Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Èèyàn Ò Gbọ́dọ̀ Wà Láàyè Nípa Oúnjẹ Nìkan—Ohun Tí Ò Jẹ́ Kí N Kú Sẹ́wọ̀n Nígbà Ìjọba Násì

Èèyàn Ò Gbọ́dọ̀ Wà Láàyè Nípa Oúnjẹ Nìkan—Ohun Tí Ò Jẹ́ Kí N Kú Sẹ́wọ̀n Nígbà Ìjọba Násì

Èèyàn Ò Gbọ́dọ̀ Wà Láàyè Nípa Oúnjẹ Nìkan—Ohun Tí Ò Jẹ́ Kí N Kú Sẹ́wọ̀n Nígbà Ìjọba Násì

Bí Joseph Hisiger ṣe sọ ọ́

Mo bi ọkùnrin kan tá a jọ wà lẹ́wọ̀n pé: “Kí nìwọ ń kà níbẹ̀ yẹn?” Ó ní: “Bíbélì ni mò ń kà. Màá fún ẹ tó o bá lè gbé gbogbo oúnjẹ tó yẹ kó o jẹ lọ́sẹ̀ kan fún mi.”

MARCH 1, ọdún 1914 ni wọ́n bí mi ságbègbè Moselle tó jẹ́ apá kan orílẹ̀-èdè Jámánì nígbà yẹn. Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kìíní parí lọ́dún 1918, àgbègbè Moselle pa dà di ti orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà tó di ọdún 1940, ìjọba orílẹ̀-èdè Jámánì tún gbà á pa dà. Lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì parí lọ́dún 1945, orílẹ̀-èdè Faransé ló tún bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso àgbègbè Moselle. Ní gbogbo àkókò táwọn ìyípadà wọ̀nyí fi ń ṣẹlẹ̀ ni mò ń yí orúkọ ọmọ orílẹ̀-èdè tí mo jẹ́ pa dà, torí náà mo gbọ́ èdè àwọn Faransé àti tàwọn ará Jámánì.

Onísìn Kátólíìkì tó gba ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn kanrí làwọn òbí mi. Ká tó lọ sùn lálaalẹ́, gbogbo wa máa ń kúnlẹ̀ láti gbàdúrà. Ní gbogbo ọjọ́ Sunday àtàwọn ọjọ́ tí ìjọba àpapọ̀ bá sọ pé ìsinmi wa la máa ń lọ sí ṣọ́ọ̀ṣì. Ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn mi jẹ mí lógún gan-an, mo sì wà lára ẹgbẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní ṣọ́ọ̀ṣì Kátólíìkì.

Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Fìtara Wàásù Gẹ́gẹ́ Bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà

Lọ́dún 1935, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà méjì bẹ àwọn òbí mi wò. Ọ̀rọ̀ nípa ìdí táwọn onísìn fi lọ́wọ́ nínú Ogun Àgbáyé Kìíní ni wọ́n sọ. Lẹ́yìn tí mo ti gbọ́ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, ó wù mí láti mọ púpọ̀ sí i nípa Bíbélì, nígbà tó sì di ọdún 1936, mo lọ bá àlùfáà bóyá wọ́n lè bá mi wá Bíbélì kan. Wọ́n sì sọ pé màá ní láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ìsìn kí n tó lè lóye Bíbélì. Àmọ́, kàkà kí ẹ̀kọ́ nípa ìsìn tẹ́ mi lọ́rùn, ńṣe ni ìfẹ́ láti ní Bíbélì àti láti kà á túbọ̀ gbà mí lọ́kàn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Lóṣù January ọdún 1937, Albin Relewicz, ọkùnrin kan tá a jọ ń ṣiṣẹ́ tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í bá mi sọ̀rọ̀ nípa àwọn ohun tí Bíbélì fi kọ́ni. Mo bi Albin léèrè pé: “Ó yẹ kó o ní Bíbélì, àbí?” Ó sọ pé òun ní, ó sì fi orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà, hàn mí nínú ẹ̀dá Bíbélì German Elberfelder, tó fún mi. Mo bẹ̀rẹ̀ sí í fìtara ka Bíbélì yìí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ sípàdé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Thionville tí ò fi bẹ́ẹ̀ jìnnà sádùúgbò mi.

