Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹgbẹ́ Búburú Ò Jẹ́ Kí Jèhóáṣì Sin Jèhófà Mọ́

Ẹgbẹ́ Búburú Ò Jẹ́ Kí Jèhóáṣì Sin Jèhófà Mọ́

Kọ́ Ọmọ Rẹ

Ẹgbẹ́ Búburú Ò Jẹ́ Kí Jèhóáṣì Sin Jèhófà Mọ́

NǸKAN ò rọgbọ rárá nílùú Jerúsálẹ́mù, ibẹ̀ sì ni tẹ́ńpìlì Ọlọ́run wà. Wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ pa Ahasáyà Ọba ni. Ohun tí Ataláyà, tó jẹ́ ìyá ọba sì wá ṣe lẹ́yìn ìgbà yẹn yani lẹ́nu gan-an ni. Ńṣe ló ní kí wọ́n lọ pa gbogbo àwọn ọmọkùnrin tí Ahasáyà Ọba bí, ìyẹn àwọn ọmọọmọ ẹ̀! Ṣó o mọ ìdí tó fi ní kí wọ́n pa wọ́n?— a Ìdí ni pé ó fẹ́ jọba dípò àwọn ọmọọmọ ẹ̀.

Àmọ́ Ataláyà ò mọ̀ pé ẹnì kan ti lọ tọ́jú Jèhóáṣì, ọ̀kan lára àwọn ọmọọmọ Ataláyà tó wà ní ìkókó nígbà yẹn. Ṣé wàá fẹ́ mọ bí Jèhóáṣì ṣe bọ́ lọ́wọ́ ikú?— Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé Jèhóṣébà, tó jẹ́ àbúrò bàbá Jèhóáṣì ló tọ́jú Jèhóáṣì sínú tẹ́ńpìlì Ọlọ́run. Ohun tó jẹ́ kó rọrùn fún un ni pé Jèhóádà tó jẹ́ Àlùfáà Àgbà lọkọ ẹ̀. Torí náà, òun àtọkọ ẹ̀ ṣe ọ̀rọ̀ náà láṣìírí, wọ́n sì jọ rí i dájú pé kò sóhun tó ṣe Jèhóáṣì.

Odindi ọdún mẹ́fà ni wọ́n fi tọ́jú Jèhóáṣì sínú tẹ́ńpìlì láìjẹ́ kí ọba mọ̀. Ibẹ̀ ni wọ́n ti kọ́ Jèhóáṣì nípa Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn òfin Rẹ̀. Nígbà tí Jèhóáṣì wá pé ọmọ ọdún méje, Jèhóádà ṣètò láti fi jọba. Ṣé wàá fẹ́ mọ bí Jèhóádà ṣe fi Jèhóáṣì jọba àtohun tó ṣẹlẹ̀ sí Ọbabìnrin Ataláyà, tó jẹ́ ìyá àgbà fún Jèhóáṣì?—

Ohun tí Jèhóádà ṣe ni pé, ó kọ́kọ́ pe àwọn ẹ̀ṣọ́ tó máa ń dáàbò bo àwọn ọba ìlú Jerúsálẹ́mù ní bòókẹ́lẹ́. Ó wá ṣàlàyé bóun àtìyàwó òun ṣe dáàbò bo Jèhóáṣì, ọmọkùnrin Ahasáyà Ọba látìgbà tí Jèhóáṣì ti wà ní ìkókó. Ó wá lọ fi Jèhóáṣì han àwọn ẹ̀ṣọ́ wọ̀nyẹn, wọ́n sì wá rí i pé Jèhóáṣì ló yẹ kó jọba lóòótọ́. Ni wọ́n bá jọ fohùn ṣọ̀kan lórí ohun tí wọ́n máa ṣe.

Ká tó ṣẹ́jú pẹ́, Jèhóádà ti lọ mú Jèhóáṣì níbi tí wọ́n tọ́jú ẹ̀ sí, ó sì gbé adé lé e lórí. Àwọn èèyàn wọ̀nyẹn sì “bẹ̀rẹ̀ sí pàtẹ́wọ́, wọ́n sì sọ pé: ‘Kí ọba kí ó pẹ́!’” Àwọn ẹ̀ṣọ́ yí Jèhóáṣì ká kí wọ́n lè dáàbò bò ó. Nígbà tí Ataláyà gbọ́ nípa gbogbo nǹkan ayọ̀ tó ń ṣẹlẹ̀ yìí, ó sáré jáde, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí í pariwo pé òun ò fara mọ́ ọn. Ni Jèhóádà bá pàṣẹ pé káwọn ẹ̀ṣọ́ wọ̀nyẹn pa Ataláyà.—2 Àwọn Ọba 11:1-16.

