Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ní Àwọn Ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba”

“Ní Àwọn Ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba”

“Ní Àwọn Ọjọ́ Hẹ́rọ́dù Ọba”

BÍ HẸ́RỌ́DÙ Ńlá tó jẹ́ ọba Jùdíà ṣe ń wá gbogbo ọ̀nà láti pa Jésù, ó ní kí wọ́n lọ pa gbogbo ọmọkùnrin kéékèèké tó wà ní Bẹ́tílẹ́hẹ́mù. Ìtàn jẹ́ ká mọ oríṣiríṣi nǹkan tó ṣẹlẹ̀ “ní àwọn ọjọ́ Hẹ́rọ́dù ọba,” àwọn nǹkan tó ṣẹlẹ̀ náà máa jẹ́ ká lóye ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Mátíù 2:1-16.

Kí nìdí tí Hẹ́rọ́dù fi fẹ́ pa Jésù? Kí sì nìdí tó fi jẹ́ pé nígbà tí wọ́n bí Jésù, àwọn Júù ní ọba, àmọ́ nígbà tí Jésù kú, Pọ́ńtù Pílátù tó jẹ́ ará Róòmù ló ń ṣàkóso wọn? Ká lè lóye tó kún rẹ́rẹ́ nípa nǹkan tí Hẹ́rọ́dù ṣe nínú àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ nínú ìtàn, ká sì lè lóye ìdí tí Hẹ́rọ́dù fi ṣe pàtàkì fún àwọn tó ń ka Bíbélì, ó yẹ ká pa dà sẹ́yìn sí ọ̀pọ̀ ọdún ṣáájú kí wọ́n tó bí Jésù.

Bí Wọ́n Ṣe Ń Du Ìjọba Jùdíà

Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ará Síríà ló ṣàkóso Jùdíà ní apá àkọ́kọ́ ọ̀rúndún kejì ṣáájú Sànmánì Kristẹni, òun sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn mẹ́rin tó jọba lórí ilẹ̀ ọba Alẹkisáńdà Ńlá lẹ́yìn tí Alẹkisáńdà kú. Àmọ́, nígbà tí Sẹ̀lẹ́úkọ́sì ọba fẹ́ láti fi òrìṣà Súúsì rọ́pò ìjọsìn Jèhófà nínú tẹ́ńpìlì nílùú Jerúsálẹ́mù ní nǹkan bí ọdún 168 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ìdílé Mákábì kó àwọn Júù sòdí láti gbéjà kò ó. Àwọn Mákábì tàbí Hasmonean ṣàkóso Jùdíà láti ọdún 142 sí 63 ṣáájú Sànmánì Kristẹni.

Ní ọdún 66 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ọmọ ọba Hasmonean méjì, ìyẹn Hyrcanus Kejì àti Àrísítóbúlù tó jẹ́ àbúrò rẹ̀ bá ara wọn du oyè. Bí ogun abẹ́lé ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn, làwọn méjèèjì bá lọ fẹjọ́ sun Pọ́ńpè, ìyẹn ọ̀gágun Róòmù kan tó wà ní ìlú Síríà nígbà yẹn. Ni Pọ́ńpè bá kúkú lo àǹfààní yìí láti dá sí ọ̀rọ̀ ìjọba wọn.

Ní ti àwọn ará Róòmù, wọ́n ti ń lo agbára wọn lórí àwọn to wà ní ìlà oòrùn, nígbà tó sì fi máa di àkókò tá à ń wí yìí wọ́n ti ń ṣàkóso èyí tó pọ̀ jù ní ilẹ̀ Éṣíà Kékeré. Àmọ́ torí pé àṣẹ àwọn ọba tó jẹ tẹ̀ léra ní ilẹ̀ Síríà kò múlẹ̀ dáadáa, àgbègbè náà di rúdurùdu, èyí sì ṣe ìdílọ́wọ́ fún àlàáfíà táwọn ará Róòmù fẹ́ kó máa wà ní àgbègbè Ìlà Oòrùn. Torí náà, Pọ́ńpè bẹ̀rẹ̀ sí í ṣàkóso ilẹ̀ Síríà.

