Ṣé Òkú Lè Ran Àwọn Alààyè Lọ́wọ́?
Ṣé Òkú Lè Ran Àwọn Alààyè Lọ́wọ́?
ỌMỌKÙNRIN kan tó ń jẹ́ Tamba, ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà fẹ́ ṣe ìdánwò níléèwé. a Màmá rẹ̀ tẹnu mọ́ ọn pé ó gbọ́dọ̀ wá ìrànwọ́ àwọn mọ̀lẹ́bí wọn tó ti kú kó bàa lè ṣàṣeyọrí. Àwọn arìnrìn-àjò tó ń ṣèbẹ̀wò sí ìlú Palermo ní erékùṣù Sísílì lórílẹ̀-èdè Ítálì máa ń lọ wo àwọn ibojì tí wọ́n ṣe sí abẹ́ ilẹ̀ níbi tí wọ́n tẹ́ ọgọ́rọ̀ọ̀rún òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ sí. Àwọn kan gbà gbọ́ pé àwọn òkú tí wọ́n kùn lọ́ṣẹ yìí máa dáàbò bo àwọn alààyè. Ní ọdọọdún, àwọn èèyàn máa ń lọ sí ìlú Lily Dale ní ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ New York, lórílẹ̀-èdè Amẹ́ríkà, ọ̀pọ̀ èèyàn mọ ìlú yìí torí pé àwọn tó ń bá òkú sọ̀rọ̀ pọ̀ gan-an níbẹ̀. Èrò àwọn tó ń ṣèbẹ̀wò yìí sì ni pé àwọn á lè bá àwọn mọ̀lẹ́bí tàbí àwọn ọ̀rẹ́ wọn tó ti kú sọ̀rọ̀, àwọn á sì lè rí ìrànwọ́ gbà lọ́dọ̀ wọn.
Kárí ayé làwọn èèyàn ti ní ìgbàgbọ́ pé àwọn òkú lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́. Kí ni èrò rẹ? Ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti fi ìgbàgbọ́ yìí kọ́ ìwọ náà tàbí kó o mọ àwọn kan tí kò fọwọ́ kékeré mú ìgbàgbọ́ yìí. Ó máa ń wu àwa èèyàn gan-an láti fẹ́ rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú. Àwọn tó ń bá òkú sọ̀rọ̀ sì máa ń ṣèlérí pé àwọn lè bá àwọn èèyàn ṣe é kí wọ́n lè bá àwọn èèyàn wọn tí wọ́n ti kú sọ̀rọ̀. Obìnrin kan tó máa ń bá òkú sọ̀rọ̀ tí wọ́n fa ọ̀rọ̀ rẹ̀ yọ nínú ìwé ìròyìn Time sọ pé, ‘ìgbà gbogbo ni ẹ̀mí àwọn òkú ṣe tán láti ṣèrànwọ́ fún ẹni tó bá wá ìrànwọ́ wá sọ́dọ̀ wọn.’ Ṣé òótọ́ lọ́rọ̀ yìí? Ṣé òótọ́ ni pé òkú lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́? Ìdáhùn Bíbélì tó ṣe kedere sáwọn ìbéèrè yìí lè yà ẹ́ lẹ́nu.
Ṣé Àwọn Òkú Wà Láàyè Níbì Kan?
Bíbélì ṣàlàyé ipò táwọn òkú wà lọ́nà tó rọrùn tó sì ṣe kedere. Kíyè sí ohun tí Oníwàásù 9:5 sọ, ó ní: “Àwọn alààyè mọ̀ pé àwọn yóò kú; ṣùgbọ́n ní ti àwọn òkú, wọn kò mọ nǹkan kan rárá.” Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe káwọn òkú mọ nǹkan kan lára? Ẹsẹ 6 dáhùn, ó ní: “Ìfẹ́ wọn àti ìkórìíra wọn àti owú wọn ti ṣègbé nísinsìnyí, wọn kò sì ní ìpín kankan mọ́ fún àkókò tí ó lọ kánrin nínú ohunkóhun tí a ó ṣe lábẹ́ oòrùn.” Tún kíyè sí pé, ẹsẹ 10 nínú orí Bíbélì kan náà yìí sọ pé, “kò sí iṣẹ́ tàbí ìhùmọ̀ tàbí ìmọ̀ tàbí ọgbọ́n ní Ṣìọ́ọ̀lù, ibi tí ìwọ ń lọ.” Ọ̀rọ̀ Hébérù náà “Ṣìọ́ọ̀lù” tí wọ́n lò níbí yìí túmọ̀ sí “ipò òkú.” Kẹ́ ẹ sì máa wò ó, “Hédíìsì” tó jẹ́ ọ̀rọ̀ Gíríìkì tóun náà ní ìtumọ̀ kan náà pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Hébérù náà Ṣìọ́ọ̀lù ni wọ́n lò nínú Ìwé Mímọ́ láti ṣàlàyé ibi tí Jésù Kristi wà nígbà tó kú.—Ìṣe 2:31.
