Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe Rí Ilé Tí Wọ́n Ń Gbé
Bí Ìgbésí Ayé Àti Àsìkò Àwọn Kristẹni
Àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ Ṣe Rí Ilé Tí Wọ́n Ń Gbé
“Èmi kò . . . fà sẹ́yìn kúrò nínú . . . kíkọ́ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé.”—ÌṢE 20:20.
BÓ O bá ṣe ń gba ẹnubodè ńlá kan wọlé báyìí, ńṣe ló máa bọ́ sínú ìlú kan tó wà ní ọgọ́rùn-ún ọdún kìíní. Orí òkè ni ìlú náà wà bíi ti ọ̀pọ̀ ìlú míì. Àwọn ilé kan tún wà lórí òkè téńté lọ́ọ̀ọ́kán. Ọ̀pọ̀ ilé olówó ńlá tí wọ́n kùn ní àwọ̀ funfun ló ń dán gbinrin nínú àwọn ọgbà wọn. Àgbègbè yìí làwọn olówó ń gbé. Àwọn ilé olókùúta tó yàtọ̀ síra ní ìrísí àti ní títóbi wà lápá ìsàlẹ̀ òkè náà. Àwọn ilé alájà púpọ̀ tí wọ́n fi òkúta kọ́ wà lọ lẹ́gbẹ̀ẹ́ ojú pópó tí wọ́n fi òkúta tẹ́, àwọn ọmọ onílẹ̀ àtàwọn tó rí já jẹ ló ni wọ́n. Tó o bá tún rìn síwájú díẹ̀, wàá rí ibi táwọn tálákà ń gbé nísàlẹ̀ pátápátá. Àwọn ilé kéékèèké onígun mẹ́rin tí ìrísí wọn kò fani mọ́ra ni wọ́n kọ́ sún mọ́ra yíká àgbàlá, àwọn ọ̀nà tóóró-tóóró sì wà láàárín àwọn ilé kan.
Bó o bá ṣe ń gba àárín àwọn pópó tó ní àwọn ilé tó fún pọ̀ yìí kọjá, wàá máa gbọ́ àwọn ìró kan àtàwọn nǹkan tó ń ta sánsán. Àwọn obìnrin ń dáná, ìtasánsán àwọn ohun tí wọ́n ń sè sì gba inú afẹ́fẹ́ kan. Wàá máa gbọ́ ohùn àwọn ọmọdé àtàwọn ẹranko tí wọ́n ń ṣeré. Àwọn ọkùnrin ń ṣiṣẹ́ láwọn ibi tí ariwo àti òórùn wà.
Inú àwọn ilé yìí làwọn ìdílé Kristẹni ń gbé, tí wọ́n ń gba ìtọ́ni nípa tẹ̀mí tí wọ́n sì ń ṣe ìjọsìn.
Àwọn Ilé Kéékèèké Bíi tòde òní, ibi tí ilé kọ̀ọ̀kan wà àti bí ìdílé kan ṣe lówó lọ́wọ́ tó ló máa ń pinnu bí ilé wọ́n ṣe máa tóbi tó àti bí wọ́n á ṣe kọ́ ọ. Àwọn ilé tó kéré jù lọ níbẹ̀ (1) jẹ́ àwọn ilé oníyàrá kan tó rí kóńkó-kóńkó, tí kò sí ìmọ́lẹ̀ nínú rẹ̀, kì í sì í sábà gbà ju ìdílé kan lọ. Bíríkì tí wọ́n ti sá sí oòrùn ni wọ́n fi kọ́ ọ̀pọ̀ lára àwọn ilé kéékèèké yìí. Òkúta gbígbẹ́ tí kò dán lára ni wọ́n sì fi kọ́ ìyókù. Orí àpáta ni wọ́n kọ́ oríṣi àwọn ilé méjèèjì yìí sí.
Wọ́n máa ń rẹ́ ògiri ilé náà ní inú, wọ́n sì máa ń fi òkúta tẹ́ ilẹ̀ rẹ̀, èyí sì máa ń gba kí wọ́n máa bójú tó o nígbà gbogbo. Ó kéré tán, ihò kan máa ń wà lórí òrùlé tàbí lára ògiri, kí èéfín láti ilé ìdáná lè máa ríbi gbà jáde. Àwọn ohun èlò tó wà nínú ilé náà kò ju àwọn ohun kòṣeémáàní lọ.
