Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú

Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Ó Kọ́ Béèyàn Ṣe Lè Jẹ́ Aláàánú

JÓNÀ ní àkókò tó pọ̀ tó láti ronú lórí ohun tó fẹ́ ṣe. Ó ní láti rìnrìn àjò tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́jọ [800] kìlómítà. Nǹkan bí oṣù kan gbáko tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ ló sì máa lò tó bá máa fẹsẹ̀ rìn débẹ̀. Ó ní láti kọ́kọ́ pinnu ọ̀nà tó máa gbà, bóyá kó gba àwọn ọ̀nà ibi tí kò jìn àmọ́ tó léwu tàbí kó gba ọ̀nà tó jìn tó sì máa fi í lọ́kàn balẹ̀. Lẹ́yìn ìyẹn lá á ṣẹ̀sẹ̀ wá mú ìrìn àjò ẹ̀ pọ̀n, àìmọye kòtò àti gegele ló sì máa gbà kọjá. Ó máa rìn kọjá ní aṣálẹ̀ tó fẹ̀ lọ salalu lágbègbè Síríà, ó máa la àwọn odò ńláńlá bí odò Yúfírétì kọjá, ọ̀dọ̀ àwọn àjèjì láwọn ìlú àtàwọn abúlé tó wà ní Síríà, Mesopotámíà àti Ásíríà ló sì máa sùn. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, Jónà ń ronú nípa ìlú tó ń bà á lẹ́rù láti lọ yẹn, ìyẹn ìlú Nínéfè, bó sì ṣe ń gbẹ́sẹ̀ kan tẹ̀ lé èkejì ló túbọ̀ ń sún mọ́ ìlú ọ̀hún.

Ohun kan dá Jónà lójú: Kò lè fiṣẹ́ yìí sílẹ̀ kó wá sá mọ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, torí ó ti gbìyànjú ẹ̀ rí. Nígbà tí Jèhófà kọ́kọ́ ní kí Jónà lọ kéde ìdájọ́ òun fáwọn ará Ásíríà tó jẹ́ alágbára láyé ọjọ́un, Jónà ò rò ó lẹ́ẹ̀mejì, òdìkejì ibi tí Ọlọ́run rán an ló gbà lọ. Jèhófà wá mú kí ìjì líle kan jà, ìgbà yẹn ni Jónà wá rí i pé àìgbọ́ràn òun ti fẹ́ mú kí gbogbo àwọn tó wà nínú ọkọ̀ yẹn pàdánù ẹ̀mí wọn. Jónà bá ní kí wọ́n ju òun sínú òkun, káwọn arìnrìn àjò tó wà nínú ọkọ̀ náà má bàa pàdánù ẹ̀mí wọn. Kò wù wọ́n kí wọ́n ju Jónà sókun, àmọ́ ohun tí wọ́n ṣe nìyẹn, Jónà sì wá rò pé ikú òun ti dé nìyẹn. Àmọ́ Jèhófà rán ẹja ńlá kan pé kó lọ gbé Jónà mì kó sì lọ pọ̀ ọ́ sí etíkun lẹ́yìn ọjọ́ mẹ́ta. Nígbà tí ẹja ńlá yẹn máa fi pọ Jónà lọ́jọ́ kẹta, ìbẹ̀rù ọlọ́wọ̀ tí Jónà ní fún Ọlọ́run ti pọ̀ sí i, ó sì wá bẹ̀rẹ̀ sí í gbọ́ràn ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. aJónà, orí 1 àti 2.

Nígbà tí Jèhófà rán Jónà lọ sílùú Nínéfè lẹ́ẹ̀kejì, Jónà ṣègbọràn láìjanpata, ó sì mú ìrìn àjò náà pọ̀n lọ sápá ìlà oòrùn. (Jónà 3:1-3) Àmọ́ ṣé Jónà ti jẹ́ kí ìbáwí tó rí gbà látọ̀dọ̀ Jèhófà yí òun pa dà bó ṣe yẹ? Bí àpẹẹrẹ, Jèhófà ti ṣàánú ẹ̀, kò jẹ́ kí omi gbé e lọ, kò fìyà jẹ ẹ́ torí pé ó ṣàìgbọràn, ó sì tún jẹ́ kó láǹfààní láti lọ jíṣẹ́ òun lẹ́ẹ̀kan sí i. Ṣáwọn nǹkan tí Jèhófà ṣe fún Jónà yìí ti mú kí Jónà kẹ́kọ̀ọ́ láti máa ṣàánú àwọn èèyàn? Kì í sábà rọrùn fáwa èèyàn tá a jẹ́ aláìpé láti kẹ́kọ̀ọ́ bá a ṣe lè jẹ́ aláàánú. Ẹ jẹ́ ká wo àwọn ẹ̀kọ́ tá a lè rí kọ́ látinú ìtàn Jónà.