Ohun tí Pọ́ńpè sì fẹ́ ṣe láti yanjú ìṣòro tó wà nínú ìdílé Hasmonean ni láti gbè sẹ́yìn Hyrcanus, nígbà tó di ọdún 63 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, àwọn ará Róòmù ya wọ ìlú Jerúsálẹ́mù wọ́n sì fi Hyrcanus sórí oyè. Àmọ́, wọ́n kàn fi Hyrcanus dí gẹrẹwu lásán ni. Àwọn ará Róòmù ti wá tọwọ́ bọ ọ̀rọ̀ ìjọba wọn, wọn kò sì ṣe tán láti jáwọ́. Hyrcanus wá di baálẹ̀ lábẹ́ ìjọba Róòmù, ìyẹn ni pé ọlá Róòmù ló fi ń ṣàkóso, ìfẹ́ inú wọn ló gbọ́dọ̀ máa ṣe, àwọn ló sì gbọ́dọ̀ máa tì í lẹ́yìn tó bá fẹ́ máa bá ìṣàkóso rẹ̀ lọ. Ó lè fúnra rẹ̀ bójú tó ọ̀ràn orílẹ̀-èdè rẹ̀ bó ṣe wù ú, àmọ́ tó bá ti kan orílẹ̀-èdè míì, ó gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé ìlànà ìjọba Róòmù.

Bí Hẹ́rọ́dù Ṣe Gorí Oyè

Àṣẹ Hyrcanus kò múlẹ̀. Àmọ́ Antipater tó jẹ́ ará Ídúmíà tó sì tún jẹ́ bàbá Hẹ́rọ́dù Ńlá ń ràn án lọ́wọ́. Antipater ni baba ìsàlẹ̀ fún ìjọba rẹ̀. Kò jẹ́ kí àwọn Júù tó ń ta ko ìjọba náà rọ́wọ́ mú, ní kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ó bẹ̀rẹ̀ sí í darí Jùdíà. Ó ran Júlíọ́sì Késárì lọ́wọ́ láti ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ nílẹ̀ Íjíbítì, ìyẹn sì jẹ́ káwọn Róòmù dá Antipater lọ́lá nípa sísọ ọ́ di aṣojú wọn, táá máa jíṣẹ́ ní tààràtà fún wọn. Antipater sì yan ọmọkùnrin rẹ̀ Phasael pé kó máa ṣe gómìnà ìlú Jerúsálẹ́mù àti Hẹ́rọ́dù tóun náà jẹ́ ọmọkùnrin rẹ̀ láti máa ṣe gómìnà ilẹ̀ Gálílì.

Antipater sọ fún àwọn ọmọkùnrin rẹ̀ pé kò sí ohun táwọn lè dá ṣe táwọn kò bá fi ti ìjọba Róòmù ṣe. Hẹ́rọ́dù kò gbàgbé ọ̀rọ̀ yẹn rárá. Ní gbogbo ìgbà tó fi jẹ́ gómìnà, kò jẹ́ kí ohun táwọn Júù, tó ń ṣàkóso lé lórí, ń fẹ́ pa tàwọn Róòmù tó fi í sórí oyè lára. Èyí sì rọrùn fún un torí ó mọ bí wọ́n ṣe ń ṣètò nǹkan àti pé ọ̀gágun ni. Bí wọ́n ṣe fi jẹ gómìnà báyìí ni Hẹ́rọ́dù tó jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n ti ń pa àwọn ògbójú olè tó wà lágbègbè rẹ̀ dà nù, èyí jẹ́ kó tètè di ẹni ńlá lójú àwọn Júù àtàwọn Róòmù.

Lẹ́yìn táwọn ọ̀tá fún Antipater ní májèlé jẹ ní ọdún 43 ṣáájú Sànmánì Kristẹni, Hẹ́rọ́dù di ẹni tó lágbára jù lọ ní Jùdíà. Síbẹ̀, ó ṣì ní àwọn ọ̀tá. Àwọn sàràkí-sàràkí ìlú Jerúsálẹ́mù fẹ̀sùn kàn án pé ńṣe ló fèrú gba ipò, wọ́n sì rọ ìjọba Róòmù láti rọ̀ ọ́ lóyè. Àmọ́ pàbó ni èrò wọn já sí. Àwọn ará Róòmù kò gbàgbé ohun tí Antipater ṣe fún wọn, wọ́n sì mọyì bí ọmọ rẹ̀ náà ṣe jẹ́ akíkanjú.

Wọ́n Fi Jẹ Ọba Jùdíà

Bí Pọ́ńpè ṣe yanjú wàhálà tó dìde nínú ìdílé Hasmonean ní nǹkan bí ogún ọdún sẹ́yìn múnú bí ọ̀pọ̀ èèyàn. Àwọn apá kejì tí kò lè gorí oyè nígbà yẹn gbìyànjú lọ́pọ̀ ìgbà láti já ìjọba gbà, nígbà tó sì di ọdún 40 ṣáájú Sànmánì Kristẹni wọ́n ṣàṣeyọrí nípasẹ̀ ìrànlọ́wọ́ àwọn ará Pátíà tí wọ́n jẹ́ ọ̀tá àwọn ará Róòmù. Wọ́n lo àǹfààní rúkèrúdò tí ogun abẹ́lé dá sílẹ̀ nílẹ̀ Róòmù láti ya bo ilẹ̀ Síríà, wọ́n lé Hyrcanus dà nù kúrò lórí oyè, wọ́n sì fi ọ̀kan lára ìdílé Hasmonean tó jẹ́ ọ̀tá àwọn Róòmù sórí oyè.