Oṣù August ọdún 1937 ni mo tẹ̀ lé Albin lọ sí àpéjọ àgbáyé kan táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe nílùú Paris. Ibi tá a ti lọ ṣe àpéjọ àgbáyé yẹn ni mo ti bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù láti ilé dé ilé. Kò pẹ́ sígbà yẹn ni mo ṣèrìbọmi, nígbà tó sì di ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1939, mo di aṣáájú-ọ̀nà déédéé, ìyẹn àwọn kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń fèyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn wàásù. Ìlú Metz ni ètò àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà rán mi lọ. Nígbà tó sì di July, ọdún 1939, mo rí lẹ́tà gbà pé kí n wá ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà nílùú Paris.

Inúnibíni Nígbà Ogun

Mi ò pẹ́ rárá lẹ́nu iṣẹ́ tí wọ́n pè mí fún ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa, torí pé nígbà tó máa fi di August ọdún 1939, ìjọba ilẹ̀ Faransé ti pè mí fún iṣẹ́ ológun. Ẹ̀rí ọkàn mi ò gbà mí láyè láti jagun, torí náà wọ́n jù mí sẹ́wọ̀n. Ẹ̀wọ̀n ni mo wà lóṣù May 1940, nígbà tí ìjọba Jámánì ṣàdédé kógun ja orílẹ̀-èdè Faransé. Nígbà tó sì fi máa di oṣù June, ìjọba Jámánì ti borí orílẹ̀-èdè Faransé, bí mo tún ṣe di ọmọ orílẹ̀-èdè Jámánì nìyẹn. Torí náà, wọ́n tú mi sílẹ̀ lẹ́wọ̀n lóṣù July 1940, mo sì pa dà sọ́dọ̀ àwọn òbí mi.

Nígbà tó ti jẹ́ pé ìjọba Násì ló ń ṣàkóso wa, kọ̀rọ̀ la ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ọwọ́ Maryse Anasiak, obìnrin kan tó nítara fún ìsìn Kristẹni tí mo máa ń bá ní ṣọ́ọ̀bù Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tó ń ṣe búrẹ́dì, la ti máa ń gba ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́. Títí di ọdún 1941, mi ò kó sí wàhálà tí èyí tó pọ̀ jù lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Jámánì ń kó sí.

Lọ́jọ́ kan, ọlọ́pàá ìjọba Násì kan wá sílé mi. Lẹ́yìn tí ọlọ́pàá náà sọ fún mi pé ìjọba ti fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó bi mí bóyá mo ṣì fẹ́ jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Nígbà tí mo sọ pé “Bẹ́ẹ̀ ni,” ó ní kí n tẹ̀ lé òun. Ẹ̀rù ba màámi débi pé wọ́n dá kú. Nígbà tí ọlọ́pàá náà róhun tó ṣẹlẹ̀, ó ní kí n dúró tì wọ́n, kí n lè tọ́jú wọn.

Níbi tí mo ti ń ṣiṣẹ́, mi kì í sọ pé “ti Hitler ni mo ṣe!” láti kí ọ̀gá iléeṣẹ́ náà. Mo sì tún kọ̀ láti jẹ́ ọ̀kan lára ẹgbẹ́ òṣèlú ìjọba Násì. Torí náà, lọ́jọ́ kejì, àwọn ọlọ́pàá ìjọba Násì wá fàṣẹ ọba mú mi. Nígbà tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò, mo kọ̀ láti dárúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kù. Ẹni tó ń fọ̀rọ̀ wá mi lẹ́nu wò gbá ìdí ìbọn mọ́ mi lórí, mo sì dá kú lọ gbári. Ní September 11 ọdún 1942, kóòtù àkànṣe tí ìjọba Násì dá sílẹ̀ ní Metz rán mi lọ sẹ́wọ̀n ọdún mẹ́ta, wọ́n fẹ̀sùn kàn mí pé mò ń “ṣe ìpolongo èké lòdì sí ìjọba Násì lórúkọ Ẹgbẹ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àti tàwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.”

