Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwárí Lobìnrin Ń Wá Nǹkan Ọbẹ̀

Àwárí Lobìnrin Ń Wá Nǹkan Ọbẹ̀

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Ireland

Àwárí Lobìnrin Ń Wá Nǹkan Ọbẹ̀

OJÚ ọjọ́ tutù kùlẹ̀ lọ́jọ́ tá à ń wí yìí. Omi òjò tó ń fún ti bo ojú fèrèsé mọ́tò mi, ìyẹn ò sì jẹ́ kí n rí bí àyíká ìlú tí mo wà ṣe rí dáadáa. Lẹ́yìn tí mo ti rin nǹkan bíi kìlómítà mẹ́rìndínlógún [16], mo dé orí òkè kan tí mo ti lè rí Westport, ìlú kékeré kan tó wà létíkun lápá ìwọ̀-oòrùn orílẹ̀-èdè Ireland. Nígbà tó yá, oòrùn lá gbogbo omi tó bo ojú fèrèsé mọ́tò mi, mo wá rí àwọn erékùṣù tó yí òkun náà ká, àwọ̀ aró tí omi òkun sì ní jẹ́ kí ìrísí ohun tí mò ń rí yìí rẹwà gan-an. Díẹ̀ lára àwọn erékùṣù yìí làwọn èèyàn ń gbé, àmọ́ àwọn àgbẹ̀ máa ń fọkọ̀ ojú omi kó àwọn ẹran wọn lọ jẹko láwọn erékùṣù tó kù.

Àwọn ilẹ̀ olókè míì tún tò lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ òkun náà lápá ìwọ̀-oòrùn. Àwọn igi òdòdó ẹ̀bá òkè àtàwọn igi tó máa ń hù létí omi wà lórí àwọn òkè náà, béèyàn bá sì ń wo àwọn òkè náà látọ̀ọ́kán lọ́sàn-án tí oòrùn ń mú ganrínganrín, ńṣe ló ń dán bíi bàbà tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ rọ. Láti ibi tí mo wà, mò ń wo àpáta Croagh Patrick, tó dà bí ilé aborí-ṣóńṣó-bìdírẹ̀kẹ̀tẹ̀ táwọn ará àdúgbò yẹn ń pè ní Reek, lọ́ọ̀ọ́kán. Mo wa mọ́tò gba àwọn òpópónà ìlú Westport táwọn èèyàn ti ń rìn lọ rìn bọ̀, mo gba Reek kọjá, mo sì wá lọ sí àgbègbè kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ti í sábà wàásù.

Ọkùnrin tí mò ń wá lọ ò mọ̀ pé òní ni mò ń bọ̀ lọ́dọ̀ òun. Àìpẹ́ yìí ni mo gba lẹ́tà pé ó ti kó wá sádùúgbò yìí, ó sì fẹ́ máa bá ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìṣó. Ṣe ni mo kàn ń bi ara mi pé: ‘Báwo lọkùnrin tí mò ń wá lọ yìí ṣe dàgbà tó? Ṣé àpọ́n ni àbí baálé ilé? Àwọn nǹkan wo ló fẹ́ràn?’ Mo tún fọpọlọ yẹ báàgì tí mo gbé wò, mo sì rántí pé mo ti gbé Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ kan tó dá lórí Bíbélì. Mo wá ronú lórí ohun tí mo lè sọ láti túbọ̀ fi kún ìfẹ́ tó ní láti gbọ́rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run.

Mo ti wa mọ́tò kọjá àpáta Reek báyìí. Àwọn òkúta tí wọ́n tò léra wọn tó dà bí fẹ́ǹsì ló yí àwọn ọgbà tó pààlà pẹ̀lú òkun ká, ọ̀nà tí wọ́n sì gbà to àwọn òkúta wọ̀nyẹn, látìgbà ọ̀wọ́n gógó oúnjẹ tó wáyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún, jẹ́ kí ìrísí àwọn ọgbà náà rẹwà gan-an. Ẹyẹ lékeléke rọra fò gba orí àwọn ọgbà rírẹwà náà kọjá. Ìjì òkun tó ń fẹ́ rọra ń bì lu àwọn igi ẹlẹ́gùn-ún pupa àti dúdú tó wà létí òkun náà, wọ́n sì ń bì síwásẹ́yìn bí àwọn ọkùnrin arúgbó tó ń tẹ̀pá rìn.

