Iṣẹ́ Ìwàásù àti Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Nílẹ̀ Áfíríkà
Iṣẹ́ Ìwàásù àti Ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ Nílẹ̀ Áfíríkà
Iye Ilẹ̀: 57
Iye Èèyàn: 848,582,269
Iye Ẹlẹ́rìí Jèhófà: 1,122,493
Àwọn Tá À Ń Kọ́ Lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì: 2,202,217
ỌDỌỌDÚN làwọn èèyàn máa ń kà nípa ìsapá táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa ń ṣe láti jẹ́ káwọn èèyàn mọ Jèhófà Ọlọ́run kí wọ́n sì nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Iye ilẹ̀ tá a ti wàásù dé báyìí ò kéré rárá, ọwọ́ pàtàkì tá a sì fi ń mú iṣẹ́ náà kọjá àfẹnusọ. Kò sí àjọ èyíkéyìí tó lè máa sanwó fún ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn kí wọ́n lè gbé ìsọfúnni èyíkéyìí sétí àwọn èèyàn tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ kárí ayé. Síbẹ̀, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ò ronú àtirí towó ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìkọ́nilẹ́kọ̀ọ́ tá à ń ṣe. Ìtọ́ni tí Jésù fáwọn ọmọlẹ́yìn ẹ̀ ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] ọdún la fi ń ṣèwà hù, Jésù ní: “Ọ̀fẹ́ ni ẹ̀yin gbà, ọ̀fẹ́ ni kí ẹ fúnni.” (Mátíù 10:8) Àwọn ìrírí tó o máa bẹ̀rẹ̀ sí í kà báyìí jẹ́ ká mọ̀ pé ohun táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ṣe gan-an nìyẹn.
Rùwáńdà Nígbà tọ́mọbìnrin kan tí ò ju ọmọ ọdún mẹ́sàn-án lọ ń bọ̀ láti iléèwé, ó rí báàgì kékeré kan tówó pọ̀ gan-an nínú ẹ̀ lójú ọ̀nà. Àwọn òbí ọmọbìnrin yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì pinnu láti fohun tí wọ́n ti kọ́ látinú Bíbélì lórí ọ̀ràn yìí ṣèwà hù. Torí náà, wọ́n wá ọkùnrin tó lowó náà lọ, wọ́n sì dá owó ẹ̀ pa dà fún un. Ọkùnrin tó lowó náà béèrè lọ́wọ́ ọmọbìnrin yẹn pé: “Tí mo bá fún ẹ lówó torí ìwà ọmọlúwàbí tó o hù yìí, kí lo máa fi ṣe?”
Ọmọbìnrin náà sọ pé: “Bíbélì ni màá fi rà.”
Ohun tó sọ ya ọkùnrin náà lẹ́nu débi tó fi sọ pé: “Mo rò pé aṣọ àti bàtà ló yẹ kó o fi rà torí mo rí i pé èyí tó o wọ̀ yìí ti gbó gan-an.” Ọmọbìnrin náà ò yí ìpinnu ẹ̀ pa dà pé Bíbélì lòun máa fowó náà rà. Ọkùnrin náà fẹ́ mọ ìdí táwọn òbí ọmọ náà ò fi ná owó yẹn. Lẹ́yìn tó gbọ́ pé wọ́n ti ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọkùnrin náà lọ ra Bíbélì méjì, ó fún ọmọbìnrin tó bá a rówó náà níkan, òun, ìyàwó àtàwọn ọmọ ẹ̀ sì ń lo èkejì. Ó sì tún ṣètò pé káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa wá kọ́ òun àti ìdílé òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ìdílé méjèèjì ń tẹ̀ síwájú dáadáa nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì wọn.
