Ọrọ̀ Tó Ń Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá
Ọrọ̀ Tó Ń Ti Ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Wá
ṢÉ ỌLỌ́RUN máa tìtorí pé o jẹ́ olóòótọ́ sọ ẹ́ di ọlọ́rọ̀? Ó ṣeé ṣe kó rí bẹ́ẹ̀, àmọ́ ó lè máà jẹ́ irú ọrọ̀ tó o lérò. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Màríà tó jẹ́ ìyá Jésù. Áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì fara hàn án, ó sì sọ fún un pé Ọlọ́run ‘ṣe ojú rere sí i lọ́nà gíga’ àti pé ó máa bí Ọmọ Ọlọ́run. (Lúùkù 1:28, 30-32) Síbẹ̀, ìyẹn ò sọ Màríà di ọlọ́rọ̀. “Oriri méjì tàbí ọmọ ẹyẹlé méjì” ni Màríà fi rúbọ lẹ́yìn tó bí Jésù, àwọn nǹkan yìí sì làwọn òtòṣì sábà fi máa ń rúbọ sí Jèhófà.—Lúùkù 2:24; Léfítíkù 12:8.
Ṣé bí Màríà ṣe jẹ́ òtòṣì yìí wá fi hàn pé Ọlọ́run ò bù kún un? Rárá o, nígbà tó lọ kí Èlísábẹ́tì tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí rẹ̀ nílé, Bíbélì ròyìn pé: “Èlísábẹ́tì . . . kún fún ẹ̀mí mímọ́, ó sì fi igbe rara ké pé: ‘Alábùkún ni ìwọ [Màríà] láàárín àwọn obìnrin, alábùkún sì ni èso ilé ọlẹ̀ rẹ!’” (Lúùkù 1:41, 42) Màríà láǹfààní láti bí Jésù, Ọmọ Ọlọ́run tó jẹ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n sórí ilẹ̀ ayé.
Jésù pàápàá kì í ṣe ọlọ́rọ̀. Yàtọ̀ sí pé àgbègbè tí nǹkan ò ti rọ̀ṣọ̀mù ni wọ́n ti bí i, tó sì jẹ́ pé àwọn òbí rẹ̀ kò rí jájẹ, òun alára kì í ṣe ọlọ́rọ̀ ní gbogbo àkókò tó fi wà láyé. Ìgbà kan tiẹ̀ wà tí Jésù sọ fún ọkùnrin kan tó fẹ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Àwọn kọ̀lọ̀kọ̀lọ̀ ní ihò, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ní ibi wíwọ̀sí, ṣùgbọ́n Ọmọ ènìyàn kò ní ibì kankan láti gbé orí rẹ̀ lé.” (Lúùkù 9:57, 58) Síbẹ̀, wíwá tí Jésù Kristi wá sórí ilẹ̀ ayé ló fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ láǹfààní láti di ọlọ́rọ̀ rẹpẹtẹ. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ó di òtòṣì nítorí yín, kí ẹ lè di ọlọ́rọ̀ nípasẹ̀ ipò òṣì rẹ̀.” (2 Kọ́ríńtì 8:9) Irú ọrọ̀ wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀? Irú ọrọ̀ wo làwa náà sì ní lónìí?
Irú Ọrọ̀ Wo?
Ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì sábà máa ń ṣàkóbá fún ìgbàgbọ́ èèyàn, torí pé ẹnì kan tó jẹ́ olówó lè gbára lé owó tó ní ju Ọlọ́run lọ. Jésù sọ pé: “Ẹ wo bí yóò ti jẹ́ ohun tí ó ṣòro fún àwọn tí wọ́n ní owó láti wọ ìjọba Ọlọ́run!” (Máàkù 10:23) Èyí jẹ́ kó ṣe kedere pé kì í ṣe owó ni ọrọ̀ tí Jésù fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.
