Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Gbógun Ti Ìbẹ̀rù àti Iyèméjì

Ó Gbógun Ti Ìbẹ̀rù àti Iyèméjì

Tẹ̀ Lé Àpẹẹrẹ Ìgbàgbọ́ Wọn

Ó Gbógun Ti Ìbẹ̀rù àti Iyèméjì

PÉTÉRÙ ti ń fi àjẹ̀ tukọ̀ kárakára ní gbogbo òru nínú òkùnkùn. Bó ṣe kíyè sí pé ọ̀yẹ̀ ti là láti ìlà-oòrùn, ọkàn rẹ̀ balẹ̀ pé ojúmọ́ ti mọ́ ní gbẹ̀yìn-gbẹ́yín. Ẹ̀yìn àti èjìká ti ń ro ó kíkankíkan. Atẹ́gùn tó mú kí Òkun Gálílì máa ru gùdù ti jẹ́ kí irun orí rẹ̀ dà rú. Ìjì tó ń jà láìdáwọ́dúró ń bì lu ọkọ̀ tó fi ń pẹja, ó sì ń fẹ́ atẹ́gùn tútù nini lu òun pàápàá. Síbẹ̀ kò yéé tukọ̀.

Pétérù àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ ti fi Jésù nìkan sílẹ̀ sí etíkun. Ní ọjọ́ yẹn, ìṣojú wọn ni Jésù ṣe fi ìṣù búrẹ́dì àti ẹja díẹ̀ bọ́ ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn tí ebi ń pa. Àwọn èèyàn yẹn wá fẹ́ fi Jésù jọba, àmọ́ Jésù kò fẹ́ bá wọn lọ́wọ́ sí ọ̀rọ̀ ìṣèlú. Kò sì fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pàápàá lọ́wọ́ sírú nǹkan bẹ́ẹ̀. Ló bá yẹra fún àwọn èèyàn yẹn, ó sì sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí èbúté tó wà ní òdìkejì, nígbà tí òun fúnra rẹ̀ dá nìkan lọ sórí òkè láti gbàdúrà.—Máàkù 6:35-45; Jòhánù 6:14, 15.

Òṣùpá àrànmọ́jú mọ́lẹ̀ rokoṣo nígbà tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn bẹ̀rẹ̀ ìrìn àjò wọn, àmọ́ ní báyìí, ilẹ̀ ti ń mọ́ bọ̀ díẹ̀díẹ̀. Síbẹ̀ wọn kò tíì rìn ju kìlómítà mélòó kan lọ. Iṣẹ́ àṣekára tí wọ́n ń ṣe láti wakọ̀ àti ariwo ìgbì òkun kò jẹ́ kó rọrùn fún wọn láti máa bára wọn sọ̀rọ̀. Ó ṣeé ṣe kí Pétérù ti ronú lọ jìnnà.

Àìmọye nǹkan ló ní láti máa ronú lé lórí. Ó ti lé lódindi ọdún méjì gbáko tó ti ń bá Jésù ará Násárétì rìn, oríṣiríṣi ìṣẹ̀lẹ̀ ló sì ti ṣojú rẹ̀. Ọ̀pọ̀ ẹ̀kọ́ ló ti kọ́, àmọ́ ó ṣì máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Bó ṣe múra tán láti gbógun ti iyèméjì àti ìbẹ̀rù mú kó jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà fún wa láti fara wé. Jẹ́ ká wo ìdí tọ́rọ̀ fi rí bẹ́ẹ̀.

“Àwa Ti Rí Mèsáyà Náà”!

Pétérù kò jẹ́ gbàgbé ọjọ́ tó rí Jésù ará Násárétì. Áńdérù, arákùnrin rẹ̀, ló ti kọ́kọ́ fi ìròyìn tó yani lẹ́nu yìí tó o létí pé: “Àwa ti rí Mèsáyà náà.” Ọ̀rọ̀ tí Pétérù gbọ́ yìí jẹ́ kí ìgbésí ayé rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí í yí pa dà. Ó dájú pé ìgbésí ayé rẹ̀ kò ní rí bíi ti tẹ́lẹ̀ mọ́.—Jòhánù 1:41.

