Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìrìn-Àjò lọ sí ‘Abúlé kan Tó Jìnnà Réré’

Ìrìn-Àjò lọ sí ‘Abúlé kan Tó Jìnnà Réré’

Lẹ́tà Kan Láti Orílẹ̀-Èdè Rọ́ṣíà

Ìrìn-Àjò lọ sí ‘Abúlé kan Tó Jìnnà Réré’

ỌKỌ̀ òfuurufú kékeré tá a wọ̀ gbéra láti ìlú Yakutsk, ó sì fò kọjá lórí Àfonífojì Tuymaada. Bá a ṣe ń lọ, à ń kọjá lórí àwọn adágún omi tó ti di yìnyín, àwọn adágún omi náà tóbi jura wọn lọ, wọn ò sì rí bákan náà, a tún fò kọjá lórí Verkhoyanskiy, ìyẹn àwọn òkè tí yìnyín ti bò mọ́lẹ̀ tí oòrùn sì wá ń tàn yanran-yanran lé lórí. Lẹ́yìn tá a ti rin ọgọ́rùn-ún mẹ́sàn [900] kìlómítà lójú òfuurufú, ọkọ̀ wa balẹ̀ sí abúlé Deputatskiy.

Ìrìn àjò mi sí àgbègbè Sakha, tí wọ́n tún máa ń pè ní Yakutia ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni, ilẹ̀ náà lẹ́wà àmọ́ aṣálẹ̀ ni, ó sì tóbi ju gbogbo Ìwọ̀ Oòrùn Yúróòpù lọ. Ojú ọjọ́ máa ń gbóná lágbègbè yìí nígbà ẹ̀rùn, àmọ́ ó máa ń tutù gan-an nígbà ọyẹ́, egungun àwọn ẹran ńláńlá tí wọ́n ti wà nígbà kan rí sì máa ń wà nínú ilẹ̀ wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún ti kọjá lẹ́yìn tí mo lọ ságbègbè yìí, ńṣe ló ṣì ń ṣe mí bíi pé àná ni torí mo ṣì ń rántí àwọn ìlú kéékèèké tí kùrukùru máa ń bò mọ́lẹ̀ yẹn, bí òfuurufú tó láwọ̀ mèremère ṣe máa ń tàn yanran àtàwọn Yakut, ìyẹn àwọn èèyàn tó ń gbé lábúlé náà, tára wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn tí wọ́n sì lómi lára.

Abúlé Deputatskiy tọ́kọ̀ òfuurufú wa balẹ̀ sí kọ́ nibi tá à ń lọ. Èmi àtẹni tá a jọ lọ ṣì máa dé àwọn abúlé míì. Abúlé àkọ́kọ́ tá a máa dé ni Khayyr, ìrìn ọ̀ọ́dúnrún [300] kìlómítà ni láti apá àríwá abúlé Deputatskiy nítòsí Òkun Laptev tó wà lápá àríwá àgbègbè Sìbéríà. Kí nìdí tá a fi pinnu láti rìnrìn àjò yìí? Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan ti wá sáwọn abúlé yìí nígbà kan rí, ó sì rí ọ̀pọ̀ èèyàn tó fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àwa tá a sì wà nílùú Yakutsk tó wà ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún kan [1,000] kìlómítà sáwọn abúlé yìí ló sún mọ́ wọn jù lọ! A mọ̀ pé àwọn èèyàn yìí nílò ìrànlọ́wọ́ àti ìṣírí.

Nígbà tá a dé Deputatskiy, a rí ọkùnrin kan tó ń wakọ̀ lọ sí Khayyr, ó sì gbà láti gbé wa débẹ̀ lówó kékeré. A ò kọ́kọ́ fẹ́ wọ ọkọ̀ yẹn torí ọkọ̀ náà ti gbó, àwọn ọkọ̀ tí wọ́n ṣe nígbà ayé ìjọba Soviet ni, ó sì ń rú èéfín tù-ù. Àmọ́ kò sóhun tá a lè ṣe, àfi ká wọ̀ ọ́, bá a ṣe gbéra lálẹ́ ọjọ́ náà nìyẹn. Àṣé, ojú wa ṣì máa rí màbo.

