Igi Kan ‘tí Àwọn Ẹ̀ka Rẹ̀ Eléwé Kì Í Rọ’
Igi Kan ‘tí Àwọn Ẹ̀ka Rẹ̀ Eléwé Kì Í Rọ’
ṢÓ O ti lọ sábúlé kan rí, tó o sì rí táwọn igi tó tutù yọ̀yọ̀ tò lọ lọ́wọ̀ọ̀wọ́? Kò sí àní-àní pé wàá gbà pé irú ìran bẹ́ẹ̀ máa ń tuni lára láti wò. Tó o bá ráwọn igi ràbàtà, tó léwé dáadáa tó sì tutù yọ̀yọ̀, ó dájú pé o ò ní ronú pé òjò kì í rọ̀ ládùúgbò yẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, wàá mọ̀ pé omi tó pọ̀ gbọ́dọ̀ wà níbì kan tó ń mú káwọn igi náà léwé lórí, kí wọ́n sì tutù yọ̀yọ̀.
Ó bá a mu wẹ́kú nígbà náà, pé Bíbélì fàwọn tó nígbàgbọ́ tó lágbára tí wọ́n sì ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú Ọlọ́run wé igi ràbàtà kan, tó láwọn ewé tó tutù yọ̀yọ̀. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó fani lọ́kàn mọ́ra tó wà nínú ẹsẹ mẹ́ta àkọ́kọ́ nínú ìwé Sáàmù yẹ̀ wò:
“Aláyọ̀ ni ènìyàn tí kò rìn nínú ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú, tí kò sì dúró ní ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀, tí kò sì jókòó ní ìjókòó àwọn olùyọṣùtì. Ṣùgbọ́n inú dídùn rẹ̀ wà nínú òfin Jèhófà, ó sì ń fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin rẹ̀ tọ̀sán-tòru. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá àwọn ìṣàn omi, tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀ èyí tí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé kì í sì í rọ, gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”
Ìwé Jeremáyà 17:7, 8 tún sọ pé: “Ìbùkún ni fún abarapá ọkùnrin tí ó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, ẹni tí Jèhófà di ìgbọ́kànlé rẹ̀. Dájúdájú, òun yóò dà bí igi tí a gbìn sẹ́bàá omi, tí ó na gbòǹgbò rẹ̀ tààrà lọ sẹ́bàá ipadò; òun kì yóò sì rí i nígbà tí ooru bá dé, ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀ka rẹ̀ eléwé yóò di èyí tí ó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ ní ti gidi. Ní ọdún ọ̀gbẹlẹ̀, òun kì yóò sì ṣàníyàn, bẹ́ẹ̀ sì ni kì yóò dẹ́kun mímú èso jáde.”
Nínú àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ méjèèjì tá a gbé yẹ̀ wò yìí, igi ni Bíbélì fi ṣàpèjúwe bí nǹkan ṣe máa ń rí fáwọn tó ń ṣe nǹkan lọ́nà tó tọ́, tí inú wọn máa ń dùn láti pa àwọn òfin Ọlọ́run mọ́, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e látòkèdélẹ̀. A wá lè béèrè pé, Báwo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ ṣe dà bí igi tó léwé tó tutù yọ̀yọ̀ tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run? Jẹ́ ká fara balẹ̀ gbé àwọn ẹsẹ wọ̀nyẹn yẹ̀ wò dáadáa.
“Igi Tí A Gbìn Sẹ́bàá Àwọn Ìṣàn Omi”
Ẹ̀gbẹ́ “àwọn ìṣàn omi” tàbí ìtòsí “omi” ni wọ́n gbin àwọn igi tó wà nínú àwọn àpèjúwe yẹn sí, kì í ṣe ẹ̀gbẹ́ odò kan tàbí ìṣàn omi kan. Àpèjúwe tó jọ èyí ni Jèhófà lò nígbà tó ń sọ̀rọ̀ nípa bóun ṣe máa bìkítà fáwọn Júù tó pa dà wálé láti ìgbèkùn Bábílónì lẹ́yìn tí wọ́n ti ronú pìwà dà. Jèhófà tipasẹ̀ wòlíì Áísáyà sọ ohun tó wà nínú ìwé Áísáyà 44:3, 4, pé: “Nítorí pé èmi yóò da omi sára ẹni tí òùngbẹ ń gbẹ, àti àwọn odò kéékèèké tí ń ṣàn sórí ibi gbígbẹ. . . . Ṣe ni wọn yóò sì rú yọ bí ẹni pé láàárín koríko tútù, bí àwọn igi pọ́pílà tí ń bẹ lẹ́bàá àwọn kòtò omi.” Nínú àpèjúwe yìí náà, “àwọn odò” àti “àwọn kòtò omi” ló máa jẹ́ káwọn tó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rí ìbùkún bí igi pọ́pílà.