Kódà, òtòṣì ni ọ̀pọ̀ Kristẹni ní ọ̀rúndún kìíní. Nígbà tí ọkùnrin kan tí wọ́n bí ní arọ bẹ Pétérù pé kó fóun lówó, Pétérù dá a lóhùn pé: “Fàdákà àti wúrà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní ni èmi fún ọ: Ní orúkọ Jésù Kristi ará Násárétì, máa rìn!”—Àwọn ọ̀rọ̀ tí Jákọ́bù tó jẹ́ ọmọ ẹ̀yìn Jésù pàápàá sọ tún jẹ́ ká mọ̀ pé òtòṣì ni ọ̀pọ̀ àwọn tó wà nínú ìjọ Kristẹni. Ó kọ̀wé pé: “Ẹ fetí sílẹ̀, ẹ̀yin ará mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n. Ọlọ́run yan àwọn tí í ṣe òtòṣì ní ti ayé láti jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìgbàgbọ́ àti ajogún ìjọba náà, èyí tí ó ṣèlérí fún àwọn tí ó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àbí kò ṣe bẹ́ẹ̀?” (Jákọ́bù 2:5) Yàtọ̀ síyẹn, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù náà sọ pé kì í ṣe ọ̀pọ̀ “ọlọ́gbọ́n nípa ti ara” tàbí “alágbára” tàbí “àwọn tí a bí ní ilé ọlá” ni Ọlọ́run pè láti wá di apá kan ìjọ Kristẹni.—1 Kọ́ríńtì 1:26.
Tí kì í bá ṣe ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì ni Jésù fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀, irú ọrọ̀ wo ló wá fún wọn? Nínú lẹ́tà kan tí Jésù fi ránṣẹ́ sí ìjọ tó wà ní ìlú Símínà, ó sọ pé: “Mo mọ ìpọ́njú àti ipò òṣì rẹ—ṣùgbọ́n ọlọ́rọ̀ ni ọ́.” (Ìṣípayá 2:8, 9) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé òtòṣì ni àwọn Kristẹni tó wà nílùú Símínà, wọ́n ní ọrọ̀ tó ṣeyebíye gan-an ju fàdákà tàbí wúrà lọ. Wọ́n jẹ́ ọlọ́rọ̀ torí pé wọ́n ní ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, wọ́n sì ń sìn ín láìyẹsẹ̀. Ìgbàgbọ́ ṣeyebíye gan-an torí “kì í ṣe ohun ìní gbogbo ènìyàn.” (2 Tẹsalóníkà 3:2) Lójú Ọlọ́run, òtòṣì paraku làwọn tí wọn ò bá nígbàgbọ́.—Ìṣípayá 3:17, 18.
Ọrọ̀ Tí Ìgbàgbọ́ Máa Ń Jẹ́ Kéèyàn Ní
Àwọn ọ̀nà wo ni ìgbàgbọ́ gbà ṣeyebíye? Àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run máa ń jàǹfààní nínú “ọrọ̀ inú rere àti ìmúmọ́ra àti ìpamọ́ra rẹ̀.” (Róòmù 2:4) Wọ́n tún máa ń rí “ìdáríjì àwọn àṣemáṣe [wọn]” gbà torí pé wọ́n nígbàgbọ́ nínú ẹbọ ìràpadà Jésù. (Éfésù 1:7) Bákan náà, wọ́n ní ọgbọ́n irú èyí tí “ọ̀rọ̀ Kristi” máa ń fún àwọn tí wọ́n nígbàgbọ́. (Kólósè 3:16) Bí wọ́n ṣe ń nígbàgbọ́ pé Ọlọ́run máa dáhùn àdúrà wọn, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ” ń ṣọ́ ọkàn-àyà wọn àti èrò inú wọn, ìyẹn sì máa ń jẹ́ kí wọ́n ní ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀.—Fílípì 4:7.