Ó Kéde Ìdájọ́ àmọ́ Ọ̀rọ̀ Ò Rí Bó Ṣe Rò

Irú ojú tí Jèhófà fi wo àwọn ará Nínéfè kọ́ ni Jónà fi wò wọ́n. Bíbélì sọ pé: “Wàyí o, Nínéfè jẹ́ ìlú ńlá tí ó tóbi lójú Ọlọ́run.” (Jónà 3:3) Ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ nínú ìwé Jónà ni Jèhófà pe ìlú Nínéfè ní “ìlú ńlá títóbi.” (Jónà 1:2; 3:2; 4:11) Kí nìdí tí ìlú yìí fi tóbi tàbí tó fi ṣe pàtàkì lójú Jèhófà?

Ọjọ́ pẹ́ tí ìlú Nínéfè ti wà, ó wà lára àwọn ìlú tí Nímírọ́dù kọ́kọ́ tẹ̀ dó lẹ́yìn Ìkún-Omi. Ìlú ńlá tó tún láwọn ìlú kéékèèké míì nínú nìlú Nínéfè, odindi ọjọ́ mẹ́ta gbáko lèèyàn máa fi rìn láti ìpẹ̀kun kan síkejì nínú ìlú náà. (Jẹ́nẹ́sísì 10:11; Jónà 3:3) Kò sí àní-àní pé ìlú tó fani lójú mọ́ra nìlú Nínéfè, àwọn tẹ́ńpìlì ńláńlá tó jojú ní gbèsè wà níbẹ̀, àwọn ògiri gìrìwò àtàwọn ilé míì lóríṣiríṣi sì kúnnú ìlú ọ̀hún. Àmọ́ àwọn nǹkan wọ̀nyí kọ́ ló jẹ́ kílùú yẹn ṣe pàtàkì sí Jèhófà Ọlọ́run. Àwọn èèyàn tó ń gbénú ìlú yẹn ló ṣe pàtàkì lójú rẹ̀. Àwọn èèyàn wọ̀nyẹn sì pọ̀ bí omi lákòókò tá à ń wí yìí. Láìka ìwà ibi tó kún ọwọ́ wọn sí, Jèhófà bìkítà nípa wọn. Ẹ̀mí wọn ṣe pàtàkì lójú rẹ̀, ó sì rí i pé ó ṣeé ṣe kí wọ́n ronú pìwà dà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan, kí wọ́n sì kọ́ láti máa ṣe rere.

Nígbà tí Jónà máa fi dé ìlú Nínéfè ní gbẹ̀yìn gbẹ́yín, báwọn èèyàn inú ìlú yẹn, tí wọ́n lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà [120,000], ṣe pọ̀ bí omi tún lè dá kún ẹ̀rù tó ń bà á. b Bó ṣe ń rìn wọnú ìlú náà lọ́jọ́ àkọ́kọ́, bẹ́ẹ̀ ló túbọ̀ ń bára ẹ̀ láàárín àwọn èèyàn ìlú náà tí wọ́n pọ̀ yamùrá, ó ṣeé ṣe kó máa wá ibi tó máa rọ̀ ọ́ lọ́rùn láti bẹ̀rẹ̀ sí í jíṣẹ́ tó mú wá. Èdè wo ló máa fi báwọn sọ̀rọ̀? Ṣó ti kọ́ èdè àwọn ará Ásíríà ni? Àbí Jèhófà fi èdè yẹn sí i lẹ́nu lọ́nà ìyanu? A ò mọ̀. Ó sì lè jẹ́ pé èdè Hébérù, tó jẹ́ èdè ìbílẹ̀ ìlú tí Jónà ti wá, ló fi bá wọn sọ̀rọ̀, kẹ́nì kan sì wá bá a tú u sí èdè táwọn ará Nínéfè gbọ́. A ò lè sọ. Àmọ́, ó dájú pé iṣẹ́ tó jẹ́ rọrùn láti lóye, kò sì sọ ọ́ lọ́nà tó máa jẹ́ káwọn èèyàn náà nífẹ̀ẹ́ ẹ̀, ohun tó ṣáà ń sọ ni pé: “Kìkì ogójì ọjọ́ sí i, a ó sì bi Nínéfè ṣubú.” (Jónà 3:4) Ó fìgboyà sọ̀rọ̀, ó sì ń sọ ọ́ ní àsọtúnsọ. Ìyẹn fi hàn pé ó nígboyà lọ́nà tó ṣàrà ọ̀tọ̀, ó sì nígbàgbọ́, ó sì yẹ káwọn Kristẹni òde òní láwọn ànímọ́ wọ̀nyí ju ti tẹ́lẹ̀ lọ.

