Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Jèhófà Fún Wa Lómìnira Láti Yan Ohun Tó Wù Wá

Jèhófà Fún Wa Lómìnira Láti Yan Ohun Tó Wù Wá

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Jèhófà Fún Wa Lómìnira Láti Yan Ohun Tó Wù Wá

Diutarónómì 30:11-20

“MO SÁBÀ máa ń ní ìbẹ̀rù tí kò tọ́ pé mo máa ṣe ohun tí Jèhófà kò fẹ́.” Ohun tí obìnrin kan tó jẹ́ Kristẹni sọ nìyẹn, èrò rẹ̀ ni pé ohun tí ojú òun rí nígbà tóun wà ní ọmọdé kò lè jẹ́ kóun ṣàṣeyọrí. Ṣé òótọ́ nìyẹn? Ṣé bí wọ́n ṣe tọ́ wa dàgbà lè nípa lórí ọjọ́ ọ̀la wa? Rárá o. Jèhófà Ọlọ́run ti fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá, torí náà, a lè ṣèpinnu lórí bá a ṣe fẹ́ gbé ìgbésí ayé wa. Jèhófà fẹ́ ká ṣe àwọn ìpinnu tó tọ́, Bíbélì Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sì sọ bá a ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀. Jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ohun tí Mósè sọ nínú ìwé Diutarónómì orí 30.

Ṣé ó ṣòro láti mọ ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa àti bá a ṣe máa ṣe é? a Mósè sọ pé: “Àwọn àṣẹ yìí tí mo ń pa fún ọ lónìí kò ṣòro rárá fún ọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí ní ibi jíjìnnàréré.” (Ẹsẹ 11) Jèhófà kò béèrè ohun tí a kò lè ṣe lọ́wọ́ wa. A lè ṣe àwọn ohun tó ń béèrè lọ́wọ́ wa torí pé wọn kò kọjá agbára wa. A sì lè mọ àwọn nǹkan náà. A kò nílò láti “gòkè re ọ̀run” tàbí rìnrìn àjò lọ “sí ìhà kejì òkun” ká tó lè kọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ń béèrè lọ́wọ́ wa. (Ẹsẹ 12 àti 13) Kedere ni Bíbélì sọ bó ṣe yẹ ká gbé ìgbésí ayé wa.—Míkà 6:8.

Àmọ́ ṣá o, Jèhófà kì í fipá mú wa pé ká ṣègbọràn sí òun. Mósè sọ pé: “Wò ó, mo fi ìyè àti ire, àti ikú àti ibi, sí iwájú rẹ lónìí.” (Ẹsẹ 15) A ní òmìnira láti yan ìyè tàbí ikú, a sì lè yan ire tàbí ibi. A lè yàn láti máa jọ́sìn Ọlọ́run ká sì máa ṣègbọràn sí i ká lè tipa bẹ́ẹ̀ rí ìbùkún rẹ̀ gbà tàbí ká ṣàìgbọràn sí i, ká sì jìyà àwọn àbájáde rẹ̀. Èyí tó wù kó jẹ́, àwa la máa pinnu.—Ẹsẹ 16 sí 18; Gálátíà 6:7, 8.

Ṣé ohun tá a bá yàn kan Jèhófà? Bẹ́ẹ̀ ni! Ọlọ́run fi ẹ̀mí mímọ́ darí Mósè láti sọ pé: “Yan ìyè.” (Ẹsẹ 19) Báwo la ṣe máa yan ìyè? Mósè ṣàlàyé pé: “Nípa nínífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ, nípa fífetí sí ohùn rẹ̀ àti nípa fífà mọ́ ọn.” (Ẹsẹ 20) Tá a bá nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, kò ní nira fún wa láti máa fi tọkàntọkàn ṣègbọràn sí i, a kò sì ní jẹ́ kí ohunkóhun yà wá kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀. Èyí ló máa túmọ̀ sí pé a yan ìyè, ìyẹn ọ̀nà ìgbésí ayé tó dáa jù lọ nísinsìnyí, èyí tó máa jẹ́ ká láǹfààní láti gbádùn ìyè ayérayé nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó ń bọ̀.—2 Pétérù 3:11-13; 1 Jòhánù 5:3.

Àwọn ọ̀rọ̀ tí Mósè sọ yìí jẹ́ kí òtítọ́ kan dá wa lójú. Ìyẹn ni pé, ohun yòówù kí ojú rẹ ti rí nínú ayé oníwà ipá yìí, má ronú pé kò sọ́nà àbáyọ tàbí pé o kò lè ṣàṣeyọrí. Jèhófà ti fún wa ní òmìnira láti yan ohun tó wù wá. Torí náà, o lè yàn láti nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, láti ṣègbọràn sí i àti láti jẹ́ adúróṣinṣin. Tó o bá ṣe irú ìpinnu yìí, Jèhófà máa bù kún ìsapá rẹ.

Ìtùnú ni òótọ́ ọ̀rọ̀ yìí jẹ́ fún obìnrin tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí nígbà tó mọ̀ pé a ní òmìnira láti pinnu pé a máa sin Jèhófà, a sì máa nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “Mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an. Àmọ́, nígbà míì mo máa ń gbàgbé pé, ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé mo nífẹ̀ẹ́ Jèhófà. Torí náà, mo jẹ́ olóòótọ́ sí i.” Ìwọ náà lè ṣe bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Jèhófà.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo àpilẹ̀kọ tá a pe àkòrí rẹ̀ ní “Sún Mọ́ Ọlọ́run—Kí Ni Jèhófà Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?” nínú Ilé Ìṣọ́ October 1, 2009.