Ìjókòó inú ọkọ̀ náà tutù bíi yìnyín tó ti dì gbagidi, dípò kó sì bẹ̀rẹ̀ sí í gbóná nígbà tá a jókòó, ńṣe ló túbọ̀ ń tutù sí i. A ní kí ọ̀gbẹ́ni náà dúró fún wa, a sì tú inú àwọn àpò wa láti wọ aṣọ tó lè gba òtútù lé àwọn tá a ti wọ̀. Àmọ́ ńṣe ni òtútù náà túbọ̀ ń pọ̀ sí i.

Awakọ̀ náà ti pẹ́ lágbègbè yìí, ó sì ń gbìyànjú láti máa dá wa lárayá. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tó ṣàdédé béèrè pé, “Ṣẹ́ ẹ ti rí òfuurufú aláwọ̀ mèremère rí?” Èmi ò tíì rí i rí, torí náà ó dúró, a sì rọra sọ kalẹ̀. Ìyẹn jẹ́ ká gbàgbé òtútù tó ń mú wa fúngbà díẹ̀. Ńṣe ni mo lanu lẹ̀ bí mo ṣe rí òfuurufú aláwọ̀ mèremère lójú ọrùn tó ń yíra pa dà bí ọ̀gà, nǹkan àrà yìí dà bíi pé ìtòsí wa gan-an ló wà.

Lọ́wọ́ ìdájí nígbà tá a dé àgbègbè kan tí kò sí igi, àmọ́ tí yìnyín ti bo gbogbo ilẹ̀ lọ salalu, ọkọ̀ wa rì sínú yìnyín. A bá awakọ̀ wa ti ọkọ̀ ẹ̀ kúrò nínú yìnyín yẹn, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan, kì í ṣe ẹ̀ẹ̀mejì tírú ẹ̀ wáyé lójú ọ̀nà tó lọ sábúlé Khayyr torí yìnyín tó dì sójú ọ̀nà. Àfìgbà tílẹ̀ mọ́ dáadáa ni mo tó mọ̀ pé odò tó ti dì gbagidi là ń pè lójú ọ̀nà! Níkẹyìn ní ọwọ́ ọ̀sán, a dé abúlé Khayyr lẹ́yìn wákàtí mẹ́rìndínlógún [16] tá a ti kúrò lábúlé Deputatskiy. A rò pé a ò ní lè dìde láàárọ̀ ọjọ́ kejì torí òtútù tó ti rọ́ sí wa lára, àmọ́ koko lara wa le. Àwọn ọmọ ìka ẹsẹ̀ mi ni kò kàn ṣeé tẹlẹ̀ dáadáa, ó sì ṣeé ṣe kó jẹ́ torí òtútù tó ti wọ̀ mí lára. Àwọn ará abúlé náà fún mi ní gírísì tí mo fi pa á.

Ohun táwa Ẹlẹ́rìí sábà máa ṣe ni pé ká lọ wàásù fáwọn èèyàn nílé wọn. Àmọ́ lábúlé yìí, báwọn èèyàn ṣe gbọ́ pé a ti dé báyìí, ńṣe ni wọ́n ń wá wa kiri! Fún nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì àtààbọ̀ la fi ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́, nígbà míì sì rèé a máa ń wàásù látàárọ̀ dòru. Ó dùn mọ́ wa nínú láti ráwọn èèyan tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀ tára wọn yọ̀ mọ́ọ̀yàn, tí wọ́n láájò, tí wọ́n sì tún nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ọ̀pọ̀ lára àwọn àgbàlagbà obìnrin lábúlé náà ló sọ fún wa pé: “A gba Ọlọ́run gbọ́. Ti pé ẹ tiẹ̀ wá sábúlé wa tó jìnnà réré yìí jẹ́ ká mọ̀ pé Ọlọ́run wà!”