Ọ̀pọ̀ èèyàn ni Jésù ràn lọ́wọ́ nígbà tó ṣì wà láàyè, àmọ́ ó mọ̀ pé òun máa kú. Ṣé ó ronú pé òun á ṣì lè máa ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ nígbà tóun bá wà nínú sàréè? Rárá o. Ìdí ni pé, ó fi ikú tóun fúnra rẹ̀ máa tó kú wé òru nígbà tí èèyàn kì í lè ṣe iṣẹ́ kankan. (Jòhánù 9:4) Jésù mọ̀ dáadáa pé téèyàn bá ti ṣaláìsí, ó tí di “aláìlè-ta-pútú nínú ikú” nìyẹn.—Aísáyà 26:14.
Jésù tún lo àfiwé kan tó bá ikú mu láti mú kí kókó ọ̀rọ̀ kan náà yìí ṣe kedere. Nígbà tí Lásárù ọ̀rẹ́ rẹ̀ kú, Jésù fi ikú wé oorun. (Jòhánù 11:11-13) A kò lè retí pé kí ẹni tó wà lójú oorun ràn wá lọ́wọ́, àbí ó lè ṣe bẹ́ẹ̀? Ẹni tó wà lójú oorun kò mọ nǹkan kan, kò sì lè ṣe ohunkóhun nítorí ẹnikẹ́ni.
Ṣé Ọkàn Máa Ń Kúrò Lára Nígbà Téèyàn Bá Kú?
Ohun tí wọ́n ti fi kọ́ ọ̀pọ̀ èèyàn ni pé ọkàn èèyàn jẹ́ ohun kan tí kò ṣeé rí tó máa ń wà Jẹ́nẹ́sísì 2:7 sọ pé ọkùnrin àkọ́kọ́ “di alààyè ọkàn” nígbà tí Ọlọ́run ṣẹ̀dá rẹ̀. Ọkàn ni èèyàn látòkè délẹ̀, ọkàn sì ni ẹranko pẹ̀lú. (Jẹ́nẹ́sísì 1:20-25) Torí náà, nígbà téèyàn tàbí ẹranko bá kú, ọkàn kú nìyẹn. Bíbélì sì fìdí èyí múlẹ̀.—Ìsíkíẹ́lì 18:4.
láàyè lẹ́yìn téèyàn bá kú. Àmọ́ ohun tó yàtọ̀ síyẹn ni Bíbélì fi kọ́ni. Ìwé Jẹ́nẹ́sísì tó jẹ́ ìwé àkọ́kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ ká mọ ohun tí ọkàn jẹ́.Àmọ́ ṣá o, àwọn kan lè béèrè pé, ‘Báwo ló ṣe jẹ́ tá a máa ń gbọ́ pé àwọn èèyàn lọ bá òkú sọ̀rọ̀, pé wọ́n gbọ́ ohùn àwọn òkú tàbí pé wọ́n rí wọn?’ Irú àwọn ìtàn báyìí wọ́pọ̀ káàkiri ayé. Àwọn ìtàn yìí máa ń fọkàn àwọn tí mọ̀lẹ́bí tàbí ọ̀rẹ́ wọn kú balẹ̀, èyí sì máa ń mú kí ọ̀pọ̀ èèyàn lọ sọ́dọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn lè bá òkú sọ̀rọ̀.