Ṣé Jèhóáṣì ń bá a nìṣó láti máa fetí sí Jèhóádà? Ṣó sì ń bá a nìṣó láti máa ṣohun tó tọ́?— Bẹ́ẹ̀ ni, ó ń ṣe dáadáa kí Jèhóádà tó kú. Ó tiẹ̀ rí i dájú pé àwọn èèyàn dáwó láti fi ṣàtúnṣe tẹ́ńpìlì Ọlọ́run, èyí tí Ahasáyà bàbá tiẹ̀ àti Jèhórámù bàbá bàbá ẹ̀ ti pa tì tipẹ́tipẹ́. Àmọ́ kí ló wá ṣẹlẹ̀ nígbà tí Jèhóádà Àlùfáà Àgbà kú?—2 Àwọn Ọba 12:1-16.

Ọmọ ogójì [40] ọdún ni Jèhóáṣì nígbà tí Jèhóádà kú. Dípò kí Jèhóáṣì máa bá a nìṣó láti yan àwọn èèyàn Jèhófà lọ́rẹ̀ẹ́, àwọn tó ń jọ́sìn ọlọ́run èké ló ń bá kẹ́gbẹ́. Sekaráyà, ọmọ Jèhóádà, ti di àlùfáà Jèhófà nígbà yẹn. Kí lo rò pé Sekaráyà ṣe nígbà tó rí àwọn nǹkan búburú tí Jèhóáṣì bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe báyìí?—

Sekaráyà sọ fún Jèhóáṣì pé: “Nítorí pé [o] ti fi Jèhófà sílẹ̀, òun, ẹ̀wẹ̀, yóò fi [ẹ́] sílẹ̀.” Ọ̀rọ̀ yẹn bí Jèhóáṣì nínú débi pé ńṣe ló ní kí wọ́n lọ sọ̀kò pa Sekaráyà. Àbóò rí nǹkan, àwọn kan gba Jèhóáṣì lọ́wọ́ apààyàn, àmọ́ òun náà ló tún ṣekú pa Sekaráyà, tó sì wá sọra ẹ̀ di apààyàn!—2 Kíróníkà 24:1-3, 15-22.

Ẹ̀kọ́ wo lo rò pé a lè rí kọ́ nínú ìtàn yìí?— Kò ní dáa ká dà bí Ataláyà, torí pé ìkà ni, ó sì kórìíra àwọn èèyàn. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó yẹ ká fẹ́ràn àwọn tá a jọ jẹ́ onígbàgbọ́ tó fi mọ́ àwọn ọ̀tá wa. Ohun tí Jésù kọ́ wa pé ká máa ṣe nìyẹn. (Mátíù 5:44; Jòhánù 13:34, 35) Má sì gbàgbé pé tá a bá ti bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe dáadáa, bíi ti Jèhóáṣì, ó yẹ ká máa bá a nìṣó láti máa kẹ́gbẹ́ pẹ̀lú àwọn èèyàn tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, tí wọ́n á sì tún máa fún wa níṣìírí láti máa sìn ín.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Tó bá jẹ́ pé ọmọdé lò ń ka ìwé yìí fún, má gbàgbé láti dánu dúró níbi tó o bá ti rí àmì dáàṣì (—), kó o sì jẹ́ kọ́mọ náà sọ tinú ẹ̀.

Ìbéèrè:

○ Ta ló fẹ́ pa Jèhóáṣì, báwo ni wọ́n sì ṣe gbà á sílẹ̀?

○ Báwo ni Jèhóáṣì ṣe di ọba, àwọn nǹkan rere wo ló sì ṣe?

○ Kí nìdí tí Jèhóáṣì fi bẹ̀rẹ̀ sí í hùwà burúkú, ta ló sì pa?

○ Àwọn ẹ̀kọ́ wo la lè rí kọ́ látinú ìtàn tó wà nínú Bíbélì yìí?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jèhóáṣì bọ́ lọ́wọ́ ikú