Àṣà àwọn ará abúlé yìí fà wá lọ́kàn mọ́ra gan-an ni. Bí àpẹẹrẹ, àwọn èèyàn máa ń to òkìtì yìnyín jọ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ilé wọn bí ìgbà téèyàn bá to igi ìdáná jọ. Nígbàkigbà tí wọ́n bá ti nílò omi, wọ́n á gbé ọ̀kan lára àwọn yìnyín náà sínú ìkòkò ńlá tó wà lórí iná kí yìnyín náà lè yọ́. Àwọn ará abúlé náà ṣe wá lálejò gan-an, ẹja tó máa ń wà nínú omi yìnyín, ìyẹn ẹja chir, ni wọ́n sè fún wa, ẹja yìí máa ń dùn yàtọ̀ tí wọ́n bá sè é bí stroganina, ìyẹn oúnjẹ aládìídùn ilẹ̀ náà. Gbàrà tí wọ́n bá mú ẹja yìí ni wọ́n ti máa fi sínú yìnyín tó máa jẹ́ kó gan pa, lẹ́yìn náà wọ́n á là á sí wẹ́wẹ́, wọ́n á wá sè é nínú omi tí wọ́n ti fi iyọ̀ àti ata sí, wọ́n á sì jẹ ẹ́ lójú ẹsẹ̀. Àwọn ará abúlé yìí tún máa ń sọ fún wa nípa báwọn ṣe máa ń rí egungun àwọn ẹran ńláńlá bí erin àtàwọn igi tí yìnyín ti bò mọ́lẹ̀.

Mo rìnrìn àjò ọgọ́rọ̀ọ̀rún kìlómítà nínú ọkọ̀ òfuurufú tí mo wọ̀ láti abúlé Khayyr, lọ sáwọn abúlé míì tó wà lágbègbè Yakutia, láti lọ kọ́ àwọn tó nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì lẹ́kọ̀ọ́. Ara àwọn èèyàn tó wà lágbègbè yìí mà yá mọ́ọ̀yàn o! Lọ́jọ́ kan, mo pàdé ọmọkùnrin kan tó wá pa dà mọ̀ látinú ọ̀rọ̀ tá a jọ ń sọ pé mo máa ń bẹ̀rù láti wọ ọkọ̀ òfuurufú. Ló bá ya nǹkan kan sínú káàdì kékeré kan láti fi fún mi níṣìírí. Ó ya ẹyẹ ológoṣẹ́ méjì àti ọkọ̀ òfuurufú kan sínú káàdì náà, ó wá kọ ọ́ síbẹ̀ pé: “Sasha, máà jẹ́ kí ẹ̀rù bà ẹ́ pé wàá já bọ́ tó o bá wà nínú ọkọ̀ òfuurufú. Mátíù 10:29.” Ọ̀rọ̀ tó kọ yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an nígbà tí mo ka ẹsẹ Bíbélì tó kọ síbẹ̀! Ẹsẹ Bíbélì yẹn sọ̀rọ̀ tí Jésù sọ nípa àwọn ẹyẹ ológoṣẹ́, ó kà pé: “Kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò jábọ́ lulẹ̀ láìjẹ́ pé Baba yín mọ̀.”

Díẹ̀ ni mo sọ yìí lára àìmọye ìrírí tí mo ní nígbà tí mo lọ ságbègbè Yakutia. Ilẹ̀ olótùútù àti aṣálẹ̀ yẹn ò ní jẹ́ kí n gbàgbé àwọn èèyàn tí wọ́n ń gbé ní ‘abúlé tó jìnnà réré’ yẹn, ara wọn yá mọ́ọ̀yàn, èèyàn gidi sì ni wọ́n.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Ara àwọn Yakut yá mọ́ọ̀yàn, wọ́n sì láájò àlejò