Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Wọ́n Ṣàwárí Bíbélì Tó Ṣeyebíye

Wọ́n Ṣàwárí Bíbélì Tó Ṣeyebíye

Wọ́n Ṣàwárí Bíbélì Tó Ṣeyebíye

NÍ Ọ̀PỌ̀ ọgọ́rùn-ún ọdún sẹ́yìn, àwọn nǹkan èlò ìkọ̀wé ò rọrùn láti rí bíi tòde òní. Awọ àtàwọn nǹkan míì tí wọ́n máa ń kọ̀wé lé lórí ni wọ́n máa ń lò ní àlòtúnlò nípa pípa àwọn ọ̀rọ̀ tí wọn ò nílò mọ́ rẹ́ kúrò lórí rẹ̀ tàbí kí wọ́n fọ àwọn ọ̀rọ̀ náà dà nù. Kódà, wọ́n pa àwọn ẹsẹ Bíbélì kan rẹ́ kúrò lórí awọ kí wọ́n lè rí ààyè kọ àwọn ìsọfúnni míì sí.

Ọ̀kan pàtàkì lára àwọn awọ tí wọ́n pa ọ̀rọ̀ Bíbélì rẹ́ kúrò lórí ẹ̀ tí wọ́n wá fi kọ àwọn nǹkan míì ni èyí tí wọ́n ń pè ní Codex Ephraemi Syri rescriptus, rescriptus túmọ̀ sí “ọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀.” Awọ yìí ṣeyebíye gan-an torí ó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì tó tíì pẹ́ jù lọ tó wà ní àrọ́wọ́tó. Ìdí nìyẹn tó fi jẹ́ pé ó wà lára àwọn orísun tó ṣeé gbára lé jù lọ láti fìdí ẹ̀ múlẹ̀ pé Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì pé pérépéré.

Wọ́n pa Ìwé Mímọ́ tí wọ́n kọ ní ọ̀rúndún karùn-ún sórí awọ yìí rẹ́ ní ọ̀rúndún kejìlá Sànmánì Kristẹni, wọ́n sì fi ìwàásù méjìdínlógójì [38] ní ìtúmọ̀ Gíríìkì tí ọ̀mọ̀wé ọmọ ilẹ̀ Síríà tó ń jẹ́ Ephraem kọ dípò rẹ̀. Ní ìparí ọ̀rúndún kẹtàdínlógún [17] làwọn ògbóǹkangí kọ́kọ́ kíyè sí pé àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì tí wọ́n kọ́kọ́ kọ sórí awọ yẹn ò pa rẹ́ tán. Ọdún bíi mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí í kọ àwọn ọ̀rọ̀ tó ti kọ́kọ́ wà lórí awọ náà jáde. Àmọ́, kò rọrùn láti rí gbogbo ọ̀rọ̀ náà kà torí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti pa rẹ́ kò fi bẹ́ẹ̀ hàn dáadáa mọ́, àwọn kan lára àwọn awọ náà ti gbó àti pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n kọ lé e lórí bọ́ sójú ibi kan náà pẹ̀lú èyí tí wọ́n kọ́kọ́ kọ. Wọ́n bu oríṣiríṣi kẹ́míkà sórí awọ náà kí wọ́n lè rí àwọn ọ̀rọ̀ Bíbélì náà, kí wọ́n sì lè kà á, àmọ́ wọn ò fi bẹ́ẹ̀ ṣàṣeyọrí. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ nínú àwọn ọ̀mọ̀wé náà fi parí èrò sí pé àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti pa rẹ́ náà ò ṣeé kà mọ́.

Àmọ́, ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1840, ọ̀gbẹ́ni Konstantin von Tischendorf, ọmọ ilẹ̀ Jámánì tó jẹ́ ọ̀jáfáfá nínú ìmọ̀ èdè yọ̀ǹda ara rẹ̀ láti ṣàwárí bí wọ́n ṣe lè ka àwọn ọ̀rọ̀ tó dà bíi pé kò ṣeé kà lórí awọ náà. Ọdún méjì gbáko ni ọ̀gbẹ́ni Tischendorf fi ṣiṣẹ́ yìí. Kí ló jẹ́ kó lè ṣàṣeyọrí ohun táwọn tó kù ò lè ṣe?

Ọ̀gbẹ́ni Tischendorf lóye tó kún rẹ́rẹ́ nípa bí wọ́n ṣe máa ń kọ àwọn lẹ́tà gàdàgbà gàdàgbà sílẹ̀ lédè Gíríìkì. a Pẹ̀lú ojú ẹ̀ tó ríran rekete, ó kíyè sí pé tóun bá kàn mú awọ náà tóun sì sún mọ́ iná, òun á lè rí àwọn ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti pa rẹ́ náà kà. Láti ṣerú ohun kan náà lónìí, àwọn ọ̀mọ̀wé máa ń lo ohun tó máa jẹ́ kí wọ́n lè ríran dáadáa títí kan ìtànṣán tó lè jẹ́ kéèyàn ríran kedere, ìyẹn infrared, ìtànṣán tó dà bíi ti oòrùn, ìyẹn ultraviolet àti ìtànṣán tó máà ń mọ́lẹ̀ rokoṣo sójú kan, ìyẹn polarized light.

