Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí nìdí tá a fi máa ń ṣe “àmín” lẹ́yìn àdúrà?
Ọ̀rọ̀ náà “àmín” lédè Yorùbá àti lédè Gíríìkì wá látinú ọ̀rọ̀ náà, ʼa·menʹ, lédè Hébérù. Ọ̀rọ̀ yìí làwọn èèyàn sábà máa ń sọ lẹ́ẹ̀kan náà láti fi hàn pé àwọ́n fara mọ́ àdúrà tẹ́nì kan gbà, ìbúra tàbí ìsúre tẹ́nì kan ṣe títí kan èpè tẹ́nì kan ṣẹ́, ohun tó sì túmọ̀ sí ni pé “kí ó rí bẹ́ẹ̀” tàbí “dájúdájú.” Ó fi hàn pé wọ́n fara mọ́ ọn pé kí gbogbo ọ̀rọ̀ náà ṣẹ. Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú ẹ̀ sọ pé, “ọ̀rọ̀ náà dúró fún ohun tó dáni lójú, ohun tó jẹ́ òótọ́, ohun téèyàn fọkàn tán, téèyàn ò sì ṣiyè méjì nípa ẹ̀.” Láyé ìgbà tí wọ́n ń kọ Bíbélì, òfin de ẹnikẹ́ni tó bá ṣe àmín sí ìbúra tàbí májẹ̀mú kan, onítọ̀hún sì máa fara gba ìyà tí kò bá mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ ṣẹ tàbí tó bá da májẹ̀mú náà.—Diutarónómì 27:15-26.
Nígbà tí Jésù ń wàásù àti nígbà tó ń kọ́ àwọn èèyàn, “àmín” ló fi bẹ̀rẹ̀ àwọn ọ̀rọ̀ kan to sọ. Ìyẹn sì fi hàn pé ọ̀rọ̀ tó fẹ́ sọ náà ṣeé gbára lé láìkù síbì kan. “Lóòótọ́” la túmọ̀ ọ̀rọ̀ Gíríìkì náà a·menʹ sí láwọn ibi tí Jésù ti fi àmín bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀. (Mátíù 5:18; 6:2, 5) Láwọn ibi tó bá ti sọ ọ̀rọ̀ náà tẹ̀ léra, “lóòótọ́-lóòótọ́” la tú u sí gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Ìhìn Rere tí Jòhánù kọ. (Jòhánù 1:51) Bí Jésù ṣe lo àmín lọ́nà yìí ṣàrà ọ̀tọ̀ nínú Ìwé Mímọ́.
Nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì, orúkọ òye náà “Àmín” ni Ọlọ́run fún Jésù láti fi hàn pé àwọn ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ ‘ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.’—Ìṣípayá 3:14.
Kí ni wọ́n ń pè ní Úrímù àti Túmímù?
Ó dà bíi pé àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ayé àtijọ́ ń lo Úrímù àti Túmímù láti fi mohun tí Jèhófà bá fẹ́ kí wọ́n ṣe lórí àwọn ọ̀ràn tó bá kan orílẹ̀-èdè náà tàbí àwọn aṣáájú wọn. Ìkáwọ́ àlùfáà àgbà ni Úrímù àti Túmímù yìí máa ń wà, inú àpò tó wà lára “aṣọ ìgbàyà ìdájọ́” ni wọ́n sì ń kó o sí. (Ẹ́kísódù 28:15, 16, 30) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Ìwé Mímọ́ ò sọ bí Úrímù àti Túmímù ṣe rí àti bí wọ́n ṣe máa ń lò ó gan-an, àmọ́ látinú àwọn ẹsẹ kọ̀ọ̀kan nínú Bíbélì, ó dà bíi pé wọ́n máa ń lò ó bí ohun tí wọ́n fi ń ṣẹ́ kèké, ìdáhùn tó sì máa fún wọn lè jẹ́ “bẹ́ẹ̀ ni,” “bẹ́ẹ̀ kọ́” tàbí kó jẹ́ pé Ọlọ́run ò sọ ohunkóhun lórí ọ̀rọ̀ náà.
Ọ̀kan lára àpẹẹrẹ tá a rí nínú Bíbélì nípa bí wọ́n ṣe máa ń lo Úrímù àti Túmímù ni ìgbà tí Dáfídì ní kí Ábíátárì mú éfódì tó ṣeé ṣe kó jẹ́ ti àlùfáà àgbà wá, inú ẹ̀ sì ni Úrímù àti Túmímù máa ń wà. Dáfídì bi Jèhófà ní ìbéèrè méjì, ó ní: ‘Ṣé Sọ́ọ̀lù máa lépa mi?’ ó sì tún béèrè pé ‘Ṣáwọn ọmọ onílẹ̀ Kéílà máa fi mí lé e lọ́wọ́?’ “Bẹ́ẹ̀ ni,” ni Jèhófà fi dáhùn ìbéèrè méjèèjì yìí, ìyẹn sì jẹ́ kí Dáfídì pinnu ohun tó yẹ kóun ṣe.—1 Sámúẹ́lì 23:6-12.
Ṣáájú ìgbà yẹn, Sọ́ọ̀lù Ọba ti lo Úrímù àti Túmímù láti fi mọ nǹkan méjì, àkọ́kọ́, láti fi mọ̀ bóyá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù ló rú òfin tàbí òun àti Jónátánì, èkejì, láti fi mọ̀ bóyá òun tàbí ọmọ òun ló jẹ̀bi. (1 Sámúẹ́lì 14:40-42) Lẹ́yìn tí Sọ́ọ̀lù ti pàdánù ojú rere Ọlọ́run, Ọlọ́run ò tọ́ ọ sọ́nà mọ́ “yálà nípasẹ̀ àwọn àlá tàbí nípasẹ̀ Úrímù tàbí nípasẹ̀ àwọn wòlíì.”—1 Sámúẹ́lì 28:6.
Ìtàn àwọn Júù sì fi hàn pé kò sẹ́ni tó tún fi Úrímù àti Túmímù wádìí nǹkan kan lọ́wọ́ Jèhófà mọ́ lẹ́yìn tí tẹ́ńpìlì Jèhófà pa run lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 27]
“Àmín,” Ìṣípayá 3:14. Látinú the Codex Alexandrinus, ọ̀rúndún karùn-ún sànmánì Kristẹni