Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Ayé Yìí Máa Pa Rẹ́?

Ṣé Ayé Yìí Máa Pa Rẹ́?

Ṣé Ayé Yìí Máa Pa Rẹ́?

ÒǸKỌ̀WÉ kan tó ń jẹ́ John Scalzi sọ pé, “òpin ayé jẹ́ ohun táwọn èèyàn máa ń sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nígbà gbogbo, wọ́n sì máa ń fi ṣe fíìmù.” Kí nìdí táwọn èèyàn tó ń wo fíìmù fi máa ń nífẹ̀ẹ́ sí àwọn fíìmù tó bá ń sọ̀rọ̀ nípa òpin ayé? Ọ̀gbẹ́ni Scalzi sọ pé, “torí ó ní í ṣe pẹ̀lú nǹkan tó ń bani lẹ́rù.” Ṣéwọ náà gbà bẹ́ẹ̀? Ǹjẹ́ àwọn ìdí tó bọ́gbọ́n mu tiẹ̀ wà tó fi yẹ ká máa bẹ̀rù nípa ìgbà tí òpin lè dé bá ayé àtohun gbogbo tó wà nínú rẹ̀ títí kan bó ṣe máa dé?

Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ pé lójoojúmọ́ là ń gbọ́ nípa àwọn àjálù tó ń runlé rùnnà yíká ayé. Wọ́n máa ń fi àwòrán irú àwọn àjálù bẹ́ẹ̀ hàn léraléra nínú tẹlifíṣọ̀n àti lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Nígbà tá a bá ń wo àwòrán àwọn ibi tó ń pa run àti bí àwọn èèyàn ṣe ń kú, ó máa ń rọrùn láti fojú inú wo òpin ayé bí ohun tó bani lẹ́rù gan-an, tí kì í wulẹ̀ ṣe fíìmù lásán.

Ohun tó máa ń pa kún irú àwọn ìbẹ̀rù bẹ́ẹ̀ ni àbá táwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì máa ń gbé jáde nípa bí ayé ṣe máa dópin. Kódà àwọn kan sàsọtẹ́lẹ̀ ọjọ́ tí ayé máa pa rẹ́. Lóṣù March ọdún 2008, ìwé kan tó ń sọ̀rọ̀ nípa sánmà, ìyẹn Monthly Notices of the Royal Astronomical Society ròyìn pé méjì lára àwọn onímọ̀ nípa àwọn ìṣẹ̀dá inú sánmà sọ tẹ́lẹ̀ pé tó bá fi máa di nǹkan bíi bílíọ̀nù méje àti ààbọ̀ ọdún sígbà tá a wà yìí, oòrùn máa gbé ayé yìí mì, ó sì máa fa gbogbo omi inú rẹ̀ gbẹ táútáú.

Ṣé òótọ́ ni pé ayé yìí máa pa run lọ́jọ́ kan?

Ǹjẹ́ Ọjọ́ Kan Wà Tí Ayé Yìí Máa Pa Rẹ́?

Bíbélì fi dá wa lójú pé: “Iran kan nlọ, iran miran si nbọ̀: ṣugbọn ayé duro titi lae.” (Oniwaasu 1:4, Bibeli Yoruba Atọ́ka) Jèhófà Ọlọ́run ti “fi ìpìlẹ̀ ayé sọlẹ̀ sórí àwọn ibi àfìdímúlẹ̀ rẹ̀,” ó sì ti ṣe é lọ́nà tó máa fi wà “fún àkókò tí ó lọ kánrin, tàbí títí láé.” (Sáàmù 104:5) Ṣé ọ̀rọ̀ tí Ọlọ́run mí sí yìí kò dà bí àlá lásán? Kí nìdí tó fi yẹ kó o gbà gbọ́ pé ayé yìí kò ní pa rẹ́ báwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì bá tiẹ̀ sọ pé ó máa pa rẹ́?

Àpẹẹrẹ kan rèé, jẹ́ ká ronú nípa àwọn ọjà tí wọ́n pàtẹ sínú ilé ìtajà kan. Wọ́n kọ ọjọ́ tí àwọn ọjà kan kò ní yẹ fún lílò mọ́ sí wọn lára. Ta ló dá ọjọ́ náà? Ṣé mọ́níjà ilé ìtajà náà ló kàn ronú ọjọ́ kan ni? Rárá o! Àwọn tó ṣe ọjà náà ló máa dá ọjọ́ tí ọjà ọ̀hún kò ní yẹ fún lílò mọ́. A kì í ṣiyèméjì lórí ọjọ́ tí wọ́n bá kọ sí ọjà náà lára torí pé àwọn tó ṣe é mọ ọjà náà ju ẹnikẹ́ni lọ. Mélòómélòó ni ti Ẹlẹ́dàá tó ṣẹ̀dá ayé wa yìí, ṣé kò yẹ ká fọkàn tán an ni? Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ sọ ọ́ lọ́nà tó ṣe kedere pé ó ti “fi ilẹ̀ ayé sọlẹ̀ gbọn-in gbọn-in” kó bàa lè wà títí láé. Kò sí ọjọ́ kankan tí ayé máa pa rẹ́ o!—Sáàmù 119:90.