Láwọn àgbègbè táwọn èèyàn ti ń ṣọ̀gbìn lónìí pàápàá, a máa ń ráwọn kòtò omi àtàwọn ìṣàn omi tó máa ń ṣàn látára àwọn ibú omi bíi kàǹga tó jìn, odò, adágún tàbí ìsédò. Àwọn orísun omi wọ̀nyí wà lára ọ̀nà táwọn èèyàn gbà ń bomi rin oko nígbà ọ̀gbìn. Nígbà míì, abẹ́ àwọn igi eléso
gan-an làwọn omi wọ̀nyí máa ń tú jáde sí. Láwọn ìgbà míì sì rèé, àwọn ìṣàn omi náà máa ń bomi rin koríko lápá kan tí wọ́n á sì bomi rin àwọn igi eléwe lódì kejì, wọ́n á sì wá tipa bẹ́ẹ̀ pààlà sóko méjèèjì.Kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ sáwọn igi táwọn èèyàn bá gbìn sétí àwọn ìṣàn omi? Sáàmù 1:3 sọ̀rọ̀ nípa igi kan “tí ń pèsè èso tirẹ̀ ní àsìkò rẹ̀.” Láwọn ilẹ̀ tí wọ́n ti kọ Bíbélì, àwọn èèyàn máa ń gbin igi ọ̀pọ̀tọ́, pómégíránétì, igi ápù, ọ̀pẹ déètì àti igi ólífì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé igi ọ̀pọ̀tọ́ máa ń ga tó pẹ̀tẹ́ẹ̀sì alájà méjì táwọn ẹ̀ka ẹ̀ tó rúwé dáadáa á sì nawọ́ síta, èyí tó pọ̀ jù lára àwọn igi eléso míì kì í ga tóyẹn. Síbẹ̀, wọ́n máa ń gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, wọ́n máa ń rúwé tó tutù yọ̀yọ̀, wọ́n sì máa ń sèso tó pọ̀ gan-an lásìkò tó yẹ.
Láyè ọjọ́un, àwọn igi pọ́pílà tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ máa ń lalẹ̀ hù létí àwọn odò àtàwọn ìṣàn omi ní Síríà àti Palẹ́sìnì. Tí Bíbélì bá ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn igi pọ́pílà, ó sábà máa ń ní í ṣe pẹ̀lú ibú omi tàbí àwọn “ọ̀gbàrá.” (Léfítíkù 23:40) Àwọn igi pankẹ́rẹ́, tó fara jọ igi pọ́pílà máa ń lalẹ̀ hù níbi tómi bá pọ̀ sí. (Ìsíkíẹ́lì 17:5) Àwọn igi tó gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀, tó sì máa ń rúwé tó tutù yọ̀yọ̀ wọ̀nyí ṣàpẹẹrẹ ohun tí onísáàmù yẹn àti Jeremáyà fẹ́ ká lóye, ìyẹn sì ni pé gbogbo àwọn to ti pinnu láti máa ṣègbọràn sáwọn òfin Ọlọ́run, tí wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e látòkèdélẹ̀ ló máa gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ nípa tẹ̀mí, ‘gbogbo nǹkan tí wọ́n bá sì dáwọ́ lé ló máa kẹ́sẹ járí.’ Ṣé ohun tí gbogbo wa ń gbàdúrà fún náà kọ́ nìyẹn, pé kí ìgbésí ayé wa kẹ́sẹ járí?
