Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Béèyàn Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Béèyàn Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Ayẹyẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́yege Kíláàsì Kẹrìndínláàádóje Nílé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

Béèyàn Ṣe Lè Ṣàṣeyọrí Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì

Ọ̀PỌ̀ ÈÈYÀN tínú wọn dùn jọjọ ló pésẹ̀ sí Ibùdó Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ ti Watchtower nílùú Patterson, ìpínlẹ̀ New York fún ayẹyẹ pàtàkì kan. Ọjọ́ Sátidé March 14, ọdún 2009 ni ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege ti kíláàsì kẹrìndínláàádóje [126] ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì. Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wà ní sẹpẹ́ láti lọ wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lórílẹ̀-èdè méjìlélógún [22].—Mátíù 24:14.

Àwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí ṣẹ̀ṣẹ̀ parí ìdálẹ́kọ̀ọ́ olóṣù márùn-ún tó fa kíki látinú Bíbélì ni, ètò Ọlọ́run ló dìídì ṣètò rẹ̀ láti ràn wọ́n lọ́wọ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wọn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì. Ọjọ́ ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege yìí ni gbogbo wọn máa láǹfààní láti wà pa pọ̀ kẹ́yìn gẹ́gẹ́ bí akẹ́kọ̀ọ́ láti gbọ́ ìmọ̀ràn ọlọ́gbọ́n lórí bí wọ́n ṣe lè ṣàṣeyọrí lẹ́nu iṣẹ́ wọn.

Arákùnrin Anthony Morris tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, tó ṣe alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà sọ pé láti ọdún 1943 ni Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ti ń fún àwọn míṣọ́nnárì ní ìdánilẹ́kọ̀ọ́. Látìgbà náà wá, iṣẹ́ kékeré kọ́ làwọn akẹ́kọ̀ọ́yege ti ṣe lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù tá à ń ṣe kárí ayé.

Olùbánisọ̀rọ̀ yẹn sọ pé, báwọn akọ̀wé òfin àtàwọn Farisí tiẹ̀ fojú àbùkù wo àwọn àpọ́sítélì Jésù, tí wọ́n sì pè wọ́n ní “ènìyàn tí kò mọ̀wé àti gbáàtúù,” wọ́n gbà nígbà tó yá pé wíwà táwọn àpọ́sítélì ti wà pẹ̀lú Jésù ló jẹ́ kí wọ́n lè máa fìgboyà sọ̀rọ̀. (Ìṣe 4:13) Ìdálẹ́kọ̀ọ́ táwọn akẹ́kọ̀ọ́ yìí gbà ló jẹ́ káwọn náà lè máa fi ìdánilójú sọ̀rọ̀.

‘Ẹ Má Ṣe Ojúsàájú’ ni àkòrí ọ̀rọ̀ tí Arákùnrin Robert Ciranko sọ, ó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ Ìgbìmọ̀ Ìkọ̀wé tó ń ṣiṣẹ́ pẹ̀lú Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ó jẹ́ káwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ mọ̀ pé wọ́n máa tó bẹ̀rẹ̀ sí í bá àwọn èèyàn tí àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ síra pà dé. Àmọ́ kò ní nira láti wàásù fáwọn èèyàn yìí táwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà bá nírú ànímọ́ tí Jèhófà ní. Téèyàn bá lóye ìtumọ̀ àwọn ọ̀rọ̀ tó wà nínú Ìwé Ìṣe 10:34 dáadáa, ohun tó túmọ̀ sí ni pé Ọlọ́run kì í ka ẹnì kan sí ju ẹlòmíì lọ. Bíbélì sọ pé, “Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú.” (Ìṣe 10:35) Arákùnrin Ciranko sọ pé: “Tẹ́ ẹ bá láwọn ànímọ́ bíi ti Ọlọ́run, tẹ́ ẹ sì ń wo gbogbo èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ ìwàásù yín bí ẹni tí Ọlọ́run lè tẹ́wọ́ gbà, ẹ máa ṣàṣeyọrí.”