Ǹjẹ́ ó ṣeé káwọn èèyànkéèyàn ba ayé yìí jẹ́ kọjá àtúnṣe? Rárá o! Jèhófà kò dà bí àwọn èèyàn, ó “lè ṣe ohun gbogbo.” (Jóòbù 42:2) Ìdí nìyẹn tó fi sọ pẹ̀lú ìdánilójú pé: “Ọ̀rọ̀ mi tí ó ti ẹnu mi jáde yóò . . . ní àṣeyọrí sí rere tí ó dájú.” (Aísáyà 55:11) Ó dá wa lójú pé “Olùṣẹ̀dá wa” kò ní jẹ́ kí ohunkóhun dí òun lọ́wọ́ láti mú ohun tó fẹ́ ṣe fún ayé yìí ṣẹ. (Sáàmù 95:6) Kí wá ni ohun tí Ọlọ́run fẹ́ ṣe fún ayé yìí, báwo ló sì ṣe máa ṣe é?

Ìjọba Ọlọ́run Máa Mú Ìfẹ́ Ọlọ́run Ṣẹ

Yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run fi dá wa lójú pé ayé yìí kò ní pa rẹ́, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tún sọ fún wa pé ó “ṣẹ̀dá rẹ̀ àní kí a lè máa gbé inú rẹ̀.” (Aísáyà 45:18) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún táwa èèyàn ti ń gbé láyé, ìyẹn kò tí ì mú ìfẹ́ Ọlọ́run ṣẹ síbẹ̀.

Jèhófà jẹ́ “Ọlọ́run aláyọ̀,” ó sì jẹ́ “olùfẹ́ ìdájọ́ òdodo.” (1 Tímótì 1:11; Sáàmù 37:28) Ohun tó fẹ́ ni pé kí gbogbo èèyàn máa gbé ní ayọ̀, kí wọ́n sì máa rí ìdájọ́ òdodo gbà. Kó lè mú ohun tó ní lọ́kàn ṣẹ, Ọlọ́run sọ tẹ́lẹ̀ pé òun máa gbé Ìjọba kan kalẹ̀ ní ọ̀run, tí yòó ṣàkóso lé ayé lórí. (Dáníẹ́lì 2:44) Nígbà tí Jésù wà láyé, ọ̀pọ̀ ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa Ìjọba Ọlọ́run. Ó ní kí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun máa gbàdúrà fún ìjọba yìí torí ó mọ̀ nípa gbogbo ìbùkún tó máa mú wá sí ayé. (Mátíù 6:9, 10; 24:14) Kí ni díẹ̀ lára àwọn ìbùkún yẹn?

Àlàáfíà àti ààbò máa gbilẹ̀ torí Ọlọ́run ti ṣèlérí pé òun máa fòpin sí gbogbo ogun. —Sáàmù 46:9.

Oúnjẹ máa wà lọ́pọ̀ yanturu fún gbogbo èèyàn. —Sáàmù 72:16.

Ọ̀rọ̀ nípa ìlera kò ní jẹ́ ìṣòro mọ́ torí pé, “kò [ní] sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’”—Aísáyà 33:24.

A kò ní máa ṣọ̀fọ̀ mọ́ torí pé,ikú kì yóò . . . sí mọ́.”—Ìṣípayá 21:4.

Ọlọ́run ṣèlérí pé àwọn èèyàn òun máa kọ́ ilé tiwọn, wọ́n á máa gbé láìsí ewu, wọ́n á sì “kún fún ìdùnnú títí láé.” Aísáyà 65:17-24.

Ó dájú pé wàá fẹ́ gbádùn àwọn nǹkan rere tá a ṣẹ̀ṣẹ̀ sọ tán yìí. Ó wu Jèhófà gan-an láti mú gbogbo àsọtẹ́lẹ̀ tó ti sọ yìí ṣẹ, ìtara rẹ̀ láti ṣe é sì ń jó bí iná. (Aísáyà 9:6, 7) Síbẹ̀, o lè máa rò pé: ‘Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ti kọjá lọ lẹ́yìn ìgbà tí wọ́n ti kọ àwọn ìlérí Ọlọ́run sílẹ̀ nínú Bíbélì. Kí nìdí táwọn ìlérí yìí kò tíì ṣẹ títí di báyìí?’