Òrùlé alámọ̀ máa ń wà lórí àwọn igi ìrólé àti esùsú tí wọ́n fi àwọn òpó igi gbé ró. Wọ́n á wá fi amọ̀ rẹ́ òrùlé náà, èyí ni kò ní jẹ́ kí omi wọnú àjà ilé. Àkàsọ̀ tí wọ́n gbé síta ni wọ́n sì máa ń gbà dé orí òrùlé.
Pẹ̀lú bí àwọn ilé wọ̀nyí ṣe sún mọ́ra, ilé àwọn Kristẹni gbádùn mọ́ni, ìdílé tó jẹ́ òtòṣì lè lọ́rọ̀ nípa tẹ̀mí níbẹ̀, kí wọ́n sì láyọ̀.
Ilé Àwọn Tó Rí Já Jẹ́ Ilé alágbèékà kan tó tóbi díẹ̀ jẹ́ (2) tàwọn tó rí já jẹ, ó sì máa ń ní yàrá àlejò. (Máàkù 14:13-16; Ìṣe 1:13, 14) Wọ́n lè ṣe ìpàdé nínú ìyẹ̀wù òkè tó máa ń tóbi yìí, wọ́n sì máa ń lò ó ní àkókò àjọyọ̀. (Ìṣe 2:1-4) Òkúta ẹfun tí wọ́n fi amọ̀ rẹ́ pọ̀ ni wọ́n fi kọ́ àwọn ilé yìí àtàwọn míì tó tún tóbi (3) tó jẹ́ ti àwọn oníṣòwò àtàwọn ọmọ onílẹ̀. Wọ́n rẹ́ gbogbo ilẹ̀ tí wọ́n fi òkúta tẹ́ àtàwọn ògiri inú ilé, wọ́n sì kun gbogbo ògiri ìta ní ọ̀dà funfun.
Àtẹ̀gùn ni wọ́n máa ń gùn lọ sí yàrá òkè àti òrùlé. Wọ́n fi ìgbátí sí etí gbogbo òrùlé pẹrẹsẹ kí èèyàn má bàa já bọ́ látibẹ̀ àti nítorí àwọn jàǹbá míì. (Diutarónómì 22:8) Nígbà tí ooru bá ń mú lọ́sàn-án, abẹ́ ilé kẹ́jẹ́bú kan tí wọ́n kọ́ sórí òrùlé ni wọ́n ti máa ń kẹ́kọ̀ọ́, ṣàṣàrò, gbàdúrà tàbí lọ gbatẹ́gùn.—Ìṣe 10:9.
Yàtọ̀ sí pé àwọn ilé ńlá tó dúró sán-ún yìí gba àwọn ìdílé ńlá, wọ́n tún láwọn yàrá ńlá míì, àwọn yàrá àdáni àti ilé ìdáná ńlá pẹ̀lú ibi ìjẹun.
Àwọn Ilé Olówó Ńlá Wọ́n kọ́ àwọn ilé yìí lọ́nà tí àwọn ará Róòmù ń gbà kọ́lé wọn (4). Bí wọ́n ṣe kọ́ ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn, títóbi wọn àti iṣẹ́ ọnà tí wọ́n ṣe sí wọn lára yàtọ̀ síra. Ilé náà ni yàrá ìjẹun ńlá kan táwọn yàrá fífẹ̀ wà yíká. Inú yàrá ìjẹun yìí ni wọ́n ti máa ń ṣe àwọn nǹkan tí wọ́n fẹ́ ṣe nínú ilé. Wọ́n kọ́ àwọn ilé kan ní alágbèékà kan tàbí alágbèékà méjì (5) àwọn míì sì wà nínú ọgbà tí wọ́n ṣe lọ́ṣọ̀ọ́.
Ó ṣeé ṣe kí àwọn ohun èlò ilé tí wọ́n fi owó gọbọi ṣe wà nínú àwọn ilé olówó ńlá yìí, eyín erin àti wúrà ni wọ́n sì fi ṣe díẹ̀ lára wọn. Àwọn ohun amáyédẹrùn bí omi ẹ̀rọ àti odò ìlúwẹ̀ẹ́ wà níbẹ̀. Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé igi tàbí mábìlì aláwọ̀ mèremère ni wọ́n fi ṣe ilẹ̀ ilé náà, kó sì jẹ́ pé igi Ìṣe 20:9, 10.
