“Mo Mọ Ìrora Tí Wọ́n Ń Jẹ Ní Àmọ̀dunjú”
Sún Mọ́ Ọlọ́run
“Mo Mọ Ìrora Tí Wọ́n Ń Jẹ Ní Àmọ̀dunjú”
“MÍMỌ́, mímọ́, mímọ́ ni Jèhófà.” (Aísáyà 6:3) Àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí wọ̀nyí jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run mọ́ látòkè délẹ̀, kò sì lábààwọ́n kankan. Ó lè máa wá ṣe ẹ́ bíi pé, ‘Ṣé Ọlọ́run tó mọ́ látòkè délẹ̀ yìí lè gbà ká sún mọ́ òun?’ ‘Ṣé Ọlọ́run tó mọ́ tó yìí á lè bìkítà nípa èmi ẹlẹ́ṣẹ̀ àti aláìpé lóòótọ́?’ Jẹ́ ká gbé àwọn ọ̀rọ̀ tó ń fọkàn ẹni balẹ̀ tí Ọlọ́run sọ fún Mósè nínú ìwé Ẹ́kísódù 3:1-10 yẹ̀ wò.
Lọ́jọ́ kan, nígbà tí Mósè ń bójú tó àwọn àgùntàn, ó rí ohun àràmérìíyìírí kan, ó rí iná lára igi ẹlẹ́gùn-ún kan àmọ́ igi ẹlẹ́gùn-ún náà ‘kò jó.’ (Ẹsẹ 2) Ó sún mọ́ igi tíná bò náà kó lè mohun tó fà á. Jèhófà lo ọ̀kan lára àwọn áńgẹ́lì láti bá Mósè sọ̀rọ̀ láti àárín igi tíná wá lára ẹ, ó sọ pé: “Má ṣe sún mọ́ ìhín. Bọ́ sálúbàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí pé ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí ìwọ dúró sí.” (Ẹsẹ 5) Rò ó wò ná, torí pé igi tíná ń jó lára ẹ̀ náà fi hàn pé Ọlọ́run mímọ́ wà nítòsí, ilẹ̀ ibi tí igi náà wà di mímọ́!
Ó nídìí tí Ọlọ́run mímọ́ fi bá Mósè sọ̀rọ̀. Ọlọ́run sọ pé: “Láìsí tàbí-ṣùgbọ́n, mo ti rí ṣíṣẹ́ tí a ń ṣẹ́ àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ní Íjíbítì níṣẹ̀ẹ́, mo sì ti gbọ́ igbe ẹkún wọn nítorí àwọn tí ń kó wọn ṣiṣẹ́; nítorí tí mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” (Ẹsẹ 7) Ọlọ́run rí gbogbo ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ń gbọ́ igbe ẹ̀bẹ̀ wọn. Ó mọ ìyà tó ń jẹ wọ́n lára. Kíyè sóhun tí Ọlọ́run sọ, ó ní: “Mo mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú.” Nígbà tí ìwé kan ń ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run lò nínú ẹsẹ yìí, ìyẹn sísọ tó sọ pé òun mọ ìrora wọn “ní àmọ̀dunjú,” ó ní: “Ọ̀rọ̀ yìí ní í ṣe pẹ̀lú fífi ọ̀ràn ẹnì kan rora ẹni wò, fífọwọ́ jẹ̀lẹ́ńkẹ́ mú nǹkan àti fífi ìyọ́nú hàn séèyàn.” Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jèhófà sọ fún Mósè yìí jẹ́ ká mọ̀ pé ó bìkítà nípa àwọn èèyàn rẹ̀, ó sì ní ire wọn lọ́kàn.
Kí ni Ọlọ́run máa ṣe? Ọlọ́run ò kàn ní máa wò wọ́n, kó káàánú wọn tàbí kó kàn máa gbọ́ àdúrà wọn pẹ̀lú ìyọ́nú. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló wá nǹkan ṣe sọ́ràn náà. Ó pinnu láti gba àwọn èèyàn ẹ̀ sílẹ̀ lọ́wọ́ àwọn ará Íjíbítì, kó sì mú wọn wá “sí ilẹ̀ kan tí ń ṣàn fún wàrà àti oyin.” (Ẹsẹ 8) Kí Ọlọ́run lè mú ìpinnu ẹ̀ ṣẹ, ó yanṣẹ́ kan fún Mósè, ó sọ fún un pé: “Mú àwọn ènìyàn mi . . . kúrò ní Íjíbítì.” (Ẹsẹ 10) Nítorí pé Mósè káràmáásìkí iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un, ó kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì lọ́dún 1513 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
Jèhófà ò tíì yí pa dà. Ó yẹ kó dá àwọn tó ń jọ́sìn rẹ̀ lónìí lójú pé ó ń rí bí ipò nǹkan ò ṣe fara rọ fún wọn, ó sì ń gbọ́ igbe wọn fún ìrànlọ́wọ́. Ó mọ ìrora tí wọ́n ń jẹ ní àmọ̀dunjú. Àmọ́, Jèhófà ò kàn ní wulẹ̀ káàánú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ o. Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ ti pinnu láti ràn wọ́n lọ́wọ́ “nítorí ó bìkítà” nípa wọn.—1 Pétérù 5:7.
Ìyọ́nú Ọlọ́run jẹ́ ká nírètí pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, àwa èèyàn aláìpé lè máa hùwà níbàámu pẹ̀lú ìlànà òdodo rẹ̀ tó jẹ́ mímọ́, ìyẹn sì lè jẹ́ kí Ọlọ́run yọ́nú sí wa. (1 Pétérù 1:15, 16) Ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Mósè níbi tíná ti ń jó lára igi ẹlẹ́gùn-ún yẹn tu obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni nínú, torí pé ọjọ́ pẹ́ tó ti ń bá ẹ̀dùn ọkàn àti ìsoríkọ́ yí. Obìnrin náà sọ pé: “Tí Jèhófà bá lè sọ ilẹ̀ tó dọ̀tí di mímọ́, á jẹ́ pé tèmi náà ṣì lè dáa nìyẹn. Ríronú lọ́nà yìí ti ràn mí lọ́wọ́ gan-an ni.”
Ṣé wàá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa Ọlọ́run mímọ́ tó ń jẹ́ Jèhófà? O lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, nítorí pé ó “mọ ẹ̀dá wa, ó rántí pé [iyẹ̀pẹ̀] ni wá.”—Sáàmù 103:14.