Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fi Ìṣòro Jẹ Wá Níyà?

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fi Ìṣòro Jẹ Wá Níyà?

Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé

Ṣé Ọlọ́run Ló Ń Fi Ìṣòro Jẹ Wá Níyà?

Ṣé ìṣẹ̀lẹ̀ búburú kan tí ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí débi tó o fi béèrè bóyá Ọlọ́run ló ń fi ìṣòro yẹn jẹ ẹ́ níyà? Àìsàn tó bẹ̀rẹ̀ lójijì, jàǹbá tó sọ ẹnì kan daláàbọ̀ ara tàbí ọ̀fọ̀ tó ṣẹ nínú ìdílé lè jẹ́ ká máa rò ó pé Ọlọ́run dìídì dójú sọ wá kó lè fìyà jẹ wá.

Jẹ́ kó dá ẹ lójú pé ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run fẹ́ káwọn èèyàn máa láyọ̀, kò sì fẹ́ kíyà máa jẹ wọ́n. Ẹ̀rí fi hàn pé Ọlọ́run fẹ́ ká máa láyọ̀ lóòótọ́ nígbà tó dá Ádámù àti Éfà, ó fi wọ́n sínú “ọgbà Édẹ́nì,” Párádísè tó dà bí ọgbà ìtura kan, níbi tí kò ti ní sí ìṣòro èyíkéyìí fún wọn.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15.

Ó ṣeni láàánú pé tọkọtaya àkọ́kọ́ fọwọ́ ara wọn gbé nǹkan ńlá yìí sọ nù, wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run. Ọ̀ràn ńlá lohun tí wọ́n ṣe yẹn yọrí sí fún wọn, kì í tún wá ṣe fáwọn nìkan, àmọ́ fún gbogbo àtọmọdọ́mọ wọn títí kan àwa náà. Kí nìdí tó fi rí bẹ́ẹ̀? Ọ̀rọ̀ yìí dà bí ìgbà tí baálé ilé kan ò bá san owó ilé tóun àti ìdílé ẹ̀ ń gbé, onílé á lé wọn síta, wọn ò ní nílé lórí mọ́, ìyà á sì bẹ̀rẹ̀ sí í jẹ wọn. Bákan náà, gbogbo èèyàn ló ń jìyà torí àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ti ṣọ̀tẹ̀. (Róòmù 5:12) Ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Jóòbù ọkùnrin olóòótọ́ náà sọ pé ká ní ìrora àti ìyà tó ń jẹ òun ṣeé gbé “lé orí òṣùwọ̀n” ni, wọ́n máa “wúwo ju iyanrìn òkun” lọ.—Jóòbù 6:2, 3.

Nǹkan míì tó tún ń fa ìṣòro ni bí àwa èèyàn kò ṣe kí ń mohun tó máa ṣẹlẹ̀ lọ́la. Bí àpẹẹrẹ, ká sọ pé ẹnì kan tó ń kọ́lé tó sì ń talé kọ́ ọ ságbègbè tí iná ti sábà máa ń jà. Àmọ́ torí pé ìwọ ò mọ irú ọṣẹ́ tí iná máa ń ṣe lágbègbè náà, o lọ ra ọ̀kan lára ilé tẹ́ni náà kọ́, o sì ń gbé níbẹ̀. Ṣé kì í ṣe inú ewu lo máa kó ara ẹ àti ìdílé ẹ sí? Ṣó o wá lè sọ pé Ọlọ́run ló ń fìyà jẹ ẹ́ tí ìṣòro èyíkéyìí bá dé torí ibi tó o ralé sí? Òótọ́ ni ohun tí ẹsẹ Bíbélì yìí sọ pé: “Ẹnikẹ́ni tí ó jẹ́ aláìní ìrírí ń ní ìgbàgbọ́ nínú gbogbo ọ̀rọ̀, ṣùgbọ́n afọgbọ́nhùwà máa ń ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Òwe 14:15.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kò sẹ́ni tí kò lè níṣòro, ó tù wá nínú láti mọ̀ pé Ọlọ́run ti ṣèlérí pé láìpẹ́ èèyàn máa bọ́ lọ́wọ́ ìpọ́njú. Tákòókò yẹn bá tó, kò sẹ́ni tó máa ní ìpọ́njú, kò sẹ́ni tó máa rí i, a ò sì ní gbúròó ohun tó ń jẹ́ bẹ́ẹ̀ mọ́ láé. Omijé ìbànújẹ́, ìrora, ikú àti ọ̀fọ̀ ti máa “kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:4) Nǹkan míì tó tún múnú wa dùn ni ìlérí tí Ọlọ́run ṣe pé ogun tàbí ìjábá ò ní ba ilé tàbí irè oko àwọn èèyàn jẹ́ mọ́. Dípò ìyẹn, iṣẹ́ ọwọ́ ara wọn làwọn èèyàn máa “lò dé ẹ̀kún rẹ́rẹ́.”—Aísáyà 65:21-25.

Bó o ṣe ń dúró dìgbà tí Ọlọ́run máa mú ìpọ́njú kúrò pátápátá, kí lo lè ṣe nísinsìnyí láti dín ìṣòro tí ìpọ́njú ń fà kù? Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Bíbélì gbà wá níyànjú pé ká ‘má ṣe gbára lé òye tara wa,’ àmọ́ ká ‘fi gbogbo ọkàn-àyà wa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.’ (Òwe 3:5) Òun ni kó o jẹ́ kó máa tọ́ ẹ sọ́nà, kó sì máa tù ẹ́ nínú. Máa fiyè sí ọgbọ́n tó ń ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá èyí tá a rí nínú Bíbélì. Ìyẹn máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti ṣèpinnu tó mọ́gbọ́n dání, á sì jẹ́ kó o bọ́ lọ́wọ́ àwọn ìṣòro tó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀.—Òwe 22:3.