Hẹ́rọ́dù sá lọ sí Róòmù, wọ́n sì gbà á tọwọ́ tẹsẹ̀. Àwọn ará Róòmù fẹ́ kí àwọn ará Pátíà káńgárá wọn kúrò ní Jùdíà, kí wọ́n sì dá ìjọba àti ẹni tí àwọn fọwọ́ sí láti jọba pa dà sórí oyè. Wọ́n nílò ẹni tó ṣeé fọkàn tán tó máa ràn wọ́n lọ́wọ́, wọ́n sì rí i pé Hẹ́rọ́dù tó gbangba sùn lọ́yẹ́. Bí àwọn Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin ṣe fi Hẹ́rọ́dù jẹ ọba Jùdíà nìyẹn. Lára ọ̀pọ̀ nǹkan tí Hẹ́rọ́dù ní láti ṣe kó bàa lè máa wà lórí oyè nìṣó ni bó ṣe ṣáájú àwọn kan láti Ilé Ìgbìmọ̀ Aṣòfin lọ sí tẹ́ńpìlì Júpítà, ibẹ̀ ló sì ti rúbọ sí àwọn ọlọ́run kèfèrí.

Pẹ̀lú ìtìlẹ́yìn ọ̀kẹ́ àìmọye àwọn ọmọ ogun Róòmù, Hẹ́rọ́dù ṣẹ́gun àwọn ọ̀tá rẹ̀ nílẹ̀ Jùdíà, ó sì gba ìjọba rẹ̀ pa dà. Ọ̀nà tó gbà gbẹ̀san lára àwọn tó ń ta kò ó lágbára gan-an ni. Ó pa ìdílé Hasmonean run àtàwọn sàràkí-sàràkí Júù tí wọ́n ń tì wọ́n lẹ́yìn, títí kan ẹnikẹ́ni tó bá ń bínú pé ọ̀rẹ́ àwọn ará Róòmù ló ń ṣàkóso àwọn.

Hẹ́rọ́dù Fìdí Ìjọba Rẹ̀ Múlẹ̀

Ní ọdún 31 ṣáájú Sànmánì Kristẹni nígbà tí Octavius ṣẹ́gun Máàkù Áńtónì nílùú Ákíṣíọ́mù, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ di alákòóso Róòmù tí kò sẹ́ni tó lè kò ó lójú, Hẹ́rọ́dù wá rí i pé àwọn èèyàn á fura tí wọléwọ̀de òun àti Máàkù Áńtónì bá pọ̀ jù. Torí náà, Hẹ́rọ́dù tètè lọ fi dá Octavius lójú pé digbí ni òun wà lẹ́yìn rẹ̀. Ọba Róòmù tuntun yìí náà sì gba Hẹ́rọ́dù gẹ́gẹ́ bí ọba Jùdíà, ó tiẹ̀ tún fi kún àgbègbè tó ń ṣàkóso lé lórí.

Ní àwọn ọdún tó tẹ̀ lé e, Hẹ́rọ́dù fìdí ìjọba rẹ̀ múlẹ̀, ó mú oríṣiríṣi àwọn nǹkan tuntun wọ ìjọba rẹ̀, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ sọ Jerúsálẹ́mù di ojúkò àṣà àwọn ará Gíríìsì. Ó bẹ̀rẹ̀ sí í dáwọ́ lé àwọn iṣẹ́ ńláńlá, irú bíi kíkọ́ àwọn ààfin, kíkọ́ ìlú kan sí etíkun Kesaréà àti kíkọ́ oríṣiríṣi àwọn ilé fún tẹ́ńpìlì Jerúsálẹ́mù. Àmọ́ gbogbo rẹ̀ náà, àwọn ìlànà tó ń tẹ̀ lé àti agbára tó ń lò kò ṣẹ̀yìn àjọṣe tó ní pẹ̀lú Róòmù.

Hẹ́rọ́dù kápá Jùdíà, ohun tó bá sì sọ labẹ gé. Hẹ́rọ́dù tún yọjú sọ́rọ̀ àwọn àlùfáà, ẹnikẹ́ni tó bá sì wù ú ló yàn gẹ́gẹ́ bí àlùfáà.