“Ẹ Ti Láwọn Nǹkan Tẹ́ Ẹ Nílò”

Arákùnrin Samuel Herd tó jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ ẹ̀ pé: “Àwọn kan máa ń sọ pé ràkúnmí ò rẹwà, síbẹ̀ ó láwọn nǹkan tó lè mú kó máa gbé nínú aṣálẹ̀ pẹ̀lú ìrọ̀rùn.” Bákan náà, àwọn míṣọ́nnárì tuntun yìí láwọn nǹkan tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ṣàṣeyọrí láwọn ibi tí wọ́n ń lọ. Ohun márùn-ún ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ máa ràn wọ́n lọ́wọ́.

1. Ìfẹ́ fún Jèhófà. (Mátíù 22:37, 38) Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí ti fi hàn pé àwọ́n ti gbára dì láti ṣiṣẹ́ sin Jèhófà.

2. Ìmọ̀ tí wọ́n ti gbà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ràkúnmí máa ń tọ́jú oúnjẹ sínú iké ẹ̀yìn rẹ̀. Síbẹ̀, kì í dáwọ́ oúnjẹ jíjẹ dúró. Àwọn míṣọ́nnárì náà ò gbọ́dọ̀ tìtorí pé àwọn ti gba ìdálẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì kí wọ́n wá dáwọ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ dúró, àmọ́ ó yẹ kí wọ́n máa báa nìṣó láti máa kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

3. Ìfẹ́ fún àwọn èèyàn. (Mátíù 22:39) Àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí láàánú àwọn èèyàn.

4. Ẹ̀mí ìmúratán. (Sáàmù 110:3) Nígbà tó bá rẹ àwọn míṣọ́nnárì tẹnutẹnu, Jèhófà máa ń fún wọn lókun.—Aísáyà 40:29.

5. Okun ìgbà ọ̀dọ́. Bí ràkúnmí ṣe máa ń gbé àwọn èèyàn la inú aṣálẹ̀ kọjá, àwọn míṣọ́nnárì pàápàá lè ní láti ran Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wọn lọ́wọ́ nínú ìjọsìn wọn. Okun kékeré kọ́ nìyẹn sì máa nílò, àmọ́ àwọn míṣọ́nnárì ní okun ìgbà ọ̀dọ́.

Àwọn Apá Tó Kù Nínú Ìtòlẹ́sẹẹsẹ Náà

Arákùnrin Michael Burnett, tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì sọ pé, álímọ́ńdì wà lára àwọn èso dídára tí Jékọ́bù fi ránṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn sí aláṣẹ ilẹ̀ Íjíbítì. (Jẹ́nẹ́sísì 43:11) Ọ̀pọ̀ èròjà aṣaralóore ló wà nínú èso álímọ́ńdì kékeré kan. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹ̀kọ́ tó dà bí èso álímọ́ńdì làwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí ti jẹ lákòókò ìdánilẹ́kọ̀ọ́ wọn. Ọ̀kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní láti fi sọ́kàn ni pé, ó ṣe pàtàkì láti ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú àwọn ohun tí Jèhófà ń pèsè, kí wọ́n sì kọ́ láti fẹ́ràn àwọn ibi tí wọ́n ń lọ.

Arákùnrin Mark Noumair tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì ṣàlàyé pé Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dà bí “ẹ̀kún àpò ọgbọ́n.” (Jóòbù 28:18) Ó yẹ ká ṣí àpò náà, ká sì lo ohun tó wà nínú rẹ̀. Tó bá ṣẹlẹ̀ pé ohun táwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ yìí ń retí lẹ́nu iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì kọ́ ni wọ́n bá níbẹ̀, kí wọ́n rántí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ní kó lọ sí ìlù ìbílẹ̀ rẹ̀ fún ọdún mẹ́sàn-án. Dípò kó máa ronú pé òun jẹ́ “ohun èlò tí a ti yàn,” tó sì yẹ kóun máa ṣiṣẹ́ sìn níbòmíì, ńṣe ni Pọ́ọ̀lù máa ń ṣiṣẹ́ kára níbikíbi tó bá ti bára rẹ̀. (Ìṣe 9:15, 28-30) Ó lè má rọrùn láti ṣohun tí Jèhófà fẹ́. Ẹlòmíì tóun náà tún ṣe bẹ́ẹ̀ ni Jónátánì. Torí Jónátánì mọ̀ pé Dáfídì ni ọba tí Jèhófà yàn, ó gbà láti tì í lẹ́yìn.

