Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?
Ṣéèyàn Fúnra Ẹ̀ Ló Máa Pinnu Póun Fẹ́ Di Àtúnbí?
TA LÓ ń sọ èèyàn di àtúnbí? Táwọn aṣáájú ẹ̀sìn kan bá ń rọ àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ wọn láti di àtúnbí, wọ́n máa ń tún ọ̀rọ̀ Jésù sọ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí.” (Jòhánù 3:7) Àwọn aṣáájú ẹ̀sìn wọ̀nyí máa ń lo ọ̀rọ̀ yìí láti fi pàṣẹ fáwọn ọmọ ìjọ wọn, ńṣe ló dà bí ìgbà tí wọ́n bá ń sọ pé, “O gbọ́dọ̀ di àtúnbí!” Ohun tí wọ́n wá ń wàásù rẹ̀ fáwọn ọmọ ìjọ wọn ni pé ọwọ́ olúkúlùkù wọn ló wà láti pinnu póun máa ṣe ohun tí Jésù sọ, kóun ṣe gbogbo ohun tó bá yẹ kóun ṣe kóun lè di àtúnbí. Ohun tí wọ́n ń dọ́gbọ́n sọ ni pé àwọn èèyàn fúnra wọn ló máa pinnu pé àwọn fẹ́ di àtúnbí. Àmọ́, ṣé ohun tí Jésù sọ fún Nikodémù nìyẹn?
Tá a bá fara balẹ̀ ka ọ̀rọ̀ Jésù dáadáa, a máa rí i pé Jésù ò kọ́ni pé ọwọ́ èèyàn ló kù sí láti pinnu bóyá òun máa di àtúnbí tàbí òun ò ní dì í. Kí nìdí tá a fi sọ bẹ́ẹ̀? Lédè Gíríìkì, gbólóhùn tá a tú sí “tún ẹnikẹ́ni bí” tún lè túmọ̀ sí “ó yẹ kí Ọlọ́run tún ẹ bí.” a Torí náà, a lè sọ pé “láti òkè,” ìyẹn “láti ọ̀run” tàbí “láti ọ̀dọ̀ Baba” lẹnì kan ti lè dí àtúnbí. (Jòhánù 19:11; àlàyé ìsàlẹ̀ NW; Jákọ́bù 1:17) Èyí fi hàn pé Ọlọ́run ló ń pinnu ẹni tó máa di àtúnbí.—1 Jòhánù 3:9.
Tá ò bá gbàgbé pé ọ̀rọ̀ Gíríìkì táwọn èèyàn wá mọ̀ sí àtúnbí tún lè túmọ̀ sí “láti òkè,” ó máa rọrùn láti rí ìdí tẹ́nì kan ò fi lè pinnu fúnra ẹ̀ póun fẹ́ di àtúnbí. Ronú lórí bí wọ́n ṣe bí ẹ ná. Ṣéwọ lo pinnu pé kí wọ́n bí ẹ ni? Ó dájú pé kì í ṣèwọ! Ọwọ́ bàbá ẹ nìyẹn wá. Bákan náà, ọwọ́ Ọlọ́run, ìyẹn Bàbá wa ọ̀run, ló wà bóyá ẹnì kan máa di àtúnbí tàbí kò ní dì í. (Jòhánù 1:13) Abájọ tí àpọ́sítélì Pétérù fi sọ pé: “Ìbùkún ni fún Ọlọ́run àti Baba Olúwa wa Jésù Kristi, nítorí ní ìbámu pẹ̀lú àánú ńlá rẹ̀, ó fún wa ní ìbí tuntun.”—1 Pétérù 1:3.
Ṣé Àṣẹ ni?
