Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Ẹja Pípa Lórí Òkun Gálílì

Iṣẹ́ Ẹja Pípa Lórí Òkun Gálílì

Iṣẹ́ Ẹja Pípa Lórí Òkun Gálílì

BÁWO ni ìgbésí ayé ṣe máa ń rí fún àwọn apẹja lórí Òkun Gálílì ní ọ̀rúndún kìíní? Ìdáhùn ìbéèrè yìí máa jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ìtàn inú àwọn ìwé Ìhìn Rere, bí irú èyí tó wà nínú àpilẹ̀kọ tó ṣáájú èyí.

Òkun yìí jẹ́ adágún omi tí kò ní iyọ̀, ó gùn tó kìlómítà mọ́kànlélógún [21], ó sì fẹ̀ tó kìlómítà méjìlá [12] níbùú. Ọjọ́ pẹ́ tí àwọn apẹja ti máa ń pẹja púpọ̀ rẹpẹtẹ nínú adágún yìí. Ẹ̀rí fi hàn pé ọjà tí wọ́n ti ń ta ẹja ló wà ní Ẹnubodè Ẹja nílùú Jerúsálẹ́mù. (Nehemáyà 3:3) Òkun Gálílì wà lára àwọn ibi tí wọ́n ti ń pa àwọn ẹja tí wọ́n ń tà níbẹ̀.

Ìlú tí wọ́n ń pè ní Bẹtisáídà létí Òkun Gálílì ni àpọ́sítélì Pétérù ti wá, ó ṣeé ṣe kí orúkọ ìlú yìí túmọ̀ sí “Ilé Apẹja.” Mágádánì tàbí Mágídálà ni orúkọ ìlú míì létí adágún náà, ibẹ̀ sì ni Jésù mú àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ lọ lẹ́yìn tó rìn lórí omi. (Mátíù 15:39) Òǹkọ̀wé kan sọ pé, orúkọ ìlú yẹn lédè Gíríìkì túmọ̀ sí “Ìlú Tí Wọ́n Ti Ń Ṣe Ẹja fún Jíjẹ.” Àwọn èèyàn mọ ìlú yìí dáadáa torí àwọn ilé iṣẹ́ ẹja tó pọ̀ níbẹ̀, ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń sá àwọn ẹja tí wọ́n bá pa, tí wọ́n á fi iyọ̀ sí i tàbí kí wọ́n fi sínú ọtí kíkan láti fi ṣe ohun jíjẹ tí wọ́n máa ń tọ́jú sínú àwọn ìkòkò oníga méjì. Wọ́n á wá dì í, wọ́n sì lè fi ránṣẹ́ sí gbogbo àgbègbè Ísírẹ́lì àtàwọn ibòmíì.

Nígbà ayé Jésù, pípa ẹja, ṣíṣe é fún jíjẹ àti títà á kì í ṣe iṣẹ́ kékeré nílùú Gálílì. Èyí lè mú kí èèyàn máa ronú pé nǹkan ní láti rọ̀ṣọ̀mù fún ọ̀pọ̀ àwọn tó ń gbé ní àgbègbè náà. Àmọ́ ọ̀rọ̀ kò fi taratara rí bẹ́ẹ̀. Ọ̀mọ̀wé kan sọ pé: “Òwò ẹja pípa kì í ṣe iṣẹ́ tẹ́nì kan kàn lè déédéé bẹ̀rẹ̀ láìkọ́kọ́ gbàṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba gẹ́gẹ́ bí àwọn kan tó ń ka Májẹ̀mú Tuntun lóde òní ti lè máa rò.” Ó wà lára àwọn “òwò tí ìjọba ní àṣẹ lé lórí, èyí sì máa ń ṣàǹfààní fún àwọn ọ̀tọ̀kùlú.”

Hẹ́rọ́dù Áńtípà ni olùṣàkóso àgbègbè Gálílì tàbí ọmọ aládé tí ìjọba Róòmù yàn láti ṣàkóso àdúgbò. Torí náà, òun ló ń ṣàkóso àwọn òpópónà tó wà ní àgbègbè náà, àwọn èbúté àtàwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ bí ẹja, igbó, irè oko àtàwọn ibi ìwakùsà. Láti inú àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ yìí ni Hẹ́rọ́dù ti ń rí owó orí tó pọ̀ jù lọ gbà. A kò mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń gba owó orí nílùú Gálílì ní ọ̀rúndún kìíní. Àmọ́, ó dà bíi pé bí Hẹ́rọ́dù ṣe ń gbowó orí kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí ti àwọn alákòóso ilẹ̀ Gíríìkì tàbí ti ìjọba ilẹ̀ Róòmù ní àwọn ìpínlẹ̀ yòókù ní ìlà oòrùn. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àpò àwọn ọ̀tọ̀kùlú ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú owó tó ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn oníṣòwò tó wà ní àgbègbè yìí àtèyí tí wọ́n ń rí láti inú àwọn nǹkan àmúṣọrọ̀ àgbègbè náà ń lọ dípò ọ̀dọ̀ àwọn gbáàtúù tí wọ́n ń ṣe èyí tó pọ̀ jù nínú iṣẹ́ náà.

