Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?

Ṣó Yẹ Kí Àwọn Kristẹni Máa Jagun?

“Kí la lè sọ pé ogun jẹ́, ṣé ìwà ọ̀daràn ni àbí ẹ̀ṣẹ̀? Àdìtú lọ̀rọ̀ yìí.” —OLIVER O’DONOVAN, Ọ̀JỌ̀GBỌ́N NÍPA ÌLÀNÀ ÌWÀ HÍHÙ KRISTẸNI

ÌRÚBỌ ni àkọlé tí wọ́n kọ sórí àwòrán kan tí wọ́n gbé síbi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan ìṣẹ̀ǹbáyé tí wọ́n fi jagun sí lórílẹ̀-èdè Kánádà. Ogun Àgbáyé Kìíní ló mú kí wọ́n ya àwòrán yìí, àwọn sójà tó kú sójú ogun, àwọn tó ti ogun dé àti àwọn mọ̀lẹ́bí wọn ló wà nínú àwòrán náà. Wọ́n gbé àwòrán Jésù Kristi tó wà lórí àgbélébùú sókè àwòrán yìí. Ó ya àwọn òǹwòran kan lẹ́nu láti rí i pé wọ́n ya Jésù tó jẹ́ “Ọmọ Aládé Àlááfíà” sẹ́gbẹ̀ẹ́ àwòrán nípa ogun. (Aísáyà 9:6) Àwọn míì sì mọrírì ohun tí àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè wọn ṣe, èrò wọn ni pé Ọlọ́run àti Ọmọ rẹ̀ fẹ́ kí àwọn Kristẹni ja ogun láti dáàbò bo ara wọn àti òmìnira orílẹ̀-èdè wọn.

Àìmọye ọdún ni àwọn aṣáájú ìsìn ti máa ń wàásù pé kò sí ohun tó burú nínú ogun jíjà. Lọ́dún 417 Sànmánì Kristẹni, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan tó ń jẹ́ Augustine kọ̀wé pé: “Ẹ kò gbọ́dọ̀ rò ó rárá pé ẹni tó ń gbé nǹkan ogun kò lè rójú rere Ọlọ́run. . . . Àwọn tó kù ń fàdúrà jagun nítorí ti yín, nígbà tí ẹ̀yin náà ń wọ̀yá ìjà lójú ogun pẹ̀lú àwọn àjèjì nítorí tiwọn.” Ní ọ̀rúndún kẹtàlá, Ọ̀gbẹ́ni Thomas Aquinas ṣàlàyé pé “kò sí ohun tó burú nínú ogun jíjà, ó sì bá òfin mu níwọ̀n ìgbà tó bá ti jẹ́ láti dáàbò bo àwọn mẹ̀kúnnù àti orílẹ̀-èdè lọ́wọ́ àwọn ọ̀tá.”

Kí ni èrò tìẹ? Tí wọ́n bá ní ojú ogun yá torí ìdí kan tó dà bíi pé ó ṣe pàtàkì, bóyá torí àtijà fún òmìnira orílẹ̀-èdè ẹni tàbí torí àwọn kan tí wọ́n ń ni lára, ṣó o rò pé inú Ọlọ́run dùn sí i? Ìlànà wo ni àwọn Kristẹni lè gbé yẹ̀ wò kí wọ́n lè mọ ojú ìwòye Ọlọ́run lórí ọ̀rọ̀ yìí?

Àpẹẹrẹ Jésù Kristi

Ṣó rọrùn láti mọ ojú ìwòye Ọlọ́run lórí àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó bíi ti ogun tí wọ́n máa ń jà lónìí? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi hàn pé òun lóye ìṣòro táwa èèyàn ń kojú, torí náà ó béèrè pé: “‘Ta ni ó ti wá mọ èrò inú Jèhófà, kí ó lè fún un ní ìtọ́ni?’ Ṣùgbọ́n àwa ní èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 2:16) Láti ràn wá lọ́wọ́, Jèhófà Ọlọ́run rán Jésù wá sáyé ká lè tẹ̀ lé àpẹẹrẹ rẹ̀. Àwọn ohun tí Jésù sọ àti àwọn ohun tó ṣe jẹ́ ká mọ èrò Jèhófà àti ohun tó máa ṣe. Torí náà, kí ni Jésù sọ lórí ọ̀rọ̀ ogun jíjà? Ṣó fọwọ́ sí ogun jíjà àbí kò fọwọ́ sí i?

