Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Kí ló ṣẹlẹ̀ gan-an sí àpótí májẹ̀mú?
Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbà gbọ́ pé ibi tí àpótí májẹ̀mú bá wà ni Ọlọ́run wà. (Ẹ́kísódù 25:22) Ó jẹ́ àpótí mímọ́ tí wọ́n fi igi ṣe, wọ́n sì fi wúrà bò ó lára, inú ẹ̀ ni Mósè kó àwọn wàláà òkúta tí wọ́n kọ Òfin Ọlọ́run sí. Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú àgọ́ ìpàdé làwọn ọmọ Ísírẹ́lì gbé Àpótí yìí sí nígbà tí wọ́n wà nínú aginjù. (Ẹ́kísódù 26:33) Nígbà tó yá, Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tí Sólómọ́nì kọ́ ni wọ́n gbé e sí.—1 Àwọn Ọba 6:19.
Inú ìwé 2 Kíróníkà 35:3 ni Bíbélì ti mẹ́nu kan Àpótí yìí kẹ́yìn, ìyẹn sì ni ìgbà tí Jòsáyà Ọba gbé e pa dà sínú tẹ́ńpìlì lọ́dún 642 ṣáájú Sànmánì Kristẹni. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé Mánásè, apẹ̀yìndà ọba tó ti jẹ ṣáájú Jòsáyà ló gbé Àpótí yìí kúrò, tó sì wá gbé ère sínú tẹ́ńpìlì. Ó sì lè jẹ́ pé ṣe ni wọ́n gbé àpótí yìí kúrò láti tọ́jú rẹ̀ nígbà tí Jòsáyà fẹ́ tún tẹ́ńpìlì ṣe. (2 Kíróníkà 33:1, 2, 7; 34:1, 8-11) Bíbélì kò sọ ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Àpótí yìí lẹ́yìn ìgbà náà torí pé kò sí lára àwọn nǹkan tó sọ pé àwọn ará Bábílónì kó nínú tẹ́ńpìlì nígbà tí wọ́n ṣẹ́gun Jerúsálẹ́mù lọ́dún 607 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.—2 Àwọn Ọba 25:13-17.
Ìwé Mímọ́ ò sọ pé wọ́n dá Àpótí náà pa dà sínú Ibi Mímọ́ Jù Lọ nínú tẹ́ńpìlì tí Serubábélì tún kọ́; kò sì jọ pé wọ́n fi àpótí míì rọ́pò rẹ̀.—Ẹ́sírà 1:7-11.
Àwọn ọkùnrin wo ló ń jẹ́ Jákọ́bù nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì?
Nínú ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì táwọn èèyàn tún mọ̀ sí Májẹ̀mú Tuntun, àwọn ọkùnrin mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ló ń jẹ́ Jákọ́bù, ó sì rọrùn láti ṣì wọ́n gbé síra. a Àkọ́kọ́ ni bàbá àpọ́sítélì Júdásì (kì í ṣe Ísíkáríótù), Bíbélì ò sì tún sọ ohunkóhun nípa rẹ̀.—Lúùkù 6:16; Ìṣe 1:13.
Ẹnì kejì ni Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè. Òun ni arákùnrin Jòhánù, àpọ́sítélì Jésù sì làwọn méjèèjì. (Mátíù 10:2) Ó jọ pé Sàlómẹ̀ tó jẹ́ mọ̀lẹ́bí ìyá Jésù ni màmá ẹ̀. (Fi Mátíù 27:55, 56 wé Máàkù 15:40, 41 àti Jòhánù 19:25.) Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, a jẹ́ pé ìbátan Jésù ni Jákọ́bù. Apẹja ni, òun àti arákùnrin rẹ̀ ni wọ́n sì jọ máa ń dẹdò pẹ̀lú Pétérù àti Áńdérù.—Máàkù 1:16-19; Lúùkù 5:7-10.
Jákọ́bù ọmọkùnrin Áfíọ́sì ni ẹnì kẹta, àpọ́sítélì Jésù sì lòun náà. (Máàkù 3:16-18) Bíbélì pè é ní “Jákọ́bù Kékeré” nínú ìwé Máàkù 15:40. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ ìrísí ẹ̀ tó kéré tàbí pé kò dàgbà tó Jákọ́bù ọmọkùnrin Sébédè ni wọ́n ṣe ń pè é ní “Kékeré.”
Ẹnì kẹrin ni ọmọkùnrin Jósẹ́fù àti Màríà, ìyẹn arákùnrin Júúdà, tó sì tún jẹ́ iyèkan Jésù. (Máàkù 6:3; Gálátíà 1:19) Nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù, Jákọ́bù yìí kì í ṣe ọ̀kan lára àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀. (Mátíù 12:46-50; Jòhánù 7:5) Àmọ́, ṣáájú Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Kristẹni, Jákọ́bù gbàdúrà pẹ̀lú màmá rẹ̀, àwọn arákùnrin rẹ̀ àtàwọn ọmọ ẹ̀yìn nínú ìyẹ̀wù òkè nílùú Jerúsálẹ́mù. (Ìṣe 1:13, 14) Nígbà tó yá, Jákọ́bù di ọ̀kan pàtàkì nínú àwọn ará ìjọ tó wà nílùú Jerúsálẹ́mù, òun ló sì kọ ìwé Bíbélì tí wọ́n ń forúkọ ẹ̀ pè.—Ìṣe 12:17; Jákọ́bù 1:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Láwọn èdè tí wọ́n fi kọ Bíbélì, ìtumọ̀ kan náà ni Jákọ́bù àti Jékọ́bù ní. Ọ̀pọ̀ ìgbà ni “Ábúráhámù, Ísákì àti Jékọ́bù” fara hàn nínú Bíbélì, ìwé Mátíù 1:16 sì jẹ́ ká mọ̀ pé Jékọ́bù ni bàbá “Jósẹ́fù ọkọ Màríà.”