Àwọn ará ìlú Nínéfè tẹ́tí sọ́rọ̀ Jónà. Ó ṣeé ṣe kí Jónà ti máa retí pé ìjà làwọn èèyàn wọ̀nyẹn máa fi pàdé òun torí iṣẹ́ tó fẹ́ jẹ́ fún wọn. Àmọ́, ọ̀rọ̀ ò rí bó ṣe rò. Àwọn ará Nínéfè gbọ́rọ̀ Jónà wọ́n sì yí pa dà! Ọ̀rọ̀ ẹ̀ tàn kálẹ̀ lẹ́yẹ ò sọkà. Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, gbogbo àwọn ará ìlú yẹn ló ti mọ̀ nípa ìparun tí Jónà wá sọ tẹ́lẹ̀. Ìwé Jónà kà pé: “Àwọn ènìyàn Nínéfè sì bẹ̀rẹ̀ sí ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì tẹ̀ síwájú láti pòkìkí ààwẹ̀, wọ́n sì gbé aṣọ àpò ìdọ̀họ wọ̀, láti orí ẹni tí ó tóbi jù lọ nínú wọn àní dórí ẹni tí ó kéré jù lọ nínú wọn.” (Jónà 3:5) Gbogbo wọn pátá, látorí olówó dórí tálákà, tọkùnrin tobìnrin tó fi mọ́ tọmọdé tàgbà ló ronú pìwà dà. Kò pẹ́ rárá tọ́rọ̀ tá à ń wí yìí fi dé etígbọ̀ọ́ ọba ìlú Nínéfè.

Ọba pàápàá fi tọkàntọkàn bẹ̀rù Ọlọ́run. Ó dìde látorí ìtẹ́ rẹ̀, ó bọ́ aṣọ aláràbarà tó wọ̀, ó sì wọ irú aṣọ àpò ìdọ̀họ táwọn aráàlú wọ̀, kódà ó “jókòó nínú eérú.” Òun àtàwọn “ẹni ńlá” rẹ̀ ìyẹn àwọn ìjòyè rẹ̀, sì pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn ará ìlú Nínéfè gbààwẹ̀, bí wọ́n ṣe sọ ààwẹ̀ tó bẹ̀rẹ̀ wẹ́rẹ́ yẹn di àṣẹ fún gbogbo aráàlú nìyẹn. Ọba pàṣẹ pé kí gbogbo aráàlú, títí kan àwọn ẹran agbéléjẹ̀, wọ aṣọ àpò ìdọ̀họ. c Tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ ló fi gbà pé àwọn èèyàn òun jẹ̀bi ìwàkiwà àti pé ìwà ipá kún ọwọ́ wọn. Ó sì nírètí pé Ọlọ́run tòótọ́ máa ṣàánú àwọn nígbà tó bá rí báwọn ṣe ronú pìwà dà, ó ní: “Ọlọ́run . . . lè yí padà . . . kúrò nínú ìbínú rẹ̀ jíjófòfò, kí a má bàa ṣègbé.”—Jónà 3:6-9.

