Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà fún Wa?
Báwo La Ṣe Mọ̀ Pé Lóòótọ́ Ni Ọlọ́run Bìkítà fún Wa?
TÍ ỌLỌ́RUN bá nífẹ̀ẹ́ wa, kí nìdí tí ìjìyà fi pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Láti ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún sẹ́yìn ni ìbéèrè pàtàkì yìí ti ń jà gùdù lọ́kàn àwọn èèyàn. Ó ṣeé ṣe kó o gbà pé tó o bá nífẹ̀ẹ́ ẹnì kan, o kò ní fẹ́ kí onítọ̀hún jìyà, tó bá sì wà nínú ìṣòro, wàá gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́. Ọ̀pọ̀ gbà pé tọ́rọ̀ bá rí báyìí, ìyà tó pọ̀ nínú ayé fi hàn pé Ọlọ́run kò bìkítà nípa wa. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì pé ká kọ́kọ́ ṣàyẹ̀wò àwọn ẹ̀rí tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa, tó sì jẹ́ ká mọ̀ pé ó bìkítà nípa wa.
Ìṣẹ̀dá Ọlọ́run Fi Hàn Pé Ó Nífẹ̀ẹ́ Wa
Jèhófà Ọlọ́run ni “Ẹni tí ó ṣe ọ̀run àti ilẹ̀ ayé àti òkun àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn.” (Ìṣe 4:24) Bá a ṣe ń ronú lórí àwọn ohun tí Jèhófà ti dá, ó dájú pé a gbọ́dọ̀ gbà pé ó bìkítà nípa wa. Bí àpẹẹrẹ, ronú lórí àwọn nǹkan tó máa ń múnú rẹ dùn, tó sì máa ń tù ọ́ lára. Ṣó o fẹ́ràn oúnjẹ aládùn? Ó ṣeé ṣe kí Jèhófà wulẹ̀ pèsè oríṣi oúnjẹ kan fún wa láti gbé ìwàláàyè wa ró. Àmọ́ kàkà bẹ́ẹ̀, ó pèsè oríṣiríṣi oúnjẹ tó máa dùn mọ́ wa lẹ́nu. Bákan náà, Jèhófà ti fi oríṣiríṣi igi ṣe ilẹ̀ ayé lọ́ṣọ̀ọ́, àwọn òdòdó lónírúurú àti ojú ilẹ̀ tó fani mọ́ra tó máa jẹ́ kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ wa, kí ilẹ̀ ayé sì dùn-ún gbé.
Tún wo ọ̀nà tí Ọlọ́run gbà dá wa. Bá a ṣe lè dẹ́rìn-ín pani, bá a ṣe mọ adùn orin àti ọgbọ́n tá a ní láti mọyì ohun tó lẹ́wà, àwọn nǹkan yìí kì í ṣe dandan kí ìwàláàyè wa tó lè máa wà nìṣó, wọ́n wulẹ̀ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run láti jẹ́ kí ìgbésí ayé gbádùn mọ́ wa. Tún ronú lórí àjọṣe tó o ní pẹ̀lú àwọn èèyàn. Ta ni inú rẹ̀ kì í dùn láti wà láàárín àwọn ọ̀rẹ́ gidi tàbí kó gbádùn gbígbá ẹni tó nífẹ̀ẹ́ gan-an mọ́ra? Kódà ti pé a lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa! Níwọ̀n bí Ọlọ́run ti dá wa lọ́nà tá a fi lè nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn, á jẹ́ pé ànímọ́ yẹn ní láti jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ Ọlọ́run nìyẹn.
Bíbélì Fi Dá Wa Lójú Pé Ọlọ́run Nífẹ̀ẹ́ Wa
Bíbélì sọ fún wa pé Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́. (1 Jòhánù 4:8) Yàtọ̀ sí pé àwọn ohun tó dá jẹ́ ká mọ̀ pé ó nífẹ̀ẹ́ wa, a tún rí ẹ̀rí rẹ̀ nínú Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìyẹn Bíbélì. Bí àpẹẹrẹ, Bíbélì fún wa láwọn ìlànà tó jẹ́ pé tá a bá tẹ̀ lé e a máa ní ìlera tó pé, ó tún fún wa níṣìírí láti máa ṣe ohun gbogbo níwọ̀ntúnwọ̀nsì, ó sì kìlọ̀ lòdì sí ọtí àmupara àti àjẹkì.—1 Kọ́ríńtì 6:9, 10.
Bíbélì tún fún wa nímọ̀ràn ọlọgbọ́n lórí bá a ṣe lè máa wà ní àlàáfíà pẹ̀lú àwọn èèyàn, ó rọ̀ wá láti nífẹ̀ẹ́ wọn, ká máa bọ̀wọ̀ fún wọn, ká máa buyì fún wọn, ká sì máa fi inú rere hàn sí wọn. (Mátíù 7:12) Ó ní ká ṣọ́ra fún àwọn ìwà tó lè fa ìjìyà fún àwọn ẹlòmíì, irú bí ọ̀kánjúwà, òfófó, ìlara, àgbèrè àti ìpànìyàn. Tí gbogbo èèyàn bá gbìyànjú láti fi àwọn ìmọ̀ràn àtàtà tó wà nínú Ìwé Mímọ́ sílò, ó dájú pé àwọn ohun tó ń fa ìjìyà máa dín kù gan-an kárí ayé.
Ẹ̀rí tó lágbára jù lọ tó fi hàn pé Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ wa ni bó ṣe fi Jésù Ọmọ rẹ̀ ṣe ìràpadà fún aráyé. Ìwé Jòhánù 3:16 sọ pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.” Torí náà, Jèhófà ti ṣètò láti mú ikú àti onírúurú ìjìyà kúrò pátápátá.—1 Jòhánù 3:8.
A ti wá rí i kedere pé ẹ̀rí pọ̀ jaburata tó fi hàn pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ wa. Nígbà náà, ó bọ́gbọ́n mu láti gbà pé inú rẹ̀ kò dùn bó ṣe rí wa tá à ń jìyà. Ó máa ṣe ohun tó máa jẹ́ kí ìjìyà dópin. Kò yẹ ká máa méfòó lórí ọ̀rọ̀ náà, torí Bíbélì sọ fún wa ní pàtó bí Ọlọ́run ṣe máa mú ìjìyà wá sópin.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 4]
Ti pé a lè nífẹ̀ẹ́ jẹ́ ẹ̀bùn láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run tó nífẹ̀ẹ́ wa