Nínú àsọyé tí àkòrí rẹ̀ sọ pé, “Àwọn Ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ń Sọ̀rọ̀ Láìṣojo,” àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ ṣàṣefihàn àwọn ìrírí tí wọ́n ní lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù lákòókò tí wọ́n wà nílé ẹ̀kọ́. Ọ̀pọ̀ nínú wọn ló bẹ̀rẹ̀ sí í kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àkòrí àsọyé tó tẹ̀ lé e ni: “Ètò Jèhófà Ń Mú Wa Gbára Dì,” nínú àsọyé yìí, wọ́n fọ̀rọ̀ wá ọ̀rọ̀ wò lẹ́nu àwọn mẹ́ta kan tí wọ́n ti pẹ́ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ló ṣàlàyé bóun ṣe kọ́ láti máa fọwọ́sowọ́pọ̀ pẹ̀lú ètò Ọlọ́run.

“Ẹ Máa Láyọ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Yín”

Arákùnrin Gerrit Lösch tóun náà jẹ́ ọ̀kan lára Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, sọ àsọyé pàtàkì nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, àkòrí àsọyé rẹ̀ ni, “Ẹ Máa Láyọ̀ Lẹ́nu Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì Yín.” Ó sọ pé, ọ̀pọ̀ ìgbòkègbodò táwọn èèyàn kà sí nǹkan amóríyá kì í fúnni láyọ̀ tòótọ́. (Òwe 14:13; Oníwàásù 2:10, 11) Ayọ̀ tòótọ́ máa ń wá látinú ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, bó tiẹ̀ jẹ́ pé kì í fìgbà gbogbo rọrùn. Iṣẹ́ àṣekára lèèyàn máa ṣe nígbà tó bá ń kẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àmọ́ ìtẹ́lọ́rùn tó kọ yọyọ ló ń fúnni.

Onírúurú nǹkan ló máa ń fún àwọn Kristẹni tòótọ́ láyọ̀. Ọlọ́run aláyọ̀ ni wọ́n ń sìn. (Sáàmù 33:12; 1 Tímótì 1:11) Wọ́n wà nínú Párádísè tẹ̀mí, Bíbélì sì jẹ́ kí wọ́n mọ̀ pé ilẹ̀ ayé máa tó di Párádísè. Wọ́n ti mọ ìdí tá a fi wà láyé, ìyẹn láti máa sin Jèhófà, ká sì máa yìn ín. Yàtọ̀ síyẹn, Jèhófà àti Jésù nífẹ̀ẹ́ wọn.

Olùbánisọ̀rọ̀ náà fi kún ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Tẹ́ ẹ bá ní ìtẹ́lọ́rùn, ẹ máa láyọ̀ lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín.” Ohun míì tó tún máa ń fúnni láyọ̀ ni pé ká nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn káwọn náà sì nífẹ̀ẹ́ wa. Torí náà, ẹ máa gbójú fo àṣìṣe àwọn èèyàn dípò kẹ́ ẹ máa tẹnu mọ́ ọn. Ẹ máa ṣe rere, ẹ máa ran àwọn tí kò lera lọ́wọ́, ẹ máa sọ àwọn ohun tó ń múnú yín dùn fáwọn ẹlòmíì. (Sáàmù 41:1, 2; Ìṣe 20:35) Èèyàn máa láyọ̀ tó bá ń lo gbogbo okun rẹ̀ lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù.—Lúùkù 11:28.