Madagásíkà Alábòójútó àyíká kan àtìyàwó ẹ̀ ń lọ bẹ ìjọ kan wò lábúlé kan. a Ojú ọ̀nà ni wọ́n wà nígbà tí wọ́n pàdé àwọn olè tó máa ń jí màlúù kó, àwọn olè wọ̀nyẹn sì mú àáké àti lẹ́bẹ́ dání. Lẹ́yìn tíyàwó alábòójútó àyíká yìí ti fọkàn gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fún òun nígboyà, ó na ẹ̀dà ìwé pélébé kan, tá a pe àkòrí ẹ̀ ní Igbesi-aye ninu Aye Titun alalaafia kan, sáwọn olè yẹn. Ó wá sọ pé: “Ṣẹ́ ẹ mọ̀ pé ẹ̀rù máa ń ba àwọn èèyàn gan-an láyé tá a wà yìí, àmọ́ Ọlọ́run máa tó pa àwọn èèyàn búburú run, ó sì máa ṣètò ayé tuntun kan níbi tí àlàáfíà ti máa jọba.” Ọ̀kan lára àwọn ọkùnrin yẹn fetí sílẹ̀, ó sì gba ìwé pélébé náà.
Ọdún kan lẹ́yìn náà, nígbà tíyàwó alábòójútó àyíká yẹn lọ sí àpéjọ kan táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe, ọkùnrin kan wá bá a, ó sì béèrè bóyá ó rántí ojú òun. Ó sọ fún ìyàwó alábòójútó
àyíká náà pé òún wà lára àwọn olè tí wọ́n pàdé lọ́nà lọ́jọ́ yẹn, òun sì lòún gba ìwé pélébé yẹn lọ́wọ́ ẹ̀. Ó wá ṣàlàyé pé: “Ibi tá a ti lọ jí màlúù kó la ti ń bọ̀ lọ́jọ́ yẹn. Àwọn ọ̀rọ̀ tẹ́ ẹ sọ lọ́jọ́ yẹn mú mi ronú gan-an. Mo sọ fún ara mi pé: ‘A ò bẹ̀rù àwọn ọlọ́pàá àtàwọn ṣọ́jà torí pé a lè bọ́ mọ́ wọn lọ́wọ́. Àmọ́, báwo ni màá ṣe bọ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run nígbà tó bá fẹ́ pa àwọn èèyàn búburú run?’ Torí náà mo pinnu láti mọ púpọ̀ sí i. Nígbà tí mo délé, mo lọ sọ́dọ̀ aládùúgbò mi kan tí ọ̀kan lára àwọn ará yín, tó máa ń lo àkókò púpọ̀ láti wàásù, ń kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Mo ṣètò pé kó máa kọ́ èmi náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, mo sì máa ṣèrìbọmi ní àpéjọ yìí.”Mòsáńbíìkì Lọ́dún 1992, obìnrin kan tó ń jẹ́ Madalena, tó lé díẹ̀ lọ́mọ ọgbọ̀n [30] ọdún, fara pa nínú jàǹbá ọkọ̀, bó ṣe darọ nìyẹn, tó sì wá ṣòro fún un láti jáde nílé. Ọdún mẹ́ta lẹ́yìn náà, ọ̀kan lára àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá bàbá ẹ̀ sọ̀rọ̀ níwájú ìta ilé wọn. Bàbá Madalena ni olórí àwọn ẹlẹ́sìn ìbílẹ̀ kan ládùúgbò náà, ẹ̀yìnkùlé wọn ni wọ́n sì ti máa ń ṣèpàdé. Nígbà tí Madalena gbọ́ ohun tí Ẹlẹ́rìí náà bá bàbá ẹ̀ sọ, tó sì tún gbọ́ pé Ẹlẹ́rìí náà béèrè òun, ó ní kí wọ́n wọlé. O ò rí bínú ẹ̀ ṣe máa dùn tó láti mọ̀ pé wọ́n fẹ́ràn òun lóòótọ́! Ó gbà pé kí wọ́n máa kọ́ òun lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í fàwọn nǹkan tó ń kọ́ ṣèwà hù. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí náà rí ìtara Madalena, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe ọ̀pọ̀ nǹkan láti ràn án lọ́wọ́, ìyẹn sì kan gbígbé e lọ sáwọn ìpàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ìrànlọ́wọ́ táwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ṣe fún Madalena jẹ́ kó ṣeé ṣe fún un láti ya ìgbésí ayé ara ẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà, ó sì ṣèrìbọmi lọ́dún 2002.
