Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹni Tó Ń Mú Ìlérí Ṣẹ

Ẹni Tó Ń Mú Ìlérí Ṣẹ

Sún Mọ́ Ọlọ́run

Ẹni Tó Ń Mú Ìlérí Ṣẹ

JÓṢÚÀ 23:14

ṢÉ Ó máa ń ṣòro fún ẹ láti fọkàn tán àwọn èèyàn? Ó ṣeni láàánú pé, inú ayé táwọn èèyàn ti ń ba ìgbẹ́kẹ̀lé téèyàn ní nínú wọn jẹ́ là ń gbé yìí. Bí ẹnì kan tó o fọkàn tán bá ṣe ohun tó dùn ẹ́ gan-an, bóyá ó parọ́ tàbí tí kò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ, kò ní rọrùn fún ẹ láti fọkàn tán ẹni náà mọ́. Àmọ́, ẹnì kan wà tó o lè gbẹ́kẹ̀ lé tí kò ní já ẹ kulẹ̀. Òwe 3:5 rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà.” Kí nìdí tá a fi gbọ́dọ̀ fi gbogbo ọkàn gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà? Láti dáhùn ìbéèré yìí, jẹ́ ká ṣàyẹ̀wò ọ̀rọ̀ Jóṣúà, ìyẹn ọkùnrin tó gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá gẹ́gẹ́ bó ṣe wà nínú ìwé Jóṣúà 23:14.

Ohun tó ṣẹlẹ̀ rèé. Jóṣúà tó rọ́pò Mósè gẹ́gẹ́ bí aṣáájú àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ti ń sún mọ́ ẹni àádọ́fà [110] ọdún. Ní gbogbo àkókò gígùn tó lò láyé, ó ti rí ọ̀pọ̀ àwọn nǹkan àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe nítorí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì, tó fi mọ́ ọ̀nà ìyanu tó gbà dá wọn nídè, tí wọ́n sì la Òkun Pupa já ní nǹkan bí ọgọ́ta [60] ọdún ṣáájú ìgbà náà. Ní báyìí tí Jóṣúà wá ń ronú lórí ìgbésí ayé tó ti gbé, ó pe gbogbo Ísírẹ́lì jọ “àwọn àgbà ọkùnrin rẹ̀ àti àwọn olórí rẹ̀ àti àwọn onídàájọ́ rẹ̀ àti àwọn onípò àṣẹ láàárín rẹ̀.” (Jóṣúà 23:2) Àwọn ọ̀rọ̀ tó bá wọn sọ kì í ṣe àwọn ọ̀rọ̀ ọgbọ́n tó ní gẹ́gẹ́ bí àgbàlagbà, àmọ́ ó jẹ́ àròjinlẹ̀ tó wá látinú ìgbàgbọ́ rẹ̀ tó lágbára.

Jóṣúà ṣàlàyé pé: “Èmi ń lọ lónìí ní ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé.” Àpólà ọ̀rọ̀ náà “ọ̀nà gbogbo ilẹ̀ ayé” jẹ́ àkànlò ọ̀rọ̀ tó túmọ̀ sí ikú. Ohun tí Jóṣúà ń sọ ní ti gidi ni pé, “kò ní pẹ́ mọ́ tóun á fi kú.” Bó ṣe mọ̀ pé òun máa tó kú, kò sí àní-àní pé Jóṣúà ti máa lo wákàtí tó pọ̀ gan-an láti ronú lórí ìgbésí ayé rẹ̀. Ọ̀rọ̀ ìdágbére wo ló fẹ́ bá àwọn tí wọ́n jọ ń sin Ọlọ́run sọ?

Jóṣúà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Kò sí ọ̀rọ̀ kan tí ó kùnà nínú gbogbo ọ̀rọ̀ rere tí Jèhófà Ọlọ́run yín sọ fún yín. Gbogbo wọn ti ṣẹ fún yín. Kò sí ọ̀rọ̀ kan lára wọn tí ó kùnà.” Wo ohun tí ọkùnrin tó ní ìgbẹ́kẹ̀lé kíkún nínú Ọlọ́run sọ! Kí nìdí tó fi sọ̀rọ̀ yìí? Nígbà tó ronú lórí àwọn ohun tó ti ṣẹlẹ̀ sẹ́yìn, ó rí i pé gbogbo ìgbà ni Jèhófà máa ń mu àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ. a Ohun tí Jóṣúà ní lọ́kàn ni pé: Ó ń fẹ́ káwọn tí wọ́n jọ jẹ́ ọmọ Ísírẹ́lì ní ìgbàgbọ́ tó dájú pé gbogbo ohun tí Jèhófà ṣèlérí nípa ọjọ́ ọ̀la wọn ló máa ṣẹ.

Ìwé kan tó ń ṣàlàyé Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa Jóṣúà 23:14 pé: “Ronú lórí gbogbo ìlérí tó wà nínú Bíbélì, gbé gbogbo àwọn ìwé ìtàn tó wà láyé yẹ̀ wò, kó o sì wádìí lọ́wọ́ gbogbo ẹ̀dá tó wà láyé, láti mọ̀ bóyá àkókò èyíkéyìí wà tí Ọlọ́run kò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ tàbí tó gbàgbé rẹ̀.” Tá a bá ṣe irú ìwádìí yìí, a máa rí i pé bí Jóṣúà ṣe sọ gan-an lọ̀rọ̀ rí, àwọn ìlérí Jèhófà kì í ṣaláì ṣẹ.—1 Àwọn Ọba 8:56; Aísáyà 55:10, 11.

Ọ̀pọ̀ ìlérí Ọlọ́run tó ti nímùúṣẹ ló wà nínú Bíbélì, tó fi mọ́ àwọn kan tó ń nímùúṣẹ lójú wa. Àwọn ìlérí àgbàyanu tí Jèhófà ṣe fún ọjọ́ ọ̀la wa tún wà nínú rẹ̀. b O ò ṣe ṣàyẹ̀wò àwọn àkọsílẹ̀ wọ̀nyẹn fúnra rẹ? Ẹ̀kọ́ Bíbélì lè jẹ́ kó dá ẹ lójú pé Ẹni tó ń mú ìlérí ṣẹ yìí ló yẹ kó o gbẹ́kẹ̀ lé.

[Àwọn Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Díẹ̀ lára àwọn ìlérí tí Jóṣúà rí ìmúṣẹ rẹ̀ rèé: Jèhófà máa fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ní ilẹ̀ wọn. (Fi Jẹ́nẹ́sísì 12:7Jóṣúà 11:23.) Jèhófà máa dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì. (Fi Ẹ́kísódù 3:8Ẹ́kísódù 12:29-32.) Jèhófà máa bójú tó àwọn èèyàn rẹ̀.—Fi Ẹ́kísódù 16:4, 13-15Diutarónómì 8:3, 4.

b Tó o bá fẹ́ ìsọfúnni síwájú sí i nípa ìlérí Ọlọ́run fún ọjọ́ ọ̀la wa, ka orí 3, 7 àti 8 nínú ìwé Kí Ni Bíbélì Fi Kọ́ni Gan-an? Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà la ṣe é.