Sùúrù Ọlọ́run Máa Yọrí sí Ìgbàlà fún Wa

Ẹ jẹ́ kó dá wa lójú pé, “Jèhófà kò fi nǹkan falẹ̀ ní ti ìlérí rẹ̀.” Bíbélì ṣàlàyé pé Ọlọ́run ń mú sùúrù fún wa tìfẹ́tìfẹ́. Torí náà, Bíbélì gbà wá níyànjú pé kí á “ka sùúrù Olúwa wa sí ìgbàlà.” (2 Pétérù 3:9, 15) Àmọ́, kí nìdí tí sùúrù Ọlọ́run fi ṣe pàtàkì fún ìgbàlà?

Lákọ̀ọ́kọ́ náà, Ọlọ́run mọ̀ pé kí òun tó lè sọ ayé di ibi tí kò léwu tó sì máa dùn ún gbé fún àwọn olódodo, òun ní láti kọ́kọ́ “run àwọn tí ń run ilẹ̀ ayé.” (Ìṣípayá 11:18, 19) Àmọ́ torí pé Jèhófà nífẹ̀ẹ́ àwa èèyàn, “kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run.” Ìdí nìyẹn tí Bàbá wa ọ̀run fi ń ní sùúrù, tó sì ń ‘kìlọ̀ fún àwọn ẹni burúkú pé kí wọ́n kúrò ní ọ̀nà burúkú wọn.’ Ìyẹn ló fà á tí Ọlọ́run fi ní kí wọ́n máa wàásù ìhìn rere nípa Ìjọba òun kárí ayé. a (Ìsíkíẹ́lì 3:17, 18) Gbogbo àwọn tó bá fetí sí ìkìlọ̀ yìí, tí wọ́n sì ń ṣe àwọn ohun tó bá ìlànà òdodo Ọlọ́run mu, máa ní ìgbàlà, wọ́n sì máa gbádùn ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè lórí ilẹ̀ ayé.

Yíjú Sọ́dọ̀ Ọlọ́run Kó O Lè Ní Ìgbàlà

Kò sí àní-àní pé “ìhìn rere” wà nínú Bíbélì fún wa. (Mátíù 24:14) Bíbélì jẹ́ ká mọ̀ pé ayé wa yìí kò ní pa rẹ́, pé Ọlọ́run tí sọ bẹ́ẹ̀ kò sì ní tàsé! Láfikún sí i, a lè nígbàgbọ́ nínú àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì pé, “ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́.” Láìpẹ́, àwọn tó jẹ́ olódodo lójú Ọlọ́run nìkan “ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.” (Sáàmù 37:9-11, 29; Mátíù 5:5; Ìṣípayá 21:3, 4) Títí dìgbà náà Ọlọ́run yóò máa fi sùúrù pe àwọn èèyàn pé: “Ẹ yíjú sọ́dọ̀ mi kí a sì gbà yín là, gbogbo ẹ̀yin tí ń bẹ ní òpin ilẹ̀ ayé.” (Aísáyà 45:22) Kí lo máa ṣe?

O ò ṣe pinnu pé wàá yíjú sọ́dọ̀ Ọlọ́run? Sáàmù 37:34 rọ̀ wá pé: “Ní ìrètí nínú Jèhófà, kí o sì máa pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́, òun yóò sì gbé ọ ga láti gba ilẹ̀ ayé.” Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà máa dùn láti ràn ẹ́ lọ́wọ́, kó o lè kẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i nípa àwọn ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe fún ayé àti bó o ṣe lè wà láàyè láti fojú ara rẹ rí bí ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe máa ṣẹ.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Láti ṣègbọràn sí àṣẹ tí Jésù pa nínú ìwé Mátíù 28:19, 20, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n lé ní mílíọ̀nù méje ní òjìlérúgba-ó-dín-mẹ́rìn [236] ilẹ̀ ń lo nǹkan bíi bílíọ̀nù kan ààbọ̀ wákàtí lọ́dọọdún láti kọ́ àwọn èèyàn lẹ́kọ̀ọ́ nípa ohun tí Ọlọ́run ní lọ́kàn láti ṣe sí ayé yìí.

[Àwòrán Credit Line tó wà lójú ìwè 22]

Fọ́tò NASA