Bó O Ṣe Lè Fẹ́ràn Òfin Jèhófà
Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀nà làwọn èèyàn gbà ń wá oríire nínú ayé lónìí. Àwọn nǹkan tó lè sọ wọ́n dọlọ́rọ̀ lọ́sàn-án kan òru kan, tí wọ́n á sì gbajúmọ̀ bí ìṣáná ẹlẹ́ẹ̀ta ni wọ́n máa ń lé kírí, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà ọwọ́ kì í tẹ ohun tí wọ́n ń wá, ìjákulẹ̀ ló sì máa ń jẹ́ fún wọn. Kí ló wá lè fún èèyàn ní ojúlówó ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀ tó máa tọ́jọ́ nígbèésí ayé? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí wà nínú ìwàásù tí Jésù ṣe lórí òkè. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni àwọn tí àìní wọn nípa ti ẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn, níwọ̀n bí ìjọba ọ̀run ti jẹ́ tiwọn.” (Mátíù 5:3) Ká sòótọ́, ayọ̀ tòótọ́ ò sí nídìí ká máa fi gbogbo ọjọ́ ayé wa kó nǹkan ìní jọ, ṣùgbọ́n a lè rí ayọ̀ tòótọ́ tá a bá mọ ohun tá a nílò tó bá dọ̀rọ̀ ìjọsìn Ọlọ́run, tá a sì ń gbìyànjú láti bójú tó àìní náà, ìgbà yẹn la tó lè jéèyàn nípa tẹ̀mí bíi ti igi eléwé tútù yọ̀yọ̀ tó ń mú èso jáde lákòókò tó bẹ́tọ̀ọ́ mu. Báwo wá la ṣe lè ṣàṣeyọrí nípa tẹ̀mí?
Bó ṣe wà nínú ọ̀rọ̀ onísáàmù yẹn, àwọn nǹkan kan wà tá ò gbọ́dọ̀ ṣe. Ó sọ̀rọ̀ nípa “ìmọ̀ràn àwọn ẹni burúkú,” “ọ̀nà àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀,” àti “ìjókòó àwọn olùyọṣùtì.” Tá a bá fẹ́ láyọ̀, a ò gbọ́dọ̀ máa báwọn tó ń ṣá òfin Ọlọ́run tì tàbí àwọn tó ń bẹnu àtẹ́ lu àwọn òfin Ọlọ́run rìn.
Yàtọ̀ síyẹn, a tún gbọ́dọ̀ fẹ́ràn òfin Jèhófà. Ó dájú pé tá a bá fẹ́ràn ohun kan, ńṣe la máa ń wá gbogbo ọ̀nà láti ṣe é. Torí náà, tá a bá nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run lóòótọ́, a gbọ́dọ̀ mọyì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì ṣe tán láti kọ́ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀ ká lè túbọ̀ lóye ẹ̀ dáadáa.
Èyí tó wá gbẹ̀yìn ni pé ká máa “fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ ka òfin [Ọlọ́run] tọ̀sán-tòru.” Ìyẹn túmọ̀ sí pé ká máa ka Bíbélì déédéé, ká sì máa ṣàṣàrò lórí àwọn nǹkan tá a bá kà. Bí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe rí lára onísáàmù yìí ló yẹ kó rí lára tiwa náà, ó sọ pé: “Mo mà nífẹ̀ẹ́ òfin rẹ o! Òun ni mo fi ń ṣe ìdàníyàn mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀.”—Sáàmù 119:97.
Tá a bá gba ìmọ̀ tó pé nípa Jèhófà Ọlọ́run, tá a mọ irú ẹni tó jẹ́, tá a nígbàgbọ́ nínú ẹ̀, tá a sì gbẹ́kẹ̀ lé àwọn ìlérí ẹ̀, ó dájú pé àwa náà máa ṣàṣeyọrí nípa tẹ̀mí. Tá a bá ṣe bẹ́ẹ̀, àwa náà máa dà bí ọkùnrin aláyọ̀ tí onísáàmù yẹn ṣàpèjúwe pé, “gbogbo nǹkan tí ó bá ń ṣe ni yóò sì máa kẹ́sẹ járí.”