kédárì ni wọ́n fi ṣe ògiri rẹ̀. Àdògán ni wọ́n fi ń dáná. Nítorí ààbò ilé náà, wọ́n fi àgánrándì onígi sí ojú fèrèsé, wọ́n wá ta aṣọ sójú fèrèsé káwọn èèyàn má bàa máa wo inú ilé. Wọ́n gbẹ́ ìjókòó sínú ògiri olókùúta níwájú fèrèsé.—Láìka bí ilé àwọn Kristẹni nígbà yẹn ṣe rí tàbí bó ṣe fẹ̀ tó, wọ́n máa ń gbàlejò, wọ́n sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Kì í ṣòro fáwọn alábòójútó arìnrìn-àjò láti rí àwọn ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ àlejò tí wọ́n sì máa fọ̀yàyà gbà wọ́n sílé títí dìgbà tí wọ́n fi máa parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn nílùú náà.—Mátíù 10:11; Ìṣe 16:14, 15.
“Ilé Símónì àti Áńdérù” Wọ́n fìfẹ́ gba Jésù lálejò sí “ilé Símónì àti Áńdérù” ní Kápánáúmù lẹ́gbẹ̀ẹ́ Òkun Gálílì. (Máàkù 1:29-31) Ilé àwọn apẹja yìí lè wà lára àwọn ilé tí kò fani mọ́ra (6) tí wọ́n kọ́ sún mọ́ra yíká àgbàlá tí wọ́n fi òkúta tẹ́.
Nírú àwọn ilé bẹ́ẹ̀, wọ́n máa ń ṣí àwọn ilẹ̀kùn àti fèrèsé tó dojú kọ àgbàlá náà sílẹ̀. Nínú àgbàlá yìí ni wọ́n ti máa ń ṣe àwọn iṣẹ́ ilé ojoojúmọ́, títí kan síse oúnjẹ, yíyan nǹkan àti lílọ ọkà. Ibẹ̀ náà ni wọ́n ti máa ń jẹun, wọ́n sì máa ń ṣe fàájì níbẹ̀.
Àwọn òkúta dúdú tí wọ́n kó látinú òkè ayọnáyèéfín ni wọ́n fi ń kọ́ àwọn ilé ilẹ̀ ní Kápánáúmù. Àtẹ̀gùn tó wà níta ni wọ́n máa ń gùn lọ sórí òrùlé ilé náà tó rí pẹrẹsẹ. Bí wọ́n ṣe ṣe òrùlé náà ni pé wọ́n fi amọ̀ tàbí àwo alámọ̀ bo esùsú àti igi ìrólé tó sinmi lé àwọn òpó. (Máàkù 2:1-5) Òkúta ni wọ́n máa fi ń tẹ́ ilẹ̀ ilé náà, wọ́n sì sábà máa ń tẹ́ ẹní sí i.
Àwọn ilé tí wọ́n kọ́ sẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn ní etíkun Òkun Gálílì ní òpópó àti àwọn ọ̀nà tóóró-tóóró láàárín. Kápánáúmù jẹ́ ibi tó dára gan-an fún àwọn apẹja láti máa gbé, torí pé inú òkun ni wọ́n ti ń rí owó tí wọ́n fi ń gbọ́ bùkátà ara wọn.
“Láti Ilé dé Ilé” Ní ṣókí, ilé àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yàtọ̀ síra wọn, àwọn kan jẹ́ ilé oníyàrá kan tí wọ́n fi bíríkì kọ́, àwọn míì jẹ́ ilé alágbàlá tí wọ́n fi òkúta olówó iyebíye kọ́.
Ohun tí wọ́n ń lo ilé wọ̀nyẹn fún ju kí wọ́n kàn máa gbé inú wọn lọ. Ibẹ̀ ni wọ́n ti máa ń gba ìtọ́ni tẹ̀mí, tí wọ́n sì ti máa ń ṣe ìjọsìn ìdílé. Wọ́n máa ń kóra jọ sí àwọn ilé àdáni láti kẹ́kọ̀ọ́ nínú Ìwé Mímọ́, wọ́n sì tún máa ń bá àwọn tí wọ́n jọ jẹ́ onígbàgbọ́ kẹ́gbẹ́ níbẹ̀. Wọ́n máa ń fi ẹ̀kọ́ tí wọ́n kọ́ nínú ilé wọn sílò dáadáa bí wọ́n ti ń ṣiṣẹ́ tó ṣe pàtàkì jù lọ, ìyẹn wíwàásù àti kíkọ́ni “láti ilé dé ilé” jákèjádò ilẹ̀ ọba Róòmù.—Ìṣe 20:20.