Àwọn kan lè ronú pé, ‘Tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ lẹnì kan ò lè pinnu fúnra ẹ̀ póun fẹ́ di àtúnbí, kí nìdí tí Jésù fi pàṣẹ pé: “A gbọ́dọ̀ tún yín bí”?’ Ìbéèrè ọlọ́gbọ́n nìyẹn. Ó ṣe tán, tó bá jẹ́ àṣẹ ni Jésù pa, á jẹ́ pé ohun tó kọjá agbára wa ló fẹ́ ká ṣe. Ìyẹn ò sì bọ́gbọ́n mu. Ó dáa, kí ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ pé ẹ gbọ́dọ̀ di “àtúnbí”?
Nígbà tá a túṣu ọ̀rọ̀ yìí désàlẹ̀ ìkòkò lédè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, a rí i pé àṣẹ kọ́ ni Jésù pa. Kàkà bẹ́ẹ̀, gbólóhùn yẹn dà bí ìgbà téèyàn kàn ń sọ̀rọ̀. Lọ́rọ̀ kan, nígbà tí Jésù sọ pé ẹ gbọ́dọ̀ di “àtúnbí,” ńṣe ló kàn ń sọ òótọ́ ọ̀rọ̀, kì í ṣe pé ó ń pàṣẹ. Ó ní: “Ó ṣe pàtàkì pé ká tún yín bí látòkè.”—Jòhánù 3:7, ìtumọ̀ Modern Young’s Literal Translation.
Ẹ jẹ́ ká fi àpèjúwe yìí ṣàlàyé ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn pàṣẹ àti kéèyàn kàn wulẹ̀ sọ òótọ́ ọ̀rọ̀. Ká sọ pé ìlú kan wà tó níléèwé tó pọ̀, tí ọ̀kan lára àwọn iléèwé náà sì jẹ́ èyí tí wọ́n dìídì dá sílẹ̀ torí àwọn ọmọ ìlú náà tó ń gbé lọ́nà jíjìn. Lọ́jọ́ kan, ọmọkùnrin kan tí kì í ṣe ọmọ ìlú yẹn sọ fún ọ̀gá iléèwé náà pé òun fẹ́ láti máa wá síléèwé wọn. Ọ̀gá iléèwé náà wá sọ fún un pé, “Kó o tó lè dọmọ iléèwé wa, o gbọ́dọ̀ jẹ́ ọmọ ìlú wa.” Ó dájú pé àṣẹ kọ́ ni ọ̀gá iléèwé yẹn pa. Kò sọ fún un pé, “O gbọ́dọ̀ di ọmọ ìlú wa!” Àmọ́, ọ̀gá iléèwé náà wulẹ̀ sọ òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà, ìyẹn sì ni ohun tọ́mọ náà gbọ́dọ̀ ṣe kó tó lè dọmọ iléèwé wọn. Bó ṣe rí náà nìyẹn nígbà tí Jésù sọ pé: “Ẹ gbọ́dọ̀ di àtúnbí.” Òótọ́ tó wà nídìí ọ̀rọ̀ náà ló sọ, ìyẹn sì ni ohun tẹ́nì kan gbọ́dọ̀ ṣe tó bá fẹ́ “wọ ìjọba Ọlọ́run.”
Ọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run tí Jésù sọ lókè yìí tún ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú apá mìíràn lórí ọ̀rọ̀ dídi àtúnbí. Ìyẹn ni pé, Kí nìdí táwọn kan fi ní láti di àtúnbí? Mímọ ìdáhùn sí ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká lóye ohun tí dídi àtúnbí túmọ̀ sí gan-an.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Bí èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ìtumọ̀ Bíbélì ṣe tú Jòhánù 3:3 nìyẹn. Bí àpẹẹrẹ, bí Bíbélì A Literal Translation of the Bible ṣe túmọ̀ ẹsẹ Bíbélì yìí rèé: “Bí Ọlọ́run ò bá tún ẹnì kan bí, kò lè wọ Ìjọba Ọlọ́run.”
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 6]
Ọ̀nà wo ni dídi àtúnbí àti bíbímọ gbà jọra?