Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ǹjẹ́ O Mọ̀?
Ta ni “olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì,” kí sì ni ojúṣe rẹ̀?
“Olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì” wà lára àwọn aṣáájú ẹ̀sìn àwọn Júù tó fàṣẹ ọba mú Pétérù àti Jòhánù nígbà tí wọ́n ń wàásù. (Ìṣe 4:1-3) Bíbélì kò sọ ohunkóhun nípa ojúṣe olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì, àmọ́ àwọn ìwé ìtàn kan jẹ́ ká mọ àwọn nǹkan kan tó fani lọ́kàn mọ́ra nípa wọn.
Nígbà tí Jésù wà láyé, ó jọ pé àlùfáà tó bá jẹ́ igbákejì àlùfáà àgbà ló máa ń wà nípò yìí. Olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì ló máa ń rí sí i pé nǹkan wà létòletò nínú àti láyìíká tẹ́ńpìlì tó wà ní Jerúsálẹ́mù. Ó máa ń bójú tó ìjọsìn nínú tẹ́ńpìlì àtàwọn ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì. Àwọn ẹ̀ṣọ́ tí ipò wọn tẹ̀ lé ti olórí ẹ̀ṣọ́ tẹ́ńpìlì ló ń bójú tó àwọn aṣọ́bodè tó máa ń ṣí ilẹ̀kùn àbáwọlé sí inú gbàgede tẹ́ńpìlì láràárọ̀, tí wọ́n sì máa ń tì í lálaalẹ́, àwọn aṣọ́bodè yìí máa ń rí sí i pé àwọn èèyàn kò wọ àwọn ibi tí kò yẹ, wọ́n sì máa ń ṣọ́ ibi tí wọ́n ń kówó sí nínú tẹ́ńpìlì.
Àwùjọ mẹ́rìnlélógún [24], ni wọ́n pín àwọn àlùfáà àtàwọn ọmọ Léfì tó máa ń ṣiṣẹ́ nínú tẹ́ńpìlì sí, àwùjọ kọ̀ọ̀kan sì máa ń ṣiṣẹ́ fún ọ̀sẹ̀ kọ̀ọ̀kan lẹ́ẹ̀mejì lọ́dún. Ó ṣeé ṣe kí àwùjọ kọ̀ọ̀kan ní olórí ẹ̀ṣọ́ tiẹ̀.—1 Kíróníkà 24:1-18.
Àwọn olórí ẹ̀ṣọ́ yìí jẹ́ àwọn ọkùnrin tí wọ́n láṣẹ. Wọ́n wà lára àwọn tí Bíbélì ròyìn pẹ̀lú àwọn olórí àlùfáà pé wọ́n gbìmọ̀ pọ̀ láti pa Jésù, wọ́n sì tún rán àwọn èèyàn láti fàṣẹ ọba mú Jésù.—Lúùkù 22:4, 52.
Ìwé Mátíù 3:4 sọ pé “eéṣú àti oyin ìgàn” ni Jòhánù ń jẹ. Ṣé eéṣú wà lára àwọn oúnjẹ tí wọ́n ń jẹ nígbà yẹn?
Àwọn kan ti sọ pé bóyá ni Jòhánù máa ń jẹ kòkòrò, wọ́n ní èso igi locust, àwọn èso inú igbó tàbí oríṣi ẹja kan ni Mátíù ní lọ́kàn. Àmọ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tí Mátíù lò ni wọ́n máa ń lò fún oríṣi àwọn tata kan táwọn èèyàn wá mọ̀ lónìí sí Acrididae. Oríṣi àwọn eéṣú tàbí tata tó wọ́pọ̀ ní Ísírẹ́lì ni àwọn eéṣú tó máa ń wà nínú aṣálẹ̀, wọ́n sábà máa ń pọ̀ rẹpẹtẹ, wọ́n sì máa ń ba irè oko jẹ́.—Jóẹ́lì 1:4, 7; Náhúmù 3:15.
Oúnjẹ aládùn ni àwọn tó gbé láyé nígbà àtijọ́ ka eéṣú sí, irú bí àwọn ará Asíríà àtàwọn ará Etiópíà, kódà àwọn Júù tí wọ́n jẹ́ Bedouin àtàwọn ará Yemen ṣì ń jẹ ẹ́ títí dòní olónìí. Nílẹ̀ Ísírẹ́lì, wọ́n gbà pé oúnjẹ àwọn tálákà ni eéṣú. Lẹ́yìn tí wọ́n bá ti já orí, ẹsẹ̀ àti abẹ́nú kúrò lára àwọn eéṣú náà, wọ́n á jẹ igbáàyà rẹ̀ ní tútù tàbí kí wọ́n yan án, wọ́n sì lè sá a gbẹ nínú oòrùn kí wọ́n tó jẹ ẹ́. Nígbà míì, wọ́n máa ń fi iyọ̀ sí i tàbí kí wọ́n rẹ ẹ́ sínú ọtí kíkan tàbí oyin. Òpìtàn Henri Daniel-Rops sọ pé àwọn eéṣú yìí máa ń dà bí edé lẹ́nu.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé inú aginjù ni Jòhánù ti wàásù, ó ṣeé ṣe kó rọrùn fún un láti máa rí eéṣú jẹ. (Máàkù 1:4) Torí pé èròjà protein tó wà lára eéṣú tó ìdá mẹ́ta nínú mẹ́rin, oúnjẹ aṣaralóore gbáà ni eéṣú tí wọ́n rẹ sínú oyin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ìránṣẹ́ tí wọ́n gbé eéṣú àti pómégíránétì dání nílẹ̀ Asíríà
[Credit Line]
Láti inú ìwé Discoveries Among the Ruins of Nineveh and Babylon (1853)