Yàtọ̀ sí gbogbo àwọn àǹfààní yìí, àwọn tó bá nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run nípasẹ̀ Jésù Kristi Ọmọ rẹ̀ ní ìrètí àgbàyanu láti wà láàyè títí láé. Gbogbo wa la mọ ọ̀rọ̀ Jésù Kristi yìí dáadáa, pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” (Jòhánù 3:16) Àǹfààní iyebíye yẹn á túbọ̀ dájú téèyàn bá ní ìmọ̀ pípéye nípa Baba àti Ọmọ torí pé Jésù pàápàá sọ pé: “Èyí túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun, gbígbà tí wọ́n bá ń gba ìmọ̀ ìwọ, Ọlọ́run tòótọ́ kan ṣoṣo náà sínú, àti ti ẹni tí ìwọ rán jáde, Jésù Kristi.”—Jòhánù 17:3.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìbùkún tó kan àjọṣe àwa àti Ọlọ́run ni Ọlọ́run ṣèlérí, a tún ń gbádùn àwọn ìbùkún tó máa ṣe ara àti ìgbésí ayé wa láǹfààní. Jẹ́ ká wo àpẹẹrẹ Dalídio tó ń gbé ní orílẹ̀-èdè Brazil. Ọ̀mùtí paraku ni tẹ́lẹ̀ kó tó di pé ó ní ìmọ̀ tó péye nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run pinnu láti ṣe. Èyí sì ń ṣàkóbá tó pọ̀ fún ìdílé rẹ̀. Bákan náà, owó kì í fi bẹ́ẹ̀ dúró lọ́wọ́ rẹ̀. Àmọ́, nígbà tó yá àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ ọ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ìyẹn sì jẹ́ kí ìyípadà tó jọni lójú ṣẹlẹ̀ nínú ayé ẹ̀.
Àwọn nǹkan tí Dalídio kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó lè pa àwọn ìwà tó léwu tó ti di bárakú fún un tì. Ó sapá gan-an láti fàwọn ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì sílò débi tó fi lè sọ pé, “Ilé ọtí kan ni mo máa ń gbà délé ọtí míì tẹ́lẹ̀, àmọ́ ní báyìí mo ti ń wàásù láti ilé-dé-ilé.” Ó ti ń lo èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò ẹ̀ láti máa fi wàásù Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Yàtọ̀ sí pé ìyípadà tó ṣe yẹn jẹ́ kí ìlera ẹ̀ túbọ̀ dára sí i, ipò ìṣúnná owó ẹ̀ náà tún ti gbé pẹ́ẹ́lí. Dalídio sọ pé: “Owó tí mò ń ná sórí ọtí tẹ́lẹ̀ ni mo wá ń lò báyìí láti fi ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ tàbí kí n fi ra àwọn nǹkan tí mo nílò.” Ó tún ti láwọn ọ̀rẹ́ gidi bó ṣe ń dara pọ̀ mọ́ àwọn tó jẹ́ pé ojú tí Ọlọ́run fi ń wo nǹkan làwọn náà fi ń wò ó. Ní báyìí, Dalídio ti ní àlááfíà ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn tí kò retí pé òun lè ní kó tó kẹ́kọ̀ọ́ nípa Ọlọ́run.
Ẹlòmíì tí ìgbésí ayé ẹ̀ tún nítumọ̀ torí ìgbàgbọ́ tó ní nínú Jèhófà Ọlọ́run ni Renato. Téèyàn bá rí i bí ọkùnrin yìí ṣe máa ń láyọ̀ nígbà gbogbo, èèyàn ò ní mọ̀ pé ojú ẹ̀ ti rí màbo nígbèésí ayé. Nígbà tó ṣì wà lọ́mọ tuntun jòjòló ni ìyá ẹ̀ ti gbé e sọ nù. Inú àpò kan ló gbé e sí lábẹ́ àga, nǹkan ti ha á lára, ó sì ti ṣèṣe gan-an, ìwọ́ tó máa ń wà lára ọmọ tuntun ṣì wà lára ẹ̀. Àwọn obìnrin méjì kan ń kọjá, wọ́n sì rí àpò kan tí nǹkan ń jà pàtàpàtà nínú ẹ̀ lábẹ́ àga. Wọ́n tiẹ̀ kọ́kọ́ rò pé ẹnì kan ló gbàgbé ọmọ ológbò sínú ẹ̀. Nígbà tí wọ́n rí i pé ọmọ tuntun jòjòló ni, wọ́n sáré gbé e lọ sílé ìwòsàn tó wà nítòsí fún ìtọ́jú.
Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni ọ̀kan lára àwọn obìnrin yẹn, ó sì sọ fún Rita tóun náà jẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà nípa ọmọ jòjòló náà. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni oyún ti bà jẹ́ lára Rita, ọmọbìnrin kan ṣoṣo ló sì bí. Ó wù ú gan-an kó bí ọmọkùnrin, torí náà ó pinnu láti gba Renato ṣọmọ.
Rita sọ fún Renato nígbà tó ṣì wà ní kékeré pé òun kọ́ lòun bí i. Àmọ́, ó fìfẹ́ tọ́jú Sáàmù 27:10.
rẹ̀, ó sì sapá láti kọ́ ọ láwọn ìlànà Bíbélì. Bí Renato sì ṣe ń dàgbà, ó bẹ̀rẹ̀ sí í nífẹ̀ẹ́ sáwọn ohun tó ń kọ́ nínú Bíbélì. Bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọrírì tó ní fún ọ̀nà tó jọni lójú gan-an tí wọ́n gbà gba ẹ̀mí ẹ̀ là túbọ̀ ń pọ̀ sí i. Gbogbo ìgbà ni omijé máa ń dà lójú ẹ̀ tó bá ń ka àwọn ọ̀rọ̀ sáàmù tí Dáfídì kọ pé: “Bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé baba mi àti ìyá mi fi mí sílẹ̀, àní Jèhófà tìkára rẹ̀ yóò tẹ́wọ́ gbà mí.”—Renato ṣèrìbọmi lọ́dún 2002 láti fi hàn pé òun mọrírì gbogbo ohun tí Jèhófà ti ṣe fóun, nígbà tó sì di ọdún tó tẹ̀ lé e, ó di Kristẹni alákòókò kíkún, ìyẹn àwọn tó ń lo àkókò tó pọ̀ láti máa fi wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Títí di báyìí, kò tíì mọ bàbá àti ìyá tó bí i, ó sì ṣeé ṣe kó má mọ̀ wọ́n láéláé. Síbẹ̀, Renato gbà pé ọ̀kan lára ẹ̀bùn tó ṣeyebíye jù lọ tóun rí gbà ni mímọ̀ tóun mọ Jèhófà, tóun sì nígbàgbọ́ nínú rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí Baba onífẹ̀ẹ́ tó ń bójú tóni.
Ó ṣeé ṣe kó wu ìwọ náà láti sún mọ́ Ọlọ́run, kó o sì ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀, èyí tó lè jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ nítumọ̀. Àǹfààní láti nírú àjọṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ Jésù Kristi ṣí sílẹ̀ fún gbogbo èèyàn, ì báà jẹ́ olówó tàbí òtòṣì. Èyí lè má sọ èèyàn dọlọ́rọ̀ o, àmọ́ ó máa jẹ́ kéèyàn ní àlááfíà ọkàn àti ìtẹ́lọ́rùn tí gbogbo owó tó wà láyé yìí ò lè rà. Òótọ́ làwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú ìwé Òwe 10:22, ó sọ pé: “Ìbùkún Jèhófà—èyíinì ni ohun tí ń sọni di ọlọ́rọ̀, kì í sì í fi ìrora kún un.”
Jèhófà Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ sáwọn tó bá wá sọ́dọ̀ rẹ̀, ó sọ pé: “Ì bá ṣe pé ìwọ yóò fetí sí àwọn àṣẹ mi ní tòótọ́! Nígbà náà, àlàáfíà rẹ ì bá dà bí odò, òdodo rẹ ì bá sì dà bí ìgbì òkun.” (Aísáyà 48:18) Ó sì ṣèlérí pé òun máa bù kún àwọn tó bá jẹ́ pé torí ìfẹ́ láti mọ òtítọ́ ni wọ́n ṣe wá sọ́dọ̀ òun, Bíbélì sọ pé: “Ìyọrísí ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀ àti ìbẹ̀rù Jèhófà ni ọrọ̀ àti ògo àti ìyè.”—Òwe 22:4.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 6]
Ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run máa ń jẹ́ kéèyàn ní àlááfíà, ìtẹ́lọ́rùn àti ayọ̀
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 5]
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìdílé Jésù lórí ilẹ̀ ayé kì í ṣe ọlọ́rọ̀, Ọlọ́run bù kún wọn jìgbìnnì