Ìlú Kápánáúmù ni Pétérù ń gbé, ìlú yìí wà ní etíkun adágún omi tí kò ní iyọ̀ tí wọ́n ń pè ní Okùn Gálílì. Òun àti Áńdérù jọ dòwò ẹja pípa pọ̀ pẹ̀lú Jákọ́bù àti Jòhánù tí wọ́n jẹ́ ọmọkùnrin Sébédè. Yàtọ̀ sí Pétérù àti ìyàwó rẹ̀, àwọn tó tún ń gbé lọ́dọ̀ rẹ̀ ni ìyá ìyàwó rẹ̀ àti Áńdérù arákùnrin rẹ̀. Kí Pétérù tó lè máa fi iṣẹ́ ẹja pípa gbọ́ bùkátà àgbo ilé rẹ̀ yìí, ó dájú pé ó ní láti jẹ́ akínkanjú ọkùnrin tó ń ṣe iṣẹ́ àṣekára. A lè fi ọkàn yàwòrán àìmọye òru tí òun àti àwọn tí wọ́n jọ ń pẹja á fi ní láti máa ṣiṣẹ́ àṣekára fún àkókò gígùn, bí wọ́n ṣe ń ta àwọ̀n wọn sáàárín ọkọ̀ méjì, tí wọ́n á sì máa kó àwọn ẹja tí wọ́n bá rí pa nínú adágún náà sí inú ọkọ̀. A tún lè fi ọkàn yàwòrán bí wọ́n á ṣe máa ṣiṣẹ́ àṣelàágùn láti àárọ̀ ṣúlẹ̀ níbi tí wọ́n ti ń ya àwọn ẹja náà sọ́tọ̀ọ̀tọ̀, tí wọ́n sì ń tà wọ́n, tí wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe, tí wọ́n sì ń fọ̀ wọ́n.

Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn Jòhánù Oníbatisí ni Áńdérù tẹ́lẹ̀. Ó dájú pé Pétérù máa ń fi ọkàn sí àwọn ìròyìn tí arákùnrin rẹ̀ máa ń sọ nípa ìwàásù Jòhánù. Lọ́jọ́ kan, Áńdérù wà níbẹ̀ nígbà tí Jòhánù nawọ́ sí Jésù ará Násárétì tó sì sọ pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run!” Lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀, Áńdérù di ọmọlẹ́yìn Jésù, ó sì fi tìtaratìtara sọ ìròyìn tó múnú rẹ̀ dùn yìí fún Pétérù pé: Mèsáyà ti dé! (Jòhánù 1:35-40) Lẹ́yìn ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé lọ́gbà Édẹ́nì ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́rin [4,000] ọdún ṣáájú ìgbà yẹn, Jèhófà Ọlọ́run ṣèlérí pé ẹnì kan tó ṣàrà ọ̀tọ̀ máa wá fún aráyé ní ìrètí tó dájú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Olùgbàlà náà sì ni Áńdérù rí yìí, ìyẹn Mèsáyà fúnra rẹ̀! Ni Pétérù náà bá gbéra láti lọ bá Jésù láìjáfara.