Àwọn kan tó máa ń ṣe lámèyítọ́ sọ pé àwọn ò gbà pé àwọn ará Nínéfè lè yára ronú pìwà dà bẹ́ẹ̀ yẹn. Àmọ́ àwọn ọ̀mọ̀wé tó máa ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ti sọ pé ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn ò ṣàjèjì, torí pé èrò àwọn èèyàn tí wọ́n nírú àwọn àṣà wọ̀nyẹn láyé àtijọ́ máa ń tètè yí pa dà, ó sì máa ń rọrùn fún wọn láti yára gba àwọn ohun asán gbọ́. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, Jésù Kristi pàápàá sọ̀rọ̀ nípa báwọn ará Nínéfè ṣe ronú pìwà dà. (Mátíù 12:41) Ó sì dájú pé ohun tó ń sọ dá a lójú, torí pé ó ti wà láàyè lọ́run kó tó wá sáyé, gbogbo ohun tó ti ṣẹlẹ̀ ṣáájú ìgbà yẹn ló sì ṣojú ẹ̀. (Jòhánù 8:57, 58) Kí ni Jèhófà wá ṣe nígbà táwọn ará Nínéfè ronú pìwà dà?

Àánú Ọlọ́run àti Agídí Èèyàn Yàtọ̀ Síra

Nígbà tó yá Jónà kọ̀wé pé: “Ọlọ́run tòótọ́ sì wá rí àwọn iṣẹ́ wọn, pé wọ́n ti yí padà kúrò nínú ọ̀nà búburú wọn; nítorí náà, Ọlọ́run tòótọ́ pèrò dà lórí ìyọnu àjálù tí ó ti sọ pé òun yóò mú bá wọn; kò sì mú un wá.”—Jónà 3:10.

Ṣé ìpinnu tí Jèhófà ṣe yìí wá fi hàn pé ó ti ṣàṣìṣe nígbà tó ní kí Jónà kéde ìdájọ́ òun sórí ìlú Nínéfè? Rárá o. Bíbélì sọ nípa Jèhófà pé: “Pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀, nítorí gbogbo ọ̀nà rẹ̀ jẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ọlọ́run ìṣòtítọ́, ẹni tí kò sí àìṣèdájọ́ òdodo lọ́dọ̀ rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé ìbínú òdodo tí Jèhófà ní sílùú Nínéfè dáwọ́ dúró. Ó rí i pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ti yí pa dà àti pé kò sídìí tóun fi ní láti fìyà jẹ wọ́n mọ́. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí mú kí Ọlọ́run ṣàánú àwọn ará Nínéfè.

Jèhófà kì í ṣe Ọlọ́run ìkà tí kì í yí ìpinnu ẹ̀ pa dà tàbí tó rorò báwọn aṣáájú ìsìn ṣe máa ń sọ̀rọ̀ ẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní ìfòyemọ̀, kì í ṣe ìpinnu tí kò ṣeé yí pa dà, ó sì jẹ́ aláàánú. Tó bá fẹ́ fìyà jẹ àwọn èèyàn burúkú, ó máa ń kọ́kọ́ rán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ tó wà láyé láti lọ kìlọ̀, torí ohun tó fẹ́ ni pé káwọn ẹni búburú ṣe bíi tàwọn ará Nínéfè, ìyẹn ni pé kí wọ́n ronú pìwà dà, kí wọ́n sì yí pa dà. (Ìsíkíẹ́lì 33:11) Jèhófà sọ fún Jeremáyà wòlíì rẹ̀ pé: “Ní ìṣẹ́jú èyíkéyìí tí mo bá sọ̀rọ̀ lòdì sí orílẹ̀-èdè kan àti lòdì sí ìjọba kan láti fà á tu àti láti bì í wó àti láti pa á run, tí orílẹ̀-èdè yẹn bá sì yí padà ní ti gidi kúrò nínú ìwà búburú rẹ̀ èyí tí mo sọ̀rọ̀ lòdì sí, èmi pẹ̀lú yóò pèrò dà dájúdájú ní ti ìyọnu àjálù tí mo ti rò láti mú ṣẹ ní kíkún sórí rẹ̀.”—Jeremáyà 18:7, 8.

Ṣẹ́yẹn wá túmọ̀ sí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni Jónà sọ fáwọn èèyàn wọ̀nyẹn? Rárá o, òótọ́ lọ̀rọ̀ Jónà, ńṣe ni Jèhófà fi àsọtẹ́lẹ̀ yẹn kìlọ̀ fáwọn èèyàn wọ̀nyẹn, wọ́n sì gbọ́ ìkìlọ̀. Ìwàkíwà tó kún ọwọ́ àwọn ará Nínéfè ló mú kí ìkìlọ̀ yẹn wáyé, àmọ́ wọ́n yí pa dà. Táwọn ará Nínéfè bá tún pa dà sí í hùwàkiwà, ìyẹn ò ní kí Ọlọ́run má pa wọ́n run. Ohun tó sì wá ṣẹlẹ̀ nígbà tó yá gan-an nìyẹn.—Sefanáyà 2:13-15.

