Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìtàn
Ọjọ́ Tó Ṣe Pàtàkì Jù Lọ Nínú Ìtàn
Ọjọ́ tí Jésù Kristi kú ni. Kí nìdí tí ikú Jésù fi ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀? Jẹ́ ká gbé àwọn ìdí mélòó kan yẹ̀ wò.
Bí Jésù ṣe jẹ́ olóòótọ́ títí dójú ikú jẹ́ ká mọ̀ pé èèyàn lè jólóòótọ́ sí Ọlọ́run.
Ikú Kristi tún máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fáwọn kan láti ṣàkóso pẹ̀lú Jésù lọ́run. Ó sì tún máa jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ọ̀pọ̀ èèyàn láti gbádùn ìwàláàyè títí láé nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.
Lálẹ́ ọjọ́ tó ṣáájú ọjọ́ tí Jésù kú, ó fi àkàrà aláìwú àti wáìnì pupa ṣàpẹẹrẹ ikú ìrúbọ tó fẹ́ kú nítorí ìfẹ́ tó ní sí wa. Ó wá sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ẹ máa ṣe èyí ní ìrántí mi.” (Lúùkù 22:19) Ṣé wàá fẹ́ láti ṣèrántí ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tí Jésù ni ká máa ṣe yìí?
Tọ̀yàyàtọ̀yàyà làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi pè ẹ́ wá sí Ìrántí Ikú Kristi. Lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ lọ́jọ́ Thursday, April 9, la máa ṣe tọdún yìí. O lè lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò ẹ láti ṣèrántí ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Jọ̀wọ́ béèrè ibi tí wọ́n ti máa ṣe é àti àkókò tí wọ́n máa ṣe é lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò rẹ̀.