Títí di ọjọ́ tá à ń wí yìí, Símónì tàbí Síméónì ni orúkọ tí àwọn èèyàn mọ Pétérù sí. Àmọ́ nígbà tí Jésù rí i, ó sọ fún un pé: “‘Ìwọ ni Símónì ọmọkùnrin Jòhánù; a óò máa pè ọ́ ní Kéfà’ (èyí tí a túmọ̀ sí Pétérù).” (Jòhánù 1:42) “Kéfà” ni ọ̀rọ̀ orúkọ tó túmọ̀ sí “òkúta,” tàbí “àpáta.” Kò sí àní-àní pé àsọtẹ́lẹ̀ lọ̀rọ̀ tí Jésù sọ yìí. Ohun tó kíyè sí ni pé Pétérù máa dà bí àpáta, ìyẹn ni pé ó máa dúró digbí, ó máa fìdí múlẹ̀, ó sì máa nípa rere lórí àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi. Ṣé Pétérù rí ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀? Kò dájú. Kódà, àwọn kan tí wọ́n ń ka àwọn ìwé Ìhìn Rere lóde òní kò fi bẹ́ẹ̀ rí àwọn nǹkan tó mú kí Pétérù dà bí àpáta. Àwọn kan tiẹ̀ sọ pé kì í mọ ohun tó yẹ kó ṣe, ó máa ń ṣe kámi-kàmì-kámi, ó sì máa ń ṣiyèméjì.

Òótọ́ ni pé Pétérù ní àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ kan, Jésù náà sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Àmọ́ Jésù máa ń wo ohun tó dáa nínú àwọn èèyàn, bíi ti Jèhófà, Bàbá rẹ̀. Jésù rí i pé Pétérù ṣì lè ṣe dáadáa, ó sì sapá láti ràn án lọ́wọ́ kó lè túbọ̀ ní àwọn ànímọ́ tó dáa. Ohun tó dáa ni Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀ ń wò lára tiwa náà lónìí. Ó lè má rọrùn fún wa láti gbà pé àwọn nǹkan rere kan wà tí wọ́n lè rí lára wa. Àmọ́, a ní láti fọkàn tán wọn, ká sì fi hàn pé a múra tán láti gba ìtọ́sọ́nà, a sì fẹ́ kí Jèhófà mọ wá bíi ti Pétérù.—1 Jòhánù 3:19, 20.

“Dẹ́kun Fífòyà”

Ó ṣeé ṣe kí Pétérù tẹ̀ lé Jésù lọ sí àwọn ibì kan tó ti lọ wàásù lẹ́yìn ìgbà náà. Ó ṣeé ṣe kó wà níbẹ̀ nígbà tí Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ àkọ́kọ́, ìyẹn bó ṣe sọ omi di ọtí wáìnì níbi àsè ìgbéyàwó tó wáyé ní Kánà. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, ó gbọ́ ìwàásù tó yani lẹ́nu tó sì fini lọ́kàn balẹ̀ tí Jésù ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run. Síbẹ̀, ó fi Jésù sílẹ̀, ó sì pa dà sẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa. Oṣù mélòó kan lẹ́yìn ìgbà náà, Pétérù àti Jésù tún pàdé, Jésù sì sọ fún un lọ́tẹ̀ yìí pé òun fẹ́ kó máa tẹ̀ lé òun nígbà gbogbo.

Pétérù àti àwọn tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́ ti fi gbogbo òru dẹ odò léraléra, àmọ́ wọn kò rí ẹja pa. Ó dájú pé Pétérù á ti lo gbogbo ọgbọ́n àti ìrírí tó ní lẹ́nu iṣẹ́ ẹja pípa bó ti ń gbìyànjú onírúurú ibi tó ti ṣeé ṣe kí àwọn ẹja ti máa jẹun nínú adágún náà. Kò sí àní-àní pé á máa wù ú, bó ti máa ń wu ọ̀pọ̀ àwọn apẹja, pé kí òun rí ibi tí àwọn ẹja pọ̀ sí nínú omi yìí tí ìsàlẹ̀ rẹ̀ kò rọrùn láti rí tàbí kí òun tiẹ̀ fi àwọ̀n kó àwọn ẹja náà. Ńṣe láá túbọ̀ máa ká a lára bó bá ṣe ń ronú pé òun kò rí ẹja pa. Eré kọ́ ni Pétérù wá ṣe lórí omi, ẹja ló wá pa kó lè gbọ́ bùkátà ìdílé rẹ̀. Nígbẹ̀yìngbẹ́yín, ó pa dà sí èbúté lọ́wọ́ òfo. Síbẹ̀, wọ́n ṣì ní láti fọ àwọ̀n tí wọ́n lò. Ìyẹn jẹ́ kọ́wọ́ rẹ̀ dí nígbà tí Jésù wá sí etíkun.

