Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà

Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà

Abala Àwọn Ọ̀dọ́

Ọkùnrin Onírẹ̀lẹ̀ àti Onígboyà

JÓNÀ—APÁ KÌÍNÍ

Ohun tó o máa ṣe: Ibi tí kò sáriwo ni kó o ti ṣe ìdánrawò yìí. Bó o bá ṣe ń ka àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó wà nísàlẹ̀ yìí, máa fojú inú wò ó bíi pé o wà níbi tọ́rọ̀ náà ti ń ṣẹlẹ̀, jẹ́ kó dà bíi pé ò ń gbọ́ bí àwọn èèyàn náà ṣe ń sọ̀rọ̀. Ronú nípa bí ohun tó ò ń kà yẹn ṣe máa rí lára àwọn èèyàn wọ̀nyẹn. Kó o sì máa fojú inú wò ó bí ohun tó ń ṣẹlẹ̀ lọ́wọ́lọ́wọ́.

1 KA ÌTÀN NÁÀ DÁADÁA.—KA JÓNÀ 1:1-17; 2:10–3:5.

Báwo ni ìró ìjì náà ṣe rí tó o bá fojú inú wò ó?

․․․․․

Báwo lo ṣe rò pé ó rí lára Jónà àtàwọn tó wà nínú ọkọ̀ náà bí wọ́n ṣe ń sọ̀rọ̀ nígbà tí ìjì yẹn ń jà?

․․․․․

Ṣàlàyé ohun tí Jónà lè máa rò lọ́kàn nígbà tó ń rì sínú òkun àti lẹ́yìn tí ẹja ńlá yẹn ti gbé e mì. (Ka Jónà 2:1-9.)

․․․․․

2 ṢÈWÁDÌÍ KÓ O SÌ RONÚ JINLẸ̀.

Irú àwọn èèyàn wo ló ń gbé nílùú Nínéfè, kí ló sì mú kí Jónà kọ́kọ́ lọ́ tìkọ̀ láti lọ wàásù fún wọn? (Náhúmù 3:1)

․․․․․

Ọ̀nà wo lo rò pé ìlú Nínéfè gbà jẹ́ “ìlú ńlá tí ó tóbi lójú Ọlọ́run”? (Jónà 3:3; 2 Pétérù 3:9)

․․․․․

Kí ni òtítọ́ tí Jónà sọ nípa àṣìṣe tó ṣe àti nípa Ọlọ́run rẹ̀ fi hàn nípa irú ẹni tí Jónà jẹ́? (Tún Jónà 1:9, 10 kà.)

․․․․․

Báwo ni Jónà ṣe mọ ohun tó ṣẹlẹ̀ nínú ọkọ̀ náà lẹ́yìn tí wọ́n ti jù ú sínú òkun? (Tún Jónà 1:15,16 kà.)

․․․․․

3 MÁA FOHUN TÓ O KỌ́ ṢÈWÀ HÙ. ṢÀKỌSÍLẸ̀ Ẹ̀KỌ́ TÓ O KỌ́ NÍPA . . .

Ìbẹ̀rù Èèyàn.

․․․․․

Ìrẹ̀lẹ̀.

․․․․․

Ìgboyà.

․․․․․

Ojú tí Jèhófà fi ń wo àwọn èèyàn, títí kan àwọn èèyàn tá a kà sí ẹni burúkú.

․․․․․

4 KÍ LÓ WÚ Ẹ LÓRÍ JÙ LỌ NÍNÚ ÌTÀN YÌÍ, KÍ SÌ NÌDÍ?

․․․․․

Tó o bá fẹ́ ṣèwádìí síwájú sí i, ka Ilé Ìṣọ́, January 1, 2009, ojú ìwé 25 sí 28.

BÍ O KÒ BÁ NÍ BÍBÉLÌ, LỌ KÀ Á LÓRÍ ÌKÀNNÌ WA, www.watchtower.org