Kí ni Jónà wá ṣe nígbà tó rí i pé Ọlọ́run ò pa àwọn èèyàn wọ̀nyẹn run nígbà tóun ń retí? Bíbélì sọ pé: “Bí ó ti wù kí ó rí, kò dùn mọ́ Jónà nínú rárá, inú rẹ̀ sì ru fún ìbínú.” (Jónà 4:1) Jónà tiẹ̀ gbàdúrà lọ́nà kan tó dà bíi pé ó ń dá Ọlọ́run lẹ́bi! Ó sọ nínú àdúrà náà pé òun ì bá ti dúró nílùú òun jẹ́jẹ́. Ó ní òun mọ̀ pé Jèhófà ò ní pa ìlú Nínéfè run, ó wá ń fìyẹn ṣàwáwí pé torí ẹ̀ náà lòun ṣe kọ́kọ́ sá lọ sílùú Táṣíṣì. Lẹ́yìn ìyẹn ló wá sọ pé ó sàn kóun kú, torí pé ikú yá ju ẹ̀sín lọ.—Jónà 4:2, 3.

Kí nìdí tí Jónà fi ń ronú bẹ́ẹ̀ yẹn? A ò lè mọ gbogbo nǹkan tó wà lọ́kàn ẹ̀, àmọ́ a mọ̀ pé ó ti kéde fáwọn èèyàn wọ̀nyẹn pé Ọlọ́run máa pa ìlú Nínéfè run. Wọ́n sì ti gbà á gbọ́. Àmọ́ ní báyìí, Ọlọ́run ò ní pa ìlú náà run mọ́. Àbí yẹ̀yẹ́ tí wọ́n máa fi í ṣe ló ń bà á lẹ́rù? Ó lè rò pé ṣe ni wọ́n á máa pe òun ní wòlíì èké. Bá ò tiẹ̀ mohun tó wà lọ́kàn ẹ̀, ẹ̀rí fi hàn pé inú ẹ̀ ò dùn nígbà tó rí i pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ronú pìwà dà, bẹ́ẹ̀ ni inú ẹ̀ ò sì dùn láti rí i pé Jèhófà ṣàánú àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló dà bíi pé ìbànújẹ́ tó lékenkà sorí ẹ̀ kodò tó sì wá ń káàánú ara ẹ̀. Àmọ́, Jèhófà, tó jẹ́ Ọlọ́run aláàánú, ṣì rí i pé èèyàn dáadáa ni Jónà. Dípò kó fìyà jẹ Jónà torí ìwà àfojúdi tó hù yìí, ìbéèrè kan ṣoṣo péré tó máa mú kó ronú jinlẹ̀ ni Jèhófà béèrè lọ́wọ́ ẹ̀, ìyẹn ni pé: “Ǹjẹ́ ríru tí inú rẹ ru fún ìbínú ha jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́ bí?” (Jónà 4:4) Ṣé Jónà tiẹ̀ dáhùn ìbéèrè yìí? Bíbélì ò sọ fún wa.

Bí Jèhófà Ṣe Kọ́ Jónà Lẹ́kọ̀ọ́

Ìbànújẹ́ ni Jónà bá kúrò nílùú Nínéfè, dípò kó sì pa dà sílé, apá ìlà oòrùn ìlú náà ló forí lé, ó lọ síbi àwọn òkè ńlá kan tí kò jìnnà sílùú náà. Ó ṣe àtíbàbà kékeré kan, ó sì jókòó síbẹ̀, ó ń retí ohun tó máa ṣẹlẹ̀ sílùú Nínéfè. Ó ṣeé ṣe kó ṣì máa retí kí Ọlọ́run pa ìlú náà run. Báwo ni Jèhófà ṣe máa kọ́ ọkùnrin alágídí yìí láti jẹ́ aláàánú?