Èrò rẹpẹtẹ ló ń rọ́ tẹ̀ lé Jésù, tí wọ́n ń fẹ́ láti gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ni Jésù bá wọ inú ọkọ̀ Pétérù, ó sì ní kó wa ọkọ̀ náà síwájú díẹ̀ kúrò lórí ilẹ̀. Àwọn èèyàn gbọ́ ohùn Jésù ketekete bó ṣe ń kọ́ wọn látorí omi. Bíi ti àwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù láti etíkun náà, Pétérù pàápàá tẹ́tí sílẹ̀ bẹ̀lẹ̀jẹ́. Kò jẹ́ kí àlàyé tí Jésù ń ṣe nípa Ìjọba Ọlọ́run tó jẹ́ lájorí ìwàásù rẹ̀ sú òun. Àǹfààní kékeré kọ́ ló máa jẹ́ láti bá Kristi tan ìhìn rere tó ń fún àwọn èèyàn nírètí yìí káàkiri ilẹ̀ náà! Àmọ́, ṣé Pétérù á lè tẹ̀ lé Jésù láti máa wàásù? Báwo ni wọ́n á ṣe máa gbọ́ bùkátà ara wọn? Ó ṣeé ṣe kí Pétérù tún ronú kan gbogbo òru tó fi ṣe wàhálà láìrí ẹja pa.—Lúùkù 5:1-3.

Nígbà tí Jésù báwọn èèyàn náà sọ̀rọ̀ tán, ó sọ fún Pétérù pé: “Wa ọkọ̀ ojú omi lọ sí ibi tí ó jindò, kí ẹ sì rọ àwọn àwọ̀n yín sísàlẹ̀ fún àkópọ̀ ẹja.” Pétérù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiyèméjì lọ́nà to lágbára. Ó ní: “Olùkọ́ni, ní gbogbo òru ni àwa ṣe làálàá, a kò sì mú nǹkan kan, ṣùgbọ́n nítorí àṣẹ àsọjáde rẹ, ṣe ni èmi yóò rọ àwọn àwọ̀n náà sísàlẹ̀.” Ó ṣe kedere pé Pétérù kò fẹ́ tún ju àwọ̀n rẹ̀ sódò láìrí ẹja kó, pàápàá nírú àkókò tí kò dájú pé àwọn ẹja á máa jẹun lọ́wọ́ yìí! Síbẹ̀, ó ṣe ohun tí Jésù ní kó ṣe, ó sì ṣeé ṣe kó tún pe àwọn tó wà nínú ọkọ̀ kejì tí wọ́n jọ ń pẹja pé kí wọ́n ká lọ.—Lúùkù 5:4, 5.

Ohun tí Pétérù kò retí ṣẹlẹ̀ bó ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í fa àwọ̀n rẹ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un bó ti túbọ̀ ń fi tagbáratagbára fa àwọ̀n náà, kò pẹ́ rárá tó fi rí ọ̀pọ̀ ẹja tó ń ta nínú àwọ̀n náà! Kò mọ ohun tó máa ṣe, ló bá wawọ́ sí àwọn tó wà nínú ọkọ̀ kejì pé kí wọ́n wá ran òun lọ́wọ́. Bí wọ́n ti ń kó àwọn ẹja náà sínú ọkọ̀, wọ́n rí i pé ọkọ̀ kan kò ní lè gbà á. Ẹja náà pọ̀ débi pé ọkọ̀ méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí í rì. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yìí jọ Pétérù lójú gan-an ni. Kì í ṣe ìgbà àkọ́kọ́ nìyí tó máa rí Kristi níbi tó ti lo agbára rẹ̀ o, àmọ́ òun gan-an ni Jésù ṣe iṣẹ́ ìyanu fún lọ́tẹ̀ yìí! Ó yà á lẹ́nu gan-an pé Jésù tún lè ṣiṣẹ́ ìyanu tó máa mú kí ẹja wọnú àwọ̀n! Ẹ̀rù bá bẹ̀rẹ̀ sí í bà á. Ló bá kúnlẹ̀, ó ní: “Kúrò lọ́dọ̀ mi, nítorí pé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa.” Ó ronú pé òun kò lẹ́tọ̀ọ́ láti wà lọ́dọ̀ Ẹni tí Ọlọ́run fún lágbára tó pọ̀ tó báyìí?—Lúùkù 5:6-9.

