Ìyanu Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì!
Abala Àwọn Ọ̀dọ́
Ìyanu Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì!
Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ báwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bóhun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.
KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA ÌṢE 2:1-21, 38-41.
Kí ló wá sí ẹ lọ́kàn bó o ṣe ń kà nípa “atẹ́gùn líle tí ń rọ́ yìì,” àti “ahọ́n bí ti iná”?
․․․․․
Kí lo rò pé àwọn èèyàn náà sọ nígbà tí wọ́n gbọ́ táwọn ọmọ ẹ̀yìn ń sọ̀rọ̀ ní ahọ́n àjèjì?
․․․․․
Báwo lo ṣe rò pé ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ṣe rí lára àwọn tó ń fi wọ́n ṣẹlẹ́yà gẹ́gẹ́ bí ẹsẹ 13 ti ṣàlàyé?
․․․․․
ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.
Àjọyọ̀ wo ni wọ́n ń pè ní Pẹ́ńtíkọ́sì, báwo nìyẹn sì ṣe lè nípa lórí ọ̀pọ̀ èèyàn tó wá sí Jerúsálẹ́mù? (Diutarónómì 16:10-12)
․․․․․
Báwo ni Pétérù ṣe bọ̀wọ̀ fáwọn tó ń bá sọ̀rọ̀, báwo ló sì ṣe bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ́nà tí wọ́n á fi nífẹ̀ẹ́ sóhun tó fẹ́ sọ? (Ìṣe 2:29)
․․․․․
Báwo ni ìgboyà tí Pétérù ní lọ́jọ́ Pẹ́ńtíkọ́sì ṣe yàtọ̀ gédégbé sóhun tó ṣe nínú àgbàlá àlùfáà àgbà nígbà kan sẹ́yìn? (Mátíù 26:69-75)
․․․․․
MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. KỌ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .
Ìdí tó fi yẹ ká máa sọ̀rọ̀ lọ́nà táwọn èèyàn á fi nífẹ̀ẹ́ sóhun tá a fẹ́ sọ àti ìdí tó fi yẹ ká máa bọ̀wọ̀ fáwọn èèyàn nígbà tá a bá ń sọ àwọn nǹkan tá a gbà gbọ́ nínú Bíbélì fún wọn.
․․․․․
Bó o ṣe lè fìgboyà jẹ́rìí nípá Jèhófà, ká tiẹ̀ sọ pé ẹ̀rù ṣì ń bà ẹ́ báyìí.
․․․․․
KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?
․․․․․
Tó o bá fẹ́ mọ púpọ̀ sí i, ka Ilé Ìṣọ́ September 15, 1996, ojú ìwé 8 àti 9.