Àbẹ̀wò sí Ilé Ìtẹ̀wé kan Tó Pabanbarì
Àbẹ̀wò sí Ilé Ìtẹ̀wé kan Tó Pabanbarì
Ó ṢEÉ ṢE kó jẹ́ pé ìwé tó ò ń kà yìí kọ́ lo máa kọ́kọ́ rí nínú àwọn ìwé ìròyìn wa. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan tiẹ̀ lè ti wá sílé yín rí, kí wọ́n sì ti fún ẹ ní ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! kó o bàa lè túbọ̀ lóye Bíbélì dáadáa. Ó sì lè jẹ́ pé o ti rí àwa Ẹlẹ́rìí níbi tá a ti ń fàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó dá lórí Bíbélì lọ àwọn èèyàn ní òpópónà tàbí láàárín ọjà kan ládùúgbò yín. Kódà iye ìwé ìròyìn yìí tá à ń pín kiri lóṣooṣù ti ju mílíọ̀nù márùnlélọ́gbọ̀n [35] lọ báyìí, ó sì wá tipa bẹ́ẹ̀ di ìwé ìròyìn tó dá lórí ìsìn tá a tíì pín kiri jù lọ lágbàáyé.
Ṣó o tiẹ̀ ti rò ó rí pé, ibo gan-an la ti ń tẹ àwọn ìwé yìí, báwo la sì ṣe ń tẹ̀ ẹ́? Láti dáhùn ìbéèrè yìí, jẹ́ ká sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan lára àwọn ilé ìtẹ̀wé táwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti máa ń tẹ àwọn ìwé wa, ìyẹn èyí tó wà nílùú Wallkill, ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà. Ó lè má rọrùn fún ọ̀pọ̀ lára àwọn òǹkàwé wa yíká ayé láti rìnrìn-àjò wá sí orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà kí wọ́n lè wá wo ilé ìtẹ̀wé wa tó wà ní New York, àmọ́ àlàyé tá a máa ṣe nínú àpilẹ̀kọ yìí àtàwọn àwòrán tó o máa rí máa jẹ́ kó o mọ̀ nípa àwọn ohun tó ń lọ níbẹ̀.
Ó ṣeé ṣe kíwọ náà ti mọ̀ pé látorí ìwé kíkọ ni iṣẹ́ ìwé títẹ̀ ti máa ń bẹ̀rẹ̀. Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Ìwé Kíkọ, ní Brooklyn, ìpínlẹ̀ New York máa ń lo kọ̀ǹpútà láti fàwọn ìwé tí wọ́n bá kọ ránṣẹ́ sí Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwòrán Yíyà. Ẹ̀ka yìí máa wá fìyẹn ṣe àwo ìtẹ̀wé. Nǹkan bí egbèje [1,400] róòlù bébà ló máa ń dé sí ilé ìtẹ̀wé wa nílùú Wallkill lóṣooṣù, a sì máa ń lo ìwọ̀n bébà tó wúwo tó ẹgbẹ̀jọ [1,600] sí ẹgbẹ̀rún méjì [2,000] àpò sìmẹ́ǹtì láti fi tẹ̀wé lójúmọ́. Àwọn róòlù bébà, táwọn kan lára wọn tẹ̀wọ̀n tó nǹkan bí àpò sìmẹ́ǹtì méjìdínlọ́gbọ̀n [28], la máa ń gbé sínú àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńláńlá márùn-ún tá a ti fi àwọn àwo ìtẹ̀wé sí. Àwọn ẹ̀rọ wọ̀nyẹn á wá tẹ ọ̀rọ̀ àtàwòrán sórí àwọn bébà wọ̀nyẹn, wọ́n á gé e sí abala-abala, wọ́n á sì ká abala kọ̀ọ̀kan sí ojú ewé méjìlélọ́gbọ̀n [32]. Abala kan látinú róòlù bébà yẹn ni ìwé ìròyìn tó ò ń kà yìí. Báwo la ṣe ń ṣe àwọn ìwé ńlá? Níbi tá a ti ń di ìwé pọ̀, a máa ń di abala kọ̀ọ̀kan, tí àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé yẹn bá ti ká, pa pọ̀ láti fi ṣe odindi ìwé. A lè ṣe ẹgbẹ̀rún lọ́nà àádọ́ta [50,000] ìwé ẹlẹ́yìn páálí tàbí ẹgbẹ̀rún lọ́nà márùndínlọ́gọ́rin [75,000] ìwé ẹlẹ́yìn rírọ̀ jáde lọ́jọ́ kan ṣoṣo látinú ọ̀kan lára àwọn ibi méjì tá a ti máa ń di ìwé pọ̀. A sì lè ṣe ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] ìwé ẹlẹ́yìn rírọ̀ jáde lójúmọ́ láti ibì kejì.
Lọ́dún 2008, àwọn ìwé tá a ṣe jáde látinú ilé ìtẹ̀wé wa yìí lé ní mílíọ̀nù méjìdínlọ́gbọ̀n [28,000,000], nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́ta lára àwọn ìwé yìí ló sì jẹ́ Bíbélì. Iye ìwé ìròyìn tá a tẹ̀ jáde jẹ́ òjìlérúgba-lé-mẹ́ta mílíọ̀nù, ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọ̀ọ́dúnrún-lé-mẹ́tàdínlógún, àti òjìdínlẹ́gbẹ̀ta-lé-mẹ́rin [243,317,564]. À ń ṣe àwọn ìwé tó dá lórí Bíbélì yìí jáde ní nǹkan bí okòó-dín-nírinwó [380] èdè. Lẹ́yìn tá a bá wá ṣe àwọn ìwé yìí tán, kí ló máa ń ṣẹlẹ̀ tẹ̀ lé e?
Ẹgbẹ̀rún lọ́nà méjìlá, ọgọ́rùn-ún méje àti mẹ́rìnléláàádọ́ta [12,754] ni iye ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà láàárín orílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, nígbà tá a ní ẹgbẹ̀rún kan, ọgọ́rùn-ún mẹ́ta àti mọ́kàndínláàádọ́rin [1,369] ìjọ láwọn erékùṣù Caribbean àti Hawaii. Àwọn ìjọ yìí sì máa ń kọ̀wé béèrè fáwọn ìwé
tá à ń tẹ̀. Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́ wa ló máa ń di àwọn ìwé tí wọ́n bá béèrè tí wọ́n á sì ṣètò bí wọ́n á ṣe gbé e lọ fáwọn ìjọ tó bá béèrè fún un. Lọ́dọọdún, a máa ń kó àwọn ìwé tó wúwo tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́tàdínlọ́gbọ̀n [27,000] àpò sìmẹ́ǹtì ránṣẹ́ sáwọn ìjọ tó wà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà.Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ló ṣe pàtàkì jù nínú ilé ìtẹ̀wé yìí, bí kò ṣe àwọn èèyàn tó ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀. Àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún mẹ́ta [300] ló ń ṣiṣẹ́ láwọn ẹ̀ka ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ tó wà nínú ilé ìtẹ̀wé náà, lára àwọn ẹ̀ka ọ̀hún ni Ẹ̀ka Tó Ń Bójú Tó Àwòrán Yíyà, Ẹ̀ka Tó Ń Ṣètò Iṣẹ́, Ibi Ìtẹ̀wé, Ibi Tá A Ti Ń Di Ìwé Pọ̀, àti Ẹ̀ka Ìkówèéránṣẹ́. Àwọn ọ̀ṣìṣẹ́ yìí kì í gbowó oṣù, ṣe ni wọ́n yọ̀nda ara wọn, ọjọ́ orí wọn sì bẹ̀rẹ̀ láti ọmọ ọdún mọ́kàndínlógún [19] sí méjìléláàádọ́rùn-ún [92].
Ire àwọn èèyàn ló jẹ wọ́n lógún, ìyẹn àwọn èèyàn tó máa gba ìwé yìí, tí wọ́n á kà á tọkàntọkàn, tí wọ́n á kẹ́kọ̀ọ́ nínú rẹ̀, tí wọ́n á rí ìṣírí gbà nípasẹ̀ rẹ̀, tí wọ́n á sì jẹ́ káwọn ìlànà Bíbélì tá a jíròrò nínú rẹ̀ darí àwọn. A nírètí pé o wà lára irú àwọn ẹni yẹn àti pé àwọn ìwé tá à ń tẹ̀ nínú ilé ìtẹ̀wé wa á máa ràn ẹ́ lọ́wọ́ láti túbọ̀ máa gba ìmọ̀ Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi, kó o lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]