Ṣé òótọ́ làwọn ìtàn yìí? Tó bá jóòótọ́, ǹjẹ́ èyí kò ní ta ko àwọn ọ̀rọ̀ inú Bíbélì tó sọ pé àwọn òkú kò mọ ohunkóhun? Kristi Jésù ṣàlàyé pé òtítọ́ ni Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Jòhánù 17:17) Òtítọ́ kì í sì í ta ko ara rẹ̀. Kedere ni Bíbélì ṣàlàyé ojú tó yẹ ká máa fi wo ohun táwọn èèyàn sọ pé òkú lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́. Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ nípa ẹnì kan tó gbìyànjú láti wá ìrànlọ́wọ́ lọ́dọ̀ òkú. Tá a bá fara bálẹ̀ ka ìtàn náà, a máa rí òtítọ́ náà kedere.
Ọba Kan Wá Ìrànlọ́wọ́ Lọ Sọ́dọ̀ Òkú
Ogun tó gbóná kan ń lọ lọ́wọ́ ní àríwá ilẹ̀ Ísírẹ́lì. Sọ́ọ̀lù Ọba àtàwọn ọmọ ogun rẹ̀ dojú kọ àwọn àkòtagìrì ọmọ ogun Filísínì. Nígbà tí Sọ́ọ̀lù rí ibùdó àwọn ará Filísínì, “ọkàn-àyà rẹ̀ sì bẹ̀rẹ̀ sí wárìrì gidigidi.” Sọ́ọ̀lù ti pa ìjọsìn tòótọ́ tì lákòókò yìí nínú ìṣàkóso rẹ̀. Àbájáde èyí sì ni pé, Jèhófà kò dáhùn àdúrà rẹ̀. Tóò, ibo ni Sọ́ọ̀lù máa wá yíjú sí fún ìrànlọ́wọ́? Wòlíì Sámúẹ́lì ti kú lákòókò tá à ń wí yìí.—1 Sámúẹ́lì 28:3, 5, 6.
Sọ́ọ̀lù wá ìrànlọ́wọ́ lọ sọ́dọ̀ obìnrin abókùúsọ̀rọ̀ kan nílùú Ẹ́ń-dórì. Ó bẹ abókùúsọ̀rọ̀ náà pé kó bá òun “mú Sámúẹ́lì gòkè wá” láti ipò òkú. Ni abókùúsọ̀rọ̀ yìí bá pe ẹ̀dá abàmì kan jáde. Ẹni tí wọ́n rò pé ó jẹ́ Sámúẹ́lì yìí sọ́ fún Sọ́ọ̀lù pé àwọn ará Filísínì máa borí àti pé Sọ́ọ̀lù àtàwọn ọmọkùnrin rẹ̀ máa kú nínú ìjà náà. (1 Sámúẹ́lì 28:7-19) Ṣé Sámúẹ́lì gan-gan lẹni tó jáde wá láti ipò òkú?
Rò ó wò ná. Bíbélì sọ pé, téèyàn bá kú, yóò “padà sínú ilẹ̀ rẹ̀” àti pé “àwọn ìrònú rẹ̀ ṣègbé.” (Sáàmù 146:4) Sọ́ọ̀lù àti Sámúẹ́lì mọ̀ pé Ọlọ́run kìlọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ lọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò. Ó ṣe tán, Sọ́ọ̀lù fúnra rẹ̀ ló ti kọ́kọ́ mú ipò iwájú láti fòpin sí àṣà ìbẹ́mìílò nílẹ̀ náà!—Léfítíkù 19:31.
Ronú lórí ọ̀rọ̀ náà. Ká ní òótọ́ ni pé Sámúẹ́lì tó jẹ́ olóòótọ́ ṣì wà láàyè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí kan, ǹjẹ́ á rú òfin Ọlọ́run táá sì lọ bá abókùúsọ̀rọ̀ kan láti bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀? Jèhófà kò bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ mọ́. Ṣé abókùúsọ̀rọ̀ kan lè wá fi dandan mú Ọlọ́run Olódùmarè pé kó bá Sọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípasẹ̀ Sámúẹ́lì tó ti kú? Rárá o. Ó ṣe kedere nígbà náà pé ẹni tí wọ́n pè ní Sámúẹ́lì yìí kì í ṣe wòlíì Ọlọ́run. Ẹ̀mí èṣù burúkú kan tó díbọ́n pé òun ni Sámúẹ́lì tó ti kú ni.
