Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Wá Ìmọ̀ràn Tó Wúlò
Ọ̀pọ̀ Èèyàn Ń Wá Ìmọ̀ràn Tó Wúlò
IBI téèyàn ti lè gbàmọ̀ràn láyé òde òní pọ̀ lọ jàra. Iṣẹ́ tó ní í ṣe pẹ̀lú gbígba àwọn ẹlòmíì nímọ̀ràn sì wà lára iṣẹ́ tó ń mówó wọlé jù lọ lágbàáyé. Láwọn ilẹ̀ tí onírúurú èèyàn wà, irú bí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, Látìn Amẹ́ríkà, Japan àti orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà àwọn ìwé tí wọ́n fi ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn lórí bí nǹkan ṣe lè dáa fún wọn ló máa ń tà jù lọ. Bẹ́ẹ̀ náà sì lọ̀pọ̀ èèyàn túbọ̀ ń ra àwọn fídíò, tí wọ́n ń gba ìdálẹ́kọ̀ọ́, tí wọ́n sì túbọ̀ ń wo àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n tó dá lórí béèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú àwọn ìṣòro tó bá ní. Wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé kò dìgbà tí wọ́n bá lọ sọ́dọ̀ àwọn afìṣemọ̀rònú ẹ̀dá, agbani-nímọ̀ràn lórí ọ̀ràn ìgbéyàwó tàbí àwọn olórí ìsìn kí wọ́n tó yanjú àwọn ìṣòro wọn. Irú àwọn ìṣòro wo gan-an ni wọ́n tiẹ̀ ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn lé lórí?
Béèyàn ṣe lè ṣàṣeyọrí nígbèésí ayé, báwọn olólùfẹ́ ṣe lè máa ṣera wọn lọ́kan àti báwọn òbí ṣe lè tọ́mọ yanjú wà lára àwọn kókó ọ̀rọ̀ tí wọ́n sábà máa ń gbàwọn èèyàn nímọ̀ràn lé lórí. Àwọ́n èèyàn tún máa ń gbàmọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè bọ́ lọ́wọ́ ìṣòro ìsoríkọ́, ẹ̀dùn ọkàn àti ìṣòro tí ìkọ̀sílẹ̀ máa ń fà. Bẹ́ẹ̀ náà sì lọ̀pọ̀ èèyàn ń gbàmọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè borí ìṣòro àjẹjù, sìgá mímu àti ọtí àmupara. Ṣáwọn ìmọ̀ràn wọ̀nyẹn wúlò lóòótọ́? A lè sọ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan àwọn ìmọ̀ràn yẹn máa ń wúlò, àmọ́ lọ́pọ̀ ìgbà kì í yanjú ìṣòro àwọn èèyàn. Ìdí nìyẹn tó fi bọ́gbọ́n mu pé ká fọkàn símọ̀ràn tí Bíbélì fún wa pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.
Àwọn ìwé tó ń sọ béèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú ìṣòro yàtọ̀ pátápátá sáwọn ìwé ìtọ́ni tó ń kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa bí wọ́n ṣe lè di akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ nínú àwọn òwò bíi fọ́tò yíyà, ìṣírò owó tàbí bí wọ́n ṣe lè kọ́ èdè tuntun. Irú àwọn ìwé ìtọ́ni bẹ́ẹ̀ wúlò gan-an, owó tó ń ná àwọn èèyàn ò sì fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ tó owó tó ṣeé ṣe kéèyàn san tó bá lọ kọ́ àwọn iṣẹ́ wọ̀nyí níléèwé. Àwọn ìwé tó ń sọ béèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú ìṣòro iṣẹ́ ajé, ìgbéyàwó, ọmọ títọ́ tàbí ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn yàtọ̀ pátápátá. Ìrònú tàbí ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn èèyàn kan ni wọ́n sábà máa ń gbé lárugẹ. Torí náà, ó bọ́gbọ́n mu láti béèrè pé: ‘Ìmọ̀ràn ta ló wà nínú ìwé ọ̀hún? Orí kí ni ẹni yẹn sì gbé ìmọ̀ràn ẹ̀ kà?’
Gbogbo ìgbà kọ́ làwọn ọ̀mọ̀ràn máa ń rí ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro láti fi ti ọ̀rọ̀ wọn lẹ́yìn. Ohun
táwọn èèyàn bá fẹ́ gbọ́ làwọn kan nínú wọn máa ń sọ, torí wọ́n mọ̀ pé ìyẹn ló máa jẹ́ káwọn pa owó rẹpẹtẹ. Abájọ táwọn òwò tó ní í ṣe pẹ̀lú béèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú ìṣòro fi ń mú ohun tó lé ní bílíọ̀nù mẹ́jọ owó dọ́là wọlé lọ́dọọdún lórílẹ̀-èdè kan ṣoṣo!Ṣáwọn Ìwé Yìí Wúlò Lóòótọ́?