Kílẹ̀ ọjọ́ kejì tó mọ́, Jèhófà mú kí igi kan tó dà bí igi akèrègbè hù jáde. Nígbà tí Jónà máa jí, ó rí igi tó ti gbẹ̀rẹ̀gẹ̀jigẹ̀ yìí, ó sì rí i pé àwọn ewé igi náà máa dáàbò bo òun ju àtíbàbà lásán tóun kọ́ lọ. Inú ẹ̀ dùn gan-an. “Jónà sì bẹ̀rẹ̀ sí yọ̀ gidigidi” torí igi tó rú yọ yìí, ó tiẹ̀ lè máa ronú pé igi tó hù lọ́nà ìyanu yẹn jẹ́ àmì pé inú Ọlọ́run dùn sóun àti pé Ọlọ́run bù kún òun. Àmọ́, kì í ṣe pé Jèhófà kàn fẹ́ dáàbò bo Jónà lọ́wọ́ ìtànṣán oòrùn, tàbí pé ó kàn fẹ́ kínú tó ń bí Jónà rọlẹ̀ nìkan ni, ńṣe ló fẹ́ kí Jónà ronú jinlẹ̀. Torí náà, Ọlọ́run jẹ́ kí àwọn kòkòrò mùkúlú jẹ igi náà, igi yẹn sì kú. Ọlọ́run sì wá jẹ́ kí “ẹ̀fúùfù ìlà-oòrùn amóhungbẹ hán-ún hán-ún” fẹ́ lu Jónà débi pé Jónà bẹ̀rẹ̀ sí í “dákú lọ.” Inú bá tún bẹ̀rẹ̀ sí í bí Jónà, ó sì wá sọ pé kí Ọlọ́run jẹ́ kóun kú, torí ikú yá jẹ̀sín.—Jónà 4:6-8.

Jèhófà tún wá bi Jónà lẹ́ẹ̀kan sí i pé ṣé inú ẹ̀ dùn sí bí igi tó dà bí igi akèrègbè yẹn ṣe kú? Dípò kí Jónà ronú pìwà dà, ńṣe ló ń dára ẹ̀ láre, ó ní: “Ríru tí inú mi ru fún ìbínú jẹ́ lọ́nà ẹ̀tọ́, títí dé ojú ikú.” Jèhófà ṣẹ̀ṣẹ̀ wá lo àǹfààní yẹn láti kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ látinú ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn.—Jónà 4:6-9.

Ọlọ́run mú kí Jónà ronú jinlẹ̀ nípa ohun tó ṣẹlẹ̀, pé ó ń banú jẹ́ torí pé igi lásán làsàn kú, igi tó kàn hù jáde lọ́sàn-án kan òru kan, tí kì í ṣe póun ló gbìn ín, tí kò sì mọ nǹkan kan nípa bó ṣe dàgbà. Lẹ́yìn náà ni Ọlọ́run wá sọ pé: “Ní tèmi, kò ha sì yẹ kí n káàánú fún Nínéfè ìlú ńlá títóbi nì, inú èyí tí àwọn ènìyàn tí ó ju ọ̀kẹ́ mẹ́fà wà, tí wọn kò mọ ìyàtọ̀ rárá láàárín ọwọ́ ọ̀tún wọn àti òsì wọn, yàtọ̀ sí ọ̀pọ̀ àwọn ẹran agbéléjẹ̀?”—Jónà 4:10, 11. d

Ṣó o rí bí ẹ̀kọ́ tí Jèhófà kọ́ Jónà ti ṣe pàtàkì tó? Jónà ò mọ nǹkan kan nípa bí igi yẹn ṣe dàgbà. Àmọ́ Jèhófà ló dá àwọn ará Nínéfè, òun ló sì ń pèsè fún wọn bó ti ń ṣe fún gbogbo nǹkan alààyè tó wà láyé. Kí tiẹ̀ nìdí tí ikú igi kan ṣoṣo péré fi ní láti ká Jónà lára ju ikú àwọn èèyàn tó tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́fà [120,000] lọ, tó fi mọ́ àwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn? Ṣé kì í ṣe torí pé Jónà ti bẹ̀rẹ̀ sí í ro tara ẹ̀ nìkan báyìí? Ó ṣe tán, àǹfààní tó rí lára igi yẹn ló jẹ́ kó dùn ún nígbà tí igi náà kú. Ó ní láti jẹ́ pé ìmọ́tara-ẹni-nìkan náà ló mú kí Jónà máa bínú nígbà tí Ọlọ́run ò pa ìlú Nínéfè run, torí pé ó fẹ́ kọ́rọ̀ òun ṣẹ, káwọn èèyàn wọ̀nyẹn má bàa mú òun lónírọ́.