Àwọn ẹ̀mí èṣù làwọn áńgẹ́lì tí wọ́n ṣọ̀tẹ̀ sí àṣẹ Ọlọ́run ní ìbẹ̀rẹ̀ ìtàn èdá èèyàn. (Jẹ́nẹ́sísì 6:1-4; Júdà 6) Àwọn ẹ̀mí èṣù yìí máa ń kíyè sáwọn èèyàn nígbà tí wọ́n bá ṣì wà láàyè, wọ́n mọ bí èèyàn kọ̀ọ̀kan ṣe ń sọ̀rọ̀, bó ṣe máa ń wo nǹkan àti bí èèyàn kọ̀ọ̀kan ṣe máa ń ṣe. Wọ́n múra tán láti jẹ́ káráyé gbà pé ohun tí Bíbélì sọ kì í ṣe òtítọ́. Abájọ tí Bíbélì fi kìlọ̀ pé ká má ṣe ní ohunkóhun ṣe pẹ̀lú àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí yìí! (Diutarónómì 18:10-12) Àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú yìí ṣì wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí.
A ti wá rí ìdí tí ọ̀pọ̀ fi máa ń sọ pé àwọn “gbọ́” tàbí pé àwọn “rí” àwọn èèyàn àwọn tó ti kú. Nígbà míì, àwọn ìran abàmì bí èyí lè dà bí ohun tó lè ṣèrànwọ́ fúnni, àmọ́ ìfẹ́ ọkàn àwọn ẹ̀dá ẹ̀mí burúkú yìí ni láti tan àwọn èèyàn jẹ. b (Éfésù 6:12) Tún gbé èyí yẹ̀ wò: Ọlọ́run ìfẹ́ tó bìkítà fún wa ni Jèhófà. Tó bá jẹ́ òótọ́ ni pé àwọn òkú wà láàyè níbì kan tí wọ́n sì lè wá ṣèrànwọ́ fún àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn ìdílé wọn, ǹjẹ́ Ọlọ́run wa onífẹ̀ẹ́ á sọ pé ká má ṣe sún mọ́ wọn, táá sì pe irú àjọṣe yẹn ní ohun “ìṣe họ́ọ̀ sí”? Kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ láé! (1 Pétérù 5:7) Ǹjẹ́ ìrànlọ́wọ́ èyíkéyìí tó ṣeé gbára lé wà?
Ojúlówó Ìrànwọ́ Fáwọn Alààyè Àtàwọn Òkú
Ohun tá à ń bá bọ̀ ti jẹ́ kó yé wa pé àwọn òkú kò lè ran àwọn alààyè lọ́wọ́. Torí náà, kì í ṣe pé èèyàn máa fàkókò ṣòfò lásán tó bá ń wá ìrànlọ́wọ́ òkú, ó tún léwu torí pé àṣà yìí ta ko òfin Ọlọ́run, ó sì tún lè jẹ́ káwọn ẹ̀mí èṣù máa darí èèyàn.
Bíbélì darí wa sọ́dọ̀ ẹni tó jẹ́ Orísun ìrànlọ́wọ́ tó dára jù lọ, ìyẹn Jèhófà Ẹlẹ́dàá wa. Jèhófà lè gbà wá sílẹ̀ lọ́wọ́ ikú. (Sáàmù 33:19, 20) Ó tún wà ní sẹpẹ́ láti ràn wá lọ́wọ́ lóde òní. Ó tipa báyìí fún wa ní ojúlówó ìrètí, èyí tó yàtọ̀ sí irọ́ táwọn abókùúsọ̀rọ̀ ń pa.
Tamba, tá a sọ̀rọ̀ rẹ̀ níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí ti kẹ́kọ̀ọ́, ó sì ti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ìrètí èké táwọn abókùúsọ̀rọ̀ máa ń fún àwọn èèyàn àti òtítọ́ tí Jèhófà fi ń kọ́ wa. Àwọn abókùúsọ̀rọ̀ sọ pé tí kò bá rúbọ sáwọn baba ńlá rẹ̀ tó ti kú, ó máa fìdí rẹmi nínú ìdánwò iléèwé tó fẹ́ ṣe. Tamba ti bẹ̀rẹ̀ sí í kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ó sì ti mọ ipò táwọn òkú wà ní tòótọ́ àti ẹni ibi tó wà lẹ́yìn àwọn ẹ̀mí burúkú tó ń ṣe bí àwọn baba ńlá tó ti kú. Pẹ̀lú bí màmá rẹ̀ ṣe ń fi dandan lé e pé kó wá ìrànwọ́ lọ́dọ̀ àwọn abókùúsọ̀rọ̀, Tamba kọ̀ jálẹ̀, ó sì sọ fún màmá rẹ̀ pé, “Tí mo bá fìdí rẹmi, màá túbọ̀ jára mọ́ ẹ̀kọ́ mi lọ́dún tó ń bọ̀.”