Jésù fi sùúrù sọ fún un pé: “Dẹ́kun fífòyà. Láti ìsinsìnyí lọ, ìwọ yóò máa mú àwọn ènìyàn láàyè.” (Lúùkù 5:10, 11) Irú àkókò yìí kọ́ ló yẹ kí Pétérù máa ṣiyèméjì tàbí kó máa bẹ̀rù. Kò yẹ kó máa ṣiyèméjì nípa bá ṣe máa rí ẹja pa; kò sì yẹ kó máa bẹ̀rù pé òun kò kúnjú ìwọ̀n tàbí kó máa bẹ̀rù nítorí àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ tó ní. Iṣẹ́ bàǹtàbanta ni Jésù ní láti ṣe, iṣẹ́ yẹn ni iṣẹ́ òjíṣẹ́ tó máa nípa lórí ọjọ́ ọ̀la aráyé. Ọlọ́run tí “yóò dárí jì lọ́nà títóbi” ni Jésù ń jọ́sìn. (Aísáyà 55:7) Jèhófà máa pèsè àwọn ohun tí wọ́n nílò nípa tara àti nípa tẹ̀mí.—Mátíù 6:33.

Bíi ti Jákọ́bù àti Jòhánù, ẹsẹ̀kẹsẹ̀ ni Pétérù tẹ̀ lé Jésù. “Wọ́n dá àwọn ọkọ̀ náà padà wá sí ilẹ̀, wọ́n sì pa ohun gbogbo tì, wọ́n sì tẹ̀ lé e.” (Lúùkù 5:11) Pétérù nígbàgbọ́ nínú Jésù àti Ẹni tó rán an. Ohun tó dáa jù lọ ni Pétérù pinnu láti ṣe yìí. Lónìí, àwọn Kristẹni tí wọ́n borí iyèméjì àti ìbẹ̀rù tí wọ́n ní, tí wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ Ọlọ́run lẹ́kùn-ún rẹ́rẹ́ náà ń fi hàn pé àwọn nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run. Irú ìgbẹ́kẹ̀lé bẹ́ẹ̀ nínú Jèhófà kì í sì í já sófo.—Sáàmù 22:4, 5.

“Èé Ṣe Tí Ìwọ Fi Bẹ̀rẹ̀ Sí Ṣe Iyèméjì?”

Nǹkan bí ọdún méjì lẹ́yìn tí Pétérù ti ń bá Jésù rìn, ó fi gbogbo òru tukọ̀ nínú Òkun Gálílì tó ń ru gùdù tá a sọ nípa rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí. Òótọ́ ni pé a kò lè mọ àwọn nǹkan tí Pétérù ń rò lọ́kàn. Onírúurú nǹkan ló ṣeé ṣe kó wà lọ́kàn rẹ̀. Jésù ti wo ìyá ìyàwó Pétérù sàn. Ó ti wàásù lórí òkè. Ó ti fi hàn léraléra nípasẹ̀ àwọn ohun tó ń kọ́ni àti àwọn iṣẹ́ ìyanu tó ṣe pé òun ni Mèsáyà, Ẹni Tí Jèhófà Yàn. Bọ́jọ́ ti ń gorí ọjọ́, bí Pétérù ṣe máa ń ṣàdédé bẹ̀rù, tá sì máa ṣiyèméjì, ti wá ń dín kù díẹ̀díẹ̀. Jésù tiẹ̀ ti yan Pétérù gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì méjìlá! Síbẹ̀, Pétérù ṣì máa rí i pé òun kò tíì borí ìbẹ̀rù àti iyèméjì tóun máa ń ní.