Báwọn Ẹlẹ́rìí wọ̀nyí ṣe ń ṣètọ́jú Madalena wú àwọn òbí ẹ̀ lórí gan-an. Màmá ẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í wá sípàdé àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì pa ẹ̀sìn ìbílẹ̀ tọ́kọ ẹ̀ ń ṣe tì. Bàbá Madalena kọ́kọ́ fàáké kọ́rí, ó lóun ò lè fẹ̀sìn òun sílẹ̀, àmọ́ nígbà tó yá, òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í wá sáwọn ìpàdé wa. Àwọn tí wọ́n jọ ń ṣẹ̀sìn bẹ̀rẹ̀ sí í yọ́ ọ lẹ́nu, ó ṣe tán, òun ni olórí wọn! Àmọ́ kò yí ìpinnu ẹ̀ pa dà, kódà gbogbo àwọn nǹkan tó fi ń bọ òòṣà tẹ́lẹ̀ ló dáná sun. Nígbà tó sì di ọdún 2007, òun àtìyàwó ẹ̀ ṣèrìbọmi. Ní báyìí, ìdílé yẹn ń tẹ̀ síwájú nínú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run.
Sìǹbábúwè Ọmọ ọdún mẹ́sàn-án kan tó ń jẹ́ Decibel wàásù fáwọn ọmọ kíláàsì àtàwọn tíṣà ẹ̀. Lọ́jọ́ kan, Decibel ṣàkíyèsí pé inú tíṣà òun ò dùn, torí náà ó lọ béèrè ohun tó fà á. Tíṣà ẹ̀ sọ fún un pé ọmọ ẹ̀gbọ́n òun obìnrin ló ṣaláìsí. Decibel ṣèlérí fún tíṣà náà pé òun á mú nǹkan kan wá fún un tó máa tù ú nínú. Nígbà tó sì délé, ó gba ìwé Nígbà Tí Ẹnìkan Tí Ìwọ Fẹ́ràn Bá Kú lọ́wọ́ àwọn òbí ẹ̀, ó sì mú un lọ fún tíṣà ẹ̀ lọ́jọ́ kejì. Lẹ́yìn tí tíṣà náà ka àwọn ìpínrọ̀ bíi mélòó kan nínú ìwé náà, ńṣe ni omijé ayọ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í dà lójú ẹ̀. Nígbà tó yá, ó kọ lẹ́tà sáwọn òbí Decibel láti dúpẹ́ lọ́wọ́ wọn fún bí wọ́n ṣe tọ́ ọmọ wọn, ó sì ṣàlàyé bí Decibel ṣe tu òun nínú nígbà tóun soríkọ́.
Gánà Olórí ìsìn làwọn òbí màmá Abigail, ọ̀dọ́ wọn ni Abigail ń gbé lápá gúúsù orílẹ̀-èdè Gánà, wọ́n sì ti kọ́ ọ pé wòlíì èké làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó gbọ́ pé àwọn òbí òun tí wọ́n ń gbé lágbègbè míì lórílẹ̀-èdè náà ti ń kẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó dùn-ún gan-an ó sì kọ lẹ́tà láti sọ fún wọn pé kí wọ́n jáwọ́ nínú ìkẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n ń ṣe. Nígbà tó rí i pé wọn ò torí lẹ́tà tóun kọ dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn dúró, ó rìnrìn àjò tó tó nǹkan bíi ẹgbẹ̀rún kan [1,000] kìlómítà láti lọ bá wọn. Ó ya Abigail lẹ́nu gan-an nígbà tó kà á nínú Bíbélì tiẹ̀ fúnra ẹ̀ pé hẹ́ẹ̀lì kì í ṣe ibi tí Ọlọ́run ti máa dá àwọn èèyàn burúkú lóró. Òun náà bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ó ń tẹ̀ lé àwọn òbí ẹ̀ lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò wọn, nígbà tó sì yá ó di àkéde tí ò tíì ṣèrìbọmi. Abigail ti ṣèrìbọmi ní àpéjọ àyíká kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe ládùúgbò náà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Òjíṣẹ́ tó máa ń ṣèbẹ̀wò sáwọn ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ kó lè jáde ìwàásù pẹ̀lú wa, la máa ń pè ní Alábòójútó àyíká.