Wọ́n Ń Fowó Orí Ni Àwọn Èèyàn Lára

Nígbà tí Jésù wà láyé, àwọn ìdílé ọlọ́ba ló máa ń ni ilẹ̀ tó bá dára jù lọ nílùú Gálílì, Hẹ́rọ́dù Áńtípà sì máa ń pín in láti fi ṣe ẹ̀bùn fún àwọn èèyàn jàǹkàn-jàǹkàn àtàwọn tó bá nífẹ̀ẹ́ sí. Àwọn ará ìlú ló ń forí fá owó tí Hẹ́rọ́dù fi ń gbé ìgbésí ayé gbẹdẹmukẹ, èyí tó fi ń kọ́ àwọn ilé ńláńlá, èyí tó fi ń ṣàkóso lọ́nà tó bùáyà àtàwọn owó tó ń fún àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìlú. Owó orí, àwọn owó tí wọ́n ń gbà ní àwọn òpópónà àtàwọn owó míì tí wọ́n ń gbà lọ́wọ́ àwọn èèyàn ni wọ́n fi ń ni wọ́n lára.

Hẹ́rọ́dù nìkan tún ló jẹ gàba lórí owó tó ń wọlé láti ọ̀dọ̀ àwọn tó ń lo àwọn odò tó wà láàárín ìlú. Torí náà, òwò ẹja pípa di apá kan àwọn òwò aládàáńlá tí Hẹ́rọ́dù tàbí àwọn tó ti pín ilẹ̀ fún gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn ń darí. Ní àwọn àgbègbè tí ọba ń fúnra rẹ̀ darí, àwọn olórí agbowó orí, ìyẹn àwọn ọlọ́rọ̀ tí wọ́n fi owó rẹpẹtẹ ra ẹ̀tọ́ láti máa gbowó orí, ló láṣẹ láti máa ṣàdéhùn òwò ẹja pípá pẹ̀lú àwọn apẹja kí àwọn apẹja bàa lè lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pẹja. Àwọn kan tó ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ sọ pé, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn olórí agbowó orí yìí ni Mátíù ń bá ṣiṣẹ́, gẹ́gẹ́ bí “ẹni tó ń fún àwọn èèyàn lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pẹja lábẹ́ àṣẹ ọba,” torí pé Kápánáúmù, tó jẹ́ ọ̀kan pàtàkì lára àwọn ibi tí wọ́n ti ń pẹja létí Òkun Gálílì, ni ọ́fíìsì tó ti ń gbowó orí wà. a

Ẹ̀rí fi hàn ní ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì pé ẹ̀bùn ni wọ́n fi ń san owó orí nílẹ̀ Palẹ́sínì. Torí náà, nǹkan bí ìdá mẹ́rin nínú mẹ́wàá ẹja tí àwọn ògbóǹkangí apẹja kan bá pa ni wọ́n máa ń san dípò owó kí wọ́n lè lẹ́tọ̀ọ́ láti pẹja. Àwọn ìwé kan tí wọ́n ti kọ nígbà àtijọ́ jẹ́ ká mọ̀ pé ní àwọn àgbègbè kan lábẹ́ ìjọba Róòmù, ìjọba ló ń dá àṣẹ pa lórí òwò ẹja pípa, wọ́n sì ti yan àwọn olùbẹ̀wò tó ń rí sí ọ̀rọ̀ náà. Nílùú Písídíà, àwọn ọlọ́pàá kan wà tó máa ń rí sí i pé kò sí ẹni tó pa ẹja láìgba àṣẹ àti pé àwọn oníṣòwò tàbí àwọn aláròóbọ̀ tó ti gba àṣẹ lọ́dọ̀ ìjọba tí wọ́n sì ń sanwó orí nìkan ni àwọn apẹja ń ta àwọn ẹja wọn fún.

Ẹnì kan tó máa ń ṣàlàyé ọ̀rọ̀ sọ pé, àtúbọ̀tán gbogbo owó orí àtàwọn àbójútó tí ìjọba ń ṣe yìí ni pé, “ọba tàbí àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó ti pín ilẹ̀ fún ló máa ń jèrè rẹpẹtẹ nígbà tí owó tí àwọn apẹja ń rí mú lọ sílé kì í ju táṣẹ́rẹ́ lọ.” Bẹ́ẹ̀ náà sì ni èrè tí àwọn tó ń ṣe àwọn òwò míì ń rí jẹ kì í tó nǹkan torí àwọn owó orí tí wọ́n fi ń ni wọ́n lára. Inú ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sanwó orí kì í sábà dùn sí owó yìí. Ó dájú pé àìṣòótọ́ àti ìwọra àwọn tó ń sọra wọn di ọlọ́rọ̀ nípa gbígba owó gọbọi lọ́wọ́ àwọn gbáàtúù ni kì í jẹ́ kí inú àwọn èèyàn dùn sí àwọn agbowó orí tí àwọn ìwé Ìhìn Rere sọ̀rọ̀ nípa wọn.—Lúùkù 3:13; 19:2, 8.

