Onídàájọ́ Tó Máa Ń Ṣohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Onídàájọ́ Tó Máa Ń Ṣohun Tó Tọ́ Nígbà Gbogbo
ÀWỌN èèyàn tí wọ́n jẹ́ adájọ́ lè ṣèdájọ́ lọ́nà tí kò tọ́ tàbí lọ́nà tó le koko jù, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú Jèhófà Ọlọ́run tó jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (Sáàmù 37:28) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó máa ń ní sùúrù, kò fàyè gbàgbàkugbà. Ohun tó tọ́ ló máa ń ṣe nígbà gbogbo. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tó ṣe nígbà tí aáwọ̀ àti ìdìtẹ̀ wáyé, bó ṣe wà lákọọ́lẹ̀ nínú ìwé Númérì orí 20.
Nígbà tí ìrìn àjò àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń parí lọ nínú aginjù, wọn ò rí omi mu. a Àwọn èèyàn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí í fìbínú sọ̀rọ̀ sí Mósè àti Áárónì pé: “Èé sì ti ṣe tí ẹ fi mú ìjọ Jèhófà wá sí aginjù yìí kí àwa àti àwọn ẹranko arẹrù wa lè kú níbẹ̀?” (Ẹsẹ 4) Àwọn èèyàn náà ṣàròyé pé “ibi búburú” ni aginjù náà, wọ́n ní kò sí “ọ̀pọ̀tọ́ àti àjàrà àti pómégíránétì,” ìyẹn àwọn èso táwọn amí ọmọ ilẹ̀ Ísírẹ́lì mú wá láti Ilẹ̀ Ìlérí lọ́dún bíi mélòó kan ṣáájú ìgbà yẹn, wọ́n tún ní kò “sí omi láti mu.” (Ẹsẹ 5; Númérì 13:23) Wọ́n ń tipa bẹ́ẹ̀ dẹ́bi fún Mósè àti Áárónì torí pé inú aginjù yẹn ò dà bí ilẹ̀ eléso tí gbogbo wọn ń lọ, àmọ́ tí ìran wọn tó ti ráhùn nígbà kan rí kò láǹfààní láti wọ̀!
Jèhófà ò kọ àwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn sílẹ̀. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó ní kí Mósè ṣohun mẹ́ta kan: kó mú ọ̀pá rẹ̀, kó pe àwọn èèyàn náà jọ, kó sì “bá àpáta gàǹgà sọ̀rọ̀ lójú wọn kí ó lè pèsè omi rẹ̀ ní tòótọ́.” (Ẹsẹ 8) Mósè ṣàwọn nǹkan méjì àkọ́kọ́, àmọ́ kò ṣe ìkẹta. Dípò kí Mósè fi ìgbàgbọ́ hàn nígbà tó ń bá àpáta náà sọ̀rọ̀, ṣe ló fìbínú sọ̀rọ̀ sáwọn èèyàn náà pé: “Ẹ gbọ́, nísinsìnyí, ẹ̀yin ọlọ̀tẹ̀! Ṣé láti inú àpáta gàǹgà yìí ni kí a ti mú omi jáde fún yín?” (Ẹsẹ 10; Sáàmù 106:32, 33) Lẹ́yìn náà ni Mósè lu àpáta náà lẹ́ẹ̀mejì, “omi púpọ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí jáde wá.”—Ẹsẹ 11.
Bí Mósè àti Áárónì ṣe dẹ́ṣẹ̀ tó burú jáì nìyẹn. Ọlọ́run sọ fún wọn pé: “Ẹ ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ ìtọ́ni mi.” (Númérì 20:24) Bí Mósè àti Áárónì ṣe kọ̀ láti ṣègbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run yìí fi hàn pé àwọn pàápàá ti di ọlọ̀tẹ̀, ìyẹn ẹ̀sùn tí wọ́n fi kan àwọn èèyàn náà. Ìdájọ́ Ọlọ́run ṣe kedere: Mósè àti Áárónì kọ́ ló máa kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Ṣé ìdájọ́ yìí le koko jù? Rárá o, jẹ́ ká wo ìdí mélòó kan.
Àkọ́kọ́ ni pé Ọlọ́run ò ní kí Mósè bá àwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ rárá débi kó wá pè wọ́n ní ọlọ̀tẹ̀. Ìkejì ni pé Mósè àti Áárónì kò fògo fún Ọlọ́run. Ọlọ́run sọ pé: “Ẹ kò . . . sọ mí di mímọ́.” (Ẹsẹ 12) Bí Mósè ṣe sọ pé, ‘kí a mú omi jáde,’ ṣe ló sọ̀rọ̀ bíi pé agbára òun àti Áárónì làwọn máa fi mú omi náà jáde, kì í ṣe ti Ọlọ́run. Ìdí kẹta ni pé ìdájọ́ tí Ọlọ́run ṣe yìí ò yàtọ̀ sáwọn ìdájọ́ tó ti ń ṣe látẹ̀yìn wá. Ọlọ́run ò jẹ́ kí ìran àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó kọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀ wọ ilẹ̀ Kénáánì, ohun tó sì ṣe fún Mósè àti Áárónì náà nìyẹn. (Númérì 14:22, 23) Ìdí kẹrin ni pé aṣáájú orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ni Mósè àti Áárónì. Àwọn tí Ọlọ́run bá sì fún ní ojúṣe tó pọ̀ máa jíhìn ohun tó pọ̀ fún Ọlọ́run.—Lúùkù 12:48.
Jèhófà máa ń ṣohun tó tọ́ nígbà gbogbo. Kì í ṣèdájọ́ lọ́nà tí kò tọ́ torí pé ó nífẹ̀ẹ́ ìdájọ́ òdodo. Ó ṣe kedere pé a ní láti fọkàn tán irú Adájọ́ yìí, ká sì máa bọ̀wọ̀ fún un.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Lẹ́yìn táwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò ní Íjíbítì, wọ́n múra tán láti wọ ilẹ̀ Kénáánì, ilẹ̀ tí Ọlọ́run ti ṣèlérí fún Ábúráhámù. Àmọ́ nígbà táwọn amí mẹ́wàá mú ìròyìn búburú wá, àwọn èèyàn náà ráhùn lòdì sí Mósè. Ìyẹn ló mú kí Jèhófà pàṣẹ pé ogójì [40] ọdún gbáko ni wọ́n máa lò nínú aginjù, káwọn ọlọ̀tẹ̀ yẹn lè kú dà nù.