Àwọn míì lè ronú pé ó tó bẹ́ẹ̀ ó jù bẹ́ẹ̀ lọ tí èèyàn bá jà láti gbèjà Jésù Kristi. Ohun tí ọ̀kan lára àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ náà rò nìyẹn. Nígbà tẹ́nì kan dalẹ̀ Jésù tí àwọn jàǹdùkú kan sì kó ohun ìjà wá láti fi àṣẹ ọba mú un láàárín òru, Pétérù ọ̀rẹ́ rẹ̀ “na ọwọ́ rẹ̀, ó sì fa idà rẹ̀ yọ, ó sì ṣá ẹrú àlùfáà àgbà, ó sì gé etí rẹ̀ dànù.” Ṣé ohun tí Pétérù ṣe yìí tọ̀nà? Jésù sọ fún Pétérù pé: “Dá idà rẹ padà sí àyè rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn tí wọ́n bá ń mú idà yóò ṣègbé nípasẹ̀ idà.”—Mátíù 26:47-52.

Ohun tí Jésù ṣe yìí kò yà wá lẹ́nu. Torí pé ní ọdún méjì ṣáájú ìgbà yẹn, ó sọ pé: “Ẹ gbọ́ pé a sọ ọ́ pé, ‘Kí ìwọ nífẹ̀ẹ́ aládùúgbò rẹ, kí o sì kórìíra ọ̀tá rẹ.’ Bí ó ti wù kí ó rí, mo wí fún yín pé: Ẹ máa bá a lọ láti máa nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá yín àti láti máa gbàdúrà fún àwọn tí ń ṣe inúnibíni sí yín; kí ẹ lè fi ara yín hàn ní ọmọ Baba yín tí ń bẹ ní ọ̀run, níwọ̀n bí ó ti ń mú kí oòrùn rẹ̀ ràn sórí àwọn ènìyàn burúkú àti rere, tí ó sì ń mú kí òjò rọ̀ sórí àwọn olódodo àti aláìṣòdodo.” (Mátíù 5:43-45) Ṣó wá bọ́gbọ́n mu láti rò pé Kristẹni kan ṣì lè nífẹ̀ẹ́ àwọn ọ̀tá rẹ̀ kó sì gbàdúrà fún wọn tó bá ń bá wọn ja ogun?

Ìtàn fi hàn pé àwọn Kristẹni ní àwọn ọ̀tá tó pọ̀. Bí àpẹẹrẹ, àwọn ará Róòmù fẹ̀sùn kan Jésù Kristi wọ́n sì pa á. Láìpẹ́ sígbà yẹn, ẹ̀sùn tó la ikú lọ ni wọ́n máa fi kan ẹnikẹ́ni tó bá sọ pé Kristẹni ni òun. Jésù mọ̀ pé ó ṣeé ṣe kí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ mú kí àwọn Kristẹni kan gbé ohun ìjà ogun láti bá ìjọba Róòmù tó ń ni wọ́n lára jà, gẹ́gẹ́ bí àwọn Júù kan ti ṣe. Ìdí nìyẹn tó fi sọ nípa àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Wọn kì í ṣe apá kan ayé, gan-an gẹ́gẹ́ bí èmi kì í ti í ṣe apá kan ayé.” (Jòhánù 17:16) Tó bá dọ̀rọ̀ ìṣèlú, àwọn Kristẹni máa ń yàn láti wà láìdásí tọ̀tún tòsì. Kò sírú àìṣèdájọ́ òdodo tàbí ìhalẹ̀mọ́ni tí wọ́n lè ṣe sí wọn tàbí sí orílẹ̀-èdè tí wọ́n ń gbé tó máa jẹ́ kí wọ́n ja ogun.

