Ọpẹ́ Mi Pọ̀ Láìka Àwọn Àjálù Tó Bá Mi Sí—Bí Bíbélì Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á
Ọpẹ́ Mi Pọ̀ Láìka Àwọn Àjálù Tó Bá Mi Sí—Bí Bíbélì Ṣe Ràn Mí Lọ́wọ́ Láti Fara Dà Á
Gẹ́gẹ́ bí Enrique Caravaca Acosta ṣe sọ ọ́
Ọjọ́ burúkú lọjọ́ kẹẹ̀ẹ́dógún, oṣù April, ọdún 1971 jẹ́ fún mi. Mò ń lọ sílé láti lọ wo àwọn aráalé mi tó wà níbi tí ìdílé wa dáko sí. Ojú mi ti wà lọ́nà láti rí gbogbo wọn torí ó ti pẹ́ díẹ̀ tí mo ti kúrò nílé. Mò ń rò ó lọ́kàn mi pé bóyá ni màá bá gbogbo wọn nílé àti pé ta tiẹ̀ ni màá kọ́kọ́ rí nínú wọn ná? Nígbà tí mo délé, orí mi fò lọ nígbà tí mo bá òkú èèyàn mẹ́rin nílẹ̀, títí kan òkú màmá mi!
MO TI kú sára. Kí ló ṣẹlẹ̀? Kí ni màá ṣe? Kò sẹ́nì kankan nítòsí láti ṣàlàyé ohun tó ṣẹlẹ̀ fún mi, jìnnìjìnnì bò mí. Kí n tó máa bá ìtàn yìí lọ, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ díẹ̀ fún yín nípa ibi tí mo ti wá. Ìyẹn á jẹ́ kẹ́ ẹ lóye bí ìtàn tí mò ń sọ yìí, àtàwọn àjálù míì tó bá mi nígbèésí ayé ṣe rí lára mi.
A Rí Òtítọ́
Ìlú Quirimán, nítòsí ìlú Nicoya lórílẹ̀-èdè Costa Rica ni wọ́n ti bí mi. Lọ́dún 1953, nígbà tí mo wà lọ́mọ ọdún mẹ́tàdínlógójì [37], mò ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí mi níbi tí ìdílé wa dáko sí. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé inú ẹ̀sìn Kátólíìkì ni wọ́n ti tọ́ wa dàgbà, inú wa ò dùn sáwọn ẹ̀kọ́ wọn kan, a sì láwọn ìbéèrè tó pọ̀ tá ò rí ìdáhùn sí.
Lọ́jọ̀ kan, ọkùnrin kan tó ń jẹ́ Anatolio Alfaro wá sílé wa, ó sì gbà wá níyànjú pé ká kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ṣàlàyé ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ àtàwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì fún wa. Bàbá mi, màmá mi, ọ̀kan lára àwọn ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àbúrò mi obìnrin àtọ̀rẹ́ ẹ̀ tó ń gbé lọ́dọ̀ wa àtèmi, gbogbo wa la jókòó tá a sì tẹ́tí sí ọkùnrin náà. Ìjíròrò yẹn gba gbogbo ọjọ́ náà lọ́wọ́ wa títí di alẹ́ pátápátá. A bi í ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè.
Ilé wa ni Anatolio sùn mọ́jú ọjọ́ kejì, ọ̀dọ̀ wa náà ló sì wà lọ́jọ́ kejì pẹ̀lú. Àwọn ohun tá a gbọ́ lọ́jọ́ yẹn dùn mọ́ wa gan-an, inú wa sì túbọ̀ dùn torí pé Bíbélì ló fi dáhùn àwọn ìbéèrè wa. Ìjíròrò yẹn nípa rere lórí wa. Nígbà tá a ronú lórí àwọn ohun tá a ti kọ́, a wá mọ̀ pé a ti rí òtítọ́. Anatolio fún wa ní díẹ̀ lára àwọn ìwé ìròyìn àtàwọn ìwé ńlá tó ṣàlàyé Bíbélì. Lálaalẹ́, ìdílé wa máa ń kẹ́kọ̀ọ́ àwọn ìwé yìí pa pọ̀. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yẹn ò rọrùn fún wa rárá, torí a ò ní iná mànàmáná. Ká tó bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́, ẹnì kọ̀ọ̀kan wa máa ń da àpò ńlá tá a fi ń kó ànàmọ́ sí bo ẹsẹ̀ wa torí ẹ̀fọn.