Ọ̀sẹ̀ méjì lẹ́yìn náà ni wọ́n gbé mi kúrò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú Metz, mo sì bára mi ní àgọ́ ìfìyàjẹni tó wà ní Zweibrücken. Nígbà tí mo fi wà níbẹ̀, àwọn ọ̀nà ojú irin la máa ń tún ṣe. Àwọn irin tó lè ṣẹ́ni léegun ẹ̀yìn la máa ń hú, tá a sì máa ń fi tuntun rọ́pò wọn, a máa ń de àwọn irin náà mọ́lẹ̀, a sì máa wá da òkúta sẹ́gbẹ̀ẹ́ wọn. Gbogbo ohun tá a sì máa rí jẹ lẹ́yìn iṣẹ́ àṣekúdórógbó yìí ò ju kọ́ọ̀pù kọfí kan àti nǹkan bí awẹ́ búrẹ́dì méjì láàárọ̀, abọ́ ọbẹ̀ olómi ṣooro kan lọ́sàn-án àti lálẹ́. Nígbà tó yá, wọ́n gbé mi wá sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà nílùú kan tí ò jìnnà sílé, iṣẹ́ sóbàtà ni mo sì ń ṣe níbẹ̀. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù lẹ́yìn náà, wọ́n dá mi pa dà sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Zweibrücken, lọ́tẹ̀ yìí, iṣẹ́ oko ni wọ́n fún mi ṣe.

Mo Wà Láàyè àmọ́ Kì Í Ṣé Nípa Oúnjẹ Nìkan

Ọ̀dọ́kùnrin kan tó wá láti orílẹ̀-èdè Netherlands la jọ wà nínú ẹ̀wọ̀n kan náà. Lẹ́yìn tí mo kọ́ èdè ẹ̀ débì kan, mo bẹ̀rẹ̀ sí í bá a sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tí mo gbà gbọ́. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í lóye àwọn ohun tó ń kọ́, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi wọ́n ṣèwà hù débi pé lọ́jọ́ kan ó ní kí n ṣèrìbọmi fóun nínú odò. Nígbà tó jáde wá látinú omi, ó dì mọ́ mi, ó sì sọ pé: “Joseph, mo ti di arákùnrin ẹ báyìí!” Nígbà tí wọ́n ní kí n pa dà lọ máa ṣiṣẹ́ lójú irin, a ní láti fira wa sílẹ̀.

Lọ́tẹ̀ yìí, ọmọ orílẹ̀-èdè Jámánì la jọ wà nínú ẹ̀wọ̀n kan náà. Nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, mo rí i tó ń ka ìwé kékeré kan, àṣé Bíbélì ni! Ọjọ́ yẹn ló sọ pé òun máa fún mi ní Bíbélì yẹn, tí mo bá gbà láti fún òun ní oúnjẹ tó yẹ kí n jẹ fún ọ̀sẹ̀ kan. Mo sọ fún un pé “Kò síṣòro!” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò rọrùn kéèyàn má jẹun fún odindi ọ̀sẹ̀ kan, àmọ́ mi ò kábàámọ̀. Ọjọ́ yẹn lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ bẹ̀rẹ̀ sí í nítumọ̀ sí mi, ó ní: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.”—Mátíù 4:4.

Ní báyìí tí mo ti wá ní Bíbélì, bí mo ṣe máa tọ́jú ẹ̀ ló tún wá di wàhálà. Ọ̀rọ̀ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò dà bíi tàwọn ẹlẹ́wọ̀n tó kù, torí wọn ò gbọ́dọ̀ rí Bíbélì lọ́wọ́ wa. Torí náà, abẹ́ aṣọ bẹ́ẹ̀dì mi ni mo ti máa ń ka Bíbélì mi lálaalẹ́. Tí ilẹ̀ bá sì ti mọ́ abẹ́ aṣọ mi ló máa ń wà ní gbogbo ìgbà. Mi kì í tọ́jú ẹ̀ sínú ẹ̀wọ̀n tí wọ́n fi mí sí torí wọ́n máa ń tú àwọn ẹrù wa tá ò bá sí nílé.

