Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkùnrin Kan Tó Gba Àwọn Ìlérí Ọlọ́run Gbọ́

Ọkùnrin Kan Tó Gba Àwọn Ìlérí Ọlọ́run Gbọ́

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Ọkùnrin Kan Tó Gba Àwọn Ìlérí Ọlọ́run Gbọ́

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JẸ́NẸ́SÍSÌ 12:1-4; 18:1-15; 21:1-5; 22:15-18.

Ṣàlàyé bó o ṣe rò pé ó máa rí lára Ábúráhámù nígbà tó gbọ́ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún un pé ó máa di bàbá ńlá “irú ọmọ” kan tó máa ṣe gbogbo aráyé láǹfààní.

․․․․․

Báwo lo ṣe rò pé àwọn ọkùnrin mẹ́ta tó dé bá Ábúráhámù lálejò ṣe rí gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 18:2 ṣe sọ?

․․․․․

Kí lo lè sọ nípa àwọn nǹkan tí ìwé Jẹ́nẹ́sísì 18:6-8 sọ pé Ábúráhámù ṣe? (Má gbàgbé pé Ábúráhámù ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé ẹni ọgọ́rùn-ún [100] ọdún nígbà yẹn.)

․․․․․

ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Ọdún mélòó ló wà láàárín ìgbà tí Jèhófà ṣèlérí fún Ábúráhámù pé ó máa bi ọmọkùnrin kan àti ìgbà tí wọ́n bí Ísákì? (Tún Jẹ́nẹ́sísì 12:4 àti 21:5 kà.)

․․․․․

Àwọn ọ̀rọ̀ ìdánilójú wo ni Jèhófà sọ fún Ábúráhámù láwọn ìgbà tí Ábúráhámù ń dúró de àwọn ìlérí tí Jèhófà ṣe fún un? (Ka Jẹ́nẹ́sísì 12:7; 13:14-17; 15:1-5, 12-21; 17:1, 2, 7, 8, 15, 16.)

․․․․․

Kí ni Jèhófà ṣe fún Ábúráhámù nígbà tí Ábúráhámù ń ṣiyèméjì pé bóyá lòun lè bímọ? (Tún Jẹ́nẹ́sísì 15:3-5, 12-21 kà.)

․․․․․

Báwo ni Jèhófà ṣe ń jẹ́ ká mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ àlàyé nípa “irú ọmọ” náà?

․․․․․

MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìdí tó fi yẹ ká gba àwọn ìlérí Ọlọ́run gbọ́.

․․․․․

Bí Jèhófà ṣe máa ń jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ nípa àwọn ohun tóun fẹ́ ṣe díẹ̀díẹ̀.

․․․․․

KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․