Lọ́dún 1843 àti ọdún 1845, ọ̀gbẹ́ni Tischendorf tẹ ohun tó rí kà nínú ìwé àfọwọ́kọ́ tí wọ́n ń pè ní Codex Ephraemi jáde. Àṣeyọrí tó ṣe yìí jẹ́ kó di aṣíwájú àwọn ọ̀mọ̀wé ilẹ̀ Gíríìkì tó ń ṣàwárí àwọn ìkọ̀wé tó ti wà tipẹ́.

Ìwé àfọwọ́kọ Ephraemi fẹ̀ tó nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mọ́kànlélọ́gbọ̀n [31], ó sì gùn tó nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n [25], òun sì ni ìwé àfọwọ́kọ́ tó tíì pẹ́ jù lọ tí wọn ò pín ọ̀rọ̀ orí ẹ̀ sí méjì lórí abala kan. Nínú igba ó lé mẹ́sàn-án [209] abala tí wọ́n ṣàwárí, márùnlélógóje [145] nínú ẹ̀ ló ní gbogbo Ìwé Mímọ́ Kristẹni Lédè Gíríìkì nínú, àyàfi ìwé Tẹsalóníkà Kejì àti Jòhánù Kejì. Àwọn apá kan nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n ti tú sí èdè Gíríìkì ló sì wà nínú àwọn abala tó kù.

Lónìí, ibi ìkówèésí ní National Library nílùú Paris, lórílẹ̀-èdè Faransé ni wọ́n tọ́jú ìwé àfọwọ́kọ yìí sí. Wọn ò mọ ibi tí ìwé àfọwọ́kọ yìí ti wá, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀gbẹ́ni Tischendorf rò pé ilẹ̀ Íjíbítì ló ti wá. Àwọn ọ̀mọ̀wé ka ìwé àfọwọ́kọ́ Ephraemi mọ́ ọ̀kan lára àwọn ìwé àfọwọ́kọ mẹ́rin pàtàkì, tó jẹ́ Bíbélì èdè Gíríìkì, tí wọ́n fi lẹ́tà gàdàgbà gàdàgbà kọ, àwọn mẹ́ta tó kù ni Sinaitic, Alexandrine, àti Vatican 1209, gbogbo wọn ló sì jẹ́ pé àárín ọ̀rúndún kẹrin àti ìkárùn-ún Sànmánì Kristẹni ni wọ́n ti kọ wọ́n.

Oríṣiríṣi ọ̀nà tó jọni lójú làwọn èèyàn ti gbà láti jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ wà nípamọ́ fún wa, títí kan kíka ọ̀rọ̀ tí wọ́n ti kọ òmíràn lé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn èèyàn kan tí kò mọ ìwúlò ọ̀rọ̀ inú Bíbélì gbìyànjú láti pa àwọn ọ̀rọ̀ kan rẹ́, síbẹ̀ àwọn ìsọfúnni inú Bíbélì ṣì wà dòní olónìí. Èyí wá jẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Pétérù túbọ̀ dá wa lójú pé: “Àsọjáde Jèhófà wà títí láé.”—1 Pétérù 1:25.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Kíkà tí ọ̀gbẹ́ni Tischendorf lè ka Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tí wọ́n tú sí èdè Gíríìkì jẹ́ káwọn èèyàn mọ̀ ọ́n dáadáa ní ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Òkè Sínáì, ìyẹn St. Catherine’s Monastery, ìwé yìí sì wà lára ìwé tó tíì pẹ́ jù lọ tí wọ́n tíì ṣàwárí rẹ̀. Wọ́n máa ń pe ìwé àfọwọ́kọ yẹn ní Codex Sinaiticus.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Codex Ephraemi Syri rescriptus tí ọ̀gbẹ́ni Tischendorf (1815 sí 1874) kọ̀rọ̀ inú ẹ̀ jáde rèé, ó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ìwé tí wọ́n ti kọ ọ̀rọ̀ lórí ọ̀rọ̀

Ọ̀RỌ̀ TÓ WÀ NÍBẸ̀ TẸ́LẸ̀

ÌWÀÁSÙ LÉDÈ GÍRÍÌKÌ TÍ WỌ́N KỌ LÉ E LÓRÍ

[Credit Line]

© Bibliothèque nationale de France

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Codex Sinaiticus, tí wọ́n rí ní St. Catherine’s Monastery

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Ọ̀gbẹ́ni Tischendorf rèé