4 Má Ṣiyèméjì
4 Má Ṣiyèméjì
“Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?”—Mátíù 14:31.
ÌDÍ TÓ FI ṢÒRO: Àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù pàápàá máa ń ṣiyèméjì nígbà míì. (Mátíù 14:30; Lúùkù 24:36-39; Jòhánù 20:24, 25) Kódà, Bíbélì jẹ́ ká lóye pé àìnígbàgbọ́ wà lára àwọn “ẹ̀ṣẹ̀ tí ó máa ń wé mọ́ wa pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” (Hébérù 12:1) Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ìgbàgbọ́ kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Kì í ṣe pé àwọn kan wà tí wọn ò lè nígbàgbọ́. Àmọ́, ọ̀pọ̀ èèyàn ni kì í sapá láti ní in. Ọlọ́run máa bù kún ìsapá gbogbo àwọn tó bá ṣiṣẹ́ kára láti nígbàgbọ́.
BÓ O ṢE LÈ ṢÀṢEYỌRÍ: Kọ́kọ́ mọ àwọn nǹkan tó máa ń mú kó o ṣiyèméjì. Bí àpẹẹrẹ, Tọ́másì tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọmọlẹ́yìn Jésù ṣiyèméjì nípa àjíǹde Jésù, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ọmọlẹ́yìn tó kù sọ fún un pé àwọn fojú ara àwọn rí Jésù. Tọ́másì fẹ́ kí wọ́n fún òun ní ẹ̀rí tó dájú kóun tó lè gbà wọ́n Jòhánù 20:24-29.
gbọ́. Kí ló wá ṣẹlẹ̀? Jésù fúnra ẹ̀ fún un ní ẹ̀rí tó nílò kó lè nígbàgbọ́ tó lágbára pé òótọ́ lọ̀rọ̀ náà.—Jèhófà Ọlọ́run ti fún wa ní Bíbélì, àwọn ọ̀rọ̀ tó wà níbẹ̀ sì ti fún wa láwọn ẹ̀rí tá a nílò tá ò fi ní ṣiyèméjì mọ́. Bí àpẹẹrẹ, lọ́nà kan tàbí òmíràn àwọn kan ò nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run torí wọ́n rò pé òun ló wà nídìí ogun, ìwà ipá àtàwọn ìṣẹ̀lẹ̀ burúkú tó ń han aráyé léèmọ̀. Kí ni Bíbélì sọ lórí ọ̀ràn yìí?
Ọlọ́run kò lo àwọn ìjọba èèyàn láti ṣàkóso aráyé. Jésù sọ pé ẹ̀dá ẹ̀mí kan tó ń jẹ́ Sátánì ni “olùṣàkóso ayé” yìí. (Jòhánù 14:30) Sátánì sọ pé òun máa fún Jésù ní gbogbo ìjọba ayé tó bá ṣáà ti lè jọ́sìn òun lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo, ó ní: “Gbogbo ọlá àṣẹ yìí àti ògo wọn ni èmi yóò fi fún ọ dájúdájú, nítorí pé a ti fi í lé mi lọ́wọ́, ẹnì yòówù tí mo bá sì fẹ́ ni èmi yóò fi í fún.” Jésù ò bá Sátánì jiyàn pé òun kọ́ ló ń ṣàkóso ayé. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ fún un pé: “A kọ̀wé rẹ̀ pé, ‘Jèhófà Ọlọ́run rẹ ni ìwọ gbọ́dọ̀ jọ́sìn, òun nìkan ṣoṣo sì ni ìwọ gbọ́dọ̀ ṣe iṣẹ́ ìsìn ọlọ́wọ̀ fún.’” (Lúùkù 4:5-8) Sátánì àtàwọn ìjọba èèyàn ló fa ìyà tó ń jẹ aráyé lónìí, kì í ṣe Ọlọ́run.—Ìṣípayá 12:9, 12.
Láìpẹ́ Jèhófà Ọlọ́run máa mú gbogbo nǹkan tó ń fa ìyà kúrò. Ọlọ́run ti ṣètò ìjọba kan tó máa fi ṣàkóso aráyé lábẹ́ ìdarí Kristi Jésù, Ọmọ rẹ̀. (Mátíù 6:9, 10; 1 Kọ́ríńtì 15:20-28) Iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere Ìjọba yìí ti ń lọ kárí ayé báyìí, ìyẹn sì fi hàn pé àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ti ń nímùúṣẹ. (Mátíù 24:14) Láìpẹ́ Ìjọba yìí máa pa àwọn tí ò fara mọ́ ọn run lẹ́yìn náà ló máa wá mú gbogbo nǹkan tó ń fa ìjìyà kúrò.—Dáníẹ́lì 2:44; Mátíù 25:31-33, 46; Ìṣípayá 21:3, 4.
ÀǸFÀÀNÍ TÓ WÀ NÍBẸ̀: Ńṣe làwọn tó máa ń ṣiyèméjì dà bí ìgbì òkun tí “gbogbo ẹ̀fúùfù ẹ̀kọ́ nípasẹ̀ ìwà àgálámàṣà àwọn ènìyàn” ń bì síhìn-ín bì sọ́hùn-ún. (Éfésù 4:14; 2 Pétérù 2:1) Àmọ́, ní tàwọn tó ń rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó ń gbé wọn nínú, ńṣe ni wọ́n máa “dúró gbọn-in gbọn-in nínú ìgbàgbọ́.”—1 Kọ́ríńtì 16:13.
Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe ìwé ìròyìn yìí, inú wa sì máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́ kó o lè rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè tó lè jẹ́ kó ṣòro fún ẹ láti nígbàgbọ́ tó lágbára. Tọ̀yàyàtọ̀yàyà la fi pè ẹ́ pé kó o wá sáwọn ìpàdé wa, kó o lè fúnra ẹ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀kọ́ wa. Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá nígbàgbọ́ tó lágbára gan-an nínú Ọlọ́run.
Fún àlàyé síwájú sí i, ka orí 8 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Kí Ni Ìjọba Ọlọ́run?” àti orí 11 tá a pe àkòrí rẹ̀ ní, “Kí Nìdí Tí Ọlọ́run Fi Fàyè Gba Ìyà Tó Ń Jẹ Aráyé?” nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Àwọn tó bá ti rí ìdáhùn tó tẹ́ wọn lọ́rùn sáwọn ìbéèrè wọn máa ń nígbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀ dáadáa