Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Láyọ̀ Ó sì Nírètí Bí Kò Tiẹ̀ Lówó Lọ́wọ́

Ó Láyọ̀ Ó sì Nírètí Bí Kò Tiẹ̀ Lówó Lọ́wọ́

Lẹ́tà Láti Orílẹ̀-Èdè Bòlífíà

Ó Láyọ̀ Ó sì Nírètí Bí Kò Tiẹ̀ Lówó Lọ́wọ́

MI Ò tíì ríbi táwọn èèyàn ti tòṣì tí wọ́n sì ń gbé láìnírètí tó báyìí rí, àyàfi ìgbà tí mo dé orílẹ̀-èdè kan tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń gòkè àgbà láti ṣiṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ńṣe ló máa ń wù mí pé kí gbogbo èèyàn rí ìtura ojú ẹsẹ̀ kúrò lọ́wọ́ ìyà. Àmọ́, mo mọ̀ pé Ìjọba Ọlọ́run nìkan ló máa yanjú àwọn ìṣòro yìí. Àkíyèsí tí mo ṣe ni pé, lọ́pọ̀ ìgbà àwọn tó bá ń ṣohun tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wí máa ń láyọ̀ láìka ipò tó nira tí wọ́n wà sí. Sabina jẹ́ ọ̀kan lára wọn.

Lọ́dún bíi mélòó kan sẹ́yìn, Sabina, mú àwọn ọmọbìnrin ẹ̀ méjèèjì dání bó ṣe ń wo ọkọ ẹ̀ tó ń wọ mọ́tò kan tó ti gbó láti lọ wá iṣẹ́ táá máa mówó gidi wá lórílẹ̀-èdè míì. Látìgbà náà, àlọ ló rí kò rí àbọ̀. Látìgbà yẹn sì ni Sabina ti ń ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó láti pèsè ohun tí òun àtàwọn ọmọ rẹ̀, Milena àti Ghelian, máa jẹ.

Ṣọ́ọ̀bù ẹ̀gbọ́n Sabina ni mo ti kọ́kọ́ pàdé ẹ̀ lọ́sàn-án ọjọ́ kan níbi tó ti ń fi sùúrù dá àwọn oníbàárà lóhùn. Nígbà tí mo wo ojú Sabina, mo kíyè sí pé ó ti rẹ̀ ẹ́, torí pé látàárọ̀ ló ti ń ṣiṣẹ́ kárakára. Mo sọ fún un pé á wù mí láti máa kọ́ òun àtàwọn ọmọ ẹ̀ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ó ní, “Ì bá wù mí, àmọ́ ọwọ́ mi máa ń dí gan-an. Síbẹ̀, màá fẹ́ kó o máa kọ́ àwọn ọmọbìnrin mi lẹ́kọ̀ọ́.” Mo gbà. Bí ìkẹ́kọ̀ọ́ wọn ṣe ń tẹ̀ síwájú, mo bẹ̀rẹ̀ sí í mọ Sabina àtohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ̀.

Aago mẹ́rin ìdájí ni Sabina ti máa ń jí. Nígbà táwọn ọmọbìnrin ẹ̀ ṣì ń sùn lọ́wọ́ nínú yàrá kan tí wọ́n ń gbé, Sabina máa ń gbé àlòkù apẹ ńlá kan kaná láti fi se ẹran tó máa ń fi sínú ìpápánu tí wọ́n ń pè ní meat pie tó máa ń tà kó lè máa rówó gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Tó bá ku ọ̀la ni Sabina ti máa ń po ìyẹ̀fun tó máa fi ṣe ìpápánu yìí.

Sabina á wá fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ to gbogbo nǹkan tó máa lò lóòjọ́ sínú bárò kan tó yá, àwọn nǹkan bí agboòrùn kan, sítóòfù kan, àtùpà tó ń lo gáàsì kan, tábìlì kan, àwọn àga ìjókòó, àwọn apẹ tó máa fi dáná, epo, ẹran, ìyẹ̀fun tó ti pò àtàwọn gálọ́ọ̀nù onírúurú ohun mímu eléso tí wọ́n ń ṣe nílùú yẹn.

Tó bá fi máa di aago mẹ́fà ìdájí, Sabina àtàwọn ọmọbìnrin ẹ̀ á ti múra tán láti lọ. Wọ́n á wá ti ilẹ̀kùn ilé wọn. Wọ́n á rọra máa lọ, ẹnì kankan nínú wọn ò ní sọ̀rọ̀, wọn ò sì ní rẹ́rìn-ín. Nǹkan tí wọ́n fẹ́ lọ ṣe ni wọ́n máa ń fọkàn wọn sí. Ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìgbà láti ojú fèrèsé ilé táwa míṣọ́nnárì ń gbé, mo máa ń wo báwọn èèyàn ṣe ń jí jáde lọ síbi iṣẹ́ láràárọ̀ bíi ti Sabina. Ńṣe ni Sabina wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára ọ̀pọ̀ obìnrin tó máa ń jí jáde nílé kí wọ́n lè lọ ta oúnjẹ àtohun mímu láwọn òpópónà tó wà lórílẹ̀-èdè Bòlífíà.

Tó bá sì fi máa di aago mẹ́fà ààbọ̀ nígbà tí oòrùn bá ń jáde bọ̀, Sabina àtàwọn ọmọbìnrin rẹ̀ á ti dé ibi tí wọ́n ti ń tajà. Wọ́n á wá já gbogbo ẹrù wọn sílẹ̀ látinú bárò náà, wọ́n á sì to ilé ìdáná wọn, láìbára wọn sọ̀rọ̀. Tó bá ju meat pie àkọ́kọ́ sínú epo tó ti gbá báyìí, ńṣe ló máa dún ṣìn-ìn. Ìtasánsán meat pie náà á wá gba inú afẹ́fẹ́ kan lọ́wọ́ àárọ̀, ká tó ṣẹ́jú pẹ́, àwọn oníbàárà á ti dé.

Sabina á wá béèrè lọ́wọ́ ẹni àkọ́kọ́ pé, “mélòó lo fẹ́?” Onítọ̀hún tí oorun ò tí ì dá lójú ẹ̀ á wá nàka méjì sókè, Sabina á wá fún un ní meat pie tó ti jiná, tó ń gbóná fẹlifẹli. Lẹ́yìn náà, Sabina á gbowó lọ́wọ́ ẹ̀. Bó sì ṣe máa ṣe nìyẹn títí táá fi tajà tán. Tí wọ́n bá sì ti tajà tán, wọ́n á palẹ̀ mọ́, wọ́n á sì máa lọ sílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹsẹ̀ á ti máa ro Sabina torí iṣẹ́ tó ti ń ṣe látàárọ̀, síbẹ̀ á tún lọ sí ṣọ́ọ̀bù ẹ̀gbọ́n ẹ̀ láti lọ bá a tajà.

Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo fẹ́ ṣèkẹ́kọ̀ọ́ àwọn ọmọ Sabina ní ṣọ́ọ̀bù náà, wọ́n ti gbé àga ìjókòó kékeré méjì síbi tá a máa jókòó sí. Látọjọ́ àkọ́kọ́ ni Milena tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́sàn-án àti Ghelian ọmọ ọdún méje nígbà yẹn ti máa ń fìdùnnú retí ọjọ́ tá a tún máa kẹ́kọ̀ọ́, wọ́n sì máa ń múra sílẹ̀ dáadáa. Bọ́jọ́ ṣe ń gorí ọjọ́, àwọn ọmọbìnrin tó máa ń tijú yìí wá bẹ̀rẹ̀ sí í sọ àwọn ohun tó wà lọ́kàn wọn fún mi, ìyẹn sì jẹ́ kí n túbọ̀ mọ̀ wọ́n dáadáa. Èyí sì dùn mọ́ Sabina nínú gan-an ni. Kò pẹ́ ni Sabina náà bá pinnu pé, láìka bí ọwọ́ òun ṣe máa ń dí tó, òun náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.

Bí òye Sabina ṣe ń pọ̀ sí i, bẹ́ẹ̀ ni ìfẹ́ rẹ̀ fún Jèhófà Ọlọ́run náà ń pọ̀ sí i. Ó wá bẹ̀rẹ̀ sí í láyọ̀ tí kì í ní tẹ́lẹ̀. Sabina tójú ẹ̀ máa ń fi hàn pé ó ti rẹ̀ tẹnutẹnu, tí kì í sì í láyọ̀ wá dẹni tí nǹkan ti yí pa dà fún báyìí. Ọkàn Sabina ti wá balẹ̀ báyìí, ojú ẹ̀ sì ń dán. Ẹ̀gbọ́n ẹ̀ pàápàá jẹ́rìí sí i, ó ní, “Ní báyìí, gbogbo ìgbà ni Sabina máa ń rẹ́rìn-ín, kò sì rí bẹ́ẹ̀ tẹ́lẹ̀.” Yàtọ̀ sí ẹ̀gbọ́n Sabina, àwọn míì náà tún rí ìyàtọ̀ nínú ìgbésí ayé Sabina àtàwọn ọmọ rẹ̀. Òtítọ́ nípa Ọlọ́run àtàwọn ohun tó máa ṣe tí Sabina ti fẹ́ mọ̀ látọjọ́ tó ti pẹ́ ló wá mọ̀ wẹ́rẹ́ yìí.