Ní ìṣọ́ kẹrin òru tàbí lẹ́yìn aago mẹ́ta ìdájí, Pétérù ṣàdédé dáwọ́ ọkọ̀ dúró, ó sì gbójú sókè. Ó rí i pé nǹkan kan ń kọjá lórí omi nínú ẹ̀fúùfù! Ṣé ó lè jẹ́ pé omi tó ń ta sókè látinú ìgbì òkun ni ìmọ́lẹ̀ òṣùpá ń tàn sí? Rárá o, èèyàn ni, torí pé ṣe ló dúró ṣánṣán! Bẹ́ẹ̀ ni, ó dájú pé ọkùnrin kan ni, ó ń rìn lórí òkun! Bí ẹni náà ti ń sún mọ́ wọn, ó dà bíi pé ó fẹ́ gba ẹ̀gbẹ́ wọn kọjá. Ẹ̀rù bà wọ́n gan-an, tórí èrò àwọn ọmọ ẹ̀yìn yìí ni pé ìran abàmì kan ni àwọ́n ń rí. Ẹni náà bá wọn sọ̀rọ̀, ó ní: “Ẹ mọ́kànle, èmi ni; ẹ má bẹ̀rù.” Àṣé Jésù ni!—Mátíù 14:25-28.

Pétérù bá fèsì pé: “Olúwa, bí ìwọ bá ni, pàṣẹ fún mi láti wá bá ọ lórí omi.” Ohun tó kọ́kọ́ ṣe yìí fi hàn pé ó nígboyà. Pétérù ti ṣe tán láti túbọ̀ fìdí ìgbàgbọ́ rẹ̀ múlẹ̀ bí ara rẹ̀ ti ń yá gágá sí iṣẹ́ ìyanu tó ṣàrà ọ̀tọ̀ yìí. Òun náà fẹ́ rìn lórí omi. Ni Jésù bá sọ pé kó máa bọ̀. Pétérù gun etí ọkọ̀, ó sì bẹ́ sórí òkun tó ń ru gùdù náà. Fi ọkàn yàwòrán bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ yìí ṣe máa rí lára Pétérù bó ṣe rí i pé òun kò rì, àmọ́ òun dúró lórí omi. Ó dájú pé ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún un bó ti ń rìn lórí omi lọ sọ́dọ̀ Jésù. Àmọ́ ṣá o, èrò míì ṣàdédé dìde lọ́kàn rẹ̀.—Mátíù 14:29.

Kò yẹ kí Pétérù mọ́kàn kúrò lọ́dọ̀ Jésù. Torí pé Jésù ló ń lo agbára Jèhófà láti jẹ́ kí Pétérù rìn lórí òkun. Ìgbàgbọ́ tí Pétérù ní ló jẹ́ kí Jésù ní kó máa bọ̀. Àmọ́ ọkàn Pétérù kò sí níbẹ̀ mọ́. Bíbélì sọ pé: “Ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà.” Bí Pétérù ṣe ń wo ìgbì òkun tó ń ru sókè nínú afẹ́fẹ́, tó sì ń bì lu ọkọ̀ náà, ẹ̀rù bà á. Ó ṣeé ṣe kó ti máa fọkàn yàwòrán bóun ṣe máa rì sínú adágún yẹn, tóun á sì mumi yó. Bí jìnnìjìnnì ṣe bò ó, bẹ́ẹ̀ ni ìgbàgbọ́ rẹ̀ pòórá. Bí ọkùnrin tí Jésù pè ní Àpáta torí ẹ̀mí tó ní láti dúró digbí ṣe bẹ̀rẹ̀ sí í rì bí òkúta nìyẹn o, ìdí sì ni pé ìgbàgbọ́ rẹ̀ ń ṣe ségesège. Pétérù mọ odò wẹ̀ dáadáa, àmọ́ kò gbára lé ìyẹn rárá. Ńṣe ló pariwo pé: “Olúwa, gbà mí là!” Ni Jésù bá dì í lọ́wọ́ mú, ó sì fà á sókè. Orí omi níbẹ̀ ni wọ́n ṣì wà nígbà tí Jésù tẹ ẹ̀kọ́ pàtàkì yìí mọ́ Pétérù lọ́kàn pé: “Ìwọ tí o ní ìgbàgbọ́ kíkéré, èé ṣe tí ìwọ fi bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iyèméjì?”—Mátíù 14:30, 31.

Ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé, Pétérù “ṣe iyèméjì” bá a mu gan-an ni. Iyèméjì lágbára láti ba ìgbésí ayé ẹni jẹ́. Tá a bá gbà á láyè, ó lè bá ìgbàgbọ́ wa jẹ́, ó sì lè sọ wá di òkú nípa tẹ̀mí. Torí náà, a kò gbọ́dọ̀ gbà á láyè lọ́nàkọnà! Báwo la ṣe máa ṣe é? A kò gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ohunkóhun pín ọkàn wa níyà. Tá a bá ń ronú lórí àwọn ohun tó ń bà wá lẹ́rù, àwọn ohun tó ń múni rẹ̀wẹ̀sì àti àwọn ohun tó ń pín ọkàn wa níyà kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, ṣe ni iyèméjì á túbọ̀ máa lágbára sí i nínú wa. Tá a bá ń jẹ́ kí ọkàn wa máa wà lọ́dọ̀ Jèhófà àti Ọmọ rẹ̀, tá à ń ronú lórí àwọn ohun tí wọ́n ti ṣe, èyí tí wọ́n ń ṣe lọ́wọ́lọ́wọ́ àti èyí tí wọ́n máa ṣe fún àwọn tó nífẹ̀ẹ́ wọn, iyèméjì kò ní lè ba ìgbàgbọ́ wa jẹ́.

Bí Pétérù ṣe tẹ̀ lé Jésù pa dà sínú ọkọ̀, ó rí i pé ìjì tó ń jà náà dáwọ́ dúró. Òkun Gálílì sì wá dákẹ́ rọ́rọ́. Pétérù àti àwọn ọmọ ẹ̀yìn yòókù sọ pé, “Ọmọ Ọlọ́run ni ìwọ jẹ́ ní ti tòótọ́.” (Mátíù 14:33) Ó dájú pé inú Pétérù dùn gan-an sí ohun tí Jésù ṣe yìí, ilẹ̀ sì ti ń mọ́ díẹ̀díẹ̀ lórí adágún náà. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ pé kò yẹ kí ìbẹ̀rù mú kóun máa ṣiyèméjì nípa Jèhófà àti Jésù. Kò sí iyèméjì pé, ọ̀pọ̀ ìyípadà ló ṣì ní láti ṣe kó tó lè di Kristẹni tó dà bí àpáta tí Jésù sọ tẹ́lẹ̀. Àmọ́, ó pinnu pé òun kò ní juwọ́ sílẹ̀, pé òun á sì túbọ̀ máa kẹ́kọ̀ọ́ sí i. Ṣé ìwọ náà ti ṣe irú ìpinnu yẹn? Tó o bá ṣe bẹ́ẹ̀, wàá rí i pé ó yẹ kí èèyàn fara wé àpẹẹrẹ ìgbàgbọ́ Pétérù.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 22, 23]

Jésù kíyè sí pé ọkùnrin apẹja yìí láwọn ànímọ́ tó lè mú kó túbọ̀ ṣe dáadáa

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

“Ẹlẹ́ṣẹ̀ ni mí, Olúwa”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24, 25]

“Ní wíwo ìjì ẹlẹ́fùúùfù náà, ó fòyà”