Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?
Àwọn Òǹkàwé Wa Béèrè Pé
Ṣé Ọlọ́run Fọwọ́ Sí Ìkóbìnrinjọ?
Rárá ni ìdáhùn sí ìbéèrè yìí, ìlànà ìgbéyàwó ọkọ-kan-aya-kan ni Ọlọ́run fi lélẹ̀ fún tọkọtaya àkọ́kọ́ lọ́gbà Édẹ́nì, kì í ṣe ìkóbìnrinjọ. Nígbà tó yá, Jésù Kristi tún fìdí ìlànà yìí múlẹ̀ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 2:18-24; Mátíù 19:4-6.
Ṣebí àwọn èèyàn bí Ábúráhámù, Jékọ́bù, Dáfídì àti Sólómọ́nì, tí wọ́n ti gbé láyé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, ní ju ìyàwó kan lọ? Bẹ́ẹ̀ ni, àmọ́ kí ni Bíbélì sọ nípa ohun tí wọ́n ṣe yẹn? Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa gbọ́nmi-si omi-ò-to tó wáyé nínu ilé Ábúráhámù àti Jékọ́bù torí ìyàwó púpọ̀ tí wọ́n fẹ́. (Jẹ́nẹ́sísì 16:1-4; 29:18–30:24) Nígbà tó yá, Ọlọ́run pàṣẹ fáwọn ọba pé: “Òun kò sì gbọ́dọ̀ sọ aya di púpọ̀ fún ara rẹ̀, kí ọkàn-àyà rẹ̀ má bàa yà kúrò.” (Diutarónómì 17:15, 17) Sólómọ́nì kọ etí ikún sí àṣẹ yẹn, ó fẹ́ ọgọ́rùn-ún méje [700] ìyàwó! Ó bani nínú jẹ́ pé, ọkàn àyà Sólómọ́nì yà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà lóòótọ́ torí ipa búburú tí ọ̀pọ̀ ìyàwó tó fẹ́ ní lórí rẹ̀. (1 Àwọn Ọba 11:1-4) Ó ṣe kedere pé Bíbélì ò fọwọ́ sí ìkóbìnrinjọ.
Síbẹ̀, àwọn kan ṣì lè máa ṣe kàyéfì pé kí nìdí tí Ọlọ́run fi gbà pé káwọn èèyàn rẹ̀ fẹ́ ju ìyàwó kan lọ. Gbé èyí yẹ̀ wò ná: Ṣó ti ṣẹlẹ̀ sí ẹ rí pé o ṣì fi àga kan tó ti tó pààrọ̀ sílẹ̀ nínú ilé, bóyá torí o rò pé kò tíì yẹ kó o gbé e kúrò tàbí kó o sọ ọ́ nù báyìí? A mọ̀ pé ọ̀nà àti ìrònú Ọlọ́run ga ju tiwa lọ fíìfíì. (Aísáyà 55:8, 9) Síbẹ̀, a lè fòye mọ àwọn ohun tó mú kó fàyè gba ìkóbìnrinjọ láwọn àkókò kan.
Má gbàgbé pé ní ọgbà Édẹ́nì, Jèhófà ṣèlérí “irú ọmọ” kan tó máa pa Sátánì run pátápátá. Nígbà tó yá, Ọlọ́run sọ fún Ábúráhámù pé ó máa di bàbá orílẹ̀-èdè ńlá àti pé Irú-Ọmọ tí Ọlọ́run ṣèlérí yẹn máa wá látinú ìran rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15; 22:18) Sátánì ṣe tán láti ṣe gbogbo ohun tó bá gbà kí Irú-Ọmọ yẹn máa bàa dé. Ìdí nìyẹn tó fi ń wá ọ̀nà èyíkéyìí tó lè gbà láti pa orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì run. Ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sínú ẹ̀ṣẹ̀ kí Ọlọ́run lè bínú sí wọn, kí ààbò Ọlọ́run sì lè kúrò lórí wọn.
Káwọn ọmọ Ísírẹ́lì má bàa jìn sọ́fìn Sátánì, Jèhófà máa ń rán àwọn wòlíì rẹ̀ léraléra, kí wọ́n lè kìlọ̀ fáwọn èèyàn rẹ̀ nígbà tí wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí í ṣohun tí kò bá ìlànà òdodo mu. Àmọ́, Ọlọ́run mọ̀ tẹ́lẹ̀ pé ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn òun á máa ṣàìgbọràn, kódà sáwọn òfin tó kéré gan-an pàápàá, bí irú òfin tó sọ pé kí wọ́n ṣọ́ra fún ìbọ̀rìṣà. (Ẹ́kísódù 32:9) Tó bá nira fún wọn láti pa òfin tó ṣe pàtàkì bẹ́ẹ̀ yẹn mọ́, báwo wá ni wọ́n á ṣe pa òfin tó sọ pé kí wọ́n má ṣe kóbìnrin jọ mọ́? Torí pé Jèhófà mohun gbogbo nípa èèyàn dáadáa, ó mọ̀ pé àkókò kò tíì tó láti ka àṣà, tí wọ́n ti ń ṣe bọ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́, yìí léèwọ̀. Ká sọ pé ó ti ṣe bẹ́ẹ̀ ni, Sátánì ì bá ti rí ọ̀nà tọ́ rọrùn gan-an láti tan àwọn ọmọ Ísírẹ́lì sínú ẹ̀ṣẹ̀.
Bí Ọlọ́run ṣe fàyè gba ìkóbìnrinjọ fúngbà díẹ̀ tún láwọn àǹfààní míì. Ó jẹ́ káwọn ọmọ Ísírẹ́lì yára pọ̀ sí i. Bí wọ́n sì ṣe pọ̀ yẹn ò jẹ́ kí wọ́n kú tán kó tó di pé Mèsáyà dé. Bí ọkùnrin kan ṣe fẹ́ ju ìyàwó kan lọ tún ṣeé ṣe kó jẹ́ ààbò fáwọn obìnrin kan, torí ìyẹn jẹ́ kí wọ́n rílé gbé, kí wọ́n sì wà lọ́ọ̀dẹ̀ ọkọ kan lákòókò tí nǹkan ò rọgbọ.
Àmọ́, má gbàgbé pé Jèhófà kọ́ ló dá ìkóbìnrinjọ sílẹ̀ o. Ó kàn fàyè gbà á fúngbà díẹ̀ ni, ó sì ṣàwọn òfin tí kò ní jẹ́ káwọn èèyàn wọ̀nyẹn ṣàṣejù. (Ẹ́kísódù 21:10, 11; Diutarónómì 21:15-17) Nígbà tí Jèhófà ṣe tán láti fòpin sí àṣà ìkóbìnrinjọ láàárín àwọn olùjọ́sìn rẹ̀, ó lo Ọmọ òun fúnra rẹ̀ láti tún fìdí ìlànà ìgbéyàwó tóun ti fi lélẹ̀ lọ́gbà Édẹ́nì múlẹ̀ lẹ́ẹ̀kan sí i. Jésù tipa báyìí ka ìkóbìnrinjọ léèwọ̀ láàárín àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀. (Máàkù 10:8) Ìyẹn jẹ́ kí òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí túbọ̀ ṣe kedere pé: Òfin Mósè dára ní àkókò tiẹ̀, àmọ́ “òfin Kristi” tún dáa ju Òfin Mósè lọ.—Gálátíà 6:2.