Àwọn ìmọ̀ràn tó wúlò lọ̀pọ̀ èèyàn ń wá nígbà tí wọ́n bá ń ka àwọn ìwé tó dá lórí béèyàn ṣe lè fúnra ẹ̀ yanjú ìṣòro. Àmọ́, ó ṣeni láàánú pé àwọn ìmọ̀ràn wọn kì í wúlò nígbà míì. Bí àpẹẹrẹ, ohun tí wọ́n sábà máa ń sọ fáwọn èèyàn ni pé: ‘Tó o bá ṣáà ti gbà pé nǹkan máa dáa, wàá kẹ́sẹ járí. Ohunkóhun tó o bá ṣáà ti fẹ́, bóyá owó ni, ìlera tó jí pépé tàbí àjọṣe tó dán mọ́rán pẹ̀lú àwọn ẹlòmíì, gbogbo ẹ̀ lo máa ní tó o bá ti gbà pé nǹkan á dáa.’ Ṣá a lè sọ pé irú ìmọ̀ràn yìí lè yanjú ìṣòro àwọn èèyàn lóòótọ́? Ṣó máa jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ lóòótọ́ pé dídùn àti kíkan lọ̀rọ̀ ìgbésí ayé?
Bí àpẹẹrẹ, ṣáwọn ìwé tó ń sọ nípa àjọṣe àwa èèyàn àtàwọn èyí tó ń sọ nípa ìgbéyàwó ti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ní ìdílé aláyọ̀, kí gbogbo àwọn tó wà nínú ìdílé sì máa ṣera wọn lọ́kan? Kò fi bẹ́ẹ̀ ràn wọ́n lọ́wọ́. Obìnrin kan tó ń ṣàyẹ̀wò ìwé kan, tó ń tà wàràwàrà nílẹ̀ Látìn Amẹ́ríkà, tí wọ́n fi ń fún àwọn èèyàn nímọ̀ràn lórí bí wọ́n ṣe lè nífẹ̀ẹ́ ara wọn sọ nípa ẹni tó kọ ìwé yẹn pé ó ń “kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ lórí bí wọ́n ṣe lè ní àjọṣe tó dáa pẹ̀lú àwọn ẹ̀lòmíì káwọn èèyàn sì máa fọ̀wọ̀ wọ̀ wọ́n.” Ẹni tó kọ ìwé yẹn sọ pé ṣe lèèyàn ń fìyà jẹra ẹ̀ tí kò bá kọ ẹni tó ń fẹ́ sílẹ̀ nígbà ìṣòro. Ohun tíyẹn túmọ̀ sí ni pé kéèyàn ṣáà ti ṣohun tó bá máa múnú ẹ̀ dùn dípò kéèyàn yanjú ìṣòro tó bá jẹ yọ.
Òótọ́ ni pé ó ṣeé ṣe káwọn ìmọ̀ràn tó dáa wà nínú àwọn ìwé tí wọ́n fi ń gba àwọn èèyàn nímọ̀ràn wọ̀nyí. Àmọ́, àwọn ìmọ̀ràn wọn tún lè fa ìṣòro. Agbaninímọ̀ràn kan lè fúnni nímọ̀ràn tó wúlò lórí ọ̀rọ̀ kan, àmọ́ kí ìmọ̀ràn tó máa fúnni lórí ọ̀rọ̀ míì dá kún ìṣòro. Kò ṣeé ṣé láti fìyàtọ̀ sí gbogbo èyí tó wúlò àtèyí tí kò wúlò nínú àwọn ìmọ̀ràn wọn tí kò lóǹkà, tó sì máa ń ta kora. Ìmọ̀ràn ta lo lè gbẹ́kẹ̀ lé nígbà náà? Béèrè lọ́wọ́ ara ẹ pé: ‘Ṣé wọ́n ti ṣèwádìí dáadáa kí wọ́n tó mú ìmọ̀ràn yìí wá àbí ẹni tó ṣèwé yẹn ló kàn ń sọ èrò ara ẹ̀? Ṣé kì í ṣe torí àtipawó sápò ara ẹ̀, tàbí torí àtidolókìkí lẹni náà ṣe ń sọ àwọn ohun tó ń sọ?’
Kò sígbà tímọ̀ràn inú Bíbélì ò wúlò ń tiẹ̀. Ọ̀pọ̀ ohun tí ìmọ̀ràn inú àwọn ìwé àtàwọn ètò tí wọ́n fi ń gbàwọn èèyàn nímọ̀ràn sábà máa ń dá lé ni Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ẹ̀. Ìyẹn sì ti jẹ́ kí ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn fetí símọ̀ràn yìí pé: “Kí ẹ di tuntun nínú ipá tí ń mú èrò inú yín ṣiṣẹ́, kí ẹ sì gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀.” (Éfésù 4:23, 24) Lọ́nà tó mọ́gbọ́n dání, Bíbélì jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan tó fa àwọn ìṣòro wa, ó sì tún kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ nípa bá a ṣe lè borí wọn. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, ó jẹ́ ká mọ àwọn ìdí tó fi ṣe pàtàkì pé ká máa ṣohun tó tọ́. Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé èyí máa ṣàlàyé òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí.