Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Wa Ń sìn?

Ṣé Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Wa Ń sìn?

Ṣé Ọlọ́run Kan Náà Ni Gbogbo Wa Ń sìn?

“Mo ti ní ẹ̀sìn tèmi, mi ò sì ní yí pa dà. Ẹ̀sìn tó bá wùùyàn lèèyàn lè ṣe, torí pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo wa ń sìn.”

ṢÓ O ti gbọ́ tẹ́nì kan sọrú ọ̀rọ̀ yìí rí? Ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà pé kò sí ẹ̀sìn téèyàn ṣe tí kò ní rójúure Ọlọ́run tí kò sì ní lóye ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí. Yàtọ̀ síyẹn, ọ̀pọ̀ èèyàn ló gbà gbọ́ pé kò sí ẹ̀sìn tí kò ní rere àti búburú tiẹ̀, kò sì sáwọn ẹlẹ́sìn tó lè sọ pé ìsìn tiwọn nìkan ninú Ọlọ́run dùn sí.

Irú èrò yìí ló wà lọ́kàn ọ̀pọ̀ èèyàn nínú ayé òde òní táwọn èèyàn ti gbàgbàkugbà láyè, tí wọ́n sì gbà pé gbogbo ẹ̀sìn ò yàtọ̀ síra. Kódà, ṣe làwọn èèyàn máa ń ka ẹni tí ò bá fara mọ́ èrò yìí sí ẹni tó ní ẹ̀tanú tó sì jẹ́ òmùgọ̀ èèyàn. Kí lèrò tìẹ? Ṣéwọ náà gbà pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo èèyàn ń sìn? Ṣé ẹ̀sìn téèyàn bá ń ṣe tiẹ̀ ṣe pàtàkì?

Ṣé Ìyàtọ̀ Wà Lóòótọ́?

Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan sọ pé ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá dín lọ́gọ́rùn-ún [9,900] ẹ̀sìn ló wà lágbàáyé báyìí, ọ̀pọ̀ nínú àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí ló sì ní ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ìjọ kárí ayé. Tá a bá ní ká fojú bù ú, ìdá méje nínú mẹ́wàá àwọn èèyàn lágbàáyé ló ń ṣe àwọn ẹ̀sìn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó gbajúmọ̀ jù lọ, ìyẹn ni ẹ̀sìn Búdà, Híńdù, Ìsìláàmù, ẹ̀sìn àwọn Júù àti Kristẹni. Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo wa ń sìn, ọ̀pọ̀ nǹkan ló yẹ kó jọra nínú àwọn ẹ̀sìn márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ yìí, irú bí ẹ̀kọ́ wọn, bí wọ́n ṣe ń ṣàpèjúwe Ọlọ́run àtàwọn àlàyé tí wọ́n máa ń ṣe nípa àwọn nǹkan tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe. Àwọn ẹ̀rí wo la ní láti fi ti ọ̀rọ̀ yìí lẹ́yìn?

Ọ̀gbẹ́ni Hans Küng, tó jẹ́ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn Kátólíìkì, sọ pé àwọn ìlànà nípa àjọṣe ẹ̀dá kò yàtọ̀ síra nínú àwọn ẹ̀sìn tọ́pọ̀ èèyàn ń ṣe kárí ayé. Bí àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ àwọn ẹ̀sìn wọ̀nyí ló ń kọ́ àwọn èèyàn pé kí wọ́n má parọ́, kí wọ́n má jalè, kí wọ́n má pààyàn, kí wọ́n máà bá ìbátan wọn ṣèṣekúṣe, káwọn ọmọ máa gbọ́ràn sáwọn òbí wọn lẹ́nu, káwọn òbí sì fẹ́ràn àwọn ọmọ wọn. Àmọ́ ṣá o, ẹnu àwọn onísìn wọ̀nyí ò kò lórí àwọn ọ̀ràn míì, pàápàá jù lọ lórí bí wọ́n ṣe ń ṣàpèjúwe irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́.

Bí àpẹẹrẹ, àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù máa ń jọ́sìn àwọn òòṣà àkúnlẹ̀bọ tí kò lóǹkà, nígbà táwọn ẹlẹ́sìn Búdà ní kò dá àwọn lójú pé Ọlọ́run wà. Àwọn ẹlẹ́sìn Ìsìláàmù gbà pé Ọlọ́run ò pé méjì. Ohun táwọn oníṣọ́ọ̀ṣì tí wọ́n gbà pé àwọ́n jẹ́ Kristẹni náà sì gbà gbọ́ nìyẹn, àmọ́ ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ló tún gbà gbọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ mẹ́talọ́kan. Kódà, ọ̀pọ̀ àwọn oníṣọ́ọ̀ṣì ni ìgbàgbọ́ wọn ò dọ́gba. Àwọn Kátólíìkì máa ń jọ́sìn Màríà, ìyá Jésù, àmọ́ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ò fara mọ́ èrò yẹn. Àwọn Kátólíìkì ò fara mọ́ ìfètòsọ́mọbíbí, àmọ́ àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ò lòdì sí ìfètòsọ́mọbíbí. Bẹ́ẹ̀ sì rèé ẹnu àwọn Pùròtẹ́sítáǹtì ò kò lórí bóyá káwọn fara mọ́ ìbẹ́yà-kan-náà-lòpọ̀ tàbí káwọn má fara mọ́ ọn.

Ṣé a wá lè sọ pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo àwọn ẹ̀sìn tí ẹ̀kọ́ wọn ò dọ́gba yìí ń sìn? Ó dájú pé a ò ní sọ bẹ́ẹ̀. Tá a bá sì wá sọ bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìdàrúdàpọ̀ nípa irú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ àtàwọn ohun tó ń retí látọ̀dọ̀ àwọn tó ń sìn ín la fẹ́ dá sílẹ̀ yẹn.

Ṣé Ìmọ̀ Wọn Ṣọ̀kan àbí Ó Ta Kora?

Tó bá jẹ́ pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo ẹlẹ́sìn ń ké pè, ó yẹ káwọn ẹ̀sìn yìí níkọ̀ọ̀kan ti máa mú káwọn èèyàn wà níṣọ̀kan àti lálàáfíà. Àmọ́, ṣé ẹ̀rí wà pé àwọn èèyàn ṣọ̀kan lóòótọ́? Àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn ti jẹ́ ká rí i pé dípò kí ẹ̀sìn mú káwọn èèyàn ṣọ̀kan, ṣe ló ń pín wọn níyà tó sì ń dá ìjà sílẹ̀. Ẹ jẹ́ ká gbé àpẹẹrẹ díẹ̀ yẹ̀ wò.

Láti ọ̀rúndún kọkànlá sí ọ̀rúndún kẹtàlá, onírúurú ogun ẹ̀sìn làwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìyẹn àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń pera wọn ni Kristẹni, jà pẹ̀lú àwọn orílẹ̀-èdè Mùsùlùmí. Ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún nílẹ̀ Yúróòpù, odindi ọgbọ̀n [30] ọdún làwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì fi wọ̀yá ìjà. Lọ́dún 1947, ṣe làwọn onísìn Híńdù àtàwọn Mùsùlùmí bẹ̀rẹ̀ sí í bára wọn jà ní gbàrà táwọn orílẹ̀-èdè tó wà lágbègbè Íńdíà gbòmìnira kúrò lábẹ́ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì. Ọ̀pọ̀ ọdún làwọn Kátólíìkì àtàwọn Pùròtẹ́sítáǹtì fi bára wọn jà láìpẹ́ yìí lágbègbè Northern Ireland. Ní Àárín Gbùngbùn Ìlà Oòrùn ayé, kò sí àlàáfíà láàárín àwọn Júù àtàwọn Mùsùlùmí. Ju gbogbo ẹ̀ lọ, gbogbo àwọn ẹlẹ́sìn márààrún tó gbajúmọ̀ jù lọ lágbàáyé ló lọ́wọ́ sí Ogun Àgbáyé Kejì, kódà àwọn tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn kan náà láti orílẹ̀-èdè ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ bára wọn jà.

Àwọn àpẹẹrẹ yìí jẹ́ kó ṣe kedere pé àwọn ìsìn tó wà lágbàáyé ò mú àlàáfíà àti ìṣọ̀kan wá, bẹ́ẹ̀ la ò sì lè sọ pé Ọlọ́run kan náà ni gbogbo wọn ń sìn. Dípò káwọn ìsìn yìí so àwọn èèyàn pọ̀ kí ìmọ̀ wọn lè ṣọ̀kan, ìpínyà ni wọ́n ń dá sílẹ̀ tí wọn ò sì jẹ́ káwọn èèyàn mọrú ẹni tí Ọlọ́run jẹ́ gan-an àti bó ṣe yẹ ká sìn ín. Torí náà, ó yẹ kẹ́ni tó bá fẹ́ jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́ fara balẹ̀ yan ìsìn tóun fẹ́ ṣe. Ìyẹn sì bá ìmọ̀ràn tó wà nínú Bíbélì mu, ọ̀kan lára àwọn ìwé ìsìn tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ dáadáa.

Ẹ Yan Ẹni Tẹ́ Ẹ Máa Sìn Fúnra Yín

Bíbélì jẹ́ kó ṣe kedere pé èèyàn gbọ́dọ̀ ronú jinlẹ̀, kó sì fúnra ẹ̀ pinnu ohun tó bá fẹ́ ṣe kó tó lè mọ ọ̀nà tó lọ sọ́dọ̀ Ọlọ́run tòótọ́. Jóṣúà, tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run tòótọ́, sọ fáwọn ọmọ Ísírẹ́lì àtijọ́ pé: “Ẹ yan ẹni tí ẹ̀yin yóò máa sìn fún ara yín, yálà àwọn ọlọ́run tí àwọn baba ńlá yín tí wọ́n wà ní ìhà kejì Odò tẹ́lẹ̀ sìn ni tàbí àwọn ọlọ́run àwọn Ámórì ní ilẹ̀ àwọn ẹni tí ẹ ń gbé. Ṣùgbọ́n ní tèmi àti agbo ilé mi, Jèhófà ni àwa yóò máa sìn.” Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, wòlíì Èlíjà tún rọ àwọn ọmọ Ísírẹ́lì láti ṣerú yíyàn kan náà, ó ní: “Yóò ti pẹ́ tó tí ẹ ó fi máa tiro lórí èrò méjì tí ó yàtọ̀ síra? Bí Jèhófà bá ni Ọlọ́run tòótọ́, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn; ṣùgbọ́n bí Báálì [ìyẹn ọlọ́run àwọn ará Kénáánì] bá ni, ẹ máa tọ̀ ọ́ lẹ́yìn.”—Jóṣúà 24:15, 16; 1 Àwọn Ọba 18:21.

Àwọn ẹsẹ Bíbélì yìí àtàwọn ẹsẹ míì tẹnu mọ́ ọn pé àwọn tó bá fẹ́ sin Ọlọ́run tòótọ́ nígbà yẹn gbọ́dọ̀ ṣèpinnu tó máa bá ẹ̀rí ọkàn wọn mu. Bọ́ràn sì ṣe rí lóde òní náà nìyẹn. Táwa náà bá fẹ́ máa jọ́sìn Ọlọ́run tòótọ́, a gbọ́dọ̀ ṣèpinnu tó tọ́. Àmọ́, kí ló máa ràn wá lọ́wọ́ ká lè ṣerú ìpinnu yẹn nípa ìjọsìn wa? Báwo la ṣe lè mọ àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ yàtọ̀?

Èso Wọn La Máa Fi Dá Wọn Mọ̀

Jésù Kristi sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ nípa àwọn tó ń ṣe ìsìn tòótọ́ àtàwọn tó ń ṣe ìsìn èké pé: “Àwọn ènìyàn kì í kó èso àjàrà jọ láti ara ẹ̀gún tàbí ọ̀pọ̀tọ́ láti ara òṣùṣú, wọ́n ha ń ṣe bẹ́ẹ̀ bí? Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, gbogbo igi rere a máa mú èso àtàtà jáde, ṣùgbọ́n gbogbo igi jíjẹrà a máa mú èso tí kò ní láárí jáde; igi rere kò lè so èso tí kò ní láárí, bẹ́ẹ̀ ni igi jíjẹrà kò lè mú èso àtàtà jáde. . . . Ní ti tòótọ́, nígbà náà, nípa àwọn èso wọn ni ẹ ó fi dá àwọn ènìyàn wọnnì mọ̀.” Ìyẹn fi hàn pé èso tàbí ìwà àwọn tó bá ń ṣe ìjọsìn tòótọ́ la máa fi dá wọn mọ̀. Àwọn èso wo wá nìyẹn?—Mátíù 7:16-20.

Àkọ́kọ́ ni pé, ìsìn tòótọ́ máa ń mú káwọn tó bá ń ṣe é wà níṣọ̀kan torí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn. Jésù ṣàlàyé fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Èmi ń fún yín ní àṣẹ tuntun kan, pé kí ẹ nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì; gan-an gẹ́gẹ́ bí mo ti nífẹ̀ẹ́ yín, pé kí ẹ̀yin pẹ̀lú nífẹ̀ẹ́ ara yín lẹ́nì kìíní-kejì. Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” Àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi tòótọ́ gbọ́dọ̀ máa fi hàn pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ ara wọn káwọn èèyàn lè rí i pé olùjọsìn tòótọ́ ni wọ́n.—Jòhánù 13:34, 35.

Torí náà, kò ní bọ́gbọ́n mu pé káwọn Kristẹni tòótọ́ máa bára wọn jà lójú ogun. Àmọ́, ṣáwọn oníṣọ́ọ̀ṣì kì í bára wọn jà lójú ogun? Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìkan làwọn onísìn tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ tó kọ̀ jálẹ̀, tí wọn ò sì yíhùn pa dà pé àwọn ò ní lọ́wọ́ sógun náà lọ́nàkọnà. Dókítà Hanns Lilje, tó jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù nígbà kan rí ní Ṣọ́ọ̀ṣì Pùròtẹ́sítáǹtì tó wà nílùú Hannover lórílẹ̀-èdè Jámánì kọ̀wé nípa àwọn Ẹlẹ́rìí pé: “Àwọn nìkan ni wọ́n lè fọwọ́ sọ̀yà pẹ̀lú ẹ̀rí ọkàn tó mọ́ pé àwọn ò lọ́wọ́ sí ìjọba Násì.” Nígbà tí ìjà yẹn ń lọ lọ́wọ́, ó tẹ́ ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà láwọn ilẹ̀ tó yàtọ̀ síra lọ́run láti jìyà ju pé kí wọ́n lọ́wọ́ sógun lọ.

Àwọn èso míì wo ni Jésù ní lọ́kàn pé ó máa jẹ́ ká mọ àwọn ọmọ ẹ̀yìn tòótọ́ yàtọ̀? Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù fi bẹ̀rẹ̀ àdúrà tọ́pọ̀ èèyàn mọ̀ sí Àdúrà Olúwa ni pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.” Bá a ṣe máa sọ orúkọ Ọlọ́run, ìyẹn Jèhófà di mímọ́ ló jẹ Jésù lógún jù lọ. Ó gbà á ládùúrà pé kí ìfẹ́ Jèhófà ṣẹ lórí ilẹ̀ ayé nípasẹ̀ Ìjọba Ọlọ́run. Àwọn ẹlẹ́sìn wo la mọ̀ tí wọ́n ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ Jèhófà, orúkọ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló lè mú àlááfíà wá sórí ilẹ̀ ayé? Igba-ó-lé-mẹ́rìndínlógójì [236] orílẹ̀-èdè àti ìpínlẹ̀ ìwàásù làwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run, tá a sì ń pín àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ ní èdè tó lé ní àádọ́rin-lé-nírinwó [470].—Mátíù 6:9, 10.

Yàtọ̀ síyẹn, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Jésù ní ti pé a kì í lọ́wọ́ sọ́rọ̀ òṣèlú àtàwọn àríyànjiyàn àdúgbò. Jésù sọ nípa àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tún gbà pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni Bíbélì, ó sì dá wa lójú pé “gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.”—Jòhánù 17:14, 17; 2 Tímótì 3:16, 17.

Ẹ̀sìn Tòótọ́ Yàtọ̀ Gedegbe

Àwọn èso tá a ti mẹ́nu bà yìí, ìyẹn ìfẹ́ àìmọ-tara-ẹni-nìkan, fífẹ́ láti sọ orúkọ Jèhófà di mímọ́, kíkéde Ìjọba Ọlọ́run, yíyara-ẹni-sọ́tọ̀ kúrò nínú ayé àti ìgbàgbọ́ nínú Bíbélì la lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ yàtọ̀. Àwọn èso wọ̀nyí tún jẹ́ káwọn tó ń ṣe ẹ̀sìn tòótọ́ yàtọ̀ gedegbe sáwọn ẹlẹ́sìn yòókù. Ọ̀dọ́bìnrin kan tó ti sábà máa ń jíròrò pẹ̀lú àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà sọ èrò ọkàn ẹ̀ lọ́jọ́ kan, ó ní: “Ọ̀pọ̀ ẹ̀sìn ni mo ti mọ̀, wọn ò sì fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ síra wọn. Àmọ́ ẹ̀yin nìkan lẹ yàtọ̀ sáwọn ẹlẹ́sìn yòókù.”

Ó ti wá ṣe kedere báyìí pé Ọlọ́run kan náà kọ́ ni gbogbo ẹlẹ́sìn ń ké pè. Àmọ́ àwọn ẹlẹ́sìn kan wà tí wọ́n dá yàtọ̀ gedegbe sáwọn yòókù, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni, wọ́n sì ti lé ní mílíọ̀nù méje kárí ayé báyìí. Torí pé wọ́n ń kéde Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń tẹ̀ lé àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, wọ́n ti ṣohun táwọn ẹlẹ́sìn tàbí àjọ míì ò lè ṣe, ìyẹn ni pé wọ́n ti mú káwọn èèyàn tó wá láti orílẹ̀-èdè tó yàtọ̀ síra, tí èdè, àṣà ìbílẹ̀ àti ìran wọn ò sì dọ́gba, wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà. Inú wọn máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà, kó o lè mohun tó fẹ́ kó o ṣe, kó o sì lè gbádùn àlááfíà àti ààbò téèyàn máa ń ní tó bá ń sin Ọlọ́run lọ́nà tí Ọlọ́run fẹ́. Àbó ò rí i pé ohun tó dáa, tó yẹ kéèyàn ṣe gan-an nìyẹn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 14]

Àlùfáà ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ń gbàdúrà fáwọn ọmọ ogun tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sílùú Ukraine lọ́dún 2004

[Credit Line]

GENIA SAVILOV/AFP/Getty Images

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń ran àwọn èèyàn níbi gbogbo lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run àti Ìjọba rẹ̀

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 12]

Ojú ìwé 12: Obìnrin ẹlẹ́sìn Búdà: © Yan Liao/Alamy; Ọkùnrin mímọ́ ẹlẹ́sìn Híńdù: © imagebroker/Alamy; ojú ìwé 13: Ọkùnrin tó ń ka Kùránì: Mohamed Amin/Camerapix; Ọkùnrin Júù: Todd Bolen/Bible Places.com