Àwọn Apẹja Tí Àwọn Ìwé Ìhìn Rere Sọ̀rọ̀ Nípa Wọn

Àwọn ìwé Ìhìn Rere jẹ́ ká mọ̀ pé Símónì Pétérù àti àwọn kan ló jọ dòwò pọ̀ nínú iṣẹ́ ẹja pípa. Àwọn “ẹlẹgbẹ́ [rẹ̀] nínú ọkọ̀ ojú omi kejì” ló wá ran Pétérù lọ́wọ́ láti fa àwọ̀n nígbà tí wọ́n pẹja lọ́nà iṣẹ́ ìyanu. (Lúùkù 5:3-7) Àwọn ọ̀mọ̀wé ṣàlàyé pé, “àwọn apẹja máa ń pawọ́ pọ̀ . . . kí wọ́n lè jọ gba iṣẹ́ ẹja pípa tàbí kí wọ́n lè lẹ́tọ̀ọ́ láti máa pẹja ní àwọn àkókò kan.” Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé báyìí ni àwọn ọmọ Sébédè, Pétérù, Áńdérù àti àwọn tí wọ́n jọ da òwò pọ̀ ṣe máa ń ṣe kí wọ́n lè ní ẹ̀tọ́ láti máa ṣe òwò ẹja pípa.

Ìwé Mímọ́ kò sọ ní pàtó bóyá àwọn apẹja tí wọ́n jẹ́ ará Gálílì yìí ló ni àwọn ọkọ̀ ojú omi àti àwọn irinṣẹ́ tí wọ́n ń lò. Àmọ́ àwọn kan gbà pé àwọn ló ni ín. Kódà, Bíbélì sọ pé Jésù pàápàá wọ ọkọ̀ “tí ó jẹ́ ti Símónì.” (Lúùkù 5:3) Àmọ́, ìwé kan tí wọ́n kọ lórí ọ̀rọ̀ yìí sọ pé, “ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé àwọn ọ̀tọ̀kùlú tó ń gbowó orí wọ̀nyẹn ló ni àwọn ọkọ̀ yìí tí àwọn apẹja sì wá ń pawọ́ pọ̀ láti yá a lò.” Èyí tó wù kó jẹ́, Ìwé Mímọ́ sọ nípa Jákọ́bù àti Jòhánù pé wọ́n ń tún àwọ̀n wọn ṣe. Ó sì ṣeé ṣe kí àwọn apẹja máa dúnàádúrà bí wọ́n á ṣe ta ẹja wọn àti bí wọ́n á ṣe gba àwọn alágbàṣe tí wọ́n bá nílò lójúmọ́.

Torí náà, iṣẹ́ àwọn apẹja nílùú Gálílì ní ọ̀rúndún kìíní pọ̀ ju bó o ṣe lè rò tẹ́lẹ̀ lọ. Ara àwọn òwò aládàáńlá tó máa ń da ọ̀pọ̀ èèyàn pọ̀ ni iṣẹ́ wọn. Tá a bá ń fi ọ̀rọ̀ yìí sí ọkàn, ìyẹn á jẹ́ ká túbọ̀ lóye àwọn ìtàn tó wà nínú àwọn ìwé Ìhìn Rere títí kan àwọn ọ̀rọ̀ Jésù nípa ẹja pípa àti àwọn apẹja. Yàtọ̀ síyẹn, ìsọfúnni yìí tún jẹ́ ká lóye irú ìgbàgbọ́ tí Pétérù, Áńdérù, Jákọ́bù àti Jòhánù ní. Iṣẹ́ ẹja pípa ni wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn. Bó ti wù kí wọ́n ṣe rí já jẹ tó nígbà tí Jésù pè wọ́n, wọ́n fi iṣẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ tó sì ń mówó wọlé fún wọn yìí sílẹ̀ láìjanpata, kí wọ́n lè lọ di “apẹja ènìyàn.”—Mátíù 4:19.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó ṣe kedere pé, àpọ́sítélì Pétérù kó láti Bẹtisáídà lọ sí Kápánáúmù, ibẹ̀ ló ti ń ṣòwò ẹja pípa pẹ̀lú Áńdérù, arákùnrin rẹ̀ àti àwọn ọmọ Sébédè. Jésù pàápàá gbé ní Kápánáúmù fún ìgbà díẹ̀.—Mátíù 4:13-16.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 25]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Adágún Húlà

Bẹtisáídà

Kápánáúmù

Mágádánì

Òkun Gálílì

Jerúsálẹ́mù

Òkun Òkú

[Credit Line]

Todd Bolen/Bible Places.com

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 26]

Todd Bolen/Bible Places.com