Kí wá ni àbájáde rẹ̀? Tamba ló gba ipò kìíní nínú ìdánwò náà! Ó ya màmá rẹ̀ lẹ́nu débi pé kò nígbàgbọ́ nínú àwọn abókùúsọ̀rọ̀ mọ́, kó sì mẹ́nu kan rírúbọ sí àwọn baba ńlá mọ́. Tamba ti kẹ́kọ̀ọ́ pé Jèhófà kìlọ̀ pé a kò gbọ́dọ̀ ‘béèrè fún nǹkan kan lọ́wọ́ àwọn òkú nítorí àwọn alààyè.’ (Aísáyà 8:19) Ohun tí Tamba kọ́ nínú Bíbélì jẹ́ kó dá a lójú pé tóun bá nífẹ̀ẹ́ òfin Ọlọ́run, òun á ṣàṣeyọrí.—Sáàmù 1:1-3.
Àwọn èèyàn wa tó ti kú ńkọ́? Ṣé ìrètí wà fún wọn? Yàtọ̀ sí ìrànlọ́wọ́ tí Jèhófà ń ṣe fún àwa alààyè báyìí, ó ti ṣèlérí pé òun tún máa ran àwọn tó wà nínú isà òkú lọ́wọ́. Lẹ́yìn tí wòlíì Aísáyà ti ṣàlàyé bí àwọn òkú kò ṣe lágbára láti ṣe ohunkóhun, kíyè sí ohun tó sọ nínú ìwé Aísáyà orí 26, ẹsẹ 19 pé: “Àwọn òkú rẹ yóò wà láàyè. . . . Ẹ jí, ẹ sì fi ìdùnnú ké jáde, ẹ̀yin olùgbé inú ekuru!” Àsọtẹ́lẹ̀ yìí tún sọ síwájú sí i pé, “àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú” máa wà láàyè lẹ́ẹ̀kan sí i.
Fojú inú wo bí àkókò yẹn ṣe máa rí! Ọ̀kẹ́ àìmọye èèyàn tí kò lè ṣe nǹkan kan mọ́, tí wọ́n ń sùn nínú sàréè tún máa pa dà wà láàyè! Kódà, Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé Jèhófà “ni ifẹ” láti fún àwọn tó ti kú ní ìwàláàyè. (Jóòbù 14:14, 15, Bibeli Mimọ) Ṣé àwọn ìlérí yìí kò dà bí àlá lásán báyìí? Àwọn ìlérí yìí dá Jésù Kristi lójú débi tó fi ṣàpèjúwe àwọn òkú bíi pé wọ́n ti wà láàyè lójú Jèhófà.—Lúùkù 20:37, 38.
Ṣé wàá fẹ́ kọ́wọ́ rẹ̀ tẹ ìlérí yìí? c Máa bá a nìṣó láti máa gba ìmọ̀ pípéye látinú Bíbélì. Èyí máa jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Jèhófà lè ran àwọn alààyè àti àwọn òkú lọ́wọ́ àti pé àwọn ìlérí rẹ̀ “ṣeé gbíyè lé, wọ́n sì jẹ́ òótọ́.”—Ìṣípayá 21:4, 5.
[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a A ti yí orúkọ náà pa dà.
b Fún àlàyé síwájú sí i lórí kókó yìí, ka ìwé pẹlẹbẹ Ẹmi Awọn Oku—Wọn Ha Le Ran Ọ Lọwọ Tabi Pa Ọ Lara Bi? Wọn Ha Wa Niti Gidi Bi? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
c Fún àlàyé síwájú sí i nípa ìlérí àjíǹde tí Bíbélì ṣe, ka orí 7 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.
[Ìsọfúnni tá a pàfiyèsí sí ní ojú ìwé 19]
Ó máa ń wu àwa èèyàn gan-an láti fẹ́ rí àwọn èèyàn wa tí wọ́n ti kú
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]
Ṣé wòlíì Sámúẹ́lì pa dà wá lẹ́yìn tó ti kú láti wá bá Sọ́ọ̀lù Ọba sọ̀rọ̀?