Wọn ò kọ nọ́ńbà sára àwọn ilé tó wà ládùúgbò yìí, wọn ò sì kọ orúkọ sára àwọn òpópónà tó wà níbẹ̀, àmọ́ Orúkọ ilé àti orúkọ àdúgbò wà lára àdírẹ́sì ọkùnrin náà tó wà lọ́wọ́ mi. a Àwọn akówèé-ránṣẹ́ ni mo kọ́kọ́ ń wá, torí àwọn ló sábà máa ń mọ ibi táwọn èèyàn ń gbé. Ọgbọ̀n [30] ìṣẹ́jú lẹ́yìn ìgbà yẹn, ni mo rí ilé ìkówèéránṣẹ́ kan. Wọ́n ti gbé àkọlé gàdàgbà kan tí wọ́n kọ̀rọ̀ sí pé “A ti ṣíwọ́,” sẹ́nu ọ̀nà. Nígbà tí wọ́n sì ti ṣíwọ́, mo lọ sí ṣọ́ọ̀bù kan tó wà nítòsí láti béèrè bí mo ṣe lè rin àdúgbò náà.

Nígbà tí mo tún rin kìlómítà mẹ́jọ míì, mo rí àmì tí wọ́n fi júwe ọ̀nà fún mi, ìyẹn ọ̀nà kan tó yà kọdọrọ sápá ọ̀tún tí ọ̀nà tóóró kan sì yà lápá òsì rẹ̀. Mo kan ilẹ̀kùn ilé tí mo kọ́kọ́ rí. Obìnrin àgbàlagbà kan ló sì wá ṣílẹ̀kùn. Pẹ̀lú ìdánilójú ló fi sọ fún mi pé àdúgbò yìí lòun ti ń gbé látìgbà tí wọ́n ti bí òun, àmọ́ ó dun òun pé òun ò mọ ọkùnrin tí mo ní mò ń wá yìí. Ó ní kí n wọlé, kóun lè pe àwọn kan lórí tẹlifóònù láti bá mi béèrè bóyá wọ́n lè mọ ẹni tí mò ń wá.

Bó ṣe ń báwọn tó ń pè sọ̀rọ̀ lórí tẹlifóònù ló ń fojú ẹ̀gbẹ́ kan wò mí, ó sì dájú pé ohun tó ń rò ni pé, ta lọkùnrin yìí, kí ló sì ń wá. Mo rí i pé ó gbé ère Màríà Wúńdíá kọ́ sára ilẹ̀kùn, ó sì gbé àwòrán Kristi tó tóbi kọ́ sára ògiri. Ìlẹ̀kẹ̀ àdúrà sì wà lórí tábìlì tó wà ní yàrá tó ti ń gbọ́ oúnjẹ. Kí ọkàn ẹ̀ lè balẹ̀, mo sọ fún un pé, “Àwọn ọ̀rẹ́ wa kan ló rán mi sí i.”

Nígbà tó yá, ọkọ ẹ̀ wá bá wa, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í sọ ìtàn àdúgbò náà fún mi. Lẹ́yìn tí obìnrin náà bá ẹni àkọ́kọ́ sọ̀rọ̀ tán lórí fóònù, ó jọ pé onítọ̀hún ò mọ ẹni tí mò ń wá, àmọ́ ó ní kí n ṣì ní sùúrù kóun tún pe àwọn míì. O jọ pé kò sẹ́ni tó mọ ọkùnrin tí mò ń wá yìí tàbí ibi tó ń gbé. Nígbà tí mo wo aago ọwọ́ mi, mo rí i pé ọjọ́ ti lọ. Mo wá rí i pé àfi kí n pa dà wá nígbà míì. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ tọkọtaya tó ti ń ràn mí lọ́wọ́ látàárọ̀, mo sì ṣíná mọ́tò láti pa dà sílé.

Mo pa dà lọ síbẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e. Lọ́tẹ̀ yìí, mo rí ọ̀kan lára àwọn tó ń ṣiṣẹ́ nílé ìkówèéránṣẹ́ náà, ó sì ṣàlàyé bí mo ṣe máa rin àdúgbò náà tí mi ò fi ní sọ nù. Ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lẹ́yìn tí mo kúrò lọ́dọ̀ ẹ̀, mo dé ìkòríta tó fi júwe ọ̀nà fún mi. Mo yíwọ́ mọ́tò mi sápá òsì, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí wá afárá ògbólógbòó kan tí wọ́n fi òkúta mọ tó sọ pé màá rí lẹ́yìn tí mo bá dé ìkòríta náà. Mo rìn lọ rìn bọ̀, àmọ́ mi ò rí afárá náà. Àmọ́, mo wá rí ohun tó ní máa rí kí n tó dé ilé tí mò ń wá, nígbà tí mo sì gbójú sókè, ilé ti mo ti ń fi gbogbo ọjọ́ wá ni mò ń wò lórí òkè yìí.