Nígbà tí Arákùnrin Lösch máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó ní: “Ẹ lọ fayọ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ míṣọ́nnárì yín, kẹ́ ẹ máa dára yá, àmọ́ kẹ́ ẹ jẹ́ kí fífi ìyìn fún Jèhófà Ọlọ́run wa aláyọ̀ máa jẹ yín lọ́kàn, kẹ́ ẹ sì máa múnú àwọn èèyàn dùn.”

Lẹ́yìn tí wọ́n ti fi ìkíni àwọn èèyàn láti àwọn ilẹ̀ bíi mélòó kan jíṣẹ́, Arákùnrin Anthony Morris fún àwọn ọmọ ilé ẹ̀kọ́ náà ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà. Lẹ́yìn náà, aṣojú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà ka lẹ́tà ìmọrírì tí wọ́n kọ sí Ìgbìmọ̀ Olùdarí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Nínú lẹ́tà yìí, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà dúpẹ́ fún ìdálẹ́kọ̀ọ́ tí wọ́n gbà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì.

Nígbà tó máa parí ọ̀rọ̀ rẹ̀, alága ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà fi “àwọn oríkèé àti àwọn iṣan adeegunpọ̀” tó wà nínú ara wa wé àwọn ọ̀nà àti ètò tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” máa ń ṣe láti fún àwọn èèyàn Jèhófà ní ìtọ́ni àti oúnjẹ tẹ̀mí. (Kólósè 2:18, 19; Mátíù 24:45) Táwọn tó ń kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì bá ń fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú àwọn aṣojú tí Ọlọ́run yàn, wọ́n á ṣàṣeyọrí ní kíkún lẹ́nu iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn.—2 Tímótì 4:5.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

ÌSỌFÚNNI NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye orílẹ̀-èdè táwọn akẹ́kọ̀ọ́ ti wá: 6

Iye orílẹ̀-èdè tá a yàn wọ́n sí: 22

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 56

Iye àwọn tọkọtaya: 28

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí wọn: 32.8

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà:17.9

Ìpíndọ́gba ọdún tí wọ́n ti lò lẹ́nu iṣẹ́ ajíhìnrere: 13.5

ÀWỌN IBI TÁ A RÁN ÀWỌN AKẸ́KỌ̀Ọ́ LỌ

Àwọn ibi tá a rán àwọn tó kẹ́kọ̀ọ́ yege lọ ni Benin, Bòlífíà, Bulgaria, Burkina Faso, Costa Rica, Gánà, Guatemala, Honduras, Kamẹrúùnù, Kẹ́ńyà, Làìbéríà, Madagásíkà, Mòsáńbíìkì, Nicaragua, Panama, Paraguay, Peru, Romania, Sierra Leone, South Áfíríkà, Tógò àti Uganda.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Kíláàsì Kẹrìndínláàádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì

A to nọ́ńbà ìlà kọ̀ọ̀kan láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì lọ sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Kirchhoff, K.; Nichols, C.; Guzmán, Y.; Coil, H.; Becker, O.; De Simone, A. (2) Manzanares, A.; Bouvier, E.; Peddle, J.; Mason, H.; Braz, J. (3) Lee, J.; Forte, A.; Boucher, T.; Marsh, A.; Leighton, S.; Glover, M. (4) Kambach, H.; Jones, T.; Ferreira, A.; Morales, J.; Chicas, S.; Davis, B.; Dormanen, E. (5) Dormanen, B.; Nichols J.; Pacho, T.; Titmas, L.; Bouvier, E.; Kirchhoff, A. (6) Leighton, G.; Pacho, A.; Van Campen, B.; Manzanares, A.; Rivard, A.; Lee, Y.; Titmas, L. (7) Boucher, M.; Coil, K.; Marsh, C.; Guzmán, J.; Jones, W.; Kambach, J. (8) Glover, A.; Ferreira, G.; Mason, E.; Forte, D.; Davis, N.; Chicas, O.; Rivard, Y. (9) Braz, D.; Van Campen, D.; Morales, A.; De Simone, M.; Becker, M.; Peddle, D.