Ẹ̀kọ́ ńlá mà lèyí o! Ṣé Jónà fi ṣàríkọ́gbọ́n báyìí? Ìbéèrè tí Jèhófà bi Jónà yẹn ló gbẹ̀yìn ìwé Jónà nínú Bíbélì, ó sì ń dún gbọnmọgbọnmọ. Àwọn kan tó ń ṣe lámèyítọ́ lè máa sọ pé Jónà ò dáhùn ìbéèrè yẹn. Àmọ́ ìdáhùn Jónà wà níbẹ̀. Ìwé tí Jónà kọ yẹn ló fi dáhùn ìbéèrè yẹn. Ẹ̀rí fi hàn pé Jónà fúnra ẹ̀ ló fọwọ́ ara ẹ̀ kọ ìwé tó ń jẹ́ orúkọ ẹ̀ yẹn. Ìwọ náà fojúunú wo bí wòlíì yẹn ṣe ń fọwọ́ ara ẹ̀ kọ ìtàn yìí sílẹ lẹ́yìn tó pa dà sílùú ìbílẹ̀ rẹ̀ láyọ̀ àti lálàáfíà. A lè máa fojúunú wo Jónà nígbà tó ti darúgbó, tó ti wá gbọ́n ju ti tẹ́lẹ̀ lọ, tí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ tó ní ti pọ̀ sí i, tó sì wá ń mi orí láti fi hàn pé ó ń kábàámọ̀ àwọn nǹkan tó ti ṣe sẹ́yìn, bó ti ń kọ àwọn àṣìṣe tóun fúnra ẹ̀ ṣe sílẹ̀, bó ṣe ya olọ̀tẹ̀ àti bó ṣe fi agídí kọ̀ jálẹ̀ láti ṣàáánú àwọn ẹlòmíì. Ẹ̀rí fi hàn pé Jónà kẹ́kọ̀ọ́ látinú àwọn ìtọ́ni ọlọ́gbọ́n tí Jèhófà fún un. Ó kọ́ béèyàn ṣe lè jẹ́ aláàánú. Ṣéwọ náà á ṣe bẹ́ẹ̀?

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkọlé ẹ̀ ní, “Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn—Ó Kọ́gbọ́n Látinú Àṣìṣe Ara Ẹ̀,” nínú Ilé Ìṣọ́ January 1, 2009.

b Àwọn tó ń ṣèwádìí ti fojú bù ú pé, ó ṣeé ṣe káwọn èèyàn tó ń gbé nílùú Samáríà, tó jẹ́ olú ìlú Ísírẹ́lì, pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ogún [20,000] sí ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgbọ̀n [30,000] nígbà ayé Jónà, ìyẹn ò sì tó ìdá kan nínú mẹ́rin àwọn tó ń gbé nílùú Nínéfè. Nígbà tí nǹkan rọ̀ṣọ̀mù nílùú Nínéfè, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìlú yẹn ló tóbi jù lọ láyé ìgbà yẹn.

c Ó lè dà bíi pé ohun tí wọ́n ṣe yìí ṣàjèjì, àmọ́ tiwọn kọ́ làkọ́kọ́ láyé ìgbà yẹn. Òpìtàn ará Gíríìkì kan tó ń jẹ́ Herodotus, sọ pé nígbà táwọn ará Páṣíà àtijọ́ ń ṣọ̀fọ̀ ikú olórí ológun kan tí wọ́n fẹ́ràn dáadáa, àwọn àtàwọn ẹran agbéléjẹ̀ wọn ni wọ́n jọ ṣọ̀fọ̀ yẹn níbàámu pẹ̀lú àṣà wọn.

d Ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run sọ pé àwọn èèyàn wọ̀nyẹn ò mọ ìyàtọ̀ láàárín ọwọ́ ọ̀tún àti òsì fi hàn pé wọn ò dákan mọ̀ tọ́rọ̀ bá kan ọ̀rọ̀ nípa àwọn ìlànà Ọlọ́run.

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 16]

Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn búburú ronú pìwà dà, kí wọ́n sì kọ ìwàkiwà sílẹ̀ bíi tàwọn ará Nínéfè

[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 17]

Ọlọ́run fi igi kan tó dà bí akèrègbè kọ́ Jónà lẹ́kọ̀ọ́ nípa béèyàn ṣe lè jẹ́ aláàánú