Ìpànìyàn Nítorí Owú

Ìṣòro wà nínú ilé Hẹ́rọ́dù. Èyí tó pọ̀ jù nínú àwọn ìyàwó mẹ́wàá tó ní ló fẹ́ kí ọmọ wọn ọkùnrin jọba lẹ́yìn baba wọn. Àwọn ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ààfin ló fà á tí Hẹ́rọ́dù fi ń fura, tó sì fi ń hùwà òǹrorò. Nítorí owú gbígbóná tó ní, ó ní kí wọ́n pa Mariamne, ìyẹn ìyàwó rẹ̀ tó fẹ́ràn jù lọ, ó sì tún pàṣẹ pé kí wọ́n fún àwọn ọmọkùnrin méjì lára ọmọ ìyàwó rẹ̀ yìí lọ́rùn pa torí ẹ̀sùn tí wọ́n fi kàn wọ́n pé wọ́n fẹ́ dìtẹ̀ mọ́ òun. Ìtàn nípa ìpakúpa tó wáyé nílùú Bẹ́tílẹ́hẹ́mù tí Mátíù sọ nípa rẹ̀ bá ohun tí Hẹ́rọ́dù máa ń ṣe tí inú bá ń bí i mu àti bó ṣe máa ń pa àwọn tó bá fura sí pé wọ́n lè fẹ́ bá òun du oyè.

Àwọn kan sọ pé bí Hẹ́rọ́dù ṣe mọ̀ pé àwọn èèyàn kò fẹ́ràn òun, ó pinnu pé gbogbo orílẹ̀-èdè náà ló máa wà nínú ìbànújẹ́ ọkàn tí òun bá kú dípò kínú wọn dùn. Kó lè rí ìyẹn ṣe, ó kó àwọn ará Jùdíà kan tí wọ́n jẹ́ abẹnugan sí àtìmọ́lé, ó sì pàṣẹ pé kí wọ́n pa wọ́n lọ́jọ́ tí wọ́n bá gbọ́ pé òun kú. Àmọ́ wọn kò ṣe bẹ́ẹ̀ rárá.

Ìlànà Tí Hẹ́rọ́dù Ńlá Fi Lélẹ̀

Lẹ́yìn tí Hẹ́rọ́dù kú, Róòmù pàṣẹ pé kí Ákíláọ́sì gbapò bàbá rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ọba Jùdíà àti pé kí ọmọ Hẹ́rọ́dù méjì míì máa ṣàkóso àwọn àgbègbè kan gẹ́gẹ́ bí ọmọ ọba tàbí baálẹ̀, wọ́n ní kí Áńtípà máa ṣàkóso lórí àgbègbè Gálílì àti Pèríà, wọ́n sì ní kí Philip máa ṣàkóso lórí àgbègbè Ítúréà àti Tírákónítì. Àwọn tó fi Ákíláọ́sì sípò àtàwọn tó ń ṣàkóso lé lórí kò fẹ́ràn rẹ̀. Lẹ́yìn ìṣàkóso ọdún mẹ́wàá tí kò lójú tó ṣe, àwọn Róòmù yọ ọ́ kúrò, wọ́n sì fi gómìnà tiwọn síbẹ̀, ìyẹn ẹni tó jẹ ṣáájú Pọ́ńtù Pílátù. Fún àwọn àkókò díẹ̀, Áńtípà, ẹni tí Lúùkù pè ní Hẹ́rọ́dù àti Philip ṣì ń ṣàkóso lórí àgbègbè tiwọn. Bí ètò ìṣèlú ṣe rí nìyí nígbà tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.—Lúùkù 3:1.

Olóṣèlú tó mòye àti apààyàn tí kò lójú àánú ni Hẹ́rọ́dù Ńlá, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ìwà òǹrorò rẹ̀ tó burú jù lọ ni bó ṣe gbìyànjú láti pa Jésù nígbà tí Jésù wà ní ọmọ ọwọ́. Ṣíṣàyẹ̀wò ipa tí Hẹ́rọ́dù kó nínú ìtàn wúlò fáwọn tó ń ka Bíbélì, ó jẹ́ kí wọ́n lóye àwọn ohun pàtàkì tó ṣẹlẹ̀ ní àkókò náà, ó ṣàlàyé bí àwọn Róòmù ṣe di alákòóso àwọn Júù, ó sì tún jẹ́ kí wọ́n lóye ìgbésí ayé Jésù lórí ilẹ̀ ayé àti iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 15]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ilẹ̀ Palẹ́sínì àtàwọn àgbègbè rẹ̀ ní àkókò Hẹ́rọ́dù

SÍRÍÀ

ÍTÚRÉÀ

GÁLÍLÌ

TÍRÁKÓNÍTÌ

Òkun Gálílì

Odò Jọ́dánì

Kesaréà

SAMÁRÍÀ

PÈRÍÀ

Jerúsálẹ́mù

Bẹ́tílẹ́hẹ́mù

JÙDÍÀ

Òkun Iyọ̀

ÍDÚMÍÀ

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Hẹ́rọ́dù wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn alákòóso tó jẹ tẹ̀ léra ní Jùdíà ní ọgọ́rùn-ún ọdún méjì ṣáájú kí Jésù tó bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