Àwọn Alátìlẹyìn Ìjọba Ọlọ́run

Àwọn ojúlówó Kristẹni máa ń ṣe ohun tí Jésù fẹ́, wọn kì í sì í dá sí tọ̀tún tòsì. Kíyè sí ohun tó ṣẹlẹ̀ ní ìlú Íkóníónì, ìlú ìgbàanì kan tó wà ní Éṣíà Kékeré. Bíbélì ròyìn pé: “Nígbà tí ìgbìdánwò lílenípá ṣẹlẹ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn àwọn orílẹ̀-èdè àti àwọn Júù pẹ̀lú àwọn olùṣàkóso wọn, láti hùwà sí [Pọ́ọ̀lù àti Bánábà] lọ́nà àfojúdi àti láti sọ wọ́n ní òkúta, nígbà tí a sọ fún wọn nípa èyí, wọ́n sá lọ sí àwọn ìlú ńlá Likaóníà, Lísírà àti Déébè àti ìgbèríko tí ń bẹ ní àyíká; wọ́n sì ń polongo ìhìn rere níbẹ̀.” (Ìṣe 14:5-7) Kíyè sí pé nígbà táwọn Kristẹni dojú kọ àdánwò tó lágbára gan-an, wọn kò gbé ohun ìjà láti fi gbèjà ara wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò gbẹ̀san. Kàkà bẹ́ẹ̀, wọ́n ń bá a nìṣó láti máa wàásù “ìhìn rere.” Ìhìn rere wo ni wọ́n ní láti wàásù rẹ̀?

Ohun tí Jésù wàásù rẹ̀ ni àwọn Kristẹni náà ń wàásù. Ó ní: “Èmi gbọ́dọ̀ polongo ìhìn rere ìjọba Ọlọ́run.” (Lúùkù 4:43) Jésù àti àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ ṣètìlẹ́yìn fún Ìjọba Ọlọ́run. Kristi kò fìgbà kankan lo àwọn ọmọ ogun orílẹ̀-èdè èyíkéyìí láti gbèjà Ìjọba náà. Ó sọ pé: “Ìjọba mi kì í ṣe apá kan ayé yìí. Bí ìjọba mi bá jẹ́ apá kan ayé yìí, àwọn ẹmẹ̀wà mi ì bá ti jà kí a má bàa fà mí lé àwọn Júù lọ́wọ. Ṣùgbọ́n, gẹ́gẹ́ bí ó ti rí, ìjọba mi kì í ṣe láti orísun yìí.”—Jòhánù 18:36.

Ẹ “Ní Ìfẹ́ Láàárín Ara Yín”

Ọ̀kan lára ohun tí èèyàn lè fi dá ìsìn tòótọ́ mọ̀ ni bí wọ́n kì í ṣeé dá sí tọ̀tún tòsì nígbà ogun. Jésù sọ pé: “Nípa èyí ni gbogbo ènìyàn yóò fi mọ̀ pé ọmọ ẹ̀yìn mi ni yín, bí ẹ bá ní ìfẹ́ láàárín ara yín.” (Jòhánù 13:35) Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn ni inú wọn dùn láti mọ àwùjọ èèyàn tí wọ́n ń fi irú ìfẹ́ bẹ́ẹ̀ hàn, kódà nígbà tí kíkọ̀ láti gbé ohun ìjà ogun mú kí wọ́n fi wọ́n ṣẹlẹ́yà, kí wọ́n jù wọ́n sẹ́wọ̀n tàbí kí wọ́n tiẹ̀ pa wọ́n.

Ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ìṣàkóso Nazi dé nílẹ̀ Yúróòpù, wọ́n fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá [10,000] àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sẹ́wọ̀n, wọ́n sì fi nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta [3,000] sí àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ torí pé wọn kì í dá sí tọ̀tún tòsì nígbà ogun. Láàárín àkókò yẹn kan náà, ó ju ẹgbẹ̀rún mẹ́rin ó lé ọ̀ọ́dúnrún [4,300] Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà tí wọ́n jù sẹ́wọ̀n torí pé wọ́n kọ̀ láti ṣe iṣẹ́ ológun. Kò sí ìkankan nínú àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní orílẹ̀-èdè Jámánì àti Amẹ́ríkà tó gbé ohun ìjà ogun tàbí tó gbéjà ko àwọn Kristẹni bíi tiwọn tàbí àwọn èèyàn míì. Wọn kò lè ṣe bẹ́ẹ̀ kí wọ́n sì tún máa sọ pé àwọ́n nífẹ̀ẹ́ láàárín ara wọn àti pé àwọn nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó kù.