Mo dúró díẹ̀ láti ronú lórí bí mo ṣe máa gbọ́rọ̀ nípa ìhìn rere náà kalẹ̀. Nígbà tí mo dé ilé náà, mo kanlẹ̀kùn, ọkùnrin àgbàlagbà sì jáde wa. Lẹ́yìn tí mo júwe ẹni tí mò ń wá fún un tán, ó ní: “Wò ó, máà bínú, ilé tó ò ń wá ló ṣì wà lọ́ọ̀ọ́kán yẹn.” Ó nawọ́ sí ilé kan táwọn igi tó wà níwájú ẹ̀ ò lè jẹ́ kéèyàn rí dáadáa. Pẹ̀lú èrò pé mo ti débi tí mò ń lọ, mo lọ sílé náà, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í kan ilẹ̀kùn. Bí mo ṣe ń dúró lẹ́nu ilẹ̀kùn náà ni mò ń wo Òkun Àtìláńtíìkì tí ò jìnnà síbẹ̀. Atẹ́gùn túbọ̀ ń fẹ́ yẹ́ẹ́, atẹ́gùn náà sí ti funfun nítorí pé ó gbé iyẹ̀pẹ̀ òkun. Mi ò réèyàn nítòsí ilé náà, kò sì dájú pé ẹnikẹ́ni wà nínú ilé ọ̀hún.

Mo pààrà ilé yìí lẹ́ẹ̀mejì sí i, kí n tó wá rí ọ̀dọ́kùnrin kan. Ó sọ pé: “Ilé tẹ́ ẹ̀ ń wá gan-an nìyí, àmọ́ ayálégbé tó wà níbí tẹ́lẹ̀, ìyẹn ọkùnrin tẹ́ ẹ̀ ń wá, ti kó kúrò níbi, mi ò sì mọ ibi tó kó lọ.” Mo ṣàlàyé ìdí tí mo fi ń wá ọkùnrin náà, mo sì wá mọ̀ nígbà tó yá pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò tíì bá ọmọkùnrin yìí sọ̀rọ̀ rí. Àwọn adigunjalè ti fojú ẹ̀ rí màbo, kò sì tíì lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba irú ìwà ìrẹ́nijẹ bẹ́ẹ̀. Kíá ló gba àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! tó ṣẹ̀ṣẹ̀ jáde, tó sọ̀rọ̀ nípa kókó yìí gan-an.

Ìwé Mímọ́ pa á láṣẹ pé ká ṣe gbogbo ohun tá a bá lè ṣe láti wá àwọn ẹni bí àgùntàn rí, bí ìgbà tóbìnrin ń wá nǹkan ọbẹ̀. Ó ṣeni láàánú pé mi ò rí ọkùnrin tí mo ti ń wá látọjọ́ yìí. Àmọ́ síbẹ̀, mi ò gbà pé gbogbo ìsapá tí mo ṣe ti já sí pàbó. Lórílẹ̀-èdè Ireland, ọ̀pọ̀ ló ń hára gàgà láti gbọ́ nípa Ìjọba Ọlọ́run, ó sì dá mi lójú pé pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà ọ̀dọ́kùnrin tí mo wàásù fún yìí lè tẹ̀ síwájú lọ́jọ́ kan kóun náà sì bẹ̀rẹ̀ sí kọ́ àwọn ẹlòmíì.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Lórílẹ̀-èdè Ireland, àwọn àdúgbò tí wọ́n ti pààlà wọn láti ọ̀rúndún kọkànlá ni wọ́n ń pè ní ìlú. Àwọn ìlú wọ̀nyí tóbi jura wọn lọ, ọgọ́rọ̀ọ̀rún ilé gbígbé lè wà nínú àwọn kan lára àwọn ìlú náà. Orúkọ àwọn ìlú yìí ni wọ́n sì máa fi ń kówèé ránṣẹ́ lórílẹ̀-èdè Ireland.