Lọ́jọ́ kan nígbà tí wọ́n pe gbogbo wa jáde, mo rántí pé mo ti gbàgbé Bíbélì mi sílẹ̀. Mo sáré lọ wò ó nírọ̀lẹ́ ọjọ́ yẹn, àmọ́ mi ò rí i níbẹ̀ mọ́. Lẹ́yìn tí mo ti gbàdúrà sí Ọlọ́run, mo lọ bá ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ wa, mo sì ṣàlàyé fún un pé ẹnì kan ti jí ìwé mi, mo sì fẹ́ gbà á pa dà. Kò kọbi ara sóhun tó ń ṣe nígbà tó ń mú ìwé náà fún mi, bí mo sì ṣe rí Bíbélì mi gbà pa dà nìyẹn. Mo dúpẹ́ gan-an lọ́wọ́ Jèhófà!

Lọ́jọ́ kan nígbà tí wọ́n ní kí n lọ wẹ̀, mo rọra dọ́gbọ́n jẹ́ kí Bíbélì náà já bọ́ nígbà tí mò ń bọ́ aṣọ mi tó ti dọ̀tí. Nígbà tí mo rí pé ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ mi ò wobẹ̀, mo rọra fẹsẹ̀ tì í sẹ́gbẹ̀ẹ́ ibi tí mo ti fẹ́ wẹ̀. Ibẹ̀ ló sì wà títí tí mo fi wẹ̀ tán. Nígbà tí mo wẹ̀ tán, mo tún rọra mú Bíbélì náà sábẹ́ àwọn aṣọ tó mọ́ ti mo fẹ́ wọ̀.

Àwọn Ìṣẹ̀lẹ̀ Tó Fún Mi Láyọ̀ Àtèyí Tó Bà Mí Nínú Jẹ́

Láàárọ̀ ọjọ́ kan lọ́dún 1943 nígbà tí wọ́n ní káwa ẹlẹ́wọ̀n tò, mo rí Albin! Àwọn ọlọ́pàá ti mú òun náà. Ó mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kójú wa ṣe mẹ́rin, ó sì gbé ọwọ́ sáyà láti jẹ́ kí n mọ̀ pé arákùnrin ṣì lòun. Ó wá fọwọ́ ṣàpèjúwe pé òun máa kọ̀wé sí mi. Lọ́jọ́ kejì nígbà tó ń kọjá, ó ju ìwé kan sílẹ̀ fún mi. Àmọ́, ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ wa rí i, wọ́n sì ju àwa méjèèjì sọ́gbà ìfìyàjẹni fún ọ̀sẹ̀ méjì. Búrẹ́dì tó ti gan àti omi là ń jẹ, orí pákó la sì ń sùn sí láìní aṣọ ìbora.

Lẹ́yìn ìgbà yẹn ni wọ́n gbé mi lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n tó wà ní Siegburg, ṣọ́ọ̀bù àwọn tó ń jó irin ni mo sì ti ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ àṣekúdórógbó ni wọ́n fún mi ṣe, wọn ò sì fún mi lóúnjẹ tó tó. Alaalẹ́ ni mo máa ń lálàá pé mò ń jẹ oúnjẹ tó dọ́ṣọ̀ bíi kéèkì àti èso, tí mo bá sì fi máa ji, àwọn aràn inú mi á ti máa kùn, táú lọ̀fun mi sì máa gbẹ. Ńṣe ni mo rù bí ẹni tó ń ṣàìsàn. Àmọ́, kò sí ọjọ́ tí mi ò ka Bíbélì mi, ìyẹn sì jẹ́ kí n rídìí tó fi yẹ kí n wà láàyè.

Mo Bọ́ Lẹ́wọ̀n!