Kò ju oṣù mẹ́fà lọ lẹ́yìn ìgbà náà táwa márùn-ún ṣèrìbọmi, títí kan èmi àtàwọn òbí mi. Inú wa dùn gan-an, a sì bẹ̀rẹ̀ sí í lọ láti ilé dé ilé ká lè sọ nǹkan tá a ti kọ́ fáwọn èèyàn. A máa ń fẹsẹ̀ rìn tàbí ká gun ẹṣin, fún nǹkan bíi wákàtí méjì láti lọ ṣèpàdé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà
tó wà nílùú kan tó ń jẹ́ Carrillo. Anatolio ṣì ń bá a nìṣó láti máa wá kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nílé wa. Lẹ́yìn náà, wọ́n ṣètò pé ká máa ṣèpàdé ìjọ nílé wa, àwa mẹ́jọ la sì máa ń pésẹ̀ síbẹ̀. Gbogbo àwọn tá a jọ ń ṣèpàdé nígbà yẹn ló ṣèrìbọmi nígbà tó yá. Kò pẹ́ sígbà yẹn táwa ẹni mẹ́jọ yẹn fi di ìjọ kékeré tó ní ogun [20] èèyàn.Mo Bẹ̀rẹ̀ Sí Í Fi Ọ̀pọ̀ Wákàtí Wàásù
Nígbà tó yá, ẹ̀ka ọ́fíìsì àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà lórílẹ̀-èdè Costa Rica ké sí àwọn ará wa tó bá ṣeé ṣe fún pé kí wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pọ̀ wákàtí wàásù. Lọ́dún 1957, èmi náà gba ìkésíni yìí, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí í fi ọ̀pọ̀ wákàtí wàásù. Mo gbádùn iṣẹ́ yẹn gan-an ni. Mo sábà máa ń dá nìkan rìn fún ọ̀pọ̀ wákàtí kí n lè dé ọ̀dọ̀ àwọn tó wà láwọn abúlé tó jìnnà réré. Ìgbà míì wà táwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́rọ̀ mi. Mo rántí pé ó tó ìgbà mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ táwọn èèyàn fi àdá halẹ̀ mọ́ mi, tí wọ́n láwọn fẹ́ mọ irú ẹni tí mo jẹ́ àtohun tí mò ń wá lábúlé àwọn.
Láwọn ọdún 1950, ojúgbó làwọn ọ̀nà táwọn èèyàn ń gbà nígbà yẹn, èyí sì jẹ́ kó nira díẹ̀ láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn. Àfi ká gun ẹṣin ká tó lè dé àwọn ibòmíì. A máa ń gba inú odò kọjá, ìgbà míì sì wà tá a máa ń sun ìta gbangba. Àwọn ẹ̀fọn tó máa ń kùn yunmu máa ń fojú wa rí màbo. A kì í sì í lè sùn wọra torí àwọn ejò àti ọ̀nì. Láìka gbogbo èyí sí, inú mi máa ń dùn gan-an láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ kí wọ́n lè mọ̀ nípa Jèhófà Ọlọ́run. Nígbà tí mo bá pa dà délé, inú mi máa ń dùn, ọkàn mi sì máa ń balẹ̀ pé mo ti láǹfààní láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe ń wàásù tí mo sì ń kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lójoojúmọ́ ni ìfẹ́ tí mo ní sí Jèhófà Ọlọ́run túbọ̀ ń pọ̀ sí i, mo sì túbọ̀ sún mọ́ Ọlọ́run.
Nígbà tó yá, mo tún láwọn àfikún iṣẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run. Ó lé lọ́dún mẹ́wàá tí mo fi ń ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò, mò ń lọ láti ìjọ àdúgbò kan sí òmíràn lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti bẹ àwọn ará wa wò àti láti gbé wọn ró. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àìlera ò jẹ́ kí n lè máa bá iṣẹ́ yìí lọ nígbà tó yá, mo ṣì ń gbádùn fifi ọ̀pọ̀ àkókò wàásù.
Àjálù Dé Bá Mi
Nígbà tí mo wà nílùú Nicoya lọ́dún 1971, mo rìnrìn àjò lọ sílé láti lọ wo àwọn èèyàn mi. Bí mo ṣe wọlé báyìí, mo rí màmá mi, ẹni ọgọ́rin [80] ọdún, nílẹ̀ẹ́lẹ̀. Ẹnì kan ti yìnbọn fún wọn, ó sì tún gún wọn lọ́bẹ. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ láti gbá wọn mú, mo rí i pé wọ́n ṣì ń mí. Àmọ́, kò pẹ́ rárá tí wọ́n fi dákẹ́ sí mi lọ́wọ́. Ìgbà tí mo sì tún máa gbójú sókè, òkú ẹni tó máa ń bá wa se oúnjẹ ni mo rí nílẹ̀ẹ́lẹ̀ ilé ìdáná tòun toyún oṣù mẹ́jọ. Àṣé mi ò tíì rí nǹkan kan, bí mo ṣe ní kí n bọ́ sáàárín ọ̀dẹ̀, òkú arábìnrin kan nínú ìjọ wa ni mo tún bá nílẹ̀, mo sì tún rí òkú ọmọkùnrin ẹni tó máa ń bá wa se oúnjẹ nílé ìwẹ̀. Gbogbo wọn ni wọ́n ti yìnbọn fún, tí wọ́n sì ti gún lọ́bẹ. Ta ló wá lè ṣe ohun tó tóyìí, kí sì nìdí tónítọ̀hún fi ṣe ohun tó tó báyìí?
Bí mo ṣe jáde síta mo rí bàbá mi. Ìbọn ti bà wọ́n lórí, àmọ́ wọn ò tí ì kú! Mo bá sáré lọ sílé àbúrò mi ọkùnrin, ìrìn ilé ẹ̀ ò ju nǹkan bí ìṣẹ́jú mẹ́ẹ̀ẹ́dógún [15] lọ, ìgbà tí mo débẹ̀ náà, mo tún gbọ́ pé wọ́n ti pa obìnrin kan àtọmọ ẹ̀ ọkùnrin níbẹ̀. Orí mi fò lọ nígbà tí mo gbọ́ pé ọmọ àbúrò mi obìnrin tí kò ju ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún [17] lọ, ló ń ṣọṣẹ́ yìí, ọmọ yìí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọ́n sì tún sọ pé ó lárùn ọpọlọ! Ó ti sá kúrò lágbègbè náà. Bí ìjọba ṣe da àwọn ọlọ́pàá sígboro nìyẹn pé kí wọ́n máa wà á, irú ẹ̀ ò ṣẹlẹ̀ rí lórílẹ̀-èdè Costa Rica.
Kò síbi tí wọn ò ti gbọ́ ìròyìn yìí lórílẹ̀-èdè Costa Rica. Lẹ́yìn ọjọ́ méje, àwọn ọlọ́pàá rí apààyàn yìí, wọ́n rí ọ̀bẹ ńlá kan lọ́wọ́ ẹ̀ àti ìbọn ìléwọ́ kan tẹ́nì kan tà fún un, tẹ́ni ọ̀hún sì mọ̀ pé orí ẹ̀ ti yí. Ìgbà tí wọn ò tètè rí i mú, ni wọ́n bá yìn ín níbọn, ó sì gbabẹ̀ kú.
Nígbà tí wọ́n ṣì ń wá ọmọ yìí lọ́wọ́, àwọn èèyàn sọ pé kí n sá kúrò nílùú torí ó ṣì lè pa dà wálé, kó sì wá pa èmi náà. Mo gbàdúrà nípa èyí torí mo mọ̀ pé ó yẹ kí n wà pẹ̀lú àwọn tó kù nínú ìdílé mi àtàwọn ará nínú ìjọ. Torí náà, mi ò lọ ibì kankan.
Bí Mo Ṣe Ń Bọ́ Nínú Àjálù Kan Ni Òmíràn Ń Dé Bá Mi
Ó ṣe mí láàánú pé bàbá mi ò lò ju ọdún kan lọ lẹ́yìn ìgbà yẹn tí wọ́n fi kú. Lọ́dún tó tẹ̀ lé e, àbúrò mi obìnrin, tó jẹ́ olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run kú nínú jàǹbá míì kan tó wáyé. Ìṣẹ̀lẹ̀ yìí tún kó ìbànújẹ́ bá gbogbo mọ̀lẹ́bí wa. Ọ̀rọ̀ ẹnu lásán ò lè ṣàlàyé àdánù àti ìbànújẹ́ táwa àtàwọn ọ̀rẹ́ wa ní. Nígbà tí gbogbo àjálù yìí wáyé, Jèhófà ni mo gbẹ́kẹ̀ lé pátápátá, mo sì ń bẹ̀ ẹ́ nígbà gbogbo pé kó fún mi lókun.
Lọ́dún 1985, mo lọ sí San José, ìyẹn olú ìlú orílẹ̀-èdè Costa Rica, fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ ọlọ́jọ́ mẹ́ta tó wà fáwọn Kristẹni alàgbà. Ìdálẹ́kọ̀ọ́ náà fún àjọṣe mi pẹ̀lú Jèhófà lókun gan-an ni. Láàárọ̀ kùtù ọjọ́ Monday, mò ń lọ síbi tí mo ti máa wọkọ̀ pa dà sílé. Bí mo ṣe ń lọ, àwọn ọmọ jàǹdùkú kan pàdé mi, wọ́n sì fipá gba gbogbo nǹkan tó wá lọ́wọ́ mi. Páá-pàà-pá ni wọ́n ṣe é, débi pé mi ò rí ojú ẹnì kankan nínú wọn. Èyí ò jẹ́ kí n lè sọ̀rọ̀ bí ọmọ orílẹ̀-èdè Costa Rica lọ́jọ́ náà. Lágbègbè Guanacaste tí mo wà, àwọn ọkùnrin máa ń kígbe tàbí kí wọ́n pariwo nígbà tí wọ́n bá ń kíra wọn tàbí tí wọ́n bá fẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ pé àwọ́n wà nítòsí. Mo máa ń pariwo dáadáa tẹ́lẹ̀, àmọ́ lẹ́yìn táwọn ọmọ jàǹdùkú yìí pàdé mi, mi ò lágbára láti pariwo mọ́.
Lọ́dún 1979, mo fẹ́ Celia, tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí nínú ìjọ kan tó wà ládùúgbò wa. Celia fẹ́ràn Bíbélì gan-an. Ojoojúmọ́ la jọ máa ń ka Bíbélì, tá a sì máa ń kẹ́kọ̀ọ́ látinú ẹ̀. Ọkàn mi gbọgbẹ́ nígbà tí àrùn jẹjẹrẹ gbẹ̀mí Celia lóṣù July ọdún 2001. Nígbà míì, mo máa ń nímọ̀lára pé mo dá nìkan wà, àmọ́ ìrètí àjíǹde máa ń fún mi lókun.—Jòhánù 5:28, 29.
Mo Láyọ̀ Láìka Àwọn Ìṣòro Mi Sí
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìṣòro ìgbésí ayé mi lè pọ̀ ju tọ̀pọ̀ èèyàn lọ, mo ka àwọn ìṣòro yìí sóhun tó máa jẹ́ kí n lè fi hàn pé mo nígbàgbọ́ nínú Jèhófà, mo sì jẹ́ adúróṣinṣin sí i. (Jákọ́bù 1:13) Káwọn ìṣòro yìí má bàa kó ìrònú bá mi ju bó ṣe yẹ lọ, mo máa ń rán ara mi létí pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ló ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníwàásù 9:11) Mo tún máa ń rántí pé àkókò tá a wà báyìí jẹ́ “àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” torí pé àwọn èèyàn jẹ́ ìkà, oníwà ipá àti aláìní ìkóra-ẹni-níjàánu. (2 Tímótì 3:1-5) Mi ò gbàgbé àpẹẹrẹ Jóòbù pàápàá. Láìka àwọn ìṣòro tó ní sí, ìyẹn àwọn ọmọ ẹ̀ tó pàdánù, àìsàn tó kọ lù ú, táwọn nǹkan ìní ẹ̀ sì ṣègbé, síbẹ̀ Jóòbù sọ pé: “Kí orúkọ Jèhófà máa bá a lọ láti jẹ́ èyí tí a bù kún fún.” Jèhófà sì bù kún Jóòbù gan-an fún bó ṣe di ìwà títọ́ rẹ̀ mú. (Jóòbù 1:13-22; 42:12-15) Gbogbo àwọn nǹkan tí mò ń rántí látinú Bíbélì yìí ràn mí lọ́wọ́ láti máa láyọ̀ láìka àwọn ìṣòro mi sí.
Gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń ràn mí lọ́wọ́ kí n lè máa fi í sípò àkọ́kọ́ nígbèésí ayé mi. Kíka Bíbélì déédéé jẹ́ orísun ìtùnú gidi fún mi, ó sì ti fún mi lókun láti fara da àwọn ìṣòro mi. Àdúrà tí mò ń gbà sí Jèhófà ti jẹ́ kí n ní “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ.” (Fílípì 4:6, 7) Èyí jẹ́ kí n ní àlááfíà ọkàn. Pípésẹ̀ sáwọn ìpàdé Kristẹni àti kíkópa nínú àwọn ìpàdé náà tún ń fún ìgbàgbọ́ mi lókun.—Hébérù 10:24, 25.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àgbà ti dé báyìí, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé mo ṣì lókun láti máa ṣiṣẹ́ pẹ̀lú àwọn tá a jọ jẹ Kristẹni, láti máa wàásù àti láti máa kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bí mo ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láwọn ọ̀nà yìí máa ń fún mi lágbára láti fara da àwọn ìṣòro mi. Tọkàntọkàn ni mo fi ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà láìka ọ̀pọ̀ ìṣòro tí mo ní nígbèésí ayé mi sí. a
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ọdún méjì lẹ́yìn tá a gba àkọsílẹ̀ ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Enrique Caravaca Acosta ló sùn nínú oorun ikú lẹ́ni àádọ́rùn-ún [90] ọdún.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 20]
Kíka Bíbélì déédéé jẹ́ orísun ìtùnú gidi fún mi, ó sì ti fún mi lókun láti fara da àwọn ìṣòro mi
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]
Èmi rèé nígbà tí mo kọ́kọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àsọyé Bíbélì
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ẹnu iṣẹ́ ìwàásù ni mo wà níbí nígbà tí mo ṣì wà lọ́dọ̀ọ́