Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Àkànṣe Àsọyé Fún Gbogbo Ènìyàn

Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ń ṣe ẹ̀sìn tí wọ́n bí wọn sí. Àwọn míì sì ń fúnra wọn yan ẹ̀sìn tí wọ́n ń ṣe nígbà tó yá. Kò sí àní-àní pé ẹ̀sìn pọ̀ lọ jàra láyé yìí. Ó ṣeé ṣe kó o ti ronú pé, ‘Ṣé ẹ̀sìn tí mo bá yàn láti ṣe tiẹ̀ ṣe pàtàkì tó bẹ́ẹ̀?’

A máa dáhùn ìbéèrè yìí nínú àsọyé fún gbogbo ènìyàn tá a pe àkọlé ẹ̀ ní, “Ṣé Gbogbo Ìsìn Ni Ọlọ́run Tẹ́wọ́ Gbà?” Àsọyé Bíbélì yìí máa wáyé láwọn ilẹ̀ tó lé ní ọgbọ̀n-lé-rúgba [230] yí ká ayé. Níbi tó pọ̀ jù lọ lágbàáyé, ọjọ́ Sunday April 26, ọdún 2009 la máa sọ àsọyé yìí ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ládùúgbò ẹ máa dùn láti sọ àkókò àti ibi tí wọ́n ti máa sọ àsọyé yìí fún ẹ. A fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà pè ẹ́ pé kó o wá.