Ọ̀pọ̀ ló gbà pé ogun jíjà ṣe pàtàkì láti dàábò bo ara ẹni. Rò ó wò ná: Bó tiẹ̀ jẹ́ pé wọ́n ṣenúnibíni sí àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní, tí wọn kò sì jà pa dà, síbẹ̀ wọn kò pa run. Ilẹ̀ Ọba Róòmù alágbára nígbà yẹn kò lè pa àwọn Kristẹni run. Bákan náà lóde òní, àwọn Kristẹni tòótọ́ kò pa run, wọ́n sì ń bá a nìṣó láti máa wà láìdá sí tọ̀tún tòsì. Ọlọ́run ni wọ́n gbára lé láti ràn wọ́n lọ́wọ́ dípò kí wọ́n máa gbèjà ara wọn. Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ pé: “Ẹ má ṣe gbẹ̀san ara yín, ẹ̀yin olùfẹ́ ọ̀wọ́n, ṣùgbọ́n ẹ yàgò fún ìrunú; nítorí a ti kọ̀wé rẹ̀ pé: ‘Tèmi ni ẹ̀san; dájúdájú, èmi yóò san ẹ̀san, ni Jèhófà wí.’”—Róòmù 12:19.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 30]

ÀWỌN OGUN TÍ ỌLỌ́RUN FỌWỌ́ SÍ

Ní àwọn àkókò kan, Ọlọ́run fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì ìgbàanì, tó dìídì yàn ní ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún ṣáájú kí ìsìn Kristẹni tó bẹ̀rẹ̀, láṣẹ pé kí wọ́n kó àwọn ọmọ ogun jọ kí wọ́n sì bá àwọn orílẹ̀-èdè kan jà. Ṣáájú kí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì tó wọ ilẹ̀ Kénáánì, ìyẹn ilẹ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún Ábúráhámù, wọ́n gba ìtọ́ni yìí pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ yóò sì jọ̀wọ́ [orílẹ̀-èdè méje] fún ọ, ìwọ yóò sì ṣẹ́gun wọn. Kí o má ṣe kùnà láti yà wọ́n sọ́tọ̀ fún ìparun. Ìwọ kò gbọ́dọ̀ bá wọn dá májẹ̀mú tàbí kí o fi ojú rere kankan hàn sí wọn.” (Diutarónómì 7:1, 2) Torí náà, Jóṣúà tó jẹ́ Ọ̀gágun ní Ísírẹ́lì ṣẹ́gun àwọn orílẹ̀-èdè ọ̀tá yẹn “gan-an gẹ́gẹ́ bí Jèhófà Ọlọ́run Ísírẹ́lì ti pàṣẹ.”—Jóṣúà 10:40.

Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ńṣe ni àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kàn ń fìkanra àti ojúkòkòrò gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tó yí wọn ká ni? Rárá o. Àwọn orílẹ̀-èdè yẹn ti fi ìbọ̀rìṣà, ìtàjẹ̀sílẹ̀ àti ìṣekúṣe tó burú jáì bara wọn jẹ́. Kódà wọ́n máa ń fi àwọn ọmọ wọn rúbọ nínú iná. (Númérì 33:52; Jeremáyà 7:31) Torí pé Ọlọ́run jẹ́ mímọ́, onídàájọ́ òdodo tó sì nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn rẹ̀ ló jẹ́ kó mú gbogbo ìwà àìmọ́ kúrò ní àwọn ilẹ̀ náà. Síbẹ̀, Jèhófà máa ń yẹ ọkàn gbogbo wa wò, kì í pa àwọn tí wọ́n ṣe tán láti kọ ìwà búburú sílẹ̀, kí wọ́n sì sìn ín run, ó dájú pé kò sí ọ̀gágun kankan tó lè ṣe bẹ́ẹ̀ lónìí.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ṣé Jésù fẹ́ kí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jà láti gbèjà òun tàbí àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ Kristẹni?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan nìyí lẹ́yìn tí wọ́n dá wọn sílẹ̀ lọ́dún 1945 ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó wà ní abúlé Buchenwald