Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Aláṣẹ Ìjọ Kátólíìkì Fẹ́ Pa Orúkọ Ọlọ́run Rẹ́

Àwọn Aláṣẹ Ìjọ Kátólíìkì Fẹ́ Pa Orúkọ Ọlọ́run Rẹ́

Àwọn Aláṣẹ Ìjọ Kátólíìkì Fẹ́ Pa Orúkọ Ọlọ́run Rẹ́

ÀWỌN aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ò fẹ́ káwọn ọmọ ìjọ wọn máa lo orúkọ Ọlọ́run mọ́ nígbà tí wọ́n bá ń ṣèsìn. Lọ́dún tó kọjá, ìgbìmọ̀ àwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì tó ń bójú tó ìjọsìn àtọ̀runwá àtàwọn ọ̀rọ̀ tó jẹ mọ́ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa fi ìsọfúnni lórí lílo orúkọ Ọlọ́run ránṣẹ́ síbi àpérò kan táwọn bíṣọ́ọ̀bù ìjọ náà ṣe kárí ayé. Póòpù ló sì ‘fún wọn láṣẹ’ láti fi ìsọfúnni yìí ránṣẹ́.

Ọjọ́ kọkàndínlọ́gbọ̀n [29] oṣù June, ọdún 2008 ni déètì tó wà lórí ìsọfúnni yẹn, àṣẹ tó sì wà níbẹ̀ sọ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìtọ́ni ti wà pé káwọn èèyàn má máa pe orúkọ Ọlọ́run, “àwọn kan tún ti bẹ̀rẹ̀ sí í pe orúkọ Ọlọ́run Ísírẹ́lì lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ìyẹn àwọn lẹ́tà mímọ́ mẹ́rin, tí wọ́n máa ń kọ báyìí: יהוה, YHWH, lédè Hébérù.” Ìsọfúnni yìí tún jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé lára onírúurú ọ̀nà tí wọ́n ti gbà pe orúkọ Ọlọ́run ni “Yahweh,” “Yahwè,” “Jahweh,” “Jahwè,” “Jave,” “Yehovah,” àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. a Àmọ́, ìtọ́ni táwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì gbé jáde yìí fi hàn pé, ńṣe ni wọ́n fẹ́ káwọn ọmọ ìjọ wọn tún pa dà máa ṣohun tí ìjọ Kátólíìkì ti ń ṣe látẹ̀yìn wá. Ìyẹn ni pé kí wọ́n fi “Olúwa” rọ́pò orúkọ Ọlọ́run. Torí náà, àwọn ọmọ ìjọ wọn “ò gbọ́dọ̀ lo” orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn “YHWH, tàbí kí wọ́n pe” orúkọ yẹn nígbà tí wọ́n bá ń jọ́sìn, tí wọ́n bá ń kọrin ìsìn tàbí tí wọ́n bá ń gbàdúrà.

Ohun tó wà nínú ìtọ́ni táwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì gbé jáde yìí bá “àṣà àtọdúnmọ́dún” tó ti wà nínú ìjọ náà mu. Nínú ìtọ́ni yẹn, àwọn aláṣẹ wọ̀nyẹn ṣàwáwí pé nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù, ní ìtumọ̀ ti Septuagint, tó ti wà ṣáájú kí wọ́n tó dá ẹ̀sìn Kristẹni sílẹ̀ pàápàá, “Olúwa,” ìyẹn Kyʹri·os, lédè Gíríìkì, ni wọ́n lò ní gbogbo ibi tí orúkọ Ọlọ́run ti fara hàn. Wọ́n wá tẹnu mọ́ ọn nínú ìtọ́ni yẹn pé, “àwọn Kristẹni pàápàá kì í pe orúkọ Ọlọ́run tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀.” Àmọ́, ohun tí wọ́n sọ yìí ta ko ẹ̀rí tí ò ṣe é já ní koro tó wà pé orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn יהוה, ló wà nínú àwọn ìtumọ̀ Bíbélì Septuagint tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe, kì í ṣe Kyʹri·os. Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi, nígbà tí ìsìn Kristẹni kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀, mọ orúkọ Ọlọ́run, wọ́n sì ń pè é. Jésù pàápàá sọ nínú àdúrà tó gbà sí Bàbá rẹ̀ pé: “Mo . . . ti sọ orúkọ rẹ di mímọ̀.” (Jòhánù 17:26) Nínú àdúrà àwòkọ́ṣe, tí ọ̀pọ̀ èèyàn mọ̀ sí àdúrà Olúwa, Jésù kọ́ wa pé ká máa gbàdúrà pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́.”—Mátíù 6:9.

Ó yẹ kí gbogbo ẹni tó bá jẹ́ Kristẹni máa fẹ́ láti sọ orúkọ Ọlọ́run di mímọ́. Báwọn aláṣẹ ìjọ Kátólíìkì ṣe ń fẹ́ láti pa orúkọ yìí rẹ́ ò fọ̀wọ̀ hàn fun Jèhófà, ẹni tó sọ pé: “Èyí ni orúkọ mi nígbà gbogbo; orúkọ yìí sì làwọn èèyàn á fi mọ̀ mí láti ìran dé ìran.”—Ẹ́kísódù 3:15, ìtumọ̀ The Jerusalem Bible.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti mọ orúkọ Ọlọ́run sí “Jèhófà” lédè Yorùbá, bó sì ṣe wà nínú ọ̀pọ̀ Bíbélì nìyẹn.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 30]

“Èyí ni orúkọ mi nígbà gbogbo.”—Ẹ́kísódù 3:15, ìtumọ̀ The Jerusalem Bible

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Àjákù Bíbélì Septuagint tí wọ́n ti ń lò látìgbà tí ẹ̀sìn Kristẹni ti bẹ̀rẹ̀. Lẹ́tà èdè Hébérù mẹ́rin, tọ́pọ̀ èèyàn wá mọ̀ sí YHWH, tó dúró fún orúkọ Ọlọ́run ló wà nínú àkámọ́ yẹn

[Credit Line]

Látọwọ́ Egypt Exploration Society