Lójijì láàárọ̀ ọjọ́ kan ní April 1945, mo bá ilẹ̀kùn ibi tí wọ́n tì mí mọ́ ní ṣíṣí, gbogbo àwọn ọlọ́pàá tó ń ṣọ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n tí mo wà ló sì ti fẹsẹ̀ fẹ́ ẹ. Bí mo ṣe bọ́ lẹ́wọ̀n nìyẹn! Àmọ́, ọsibítù ni mo kọ́kọ́ gbà lọ láti lọ tọ́jú ara mi. Nígbà tóṣù May fi máa parí, mo ti wà nílé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi. Wọ́n ti gba kámú pé mi ò lè pa dà wálé láàyè. Bí màámi ṣe rí mi báyìí, ńṣe ni wọ́n bú sẹ́kún, tí omijé ayọ̀ sì ń dà pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ lójú wọn. Ó bà mí nínú jẹ́ pé, kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo tẹ̀wọ̀n dé làwọn òbí mi méjèèjì kú.

Mo tún bẹ̀rẹ̀ sí í dara pọ̀ mọ́ Ìjọ Thionville. Ayọ̀ mi kún nígbà tí mo tún pa dà ráwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tá a jọ ń jọ́sìn Jèhófà! Orí mi wú nígbà tí mo gbọ́ gudugudu méje àti yàyà mẹ́fà tí wọ́n ti ṣe láti jólóòótọ́ sí Ọlọ́run láìka inúnibíni sí. Albin, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n ti kú sílùú Regensburg, lórílẹ̀-èdè Jámánì. Nígbà tó yá, mo gbọ́ pé ọmọ àbúrò bàbá mi, tó ń jẹ́ Jean Hisiger, ti di ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ìjọba sì ti pa á nítorí pé ó kọ̀ láti bá wọn jagun. Jean Queyroi tá a jọ ṣiṣẹ́ ní ẹ̀ka ọ́fíìsì wa tó wà nílùú Paris náà ti lo ọdún márùn-ún lẹ́wọ̀n lórílẹ̀-èdè Jámánì. a

Kò pẹ́ lẹ́yìn tí mo bọ́ lẹ́wọ̀n ni mo pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù nílùú Metz. Nígbà yẹn, mo sábà máa ń lọ sọ́dọ̀ ìdílé kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Minzani. Tina, ọmọbìnrin wọn ti ṣèrìbọmi ní November 2, ọdún 1946. Ó ń fìtara wàásù, ìfẹ́ ẹ̀ sì wọ̀ mí lọ́kàn. Nígbà tó di December 13, ọdún 1947, a ṣègbéyàwó. Tina di aṣáájú-ọ̀nà lóṣù September ọdún 1967, ó sì ń fìtara wàásù títí tó fi kú lóṣù June, ọdún 2003 lọ́mọ ọdún méjìdínlọ́gọ́rùn-un [98]. Àárò ẹ̀ ń sọ mí gidi gan-an.

Bí mo ṣe ń sọ̀rọ̀ yìí, mo ti lé lọ́mọ àádọ́rùn-ún [90] ọdún mo sì ti rí i pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ló ń fún mi lókun láti kojú àdánwò, tó sì ń jẹ́ kí n lè máa borí ẹ̀. Ìgbà kan ti wà táwọn aràn inú mi ń kùn nítorí ebi, àmọ́ kò sígbà tí mi kì í fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bọ́ ọkàn mi. Jèhófà sì ti sọ mí dalágbára. “Àsọjáde [tirẹ̀] ti pa mí mọ́ láàyè.”—Sáàmù 119:50.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ka ìtàn ìgbésí ayé Jean Queyroi, nínú Ilé Ìṣọ́nà October 1, 1989, ojú ìwé 22 sí 26.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Albin Relewicz, ọ̀rẹ́ mi ọ̀wọ́n rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Maryse Anasiak nìyí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22]

Bíbélì tí mi ò torí ẹ̀ jẹun fún ọ̀sẹ̀ kan rèé

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Èmi àti Tina rèé lọ́dún 1946, ká tó ṣègbéyàwó

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Jean Queyroi àti Titica, ìyàwó ẹ̀ rèé