Ó Fẹ́ Ká Ṣàṣeyọrí
Sún Mọ́ Ọlọ́run
Ó Fẹ́ Ká Ṣàṣeyọrí
ÀWỌN òbí tó nífẹ̀ẹ́ àwọn ọmọ wọn máa ń fẹ́ kí wọ́n ṣàṣeyọrí, kí ìgbésí ayé wọn nítumọ̀, kí wọ́n sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Bákan náà, Jèhófà Baba wa ọ̀run fẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ tó wà lórí ilẹ̀ ayé ṣàṣeyọrí. Ó jẹ́ ká mọ bá a ṣe lè ṣàṣeyọrí torí ìfẹ́ àtọkànwá tó ní sí wa. Bí àpẹẹrẹ, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ tó sọ fún Jóṣúà gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Jóṣúà 1:6-9.
Fojú inú wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe rí. Lẹ́yìn ikú Mósè, Jóṣúà ni aṣíwájú tuntun fún ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ Ísírẹ́lì. Àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ń gbára dì láti wọ ilẹ̀ tí Ọlọ́run ṣèlérí fún àwọn baba ńlá wọn. Ọlọ́run fún Jóṣúà ní ìmọ̀ràn mélòó kan. Èyí tó jẹ́ pé tó bá fi sílò, ó máa ràn án lọ́wọ́ láti ṣàṣeyọrí. Àmọ́ ṣá o, kì í ṣe àǹfààní Jóṣúà nìkan ni ìmọ̀ràn yìí wà fún. Àwa náà lè ṣàṣeyọrí tá a bá fi sílò.—Róòmù 15:4.
Ẹ̀ẹ̀mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni Jèhófà sọ fún Jóṣúà pé kó jẹ́ onígboyà àti alágbára. (Ẹsẹ 6, 7, 9) Ó ṣe kedere pé, Jóṣúà nílò ìgboyà àti agbára kó tó lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì dé Ilẹ̀ Ìlérí. Báwo ló ṣe máa wá ṣe é tó fi máa jẹ́ onígboyà àti alágbára?
Jóṣúà lè rí ìgboyà àti agbára látinú ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí tó wà lákọọ́lẹ̀. Jèhófà sọ pé: “Kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo òfin tí Mósè ìránṣẹ́ mi pa láṣẹ fún ọ.” (Ẹsẹ 7) Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwé Bíbélì bíi mélòó kan ni Jóṣúà ní lọ́wọ́ nígbà yẹn. a Àmọ́, wíwulẹ̀ ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ́wọ́ kó túmọ̀ sí pé èèyàn á ṣàṣeyọrí. Jóṣúà ní láti ṣe nǹkan méjì kó tó lè jàǹfààní látinú rẹ̀.
Àkọ́kọ́ ni pé, Jóṣúà ní láti máa fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún inú ọkàn rẹ̀ déédéé. Jèhófà sọ pé: “Kí o sì máa fi ohùn jẹ́ẹ́jẹ́ẹ́ kà láti inú rẹ̀ ní ọ̀sán àti ní òru.” (Ẹsẹ 8) Ìwé kan tá a ṣèwádìí nínú rẹ̀ sọ pé: “Ọlọ́run pàṣẹ fún Jóṣúà pé kó máa rántí Òfin òun nípa fífi ‘ohùn jẹ́jẹ́’ kà á, kó máa ‘ronú lé e lórí,’ kó sì máa ‘yẹ̀ ẹ́ wò tìṣọ́ratìṣọ́ra.’” Kíkà àti ríronú lórí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lójoojúmọ́ máa ran Jóṣúà lọ́wọ́ láti bójú tó ohun tó wà níwájú rẹ̀.
Ìkejì ni pé, Jóṣúà ní láti máa fi ohun tó ń kọ́ nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò. Jèhófà sọ fún un pé: “Kíyè sára láti máa ṣe gẹ́gẹ́ bí gbogbo ohun tí a kọ sínú rẹ̀; nítorí nígbà náà ni ìwọ yóò mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere.” (Ẹsẹ 8) Pípa òfin Ọlọ́run mọ́ ló máa jẹ́ kí Jóṣúà ṣàṣeyọrí. Ó dájú pé Ọlọ́run kò jẹ́ kó Jóṣúà ṣìnà. Torí pé rere ni àwọn ìlànà Ọlọ́run máa ń yọrí sí ní gbogbo ìgbà.—Aísáyà 55:10, 11.
Jóṣúà fi ìmọ̀ràn tí Jèhófà fún un sílò. Àbájáde rẹ̀ sì ni pé, ó gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ tó sì tẹ́rùn gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà olóòótọ́.—Jóṣúà 23:14; 24:15.
Ṣé o fẹ́ gbé ìgbésí ayé tó nítumọ̀ bíi ti Jóṣúà? Jèhófà fẹ́ kó o ṣàṣeyọrí. Àmọ́, kí èèyàn kàn ní Bíbélì Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run nìkan kò tó. Kristẹni kan tó ti ń fi òótọ́ ọkàn sin Ọlọ́run láti ọjọ́ tó ti pẹ́ fún wa ní àbá yìí pé: “Ka Bíbélì, kó o sì fi àwọn nǹkan tó wà níbẹ̀ sọ́kàn.” Tó o bá ń fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kún inú ọkàn rẹ déédéé, tó o sì ń fi àwọn nǹkan tó ò ń kọ́ sílò, wàá “mú kí ọ̀nà rẹ yọrí sí rere” bíi ti Jóṣúà.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Ó ṣeé ṣe kí ìwé márùn-ún tí Mósè kọ (Jẹ́nẹ́sísì, Ẹ́kísódù, Léfítíkù, Númérì àti Diutarónómì), ìwé Jóòbù àti Sáàmù kan tàbí méjì wà nínú àwọn ìwé Bíbélì tí Jóṣúà ní lọ́wọ́.