹranko èyíkéyìí tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé, àwòrán ẹyẹ abìyẹ́lápá èyíkéyìí tí ń fò ní ojú ọ̀run, àwòrán ohunkóhun tí ń rìn lórí ilẹ̀ tàbí àwòrán ẹja èyíkéyìí tí ń bẹ nínú omi lábẹ́ ilẹ̀ ayé.’ (Diutarónómì 4:15-18) Ó ṣe kedere pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ò gbọ́dọ̀ lo ère èyíkéyìí láti jọ́sìn Ọlọ́run.

Síbẹ̀, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run, torí wọ́n bọ̀rìṣà. Kí wọ́n lè ronú pìwà dà, Jèhófà rán àwọn wòlíì rẹ̀ láti kìlọ̀ fún wọn pé tí wọn ò bá jáwọ́ nínú ìbọ̀rìṣà, òun máa fìyà jẹ wọ́n. (Jeremáyà 19:3-5; Ámósì 2:8) Orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì kọtí ikún sáwọn ìkìlọ̀ wọ̀nyẹn. Torí náà, Jèhófà gba àwọn ará Bábílónì láyè láti pa Jerúsálẹ́mù run, kí wọ́n sì kó àwọn èèyàn ilẹ̀ náà lọ sígbèkùn lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.— 2 Kíróníkà 36:20, 21; Jeremáyà 25:11, 12.

Kí Làwọn Tó Kọ́kọ́ Bẹ̀rẹ̀ Ẹ̀sìn Kristẹni Gbà Gbọ́?

Nígbà táwọn tí kì í ṣe Júù di Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní, wọ́n jáwọ́ nínú fífi ère jọ́sìn Ọlọ́run. Ṣó o rántí ohun tí Dímẹ́tíríù, alágbẹ̀dẹ fàdákà nílùú Éfésù sọ nípa ìwàásù àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù? Ó ní: “Ẹ̀yin ènìyàn, ẹ mọ̀ dunjú pé inú iṣẹ́ òwò yìí ni a ti ní aásìkí wa. Pẹ̀lúpẹ̀lù, ẹ rí, ẹ sì gbọ́, kì í ṣe ní Éfésù nìkan, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ ní gbogbo àgbègbè Éṣíà, bí Pọ́ọ̀lù yìí ti yí ogunlọ́gọ̀ tí ó tóbi púpọ̀ lérò padà, tí ó sì ti yí wọn padà sí èrò mìíràn, tí ó ń wí pé àwọn èyí tí a fi ọwọ́ ṣe kì í ṣe ọlọ́run.”—Ìṣe 19:25, 26

Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù fúnra ẹ̀ sọ lẹ́yìn náà jẹ́ ká mọ̀ pé ẹ̀sùn èké kọ́ ni Dímẹ́tíríù fi kàn án. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Gíríìkì tó wà ní Áténì sọ̀rọ̀, ó ní: “Kò yẹ kí a lérò pé Olù-Wà Ọ̀run rí bí wúrà tàbí fàdákà tàbí òkúta, bí ohun tí a gbẹ́ lére nípasẹ̀ ọnà àti ìdọ́gbọ́nhùmọ̀ ènìyàn. Lóòótọ́, Ọlọ́run ti gbójú fo irúfẹ́ àwọn àkókò àìmọ̀ bẹ́ẹ̀, síbẹ̀ nísinsìnyí, ó ń sọ fún aráyé pé kí gbogbo wọn níbi gbogbo ronú pìwà dà.” (Ìṣe 17:29, 30) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sáwọn ará Tẹsalóníkà lórí ọ̀rọ̀ yìí kan náà, ó gbóríyìn fún wọn nípa sísọ pé: “Ẹ . . . yí padà sọ́dọ̀ Ọlọ́run kúrò nínú òrìṣà yín.”—1 Tẹsalóníkà 1:9.

Pọ́ọ̀lù nìkan kọ́ ló sọ̀rọ̀ yìí, àpọ́sítélì Jòhánù náà kìlọ̀ fáwọn Kristẹni pé lílo ère láti jọ́sìn Ọlọ́run ò dáa. Nígbà tí ọ̀rúndún kìíní ń parí lọ, Jòhánù sọ fáwọn Kristẹni láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n pé: “Ẹ máa ṣọ́ra fún àwọn òrìṣà.”—1 Jòhánù 5:21.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣègbọ́ràn sí àṣẹ Ọlọ́run tó ní ká má ṣe lo ère èyíkéyìí láti jọ́sìn òun. A gbà pé Jèhófà ò lè yí ọ̀rọ̀ ẹ̀ pa dà, nígbà tó sọ pé: “Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”—Aísáyà 42:8.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a O lè rí àwòrán àwọn èèyàn tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa wọn láwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan. Àmọ́, ńṣe la fi irú àwòrán bẹ́ẹ̀ ṣe ọ̀ṣọ́ sára àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba wọ̀nyẹn, wọn kì í ṣe ère fún ìjọsìn. Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í gbàdúrà sáwọn àwòrán wọ̀nyí, a kì í sì í forí balẹ̀ fún wọn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 31]

“Èmi ni Jèhófà. Èyí ni orúkọ mi; èmi kì yóò sì fi ògo mi fún ẹlòmíràn, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò fi ìyìn mi fún àwọn ère fífín.”—Aísáyà 42:8