Sabina ń gbádùn ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, àmọ́ ọwọ́ ẹ̀ tó máa ń dí kò jẹ́ kó lè máa lọ sípàdé ní Gbọ̀ngàn Ìjọba àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nígbà tó yá, Sabina gbà láti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Látìgbà yẹn ló sì ti ń wá déédéé. Sabina láwọn ọ̀rẹ́ tòótọ́ nínú ìjọ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó tún wá rí i pé Jèhófà máa ń pèsè ohun kòṣeémáàní fáwọn tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì pa àwọn nǹkan tó ń dí wọn lọ́wọ́ tì torí kí wọ́n lè sìn ín.—Lúùkù 12:22-24; 1 Tímótì 6:8.

Sabina fẹ́ràn ohun tó ń kọ́, ó sì fẹ́ láti sọ ọ́ fáwọn ẹ̀lòmíì. Àmọ́ ó sọ pé, “Ẹ̀rù máa ń bà mí nígbàkigbà tí mo bá ronú pé ó yẹ kí n wàásù fáwọn èèyàn.” Èrò ẹ̀ ni pé, ‘Báwo lèmi tí mo máa ń tijú, tí mi ò sì mọ̀wé á ṣe lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́?’ Àmọ́ inúure tí wọ́n fi hàn sí i àti àtúnṣe tó bá ìgbésí ayé rẹ̀ lọ́nà tó yà á lẹ́nu mú kó ṣe tán láti ṣe iṣẹ́ tó ṣe pàtàkì yìí. Ó tún rí i pé àpẹẹrẹ òun làwọn ọmọ òun ń wò. Torí èyí, ó bẹ̀rẹ̀ sí í wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Làwọn ọmọ ẹ̀ náà bá dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì ń fìtara ṣe iṣẹ́ náà.

Ní báyìí, ìgbésí ayé Sabina ti yàtọ̀, ọ̀rọ̀ ẹ̀ kò rí bíi tìgbà kan tó máa ń ṣe iṣẹ́ àṣekúdórógbó, tí kì í sì í láyọ̀. Lóòótọ́, ipò ìṣúnná owó rẹ̀ kò tíì fi bẹ́ẹ̀ yí pa dà. Àmọ́, èrò ẹ̀ nípa ìgbésí ayé ti yàtọ̀. Ní báyìí tó ti ṣèrìbọmi, òun náà ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ ojútùú kan ṣoṣo sí ipò òṣì àti àìnírètí tó wà nínú ayé.—Mátíù 6:10.

Aago márùn-ún ti lù, Sabina tún ti múra tán láti jáde nínú yàrá kan tó ń gbé. Àmọ́ kì í ṣe meat pie ló fẹ́ lọ tà lówùúrọ̀ yìí. Ńṣe ló fẹ́ lọ bá àwọn Kristẹni bíi tiẹ̀ láti lọ wàásù láwọn òpópónà. Bí Sabina ṣe ń yọ̀ǹda díẹ̀ lára àkókò rẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀ láti ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ yìí ti túbọ̀ jẹ́ kó láyọ̀. Ó ti ìlẹ̀kùn rẹ̀, ó sì fìdùnnú jáde láti lọ wàásù fáwọn èèyàn láwọn òpópónà. Dípò bárò tó máa ń tì lójoojúmọ́, báàgì ló gbé lọ́tẹ̀ yìí. Bíbélì àtàwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló kó síbẹ̀, èyí tó máa fi wàásù fáwọn èèyàn pé nǹkan ṣì ń bọ̀ wá dáa. Sabina rẹ́rìn-ín músẹ́, ó wá fi ìfọ̀kànbalẹ̀ sọ pé, “Mi ò fìgbà kankan rí rò ó pé màá lè kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì.” Ó fi kún un pé, “Mo fẹ́ràn iṣẹ́ náà gan-an ni!”